Ìbéèrè Ṣókí Tó Lè Mú Káwọn Èèyàn Kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì
Ọ̀pọ̀ ọmọ orílẹ̀-èdè Philippines máa ń lọ ṣiṣẹ́ lórílẹ̀-èdè tí Arábìnrin Mary àti John a ọkọ ẹ̀ ń gbé, tọkọtaya yìí sì máa ń wàásù fún wọn. Lásìkò àjàkálẹ̀ àrùn kòrónà, Mary bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lórílẹ̀-èdè tó ń gbé àti láwọn orílẹ̀-èdè míì. Báwo ló ṣe ṣe é?
Mary máa ń bi àwọn tó ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pé, “Ṣé ẹ mọ ẹni tó fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì?” Tí wọ́n bá sọ pé bẹ́ẹ̀ ni, á tún bi wọ́n pé, “Ṣé ẹ lè jẹ́ kí n mọ̀ wọ́n?” Irú ìbéèrè ṣókí báyìí lè jẹ́ káwọn èèyàn wá kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́. Kí nìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀? Ìdí ni pé bí wọ́n ṣe ń mọ ẹ̀kọ́ òtítọ́ inú Bíbélì, ó máa ń wù wọ́n kí wọ́n sọ ọ́ fáwọn mọ̀lẹ́bí àtàwọn ọ̀rẹ́ wọn torí pé wọ́n nífẹ̀ẹ́ wọn. Nígbà tí Mary bi àwọn tó ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ní ìbéèrè yẹn, kí ni wọ́n ṣe?
Mary ń kọ́ ẹnì kan lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, orúkọ ẹ̀ ni Jasmin. Ó sọ fún Mary pé àwọn ọ̀rẹ́ òun mẹ́rin kan máa fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ọ̀kan nínú wọn tó ń jẹ́ Kristine nífẹ̀ẹ́ ohun tó ń kọ́ débi pé ó sọ fún Mary pé kó máa kọ́ òun lẹ́kọ̀ọ́ lẹ́ẹ̀mejì lọ́sẹ̀. Mary tún bi òun náà pé ṣé ó mọ ẹni tó fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì? Kristine sọ pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, àwọn ọ̀rẹ́ mi máa fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́.” Ọ̀sẹ̀ díẹ̀ lẹ́yìn náà, Mary bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ àwọn ọ̀rẹ́ Kristine mẹ́rin lẹ́kọ̀ọ́. Nígbà tó yá, Kristine tún sọ fún Mary pé àwọn ọ̀rẹ́ òun kan sọ pé àwọn fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́. Àwọn kan lára wọn tún sọ fún Mary pé àwọn ní àwọn ọ̀rẹ́ kan tó máa fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́.
Ó wu Kristine pé káwọn mọ̀lẹ́bí ẹ̀ tó wà ní Philippines náà kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Torí náà, ó bá ọmọbìnrin ẹ̀ tó ń jẹ́ Andrea sọ̀rọ̀. Ohun tí Andrea rò tẹ́lẹ̀ ni pé, ẹlẹ́gbẹ́ òkùnkùn làwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà, a ò gba Jésù gbọ́ àti pé Bíbélì Májẹ̀mú Láéláé nìkan la máa ń lò. Àmọ́ lẹ́yìn ìkẹ́kọ̀ọ́ àkọ́kọ́ tó ṣe, ó rí i pé èrò tóun ní ò tọ́. Tó bá ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́, ó máa ń sọ pé, “Tó bá ṣáà ti jẹ́ pé ohun tí Bíbélì sọ nìyẹn, mo gbà pé òótọ́ ni!”
Nígbà tó yá, Andrea tún sọ fún Mary pé àwọn ọ̀rẹ́ òun méjì àtẹnì kan táwọn jọ ń ṣiṣẹ́ fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, Mary sì bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́. Bákan náà, Mary ò mọ̀ pé àbúrò bàbá Andrea tó ń jẹ́ Angela tí ò ríran máa ń gbọ́ ohun táwọn ń sọ nígbà ìkẹ́kọ̀ọ́. Lọ́jọ́ kan, Angela sọ pé kí Andrea bá òun sọ fún Mary pé kó máa kọ́ òun náà lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ni Mary bá bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ Angela lẹ́kọ̀ọ́, ó sì fẹ́ràn ohun tó ń kọ́. Láàárín oṣù kan péré, ó ti mọ ọ̀pọ̀ ẹsẹ Bíbélì sórí, ó sì fẹ́ kí Mary máa kọ́ òun lẹ́kọ̀ọ́ lẹ́ẹ̀mẹrin lọ́sẹ̀! Kò pẹ́ sígbà yẹn, Andrea ràn án lọ́wọ́ kó lè máa dara pọ̀ mọ́ ìpàdé déédéé lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì.
Nígbà tí Mary mọ̀ pé Joshua ọkọ Kristine máa ń gbọ́ ohun tí wọ́n ń sọ nígbà ìkẹ́kọ̀ọ́, ó bi í pé, ṣé ẹ̀yin náà máa fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì? Ni Joshua bá sọ pé, “Màá máa gbọ́ ohun tẹ́ ẹ̀ ń sọ, àmọ́ má bi mí ní ìbéèrè kankan o, tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, màá jáde.” Láàárín ìṣẹ́jú márùn-ún péré tó dara pọ̀ mọ́ wọn, ìbéèrè tí Joshua béèrè ju ti Kristine lọ, ó sì fẹ́ kí wọ́n máa kọ́ òun náà lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.
Ìbéèrè ṣókí tí Mary béèrè yìí ló jẹ́ kó lè máa kọ́ ọ̀pọ̀ èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Torí pé àwọn tí Mary ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ pọ̀, ó ní kí àwọn ará máa kọ́ ọ̀pọ̀ lára wọn lẹ́kọ̀ọ́. Gbogbo àwọn tí Mary bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wọn jẹ́ méjìdínlọ́gbọ̀n (28) ní orílẹ̀-èdè mẹ́rin.
Jasmin lẹni àkọ́kọ́ tá a sọ níbẹ̀rẹ̀ tí Mary ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ó sì ṣèrìbọmi ní April 2021. Kristine ṣèrìbọmi ní May 2022, ó sì ti pa dà sọ́dọ̀ àwọn èèyàn ẹ̀ lórílẹ̀-èdè Philippines. Méjì lára àwọn tí Kristine sọ pé kí Mary máa kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ náà ti ṣèrìbọmi. Oṣù díẹ̀ lẹ́yìn tí Kristine ṣèrìbọmi ni Angela náà ṣèrìbọmi, ó sì ti di aṣáájú-ọ̀nà déédéé báyìí. Joshua ọkọ Kristine, ọmọ wọn obìnrin tó ń jẹ́ Andrea àtàwọn míì tó ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ń tẹ̀ síwájú, wọ́n sì ń fi ohun tí wọ́n ń kọ́ sílò.
Nígbà ayé Jésù àtàwọn àpọ́sítélì, ọ̀pọ̀ lára wọn ló sọ ohun tí wọ́n gbọ́ nípa Jésù fún mọ̀lẹ́bí àtàwọn ọ̀rẹ́ wọn. (Jòh. 1:41, 42a; Ìṣe 10:24, 27, 48; 16:25-33) Torí náà, tó o bá ń kọ́ ẹnì kan lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, o lè bi í pé, “Ṣé o mọ ẹni tó fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì?” Tó o bá bi í ní ìbéèrè ṣókí yìí, a ò lè sọ, ìwọ náà lè bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ ọ̀pọ̀ èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.
a A ti yí àwọn orúkọ kan pa dà.