ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 1
Jẹ́ Kó Túbọ̀ Dá Ẹ Lójú Pé Òtítọ́ Ni Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
ẸSẸ ÌWÉ MÍMỌ́ TI ỌDÚN 2023: “Òtítọ́ ni kókó inú ọ̀rọ̀ rẹ.”—SM. 119:160.
ORIN 96 Ìṣúra Ni Ìwé Ọlọ́run
OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒ a
1. Kí nìdí tí ọ̀pọ̀ èèyàn lónìí ò fi gbà pé òtítọ́ lohun tó wà nínú Bíbélì?
Ọ̀PỌ̀ èèyàn lónìí ni kì í fọkàn tán àwọn èèyàn. Ìdí sì ni pé wọn ò mọ ẹni tí wọ́n lè fọkàn tán. Kò dá wọn lójú pé àwọn olóṣèlú, àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì àtàwọn oníṣòwò ń gba tiwọn rò. Yàtọ̀ síyẹn, wọn kì í bọ̀wọ̀ fáwọn olórí ẹ̀sìn tó pe ara wọn ní Kristẹni. Torí náà, kò yà wá lẹ́nu pé wọn ò fọkàn tán Bíbélì táwọn olórí ẹ̀sìn yẹn sọ pé àwọn ń tẹ̀ lé.
2. Kí ni Sáàmù 119:160 sọ pé ó yẹ kó dá wa lójú?
2 Àwa ìránṣẹ́ Jèhófà gbà pé òun ni “Ọlọ́run òtítọ́” àti pé ohun tó dáa jù ló fẹ́ fún wa. (Sm. 31:5; Àìsá. 48:17) A fọkàn tán ohun tá a kà nínú Bíbélì pé “òtítọ́ ni kókó inú ọ̀rọ̀ [Ọlọ́run].” b (Ka Sáàmù 119:160.) A gbà pé òótọ́ lohun tí ọ̀mọ̀wé kan tó ń ṣàlàyé Bíbélì sọ pé: “Kò sí irọ́ kankan nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, gbogbo nǹkan tó bá sì sọ ló máa ń ṣẹ. Àwọn èèyàn Ọlọ́run máa ń gba ohun tó sọ gbọ́ torí pé wọ́n fọkàn tán Ọlọ́run.”
3. Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí?
3 Báwo la ṣe lè ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ káwọn náà lè gbà pé òótọ́ ni Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run? Ẹ jẹ́ ká jíròrò nǹkan mẹ́ta tó mú ká fọkàn tán Bíbélì. A máa sọ̀rọ̀ nípa bí Bíbélì ṣe péye, bí àwọn àsọtẹ́lẹ̀ inú ẹ̀ ṣe ń ṣẹ àti bó ṣe ń yí ìgbésí ayé àwọn èèyàn pa dà.
Ọ̀RỌ̀ INÚ BÍBÉLÌ Ò YÍ PA DÀ
4. Kí nìdí táwọn kan fi ronú pé ọ̀rọ̀ inú Bíbélì ti yí pa dà?
4 Nǹkan bí ogójì (40) ọkùnrin olóòótọ́ ni Jèhófà lò láti kọ Bíbélì. Àmọ́ kò sí ìkankan nínú àwọn ìwé tí wọ́n fọwọ́ kọ fúnra wọn tó ṣì wà títí di báyìí. Àwọn ìwé tí wọ́n dà kọ la ní lọ́wọ́ báyìí. Ìyẹn ló jẹ́ káwọn kan máa ronú pé Bíbélì tó wà lọ́wọ́ wa lónìí ti yí pa dà, ó sì yàtọ̀ sí èyí tí wọ́n kọ́kọ́ kọ. Ṣé o ti bi ara ẹ rí pé, ṣé ohun tó wà nínú Bíbélì ti yí pa dà lóòótọ́?
