Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 27

Má Ṣe Ro Ara Rẹ Ju Bó Ṣe Yẹ Lọ

Má Ṣe Ro Ara Rẹ Ju Bó Ṣe Yẹ Lọ

Mo sọ fún gbogbo ẹni tó wà láàárín yín níbẹ̀ pé kó má ro ara rẹ̀ ju bó ṣe yẹ lọ, àmọ́ kó máa ronú lọ́nà tó fi hàn pé ó láròjinlẹ̀.”​RÓÒMÙ 12:3.

ORIN 130 Ẹ Máa Dárí Jini

OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒ *

1. Bó ṣe wà nínú Fílípì 2:​3, báwo ni ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ ṣe ń mú ká ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú àwọn míì?

Ẹ̀MÍ ìrẹ̀lẹ̀ tá a ní ń mú ká ṣègbọràn sí Jèhófà torí a mọ̀ pé àwọn ìlànà rẹ̀ ló dáa jù fún wa. (Éfé. 4:22-24) Ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ yìí kan náà ló ń jẹ́ ká fi ìfẹ́ Jèhófà ṣáájú tiwa ká sì gbà pé àwọn míì sàn jù wá lọ. Nípa bẹ́ẹ̀, a ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà àtàwọn ará wa.​—Ka Fílípì 2:3.

2. Kí ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ, kí la sì máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí?

2 Àmọ́ o, tá ò bá ṣọ́ra àwọn èèyàn ayé lè mú ká di agbéraga àti ẹni tí kò mọ̀ ju tara ẹ̀ lọ. * Ó jọ pé irú nǹkan bẹ́ẹ̀ ṣẹlẹ̀ ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní torí nínú lẹ́tà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ sáwọn ará Róòmù, ó sọ pé: “Mo sọ fún gbogbo ẹni tó wà láàárín yín níbẹ̀ pé kó má ro ara rẹ̀ ju bó ṣe yẹ lọ, àmọ́ kó máa ronú lọ́nà tó fi hàn pé ó láròjinlẹ̀.” (Róòmù 12:3) Pọ́ọ̀lù sọ pé kò yẹ ká ro ara wa ju bó ṣe yẹ lọ, àmọ́ kì í ṣe pé ká wá ro ara wa pin bíi pé a ò já mọ́ nǹkan kan. Torí náà, tá a bá lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀, àá wà níwọ̀ntúnwọ̀nsì. Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa jíròrò apá mẹ́ta tó ti yẹ ká lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀ ká má sì ro ara wa ju bó ti yẹ lọ. A máa rí bá a ṣe lè ṣe bẹ́ẹ̀ nínú ìgbéyàwó wa, tá a bá ní àwọn ojúṣe kan nínú ètò Ọlọ́run àti nígbà tá a bá ń lo ìkànnì àjọlò.

MÁA FI Ẹ̀MÍ ÌRẸ̀LẸ̀ HÀN NÍNÚ ÌGBÉYÀWÓ RẸ

3. Kí ló máa ń fa èdèkòyédè nínú ìgbéyàwó, kí làwọn kan sì gbà pé ó lè yanjú ìṣòro náà?

3 Jèhófà fẹ́ káwọn tọkọtaya máa láyọ̀. Àmọ́ torí pé aláìpé ni gbogbo wa, kò sí kí èdèkòyédè má wáyé. Kódà Pọ́ọ̀lù gan-an sọ pé àwọn tó ṣègbéyàwó máa ní àwọn ìṣòro kan. (1 Kọ́r. 7:28) Àwọn tọkọtaya kan ò lè ṣe kí wọ́n má jà, torí náà wọ́n lè ronú pé àwọn ò bára wọn mu. Tí wọ́n bá sì ronú bíi tàwọn èèyàn ayé, wọ́n á gbà pé ìkọ̀sílẹ̀ ló máa yanjú ẹ̀. Wọ́n á ronú pé káwọn tẹ́ ara àwọn lọ́rùn ṣe pàtàkì ju káwọn ṣe ohun tí Jèhófà fẹ́ lọ.

