Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

OHUN TÓ O LÈ KẸ́KỌ̀Ọ́ NÍPA Ẹ̀

Máa Fìgboyà Ṣe Ohun Tó Tọ́

Máa Fìgboyà Ṣe Ohun Tó Tọ́

Ka Jeremáyà 38:1-13 kó o lè kẹ́kọ̀ọ́ ìgboyà lára wòlíì Jeremáyà àti ìwẹ̀fà kan tó ń jẹ́ Ebedi-mélékì.

Bi ara ẹ láwọn ìbéèrè kan nípa ohun tó ò ń kà. Báwo ni Jeremáyà ṣe fìgboyà sọ̀rọ̀ Jèhófà? (Jer. 27:12-14; 28:15-17; 37:6-10) Kí làwọn èèyàn ṣe nígbà tí wọ́n gbọ́ ọ̀rọ̀ ẹ̀?—Jer. 37:15, 16.

Kẹ́kọ̀ọ́ jinlẹ̀. Kí làwọn èèyàn fẹ́ kí Jeremáyà ṣe? (jr 26-27 ¶20-22) Ṣèwádìí nípa àwọn kòtò omi tó wà láyé àtijọ́. (it-1 471, lédè Gẹ̀ẹ́sì) Báwo ló ṣe rí lára Jeremáyà nígbà tó wà nínú kòtò omi ẹlẹ́rẹ̀? Kí ló ń ba Ebedi-mélékì lẹ́rù?—w12 5/1 31 ¶2-3.

Wá àwọn ẹ̀kọ́ inú ẹ̀. Bi ara ẹ pé:

  • ‘Kí ni ìtàn yìí kọ́ mi nípa bí Jèhófà ṣe ń dáàbò bo àwọn ìránṣẹ́ ẹ̀ olóòótọ́?’ (Sm. 97:10; Jer. 39:15-18)

  • ‘Àwọn nǹkan wo ló lè ṣẹlẹ̀ tó máa gba pé kí n nígboyà?’

  • ‘Báwo ni mo ṣe lè máa fìgboyà ṣe ohun tó tọ́ báwọn èèyàn ò tiẹ̀ fẹ́ kí n ṣe bẹ́ẹ̀?’(w11 3/1 30) a

a Kó o lè mọ ohun tó o lè kẹ́kọ̀ọ́ nípa ẹ̀, wo “Ohun Tó O Lè Fi Kẹ́kọ̀ọ́” nínú Ilé Ìṣọ́ July 2023.