5. Báwo ni wọ́n ṣe da Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù kọ? (Wo àwòrán iwájú ìwé.)
5 Kí ọ̀rọ̀ inú Bíbélì má bàa pa run, Jèhófà ní kí wọ́n dà wọ́n kọ. Ó pàṣẹ fáwọn ọba Ísírẹ́lì pé kí wọ́n da Òfin Ọlọ́run kọ fúnra wọn, ó sì ní káwọn ọmọ Léfì máa kọ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní Òfin náà. (Diu. 17:18; 31:24-26; Neh. 8:7) Lẹ́yìn táwọn Júù dé láti ìgbèkùn Bábílónì, àwùjọ àwọn adàwékọ tó mọṣẹ́ bẹ̀rẹ̀ sí í da Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù kọ. (Ẹ́sírà 7:6, àlàyé ìsàlẹ̀) Àwọn ọkùnrin yìí fara balẹ̀ da ìwé náà kọ. Nígbà tó yá, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í ka iye ọ̀rọ̀ tó wà nínú ìwé tí wọ́n dà kọ, wọ́n sì tún ka lẹ́tà kọ̀ọ̀kan tó wà nínú ọ̀rọ̀ kí wọ́n lè rí i pé ó pé pérépéré. Àmọ́ torí pé aláìpé làwọn adàwékọ yìí, wọ́n ṣe àwọn àṣìṣe kan nígbà tí wọ́n ń dà á kọ. Torí pé ẹ̀dà ìwé Bíbélì kọ̀ọ̀kan tí wọ́n kọ pọ̀, ó rọrùn láti rí àwọn àṣìṣe tí wọ́n ṣe. Ọgbọ́n wo ni wọ́n dá sí i?
6. Báwo ni wọ́n ṣe rí àwọn àṣìṣe tó wà nínú àwọn ẹ̀dà Bíbélì tí wọ́n kọ?
6 Àwọn ọ̀mọ̀wé òde òní mọ ọ̀nà tó dáa jù láti rí àwọn àṣìṣe táwọn adàwékọ yẹn ṣe. Bí àpẹẹrẹ, ká sọ pé wọ́n ní kí ọgọ́rùn-ún (100) ọkùnrin da ọ̀rọ̀ tó wà lójú ìwé kan kọ, àmọ́ ọ̀kan lára wọn ṣe àṣìṣe nínú ẹ̀dà tiẹ̀. Ọ̀nà kan tá a lè gbà rí àṣìṣe tó ṣe ni pé ká fi ẹ̀dà ìwé tiẹ̀ wé tàwọn yòókù. Lọ́nà kan náà, nígbà táwọn ọ̀mọ̀wé fi àwọn ìwé Bíbélì tí wọ́n dà kọ wé ara wọn, wọ́n rí àwọn àṣìṣe àtàwọn ọ̀rọ̀ tójú wọn fò.
7. Kí ló fi hàn pé àwọn tó da Bíbélì kọ ṣe iṣẹ́ tó péye?
7 Iṣẹ́ ńlá làwọn tó da Bíbélì kọ ṣe kí wọ́n lè rí i pé kò sí àṣìṣe kankan nínú ẹ̀. Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ kan tó fi hàn pé bó ṣe rí nìyẹn. Odindi Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù tí wọ́n dà kọ tó tíì pẹ́ jù ni èyí tí wọ́n ṣe lọ́dún 1008 tàbí lọ́dún 1009 S.K. Òun ni wọ́n ń pè ní Leningrad Codex. Àmọ́ lẹ́nu àìpẹ́ yìí, wọ́n tún ti rí àwọn ìwé Bíbélì àtàwọn àjákù kéékèèké míì tó ti wà ní nǹkan bí ẹgbẹ̀rún ọdún (1,000) ṣáájú kí Leningrad Codex tó wà. Ẹnì kan lè wá máa ronú pé lẹ́yìn tí wọ́n ti da àwọn ìwé Bíbélì náà kọ léraléra ní ohun tó ju ẹgbẹ̀rún ọdún kan lọ, ohun tó wà nínú Leningrad Codex yẹn máa yàtọ̀ gan-an sóhun tó wà nínú àwọn ìwé Bíbélì tó wà ṣáájú ẹ̀. Àmọ́ ọ̀rọ̀ ò rí bẹ́ẹ̀ rárá. Àwọn ọ̀mọ̀wé tó fi àwọn ìwé tí wọ́n dà kọ tipẹ́tipẹ́ wé àwọn tí wọ́n dà kọ lẹ́yìn ìgbà yẹn rí i pé bó tiẹ̀ jẹ́ pé ìyàtọ̀ díẹ̀díẹ̀ wà nínú ẹ̀, àwọn ọ̀rọ̀ inú Bíbélì ò yí pa dà.