4. Kí la ò gbọ́dọ̀ ṣe?

4 A ò gbọ́dọ̀ jẹ́ kí ìgbéyàwó wa sú wa. Ó yẹ ká rántí pé ìṣekúṣe nìkan ni Bíbélì sọ pé ó lè mú kí tọkọtaya pinnu pé àwọn á kọra wọn sílẹ̀. (Mát. 5:32) Torí náà, bí ìṣòro tí Pọ́ọ̀lù sọ̀rọ̀ ẹ̀ bá yọjú, a ò ní ro ara wa ju bó ṣe yẹ lọ ká wá máa ronú pé: ‘Ṣé irú ìgbéyàwó tí mo fẹ́ nìyí? Ṣé ọkọ tàbí ìyàwó mi nífẹ̀ẹ́ mi bó ṣe yẹ? Ṣé màá túbọ̀ láyọ̀ tí mo bá fẹ́ ẹlòmíì?’ Ẹ kíyè sí pé ẹni tó ń ronú báyìí kò ro tẹnì kejì mọ́ tiẹ̀, tara ẹ̀ nìkan ló ń rò. Nínú ayé, wọ́n máa ń sọ pé ohun tọ́kàn ẹ bá sọ fún ẹ ni kó o ṣe, ohun tó sì máa fún láyọ̀ nìyẹn, kódà tó bá gba pé kó o fi ọkọ tàbí ìyàwó ẹ sílẹ̀. Àmọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ pé kó o máa ‘wá ire àwọn ẹlòmíì, kì í ṣe tìẹ nìkan.’ (Fílí. 2:4) Jèhófà ò fẹ́ kó o fi ọkọ tàbí ìyàwó rẹ sílẹ̀, ṣe ló fẹ́ kẹ́ ẹ ṣe ara yín lọ́kan. (Mát. 19:6) Ìfẹ́ Jèhófà ló yẹ kó o fi síwájú, kì í ṣe tìẹ.

5. Bó ṣe wà nínú Éfésù 5:​33, báwo ló ṣe yẹ kí ọkọ àtìyàwó máa ṣe síra wọn?

5 Ó yẹ kí tọkọtaya nífẹ̀ẹ́ ara wọn kí wọ́n sì máa bọ̀wọ̀ fún ara wọn. (Ka Éfésù 5:33.) Bíbélì sọ pé ká máa fún àwọn míì ní nǹkan dípò ká máa wá bá a ṣe máa gba tọwọ́ wọn. (Ìṣe 20:35) Kí ló máa jẹ́ kí tọkọtaya nífẹ̀ẹ́ ara wọn kí wọ́n sì máa bọ̀wọ̀ fún ara wọn? Ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ ni. Ńṣe ni ọkọ tàbí aya tó lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀ á máa wá ire tẹnì kejì rẹ̀ “kì í ṣe ti ara rẹ̀” nìkan.​—1 Kọ́r. 10:24.

Àwọn tọkọtaya tó lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀ kì í jọra wọn lójú, ṣe ni wọ́n máa ń fọwọ́ sowọ́ pọ̀ ṣe nǹkan (Wo ìpínrọ̀ 6)

6. Kí lo rí kọ́ látinú ohun tí Steven àti Stephanie sọ?

6 Ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ ti mú kí ọ̀pọ̀ tọkọtaya tó jẹ́ Kristẹni túbọ̀ láyọ̀ nínú ìgbéyàwó wọn. Bí àpẹẹrẹ, ọkọ kan tó ń jẹ́ Steven sọ pé: “Tẹ́ ẹ bá ṣera yín lọ́kan, ẹ̀ẹ́ jọ mọ bẹ́ ẹ ṣe lè yanjú ìṣòro tó bá yọjú. Dípò kó o máa ronú pé ‘kí ló máa múnú mi dùn?’ ṣe ni kó o ronú pé ‘kí ló máa múnú wa dùn?’ ” Bó ṣe rí lára Stephanie ìyàwó ẹ̀ náà nìyẹn, ó sọ pé: “Kò sẹ́ni tó fẹ́ máa bá oníjà gbélé. Tí èdèkòyédè bá wáyé láàárín wa, a máa ń sapá láti mọ ohun tí ìṣòro náà jẹ́ gan-an. Lẹ́yìn náà, àá gbàdúrà, àá ṣèwádìí nínú ìwé ètò Ọlọ́run, àá sì jọ sọ ọ́ yanjú. Dípò ká bára wa jà, ìṣòro yẹn la máa ń yanjú.” Tí ọkọ tàbí aya kan bá ń ro tẹnì kejì rẹ̀ mọ́ tiẹ̀, inú àwọn méjèèjì máa dùn.

