Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Má Fìwà Jọ Àwọn Tó Mọ Tara Wọn Nìkan

Má Fìwà Jọ Àwọn Tó Mọ Tara Wọn Nìkan

ṢÉ O ti kíyè sí i pé lásìkò wa yìí, ọ̀pọ̀ èèyàn máa ń rò pé àwọn sàn ju àwọn míì lọ? Torí náà, wọ́n máa ń fẹ́ kí wọ́n fún wọn nípò pàtàkì láwùjọ tàbí kí wọ́n máa rò pé ohun kan tọ́ sáwọn. Kò sí bí wọ́n ṣe gbayì tó, wọ́n ṣì máa ń fẹ́ kí wọ́n gbé àwọn ga jù bẹ́ẹ̀ lọ. Ohun tó jẹ́ káwọn èèyàn máa nírú èrò yìí ni pé wọ́n mọ tara wọn nìkan, wọ́n sì jẹ́ aláìmoore. Bíbélì sì jẹ́ ká mọ̀ pé àwọn èèyàn máa nírú ìwà yẹn láwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí.—2 Tím. 3:2.

Ká sòótọ́, ọjọ́ pẹ́ táwọn èèyàn ti ń mọ tara wọn nìkan. Bí àpẹẹrẹ, Ádámù àti Éfà fẹ́ máa pinnu ohun tó tọ́ àtohun tí kò tọ́, ìpinnu tí wọ́n ṣe sì kóyà jẹ wá. Ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn ìgbà yẹn, Ùsáyà ọba Júdà rò pé òun lẹ́tọ̀ọ́ láti sun tùràrí nínú tẹ́ńpìlì, àmọ́ àṣìṣe gbáà ló ṣe. (2 Kíró. 26:18, 19) Bákan náà, àwọn Farisí àtàwọn Sadusí rò pé ó yẹ kí Ọlọ́run ṣojúure àrà ọ̀tọ̀ sáwọn torí pé àwọn jẹ́ àtọmọdọ́mọ Ábúráhámù.—Mát. 3:9.

Bákan náà lónìí, àwọn èèyàn tó mọ tara wọn nìkan, tí wọ́n sì jẹ́ agbéraga ló yí wa ká, ìwà wọn sì lè kó bá wa. (Gál. 5:26) Àwa náà lè máa rò pé ó yẹ kí wọ́n fún wa láǹfààní kan tàbí kí wọ́n máa pọ́n wa lé ju àwọn míì lọ. Kí ni ò ní jẹ́ ká nírú èrò yìí? Ohun tó máa ràn wá lọ́wọ́ ni pé ká mọ èrò Jèhófà lórí ọ̀rọ̀ yìí. Ẹ jẹ́ ká gbé ìlànà Bíbélì méjì yẹ̀ wò.

Jèhófà ló máa sọ bóyá ohun kan tọ́ sí wa. Ẹ jẹ́ ká gbé àwọn àpẹẹrẹ kan yẹ̀ wò.

  • Nínú ìdílé, Jèhófà fẹ́ kí ìyàwó máa bọ̀wọ̀ fún ọkọ ẹ̀, kí ọkọ sì nífẹ̀ẹ́ ìyàwó ẹ̀. (Éfé. 5:33) Jèhófà retí pé ọkọ àti aya nìkan ló lè bá ara wọn lò pọ̀. (1 Kọ́r. 7:3) Jèhófà tún retí pé káwọn ọmọ máa gbọ́ràn sáwọn òbí wọn lẹ́nu, káwọn òbí náà sì nífẹ̀ẹ́ àwọn ọmọ wọn, kí wọ́n sì máa pèsè ohun tí wọ́n nílò fún wọn.—2 Kọ́r. 12:14; Éfé. 6:2.

  • Nínú ìjọ, Jèhófà sọ pé káwọn ará máa bọ̀wọ̀ fáwọn alàgbà tó ń ṣiṣẹ́ kára. (1 Tẹs. 5:12) Àmọ́ Jèhófà ò fẹ́ káwọn alàgbà jẹ ọ̀gá lórí àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin nínú ìjọ.—1 Pét. 5:2, 3.

  • Ọlọ́run tún gba àwọn ìjọba láyè kí wọ́n máa gba owó orí, ó sì fẹ́ ká máa bọ̀wọ̀ fún wọn.—Róòmù 13:1, 6, 7.