8. Ìyàtọ̀ wo ló wà láàárín Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì àtàwọn ìwé àtijọ́ míì?
8 Àwọn Kristẹni àkọ́bẹ̀rẹ̀ náà da Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì kọ bíi tàwọn tó da Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù kọ. Wọ́n fara balẹ̀ ṣe ẹ̀dà ìwé mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n (27) tó wà nínú Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì, wọ́n ń lo àwọn ìwé náà nípàdé, wọ́n sì fi ń wàásù. Nígbà tí wọ́n fi àwọn ẹ̀dà Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì tó ṣì wà lónìí wé àwọn ìwé tí kì í ṣe ìwé Bíbélì tí wọ́n kọ lásìkò yẹn, ọ̀mọ̀wé kan sọ pé: ‘Ohun tá a rí ni pé àwọn ẹ̀dà Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì pọ̀ ju àwọn ìwé míì lọ, ọ̀rọ̀ inú ẹ̀ sì péye.’ Ìwé náà Anatomy of the New Testament sọ pé: “Tẹ́nì kan bá ń ka Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì tí wọ́n tú lọ́nà tá à ń gbà sọ̀rọ̀ lónìí, ó yẹ kí ọkàn ẹ̀ balẹ̀ pé gbogbo nǹkan tí wọ́n kọ níbẹ̀rẹ̀ ò yí pa dà, gbogbo ẹ̀ ló pé síbẹ̀.”
9. Kí ni Àìsáyà 40:8 sọ nípa ọ̀rọ̀ inú Bíbélì?
9 Iṣẹ́ takuntakun tí ọ̀pọ̀ adàwékọ ṣe lọ́pọ̀ ọdún sẹ́yìn ló jẹ́ ká ní Bíbélì tó péye tá à ń kà, tá a sì ń kẹ́kọ̀ọ́ lónìí. c Ó dájú pé Jèhófà ni ò jẹ́ kí Bíbélì pa run, tí ò sì jẹ́ kí ọ̀rọ̀ inú ẹ̀ yí pa dà. (Ka Àìsáyà 40:8.) Àwọn kan máa ń sọ pé bí Bíbélì ò ṣe pa run títí di báyìí ò fi hàn pé Ọlọ́run ló fẹ̀mí ẹ̀ darí àwọn tó kọ ọ́. Torí náà, ẹ jẹ́ ká wá wo àwọn ẹ̀rí kan tó jẹ́ ká mọ̀ pé Ọlọ́run ló fẹ̀mí ẹ̀ darí àwọn tó kọ Bíbélì.
