Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

‘Ẹ Máa Sunkún Pẹ̀lú Àwọn Tí Ń Sunkún’

‘Ẹ Máa Sunkún Pẹ̀lú Àwọn Tí Ń Sunkún’

“Ẹ máa tu ara yín nínú lẹ́nì kìíní-kejì, kí ẹ sì máa gbé ara yin ró lẹ́nì kìíní-kejì.”​1 TẸS. 5:11.

ORIN: 121, 75

1, 2. Kí la máa jíròrò báyìí? Kí nìdí tó fi yẹ ká jíròrò rẹ̀? (Wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.)

ARÁBÌNRIN kan tó ń jẹ́ Susi sọ pé: “Ọkàn wa ṣì máa ń gbọgbẹ́ kódà lẹ́yìn nǹkan bí ọdún kan tí ọmọkùnrin wa kú.” Arákùnrin míì tí ìyàwó rẹ̀ kú lójijì sọ pé “ikú ìyàwó mi dá nǹkan sí mi lára.” Ó ṣeni láàánú pé ọ̀pọ̀ èèyàn nirú àdánù yìí ti ṣẹlẹ̀ sí. Ọ̀pọ̀ wa ló gbà pé àwa àtàwọn èèyàn wa jọ máa la Amágẹ́dọ́nì já, àá sì fẹsẹ̀ rìn wọnú ayé tuntun, a kì í ronú ẹ̀ pé ẹnikẹ́ni máa kú lára wa. Yálà a ti pàdánù èèyàn wa kan nínú ikú tàbí a mọ ẹnì kan tó ń ṣọ̀fọ̀, ó ṣeé ṣe ká máa ronú pé, ‘Báwo làwọn tó ń ṣọ̀fọ̀ ṣe lè rí ìtùnú?’

2 Bóyá o ti gbọ́ táwọn èèyàn máa ń sọ pé kò dé lara ò gbà, bópẹ́ bóyá, ọgbẹ́ ọkàn máa jinná. Àmọ́, ṣé lóòótọ́ ni pé èèyàn á gbàgbé ọ̀fọ̀ tó ṣẹ̀ ẹ́ tí ìgbà bá ti kọjá lórí ohun tó ṣẹlẹ̀? Obìnrin kan tó jẹ́ opó sọ pé, “Ohun tí mo gbà pé ó lè jẹ́ kí ọgbẹ́ ọkàn náà jinná ni ohun téèyàn bá fi àkókò náà ṣe.” Ọ̀rọ̀ náà wá dà bí ìgbà téèyàn ní egbò lára, téèyàn bá tọ́jú rẹ̀ dáadáa bópẹ́ bóyá ó máa jinná. Torí náà, àwọn nǹkan wo ló lè mú kí ọgbẹ́ ọkàn ẹni tó ń sọ̀fọ̀ jinná?

JÈHÓFÀ NI “ỌLỌ́RUN ÌTÙNÚ GBOGBO”

3, 4. Kí nìdí tó fi dá wa lójú pé Jèhófà mọ bó ṣe máa ń rí lára téèyàn ẹni bá kú?

3 Tó bá di pé ká tu èèyàn nínú, kò sẹ́ni tó lè tuni nínú bíi Jèhófà Baba wa ọ̀run tó jẹ́ Ọlọ́run àánú. (Ka 2 Kọ́ríńtì 1:​3, 4.) Jèhófà ò lẹ́gbẹ́ tó bá di pé ká gba tèèyàn rò, ó sì fi dá àwa èèyàn rẹ̀ lójú pé: “Èmi fúnra mi ni Ẹni tí ń tù yín nínú.”​—Aísá. 51:12; Sm. 119:​50, 52, 76.

4 Jèhófà, Baba àánú oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ náà mọ bó ṣe máa ń rí lára téèyàn ẹni bá kú. Ó ṣe tán, òun náà ti pàdánù àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ tó nífẹ̀ẹ́, àwọn bí Ábúráhámù, Ísákì, Jékọ́bù, Mósè àti Ọba Dáfídì. (Núm. 12:​6-8; Mát. 22:​31, 32; Ìṣe 13:22) Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run jẹ́ kó dá wa lójú pé taratara ni Jèhófà fi ń retí ìgbà tó máa jí àwọn olóòótọ́ yìí dìde. (Jóòbù 14:​14, 15) Nígbà tí wọ́n bá jíǹde, wọ́n á láyọ̀, wọ́n á sì ní ìlera tó jí pépé. Yàtọ̀ síyẹn, “ẹni tí [Ọlọ́run] ní ìfẹ́ni sí lọ́nà àkànṣe,” ìyẹn Jésù Ọmọ rẹ̀ náà kú ikú oró. (Òwe 8:​22, 30) Kò sí bá a ṣe lè ṣàlàyé bọ́rọ̀ náà ṣe máa dun Jèhófà tó.​—Jòh. 5:20; 10:17.