FI “ÌRẸ̀LẸ̀” SIN JÈHÓFÀ

7. Irú ẹ̀mí wo ló yẹ kí arákùnrin kan ní tí wọ́n bá fún un ní àǹfààní iṣẹ́ ìsìn kan?

7 Àǹfààní ńlá ló jẹ́ pé à ń sin Jèhófà. (Sm. 27:4; 84:10) Ó dáa gan-an tí arákùnrin kan bá yọ̀ǹda ara ẹ̀ láti ṣe púpọ̀ sí i nínú ètò Jèhófà. Kódà, Bíbélì sọ pé: “Tí ọkùnrin kan bá ń sapá láti di alábòójútó, iṣẹ́ rere ló fẹ́ ṣe.” (1 Tím. 3:1) Àmọ́ tó bá wá ní àwọn àǹfààní iṣẹ́ kan, kò yẹ kó ro ara rẹ̀ ju bó ṣe yẹ lọ. (Lúùkù 17:​7-10) Kàkà bẹ́ẹ̀, ó yẹ kó lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀, kó sì ṣe tán láti ṣiṣẹ́ sin àwọn míì.​—2 Kọ́r. 12:15.

8. Kí la rí kọ́ látinú ohun tí Díótíréfè, Ùsáyà àti Ábúsálómù ṣe?

8 Àpẹẹrẹ àwọn tó ro ara wọn ju bó ṣe yẹ lọ wà nínú Bíbélì ká lè kẹ́kọ̀ọ́ lára wọn. Bí àpẹẹrẹ, Díótíréfè fẹ́ fi ara rẹ̀ “ṣe olórí” nínú ìjọ, ìyẹn sì fi hàn pé kò mọ̀wọ̀n ara ẹ̀. (3 Jòh. 9) Ìgbéraga mú kí Ùsáyà ṣe ohun tí kò láṣẹ láti ṣe. (2 Kíró. 26:​16-21) Ábúsálómù lo ọgbọ́n àrékérekè láti mú káwọn èèyàn gba tiẹ̀ torí pé ó fẹ́ di ọba. (2 Sám. 15:​2-6) Àwọn àpẹẹrẹ yìí fi hàn pé inú Jèhófà kì í dùn sáwọn tó bá ń wá ògo ara wọn. (Òwe 25:27) Bó pẹ́ bó yá, ìparun ló máa ń gbẹ̀yìn ìgbéraga.​—Òwe 16:18.

9. Àpẹẹrẹ wo ni Jésù fi lélẹ̀?

9 Àmọ́ Jésù yàtọ̀ sí àwọn tá a sọ̀rọ̀ wọn tán yìí torí Bíbélì sọ nípa Jésù pé “bí ó tilẹ̀ wà ní ìrísí Ọlọ́run, kò ronú rárá láti já nǹkan gbà, ìyẹn, pé kó bá Ọlọ́run dọ́gba.” (Fílí. 2:6) Lẹ́yìn Jèhófà, Jésù ló lágbára jù láyé àti lọ́run, síbẹ̀ kò ro ara ẹ̀ ju bó ṣe yẹ lọ. Ó sọ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Ẹni tó bá hùwà bí ẹni tó kéré láàárín gbogbo yín ni ẹni tó tóbi.” (Lúùkù 9:48) Ẹ ò rí i pé àǹfààní ńlá ni bá a ṣe ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwọn aṣáájú-ọ̀nà, àwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́, àwọn alàgbà àtàwọn alábòójútó àyíká tí wọ́n lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀ bíi ti Jésù! Àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà tó lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀ ń mú kí ìfẹ́ túbọ̀ gbilẹ̀ nínú ètò Ọlọ́run.​—Jòh. 13:35.

10. Kí ló yẹ kó o ṣe tó o bá ronú pé àwọn alàgbà ò bójú tó ìṣòro kan bó ṣe tọ́?

10 Táwọn ìṣòro kan bá wáyé nínú ìjọ, tó o sì ronú pé àwọn alàgbà ò bójú tó ọ̀rọ̀ náà bó ṣe yẹ, kí lo máa ṣe? Dípò tí wàá fi máa ráhùn, ṣe ni kó o fẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ hàn, kó o sì kọ́wọ́ ti ìpinnu táwọn alábòójútó bá ṣe. (Héb. 13:17) Kó lè rọrùn fún ẹ, á dáa kó o bi ara ẹ pé: ‘Ṣé bẹ́ẹ̀ lọ̀rọ̀ náà lágbára tó? Tó bá sì yẹ kí wọ́n bójú tó o, ṣé àsìkò tó yẹ kí wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀ nìyí? Ṣé èmi ló yẹ kí n pe àfiyèsí wọn sí i? Ká sòótọ́, ṣé àlàáfíà ìjọ ni mò ń wá, àbí mo fẹ́ káwọn èèyàn máa gbé mi gẹ̀gẹ̀?’