ÀWỌN ÀSỌTẸ́LẸ̀ BÍBÉLÌ ṢEÉ GBÁRA LÉ
10. Sọ àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì kan tó ṣẹ tó jẹ́ ká mọ̀ pé òótọ́ lohun tó wà nínú 2 Pétérù 1:21. (Wo àwọn àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)
10 Ọ̀pọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ tó ti ṣẹ ló wà nínú Bíbélì, kódà ọ̀pọ̀ ọdún káwọn àsọtẹ́lẹ̀ kan tó ṣẹ ni wọ́n ti kọ wọ́n sílẹ̀. Ìtàn sì fi hàn pé àwọn àsọtẹ́lẹ̀ náà ṣẹ. Èyí ò yà wá lẹ́nu torí a mọ̀ pé Jèhófà ló sọ àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tó wà nínú Bíbélì. (Ka 2 Pétérù 1:21.) Ẹ jẹ́ ká wo àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tí Bíbélì sọ nípa bí wọ́n ṣe máa ṣẹ́gun ìlú Bábílónì àtijọ́. Ní nǹkan bí ọdún 778 sí 732 Ṣ.S.K., Jèhófà mí sí wòlíì Àìsáyà láti sọ tẹ́lẹ̀ pé wọ́n máa ṣẹ́gun ìlú Bábílónì. Kódà, ó sọ pé Kírúsì ló máa ṣẹ́gun ìlú náà, ó sì sọ bí wọ́n ṣe máa ṣẹ́gun ẹ̀. (Àìsá. 44:27–45:2) Àìsáyà tún sọ tẹ́lẹ̀ pé wọ́n máa pa ìlú náà run pátápátá, kò sì sẹ́ni táá máa gbébẹ̀ mọ́ láé. (Àìsá. 13:19, 20) Ohun tó ṣẹlẹ̀ gẹ́lẹ́ nìyẹn. Níkẹyìn, àwọn ará Mídíà àti Páṣíà ṣẹ́gun ìlú Bábílónì lọ́dún 539 Ṣ.S.K., ìlú alágbára yìí sì ti pa run pátápátá báyìí.—Wo fídíò náà, Bíbélì Sọ Àsọtẹ́lẹ̀ Nípa Bí Wọ́n Ṣe Máa Ṣẹ́gun Bábílónì nínú ìwé Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!, ẹ̀kọ́ 03 kókó 5.
11. Ṣàlàyé bí Dáníẹ́lì 2:41-43 ṣe ń ṣẹ lónìí.
11 Kì í ṣe ìgbà àtijọ́ nìkan làwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì ṣẹ, à ń rí bí àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì míì ṣe ń ṣẹ lásìkò tiwa yìí náà. Bí àpẹẹrẹ, ẹ jẹ́ ká wo bí àsọtẹ́lẹ̀ tí Dáníẹ́lì sọ nípa ìjọba Gẹ̀ẹ́sì àti Amẹ́ríkà tó ń ṣàkóso ayé ṣe ṣẹ. (Ka Dáníẹ́lì 2:41-43.) Àsọtẹ́lẹ̀ yẹn sọ pé ìjọba alágbára méjì tó ń ṣàkóso ayé yìí máa “lágbára lápá kan,” á dà bí irin, “kò sì ní lágbára lápá kan,” á dà bí amọ̀. Bó sì ṣe rí gan-an nìyẹn. Ìjọba Gẹ̀ẹ́sì àti Amẹ́ríkà ti fi hàn pé àwọn lágbára bí irin torí wọ́n kó ipa pàtàkì nínú bí wọ́n ṣe ṣẹ́gun Ogun Àgbáyé méjèèjì, wọ́n sì láwọn ohun ìjà ogun tó lágbára gan-an. Síbẹ̀, àwọn ará ìlú wọn ò jẹ́ kí wọ́n lè lo agbára wọn bí wọ́n ṣe fẹ́. Wọ́n máa ń jà fún ara wọn nípasẹ̀ ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́, àwọn tó ń jà fún ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn àtàwọn tó ń jà fún òmìnira àwọn aráàlú. Ọ̀jọ̀gbọ́n kan tó mọ̀ nípa ọ̀rọ̀ òṣèlú lágbàáyé sọ lẹ́nu àìpẹ́ yìí pé: “Kò sí òṣèlú ọlọ́làjú táwọn èèyàn ti pín yẹ́lẹyẹ̀lẹ, tí ọ̀rọ̀ òṣèlú wọn sì dojú rú bíi ti orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà.” Ìjọba Gẹ̀ẹ́sì tó jẹ́ apá kejì ìjọba alágbára yìí náà ti pín yẹ́lẹyẹ̀lẹ torí lẹ́nu àìpẹ́ yìí, Àwùjọ Àwọn Orílẹ̀-Èdè Ilẹ̀ Yúróòpù ń bá ara wọn jà, ìjọba ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì sì sọ pé òun ò fẹ́ bá wọn da nǹkan pọ̀ mọ́. Bí wọ́n ṣe pín yẹ́lẹyẹ̀lẹ yìí ni ò jẹ́ kí ìjọba Gẹ̀ẹ́sì àti Amẹ́ríkà lágbára láti pàṣẹ bó ṣe wù wọ́n.