5, 6. Báwo ni Jèhófà ṣe ń tù wá nínú?

5 Ọkàn wa balẹ̀ pé Jèhófà máa ràn wá lọ́wọ́. Torí náà, ká sọ gbogbo ohun tó wà lọ́kàn wa fún Jèhófà, ká sì jẹ́ kó mọ bí ẹ̀dùn ọkàn tá a ní ṣe rí lára wa. A mà dúpẹ́ o, pé Jèhófà lóye wa, ó mọ ẹ̀dùn ọkàn wa, ó sì ń pèsè ìtùnú tá a nílò gan-an! Àmọ́ báwo ló ṣe ń tù wá nínú?

6 Lára ohun tí Ọlọ́run ń pèsè fún wa ni “ìtùnú ẹ̀mí mímọ́.” (Ìṣe 9:31) Ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run lágbára gan-an tó bá di pé ká tuni nínú. Jésù sì ṣèlérí pé Baba òun “yóò fi ẹ̀mí mímọ́ fún àwọn tí ń béèrè lọ́wọ́ rẹ̀.” (Lúùkù 11:13) Arábìnrin Susi tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ lẹ́ẹ̀kan sọ pé: “Ọ̀pọ̀ ìgbà la máa ń kúnlẹ̀, tá a sì máa bẹ Jèhófà pé kó tù wá nínú. Ní gbogbo ìgbà tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, ṣe ni àlàáfíà Ọlọ́run máa ń mú kí ọkàn wa balẹ̀ pẹ̀sẹ̀.”​—Ka Fílípì 4:​6, 7.

JÉSÙ NI ÀLÙFÁÀ ÀGBÀ TÓ LÈ BÁNI KẸ́DÙN

7, 8. Báwo la ṣe mọ̀ pé Jésù lè tuni nínú?

7 Nígbà tí Jésù wà láyé, ó fi hàn nínú ọ̀rọ̀ àti ìṣe rẹ̀ pé òun láàánú àwọn èèyàn bíi ti Jèhófà Bàbá rẹ̀. (Jòh. 5:19) Jèhófà rán Jésù wá sáyé kó lè tu “àwọn oníròbìnújẹ́-ọkàn” àti “gbogbo àwọn tí ń ṣọ̀fọ̀” nínú. (Aísá. 61:​1, 2; Lúùkù 4:​17-21) Ó ṣe kedere nígbà náà pé Jésù láàánú àwọn èèyàn gan-an, ó ń rí ìyà tó ń jẹ wọ́n, ó mọ̀ ọ́n lára, ó sì máa ń wù ú gan-an pé kó ràn wọ́n lọ́wọ́.​—Héb. 2:17.

8 Ẹ̀rí fi hàn pé nígbà tí Jésù wà ní ọ̀dọ́, òun náà mọ bó ṣe máa ń rí lára téèyàn ẹni bá kú. Ó jọ pé ìgbà tí Jésù ṣì wà lọ́dọ̀ọ́ ni Jósẹ́fù tó jẹ́ alágbàtọ́ rẹ̀ kú. * Ó ṣeé ṣe kí Jésù má tíì pé ọmọ ogún ọdún nígbà yẹn tàbí kó ṣẹ̀ṣẹ̀ lé lọ́mọ ogún ọdún. Ẹ wo bí ìṣẹ̀lẹ̀ yẹn ṣe máa ká Jésù tó jẹ́ ẹlẹ́yinjú àánú lára tó, ẹ sì wo bó ṣe máa dùn ún tó bó ṣe ń rí tí ìyá rẹ̀ àtàwọn àbúrò rẹ̀ ń ṣọ̀fọ̀.