Torí pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa, ohun tó ń ṣe fún wa ju ohun tó yẹ wá lọ. A mọ̀ pé ẹlẹ́ṣẹ̀ ni wá, ikú ló sì tọ́ sí wa, àmọ́ Jèhófà rà wá pa dà. (Róòmù 6:23) Ọ̀pọ̀ nǹkan rere ni Jèhófà máa ń ṣe fún wa torí pé ó nífẹ̀ẹ́ wa. (Sm. 103:10, 11) Gbogbo ìgbà tá a bá rọ́wọ́ Jèhófà láyé wa tàbí tó fún wa láǹfààní láti ṣe iṣẹ́ ìsìn kan nínú ìjọ, inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí ló fi hàn sí wa yẹn.—Róòmù 12:6-8; Éfé. 2:8.

OHUN TÍ Ò NÍ JẸ́ KÁ MỌ TARA WA NÌKAN TÀBÍ KÁ MÁA GBÉRA GA

Má fìwà jọ àwọn èèyàn ayé. Tá ò bá ṣọ́ra, a lè bẹ̀rẹ̀ sí í rò pé a sàn ju àwọn míì lọ. Jésù fi hàn pé ó lè ṣẹlẹ̀ sí wa nígbà tó sọ àpèjúwe àwọn tó ṣiṣẹ́ nínú ọgbà àjàrà kan, tí ọ̀gá wọn sì san owó dínárì kan fún ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn. Àwọn òṣìṣẹ́ kan bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ láàárọ̀ kùtù, wọ́n sì ṣiṣẹ́ jálẹ̀ ọjọ́ yẹn nínú oòrùn tó mú gan-an, àmọ́ iṣẹ́ wákàtí kan péré làwọn tó dé kẹ́yìn ṣe. Àwọn tó kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ rò pé ó yẹ kówó àwọn ju owó àwọn òṣìṣẹ́ tó dé kẹ́yìn lọ torí pé àtàárọ̀ làwọn ti ń ṣiṣẹ́. (Mát. 20:1-16) Ẹ̀kọ́ tí Jésù fi àpèjúwe yìí kọ́ àwa ọmọlẹ́yìn ẹ̀ ni pé ká jẹ́ kí àwọn nǹkan tí Ọlọ́run ń pèsè fún wa tẹ́ wa lọ́rùn.

Àwọn ọkùnrin tó ti ń ṣiṣẹ́ látàárọ̀ rò pé ó yẹ kí owó wọn ju tàwọn òṣìṣẹ́ tó dé kẹ́yìn lọ

Jẹ́ ẹni tó moore, kó o sì nítẹ̀ẹ́lọ́rùn. (1 Tẹs. 5:18) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ò retí pé káwọn ará ní Kọ́ríńtì pèsè ohun tóun nílò, bó tiẹ̀ jẹ́ pé ó lẹ́tọ̀ọ́ láti béèrè, torí náà ó yẹ ká fara wé e. (1 Kọ́r. 9:11-14) Ó yẹ ká mọyì ohunkóhun táwọn èèyàn bá fún wa, ká má sì fipá mú àwọn èèyàn pé kí wọ́n fún wa ní nǹkan.

Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kì í béèrè owó lọ́wọ́ àwọn ará

Jẹ́ onírẹ̀lẹ̀. Tẹ́nì kan bá ń ro ara ẹ̀ ju bó ṣe yẹ lọ, ó lè má nítẹ̀ẹ́lọ́rùn, kó sì máa rò pé àwọn nǹkan kan tọ́ sóhun. Ìrẹ̀lẹ̀ ni ò ní jẹ́ ká nírú èrò burúkú bẹ́ẹ̀.

Dáníẹ́lì nírẹ̀lẹ̀, ìyẹn ló mú kí Jèhófà sọ pé ó ṣeyebíye

Onírẹ̀lẹ̀ ni wòlíì Dáníẹ́lì, ó sì yẹ ká fara wé e. Ó ṣeé ṣe kí Dáníẹ́lì rò pé àwọn àǹfààní tóun ní tọ́ sóun torí pé ilé ọlá lòun ti wá, òun dùn ún wò lọ́mọkùnrin, ọpọlọ òun pé, òun sì lè ṣe onírúurú iṣẹ́. (Dán. 1:3, 4, 19, 20) Àmọ́ Dáníẹ́lì nírẹ̀lẹ̀, ìyẹn ló mú kí Jèhófà sọ pé ó ṣeyebíye gan-an.—Dán. 2:30; 10:11, 12.

Torí náà, ẹ jẹ́ ká sá fún ìmọtara-ẹni-nìkan àti ìgbéraga tó kúnnú ayé lónìí. Àmọ́, ẹ jẹ́ ká máa mọyì àwọn nǹkan rere tí Jèhófà ń ṣe fún wa torí pé inú rere tá ò lẹ́tọ̀ọ́ sí ni.