12. Kí làwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì jẹ́ kó túbọ̀ dá wa lójú?
12 Ọ̀pọ̀ àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tó ti ṣẹ nínú Bíbélì ti jẹ́ kó túbọ̀ dá wa lójú pé àwọn ohun tí Jèhófà sọ pé òun máa ṣe lọ́jọ́ iwájú máa ṣẹ. Ó ń ṣe wá bíi ti onísáàmù tó gbàdúrà sí Jèhófà pé: “Ọkàn mi ń fà sí ìgbàlà rẹ, nítorí ọ̀rọ̀ rẹ ni ìrètí mi.” (Sm. 119:81) Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé Jèhófà ti fún wa ní “ọjọ́ ọ̀la kan àti ìrètí kan.” (Jer. 29:11) Jèhófà ló máa ṣe àwọn nǹkan tá à ń retí lọ́jọ́ iwájú, kì í ṣe àwọn èèyàn. Torí náà, ẹ jẹ́ ká máa kẹ́kọ̀ọ́ nípa àwọn àsọtẹ́lẹ̀ inú Bíbélì, ìyẹn lá jẹ́ ká túbọ̀ máa gbára lé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.
ÌMỌ̀RÀN BÍBÉLÌ MÁA Ń RAN Ọ̀PỌ̀ ÈÈYÀN LỌ́WỌ́ LÓNÌÍ
13. Nǹkan míì wo ló wà nínú Sáàmù 119:66, 138 tó fi hàn pé Bíbélì ṣeé gbára lé?
13 Nǹkan míì tó jẹ́ ká gbára lé Bíbélì ni pé ó máa ń yí ìgbésí ayé àwọn èèyàn pa dà tí wọ́n bá ń fi ìmọ̀ràn inú ẹ̀ sílò. (Ka Sáàmù 119:66, 138.) Bí àpẹẹrẹ, àwọn tọkọtaya kan tí wọ́n fẹ́ kọ ara wọn sílẹ̀ ti ń fayọ̀ gbé pa pọ̀ báyìí. Inú àwọn ọmọ wọn ń dùn torí àwọn òbí wọn ń fìfẹ́ bójú tó wọn, wọ́n sì ń kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.—Éfé. 5:22-29.