9. Kí ni Jésù ṣe tó fi hàn pé ó bá àwọn ẹbí Lásárù kẹ́dùn?

9 Ní gbogbo àsìkò tí Jésù fi ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀, ó fi hàn pé òun lóye bí nǹkan ṣe rí lára àwọn èèyàn, ó sì fàánú hàn sí wọn. Àpẹẹrẹ kan ni ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà tí Lásárù ọ̀rẹ́ rẹ̀ kú. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jésù mọ̀ pé òun máa jí Lásárù dìde, síbẹ̀ ó dùn ún gan-an nígbà tó rí bí ìbànújẹ́ ṣe dorí Màríà àti Màtá kodò. Ọ̀rọ̀ náà ká a lára débi pé ọkàn òun alára gbọgbẹ́, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í da omi lójú.​—Jòh. 11:​33-36.

10. Báwo la ṣe mọ̀ pé Jésù ṣì lè bá wa kẹ́dùn?

10 Tá a bá ronú lórí bí Jésù ṣe sọ̀rọ̀ ìtùnú fún àwọn èèyàn àti bó ṣe bá wọn kẹ́dùn, àǹfààní wo nìyẹn máa ṣe wá? Ìwé Mímọ́ fi dá wa lójú pé “Jésù Kristi jẹ́ ọ̀kan náà lánàá àti lónìí, àti títí láé.” (Héb. 13:8) Torí pé Jésù tí Bíbélì pè ní “Olórí Aṣojú ìyè” mọ bó ṣe máa ń rí lára téèyàn bá ń ṣọ̀fọ̀, ó lè ran àwọn tó ń ṣọ̀fọ̀ lọ́wọ́. (Ìṣe 3:15; Héb. 2:​10, 18) Torí náà, ọkàn wa balẹ̀ pé Jésù ṣì máa ń kíyè sí àwọn tó ní ẹ̀dùn ọkàn, ó mọ bí nǹkan ṣe rí lára wọn, ó sì máa ń tù wọ́n nínú “ní àkókò tí ó tọ́.”​—Ka Hébérù 4:​15, 16.

“ÌTÙNÚ LÁTI INÚ ÌWÉ MÍMỌ́”

11. Àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ wo ló tù ẹ́ nínú gan-an?

11 Àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó ń tuni nínú pọ̀ gan-an nínú Bíbélì, ọ̀kan lára wọn lèyí tó sọ bí ẹ̀dùn ọkàn ṣe bá Jésù tó sì sunkún níbi òkú Lásárù. Abájọ tí Bíbélì fi sọ pé, “nítorí gbogbo ohun tí a ti kọ ní ìgbà ìṣáájú ni a kọ fún ìtọ́ni wa, pé nípasẹ̀ ìfaradà wa àti nípasẹ̀ ìtùnú láti inú Ìwé Mímọ́, kí a lè ní ìrètí.” (Róòmù 15:4) Bí àpẹẹrẹ, àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó wà nísàlẹ̀ yìí lè tù ẹ́ nínú nígbàkígbà tó o bá ń ṣọ̀fọ̀:

  • “Jèhófà sún mọ́ àwọn oníròbìnújẹ́ ní ọkàn-àyà; ó sì ń gba àwọn tí a wó ẹ̀mí wọn palẹ̀ là.”​—Sm. 34:​18, 19.

  • “Nígbà tí ìrònú tí ń gbé mi lọ́kàn sókè di púpọ̀ nínú mi, ìtùnú tìrẹ ni ó bẹ̀rẹ̀ sí ṣìkẹ́ ọkàn mi.”​—Sm. 94:19.

  • “Kí Olúwa wa Jésù Kristi fúnra rẹ̀ àti Baba wa Ọlọ́run, ẹni tí ó nífẹ̀ẹ́ wa, tí ó sì fúnni ní ìtùnú àìnípẹ̀kun àti ìrètí rere nípasẹ̀ inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí, tu ọkàn-àyà yín nínú, kí ó sì fìdí yín múlẹ̀ gbọn-in.”​—2 Tẹs. 2:​16, 17. *

À Ń RÍ ÌTÙNÚ GBÀ NÍNÚ ÌJỌ

12. Kí ló dáa jù tá a lè ṣe láti tu àwọn tó ń ṣọ̀fọ̀ nínú?

12 Àwọn tó ń ṣọ̀fọ̀ tún lè rí ìtùnú nínú ìjọ Kristẹni. (Ka 1 Tẹsalóníkà 5:11.) Kí la lè ṣe láti tu àwọn “tí ìdààmú bá” nínú, ká sì gbé wọn ró? (Òwe 17:22) Ó yẹ ká fi sọ́kàn pé “ìgbà dídákẹ́ jẹ́ẹ́ àti ìgbà sísọ̀rọ̀” wà. (Oníw. 3:7) Arábìnrin Dalene tọ́kọ rẹ̀ ti kú sọ pé: “Àwọn tó ń ṣọ̀fọ̀ máa ń fẹ́ tú gbogbo ohun tó wà lọ́kàn wọn jáde. Torí náà, ohun tó dáa jù téèyàn lè ṣe fún àwọn tó ń ṣọ̀fọ̀ ni pé kéèyàn tẹ́tí sí wọn dáadáa, kó má sì dá ọ̀rọ̀ mọ́ wọn lẹ́nu.” Arábìnrin Junia tí ẹ̀gbọ́n rẹ̀ ọkùnrin pa ara rẹ̀ sọ pé: “Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò sí bó o ṣe lè lóye bọ́rọ̀ ṣe rí lára wọn gan-an, ohun tó ṣe pàtàkì ni pé kó o gbìyànjú láti fi ara rẹ sí ipò wọn.”

13. Kí ló yẹ ká fi sọ́kàn nípa bí ẹ̀dùn ọkàn ṣe máa ń rí lára ẹnì kọ̀ọ̀kan?

13 Bákan náà, ó yẹ ká fi sọ́kàn pé bọ́rọ̀ ṣe máa ń rí lára wa yàtọ̀ síra, ìyàtọ̀ sì wà nínú bí kálukú ṣe máa ń fi ẹ̀dùn ọkàn hàn. Lọ́pọ̀ ìgbà, ẹni tí ọ̀fọ̀ ṣẹ̀ nìkan ló mọ bí ẹ̀dùn ọkàn tó ní ṣe pọ̀ tó, torí pé ẹni tó kàn ló mọ̀. Bákan náà, ó lè ṣòro fún un láti ṣàlàyé bí nǹkan ṣe rí lọ́kàn rẹ̀. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ pé: “Ọkàn-àyà mọ ìkorò ọkàn ẹni, kò sì sí àjèjì tí yóò tojú bọ ayọ̀ yíyọ̀ rẹ̀.” (Òwe 14:10) Kódà, tí ẹni náà bá tiẹ̀ gbìyànjú láti ṣàlàyé bí nǹkan ṣe rí lára rẹ̀, kì í fi bẹ́ẹ̀ rọrùn fáwọn èèyàn láti lóye ohun tó ń sọ.

14. Kí la lè ṣe láti tu ẹni tó ń ṣọ̀fọ̀ nínú?

14 Ká sòótọ́, a lè má mọ ohun tá a máa sọ fún ẹni tí ọ̀fọ̀ ṣẹ̀. Síbẹ̀, Bíbélì sọ pé “ahọ́n ọlọ́gbọ́n jẹ́ ìmúniláradá.” (Òwe 12:18) Ọ̀pọ̀ máa ń lo àwọn ọ̀rọ̀ ìtùnú tó wà nínú ìwé Nígbà Tí Ẹnìkan Tí Ìwọ Fẹ́ràn Bá Kú, láti tu àwọn tó ń ṣọ̀fọ̀ nínú. * Àmọ́ o, ohun tó dáa jù ni pé ká “sunkún pẹ̀lú àwọn ènìyàn tí ń sunkún.” (Róòmù 12:15) Arábìnrin Gaby tí ọkọ rẹ̀ kú sọ pé: “Ṣe ni mo máa ń wa ẹkún mu. Àmọ́ ara máa ń tù mí táwọn ọ̀rẹ́ mi bá wá kí mi táwọn náà sì ń sunkún. Bí wọ́n ṣe ń sunkún yẹn máa ń mú kí n gbà pé mi ò dá nìkan ṣọ̀fọ̀.”

15. Báwo la ṣe lè tu ẹnì kan nínú tá ò bá tiẹ̀ mọ ohun tá a lè sọ fún ẹni náà? (Tún wo àpótí náà “ Àwọn Ọ̀rọ̀ Tó Lè Tuni Nínú.”)