14. Sọ àpẹẹrẹ kan tó fi hàn pé táwọn èèyàn bá fi ìmọ̀ràn Bíbélì sílò, ó máa ń yí ìgbésí ayé wọn pa dà.
14 Àwọn ọ̀daràn paraku ti yí pa dà nígbà tí wọ́n fi ìmọ̀ràn Bíbélì sílò. Ẹ jẹ́ ká wo bí Bíbélì ṣe yí ìgbésí ayé ẹlẹ́wọ̀n kan tó ń jẹ́ Jack pa dà. d Oníjàgídíjàgan ni, ó sì wà lára àwọn tó burú jù láàárín àwọn tí wọ́n dájọ́ ikú fún nínú ẹ̀wọ̀n. Àmọ́ lọ́jọ́ kan, Jack jókòó síbi tí wọ́n ti ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Inúure táwọn arákùnrin tó ń kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ fi hàn wọ̀ ọ́ lọ́kàn, lòun náà bá bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Bó ṣe ń fi àwọn nǹkan tó ń kọ́ sílò, ìwà ẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í yí pa dà, ó sì ń ṣe dáadáa. Nígbà tó yá, Jack di akéde tí kò tíì ṣèrìbọmi, lẹ́yìn náà, ó ṣèrìbọmi. Ó máa ń fìtara wàásù fáwọn ẹlẹ́wọ̀n yòókù, kódà ó kéré tán, mẹ́rin lára àwọn tó kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ ló ṣèrìbọmi. Nígbà tó fi máa di ọjọ́ tí wọ́n fẹ́ pa á, Jack ti yí pa dà pátápátá. Kódà, ọ̀kan lára àwọn agbẹjọ́rò ẹ̀ sọ pé: “Jack tẹ́ ẹ̀ ń wò yìí kì í ṣe Jack tí mo mọ̀ ní nǹkan bí ogún (20) ọdún sẹ́yìn. Ohun táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kọ́ ọ ti yí ìgbésí ayé ẹ̀ pa dà.” Bó tiẹ̀ jẹ́ pé wọ́n pa Jack, àpẹẹrẹ ẹ̀ jẹ́ ká mọ̀ pé a lè gbára lé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àti pé ó lágbára láti yí ìgbésí ayé àwọn èèyàn pa dà sí rere.—Àìsá. 11:6-9.
15. Báwo ni ìmọ̀ràn Bíbélì táwa èèyàn Jèhófà ń tẹ̀ lé ṣe mú ká yàtọ̀ sáwọn èèyàn inú ayé? (Wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)
15 Àwa èèyàn Jèhófà wà níṣọ̀kan torí pé à ń fi òtítọ́ Bíbélì ṣèwà hù. (Jòh. 13:35; 1 Kọ́r. 1:10) Àlàáfíà àti ìṣọ̀kan tó wà láàárín wa ṣàrà ọ̀tọ̀ torí pé a yàtọ̀ sáwọn tó wà nínú ayé tó jẹ́ pé ọ̀rọ̀ òṣèlú, ẹ̀yà wọn àti ipò tí wọ́n wà láwùjọ ti pín wọn yẹ́lẹyẹ̀lẹ. Ìṣọ̀kan tó wà láàárín àwa èèyàn Jèhófà yìí ya ọ̀dọ́kùnrin kan tó ń jẹ́ Jean lẹ́nu. Orílẹ̀-èdè kan nílẹ̀ Áfíríkà ló dàgbà sí. Nígbà tí ogun abẹ́lé ṣẹlẹ̀ nílùú wọn, ó dara pọ̀ mọ́ àwọn ológun, àmọ́ lẹ́yìn ìyẹn ó sá lọ sí orílẹ̀-èdè tó wà nítòsí. Ibẹ̀ ló ti rí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Jean sọ pé: “Mo ti kẹ́kọ̀ọ́ pé àwọn tó ń ṣe ìsìn tòótọ́ kì í dá sọ́rọ̀ òṣèlú, wọn kì í sì í pín yẹ́lẹyẹ̀lẹ. Kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n nífẹ̀ẹ́ ara wọn.” Ó tún sọ pé: “Gbogbo ọkàn mi ni mo fi jà fún orílẹ̀-èdè mi. Àmọ́ nígbà tí mo kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, gbogbo ọkàn mi ni mo fi ya ara mi sí mímọ́ fún Jèhófà.” Jean wá yí pa dà pátápátá. Dípò kó máa bá àwọn tí kì í ṣe ọmọ ìlú ẹ̀ jà, ó ti ń wàásù òtítọ́ Bíbélì fún gbogbo àwọn tó bá rí. Ìmọ̀ràn Bíbélì wúlò fáwọn èèyàn tó wá láti orílẹ̀-èdè àti ẹ̀yà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, ìyẹn sì jẹ́ ẹ̀rí míì pé a lè gbára lé Bíbélì Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.
MÁA GBÁRA LÉ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN NÌṢÓ
16. Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká túbọ̀ gbára lé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run?