15 Tó ò bá mọ ohun tó o lè sọ fún ẹni náà, o lè fún un ní lẹ́tà tàbí káàdì tó o kọ ọ̀rọ̀ ìtùnú sí, o sì lè fọ̀rọ̀ ránṣẹ́ sí i lórí fóònù. O lè kọ ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan tó ń tuni nínú, o lè mẹ́nu ba ànímọ́ rere kan tẹ́ni tó kú náà ní tàbí kó o sọ àwọn nǹkan dáadáa tẹ́ ẹ jọ ṣe kẹ́ni náà tó kú. Junia tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ lẹ́ẹ̀kan sọ pé: “Ó máa ń tù mí lára gan-an tí mo bá gba káàdì tàbí lẹ́tà tí ọ̀rọ̀ ìtùnú wà nínú rẹ̀ tàbí táwọn ará bá ní kí n wá sílé àwọn. Àwọn nǹkan yìí máa ń jẹ́ kí n mọ̀ pé àwọn ará nífẹ̀ẹ́ mi, ọ̀rọ̀ mi sì jẹ wọ́n lọ́kàn.”

16. Kí lohun míì tá a tún lè ṣe láti tu ẹnì kan nínú?

16 Jẹ́ kó dá ẹ lójú pé ẹni tó ń ṣọ̀fọ̀ máa mọrírì rẹ̀ gan-an tó o bá gbàdúrà fún un tàbí tẹ́ ẹ jọ gbàdúrà. O lè má mọ ohun tó o máa sọ nínú àdúrà náà, àmọ́ ara lè tu ẹni náà bó ṣe ń gbọ́ tó ò ń gbàdúrà àtọkànwá, bóyá tí omijé tiẹ̀ ń dà lójú rẹ, tí ohùn rẹ sì ń gbọ̀n. Arábìnrin Dalene sọ pé: “Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan táwọn arábìnrin bá wá kí mi, mo máa ń sọ pé kí wọ́n gbàdúrà fún mi. Níbẹ̀rẹ̀, wọn kì í mọ ohun tí wọ́n máa sọ, àmọ́ bí wọ́n ṣe ń bá àdúrà náà lọ, ọ̀rọ̀ wọn máa ń sọjú abẹ níkòó, ó sì máa ń jẹ́ àtọkànwá. Ìgbàgbọ́ tí wọ́n ní àti bí wọ́n ṣe fìfẹ́ hàn sí mi máa ń mára tù mí, ó sì máa ń fún mi lókun.”

MÁA TU ÀWỌN ÈÈYÀN NÍNÚ

17-19. Kí nìdí tá ò fi gbọ́dọ̀ dẹ́kun àtimáa tu àwọn tó ń ṣọ̀fọ̀ nínú?

17 Àkókò tó máa ń gbà kí ẹ̀dùn ọkàn tó lọ lára ẹnì kọ̀ọ̀kan yàtọ̀ síra. Torí náà, ká má ṣe fi lílọ sọ́dọ̀ àwọn tó ń ṣọ̀fọ̀ mọ sígbà tí àjálù náà ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣẹlẹ̀, táwọn ẹbí àti ọ̀rẹ́ wà pẹ̀lú wọn, àmọ́ ká tún máa bẹ̀ wọ́n wò kódà lẹ́yìn ọ̀pọ̀ oṣù tí tẹbítọ̀rẹ́ ti pa dà sílé wọn. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ pé: “Alábàákẹ́gbẹ́ tòótọ́ a máa nífẹ̀ẹ́ ẹni ní gbogbo ìgbà, ó sì jẹ́ arákùnrin tí a bí fún ìgbà tí wàhálà bá wà.” (Òwe 17:17) Orísun ìtùnú làwa Kristẹni gbọ́dọ̀ jẹ́ fún àwọn tó ń ṣọ̀fọ̀ títí dìgbà tí wọ́n á gbé e kúrò lára.​—Ka 1 Tẹsalóníkà 3:7.

18 Ká rántí pé àròkàn ní í fa ẹkún àsun-ùndá. Torí náà, déètì kan nínú ọdún lè mú kẹ́ni téèyàn rẹ̀ kú rántí ọ̀fọ̀ tó ṣẹ̀ ẹ́, ó sì lè jẹ́ orin kan tẹ́ni náà fẹ́ràn tàbí fọ́tò rẹ̀, kódà ó lè jẹ́ òórùn lásán tàbí àwọn nǹkan míì. Ọ̀pọ̀ nǹkan làwọn méjèèjì ti jọ ń ṣe pa pọ̀, àmọ́ ní báyìí tó ku òun nìkan, ó lè ṣòro fún un láti ṣe àwọn nǹkan kan, bíi lílọ sí àpéjọ tàbí Ìrántí Ikú Kristi. Bí àpẹẹrẹ, arákùnrin kan sọ pé: “Mo mọ̀ pé tó bá máa di déètì ọjọ́ tá a ṣègbéyàwó, kò sí bí mi ò ṣe ní rántí ìyàwó mi tó kú, ó sì dájú pé ọkàn mi máa gbọgbẹ́ gan-an. Kò rọrùn fún mi lọ́jọ́ yẹn, àmọ́ àwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin ṣètò àpèjẹ ráńpẹ́ kan, wọ́n sì pe àwọn ọ̀rẹ́ mi tímọ́tímọ́ kí n má bàa dá nìkan wà.”

19 Àmọ́ o, kì í ṣe irú àwọn àsìkò báyìí nìkan làwọn tó ń ṣọ̀fọ̀ nílò ìṣírí. Arábìnrin Junia sọ pé: “Ó máa ń ṣèrànwọ́ gan-an táwọn èèyàn bá wà pẹ̀lú wa láwọn àsìkò míì, yàtọ̀ sí àwọn ọjọ́ pàtàkì nìkan. Ó máa ń tù wá lára táwọn ará bá bẹ̀ wá wò láwọn ìgbà tá ò retí.” Ká sòótọ́, kò sóhun tá a ṣe tó lè mú káwọn tó ń ṣọ̀fọ̀ gbàgbé ohun tó ṣẹlẹ̀ sí wọn pátápátá, bẹ́ẹ̀ sì ni ojú olójú kò lè dà bí ojú ẹni. Àmọ́, a lè tu àwọn tó ń ṣọ̀fọ̀ nínú tá a bá ṣe àwọn nǹkan pàtó fún wọn. (1 Jòh. 3:18) Arábìnrin Gaby sọ pé: “Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà pé ó fún wa láwọn alàgbà tí wọ́n ràn mí lọ́wọ́ ní gbogbo àsìkò tí nǹkan le gan-an fún mi. Ó jẹ́ kí n rí i pé lóòótọ́ ni Jèhófà nífẹ̀ẹ́ mi.”

20. Kí nìdí tí àwọn ìlérí Jèhófà fi tù wá nínú?

20 Inú wa dùn pé Jèhófà, Ọlọ́run ìtùnú gbogbo máa mú àwọn nǹkan tó ń fa ẹ̀dùn ọkàn kúrò, á sì tu aráyé nínú nígbà tí “gbogbo àwọn tí wọ́n wà nínú ibojì ìrántí yóò gbọ́ ohùn [Kristi] wọn yóò sì jáde wá”! (Jòh. 5:​28, 29) Ọlọ́run ṣèlérí pé “òun yóò gbé ikú mì títí láé, dájúdájú, Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ yóò nu omijé kúrò ní ojú gbogbo ènìyàn.” (Aísá. 25:8) Nígbà yẹn, dípò tí aráyé á fi máa “sunkún pẹ̀lú àwọn ènìyàn tí ń sunkún,” ṣe làá máa “yọ̀ pẹ̀lú àwọn ènìyàn tí ń yọ̀.”​—Róòmù 12:15.

^ ìpínrọ̀ 8 Ìgbà tí Jésù wà lọ́mọ ọdún méjìlá [12] la gbúròó Jósẹ́fù kẹ́yìn. Bíbélì kò dárúkọ rẹ̀ nígbà tí Jésù ṣe iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ àkọ́kọ́, ìyẹn nígbà tó sọ omi di ọtí wáìnì, a ò sì tún gbúròó rẹ̀ lẹ́yìn náà. Nígbà tí Jésù wà lórí òpó igi oró, ó ní kí àpọ́sítélì Jòhánù máa tọ́jú Màríà. Kò sì dájú pé Jésù máa ṣe bẹ́ẹ̀ ká sọ pé Jósẹ́fù ṣì wà láàyè.​—Jòh. 19:​26, 27.

^ ìpínrọ̀ 14 Tún wo àpilẹ̀kọ náà “Máa Tu Àwọn Tó Ń Ṣọ̀fọ̀ Nínú bí Jésù Ti Ṣe” nínú Ilé Ìṣọ́ November 1, 2010.