16 Bí ayé yìí ṣe ń burú sí i, àwọn nǹkan kan máa dán wa wò bóyá a gbà pé òótọ́ lohun tó wà nínú Bíbélì. Àwọn kan lè mú ká bẹ̀rẹ̀ sí í ṣiyèméjì. Wọ́n lè fẹ́ ká máa ṣiyèméjì pé ṣé òótọ́ lohun tó wà nínú Bíbélì àti pé ṣé òótọ́ ni Jèhófà yan ẹrú olóòótọ́ àti olóye pé kó máa darí àwa èèyàn ẹ̀ lónìí? Àmọ́ tó bá dá wa lójú pé òtítọ́ ni Ọ̀rọ̀ Jèhófà, irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀ ò ní mi ìgbàgbọ́ wa. A máa ‘pinnu láti máa tẹ̀ lé àwọn ìlànà Jèhófà nígbà gbogbo, àá sì ṣe bẹ́ẹ̀ délẹ̀délẹ̀.’ (Sm. 119:112) A ò “ní tijú” láti sọ òtítọ́ Bíbélì fáwọn èèyàn, àá sì gbà wọ́n níyànjú pé kí wọ́n máa fi sílò. (Sm. 119:46) Ju gbogbo ẹ̀ lọ, àá lè fara da àwọn ìṣòro tí ò rọrùn títí kan inúnibíni, àá sì máa ṣe bẹ́ẹ̀ “pẹ̀lú sùúrù àti ìdùnnú.”—Kól. 1:11; Sm. 119:143, 157.
17. Kí ni ẹsẹ Ìwé Mímọ́ ọdún yìí á máa rán wa létí ẹ̀?
17 A mà dúpẹ́ o pé Jèhófà ti fi òtítọ́ hàn wá! Òtítọ́ yìí ń fi wá lọ́kàn balẹ̀, ó sì ń jẹ́ ká mọ ohun tó yẹ ká fi ayé wa ṣe nínú ayé burúkú tí gbogbo nǹkan ti dojú rú yìí. Yàtọ̀ síyẹn, ó tún ń jẹ́ ká nírètí pé ọjọ́ ọ̀la ń bọ̀ wá dáa nígbà tí Ìjọba Ọlọ́run bá ń ṣàkóso. Torí náà, ẹ jẹ́ kí ẹsẹ Ìwé Mímọ́ ọdún 2023 yìí mú kí ìgbàgbọ́ tá a ní nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run túbọ̀ lágbára pé òtítọ́ ni kókó inú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run!—Sm. 119:160.
ORIN 94 A Mọyì Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
a Ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tá a yàn fún ọdún 2023 máa fún ìgbàgbọ́ wa lókun gan-an, ó sọ pé: “Òtítọ́ ni kókó inú ọ̀rọ̀ rẹ.” (Sm. 119:160) Ó dájú pé ìwọ náà gbà bẹ́ẹ̀. Àmọ́ ọ̀pọ̀ ni ò gbà pé òtítọ́ lohun tó wà nínú Bíbélì àti pé ó lè tọ́ wa sọ́nà. Torí náà nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa jíròrò nǹkan mẹ́ta táá jẹ́ kí àwọn olóòótọ́ èèyàn gbà pé wọ́n lè gbára lé Bíbélì àti pé ó lè tọ́ wa sọ́nà.
b ÀLÀYÉ Ọ̀RỌ̀: Ọ̀rọ̀ Hébérù tí wọ́n tú sí “kókó” nínú ẹsẹ yìí túmọ̀ sí gbogbo ẹ̀ tàbí àwọn nǹkan pàtàkì tó wà nínú ohun kan.
c Kó o lè mọ púpọ̀ sí i nípa bí Jèhófà ò ṣe jẹ́ kí Bíbélì pa run, lọ sí ìkànnì jw.org/yo, kó o sì tẹ “Ìtàn àti Bíbélì” sínú àpótí tí wọ́n fi ń wá ọ̀rọ̀.
d A ti yí àwọn orúkọ kan pa dà.