Ohun tó yẹ kí wọ́n mọ̀ mọ́ ẹnì kan tó jẹ́ alábòójútó ni ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ rẹ̀, kì í ṣe ẹ̀bùn tó ní tàbí àǹfààní iṣẹ́ ìsìn rẹ̀ (Wo ìpínrọ̀ 11) *

11. Bó ṣe wà nínú Éfésù 4:​2, 3, kí ló máa yọrí sí tá a bá ń fìrẹ̀lẹ̀ sin Jèhófà?

11 Jèhófà mọyì ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ wa ju ẹ̀bùn èyíkéyìí tá a ní lọ, ká wà ní àlàáfíà pẹ̀lú ara wa sì ṣe pàtàkì sí i ju ká mọ nǹkan ṣe lọ. Torí náà, ṣe gbogbo ohun tó o lè ṣe kó o lè lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀. Tó o bá ń fìrẹ̀lẹ̀ sin Jèhófà, wàá fi kún àlàáfíà àti ìṣọ̀kan tó wà nínú ìjọ. (Ka Éfésù 4:​2, 3.) Máa lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ìwàásù déédéé. Máa ṣiṣẹ́ sin àwọn míì, kó o sì máa fi inúure hàn sí wọn. Máa fi aájò àlejò hàn sí gbogbo èèyàn, títí kan àwọn tí kò ní àǹfààní iṣẹ́ ìsìn kankan. (Mát. 6:​1-4; Lúùkù 14:​12-14) Tó o bá lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀ lóòótọ́, kì í ṣe àwọn ẹ̀bùn tó o ní nìkan làwọn èèyàn máa rí, wọ́n á tún kíyè sí ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ rẹ.

MÁ GBÉRA Ẹ GA TÓ O BÁ Ń LO ÌKÀNNÌ ÀJỌLÒ

12. Ṣé Jèhófà fẹ́ ká lọ́rẹ̀ẹ́? Ṣàlàyé.

12 Jèhófà fẹ́ ká máa gbádùn ìfararora pẹ̀lú àwọn tá a jọ wà nínú ìdílé àtàwọn ọ̀rẹ́ wa míì. (Sm. 133:1) Jésù náà láwọn ọ̀rẹ́ gidi. (Jòh. 15:15) Bíbélì sọ àǹfààní téèyàn máa ń rí tó bá láwọn ọ̀rẹ́ gidi. (Òwe 17:17; 18:24) Ó tún jẹ́ ká mọ̀ pé kò yẹ ká ya ara wa sọ́tọ̀. (Òwe 18:1) Àwọn kan gbà pé ìkànnì àjọlò máa jẹ́ káwọn ní ọ̀rẹ́ tó pọ̀ káwọn má sì dá wà. Àmọ́ ó yẹ ká ṣọ́ra tá a bá ń lo ìkànnì àjọlò.

13. Kí nìdí táwọn tí ìkànnì àjọlò ti di bárakú fún fi máa ń dá wà tí wọ́n sì máa ń rẹ̀wẹ̀sì?

13 Ìwádìí fi hàn pé àwọn tó máa ń gbé fọ́tò sórí ìkànnì àjọlò ṣáá tí wọ́n sì máa ń lo ọ̀pọ̀ àkókò láti yẹ ohun táwọn míì gbé síbẹ̀ wò máa ń dá wà, wọn kì í sì í láyọ̀. Kí nìdí? Ohun kan ni pé fọ́tò wọn tó dáa jù àtàwọn nǹkan tó jọjú táwọn èèyàn ṣe ni wọ́n máa ń gbé sórí ìkànnì yìí. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n máa ń gbé fọ́tò àwọn ibi tí wọ́n lọ, bí wọ́n ṣe gbádùn ara wọn, fọ́tò àwọn ọ̀rẹ́ wọn àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ sórí ìkànnì náà. Tẹ́nì kan bá jókòó ti àwọn fọ́tò náà, ó lè gbà pé ìgbésí ayé òun ò nítumọ̀ àti pé òun ò já mọ́ nǹkan kan lẹ́gbẹ̀ẹ́ àwọn tó kù. Arábìnrin kan tó jẹ́ ọmọ ọdún mọ́kàndínlógún (19) sọ pé: “Inú mi ò dùn, mo sì bẹ̀rẹ̀ sí í jowú bí mo ṣe ń wo fọ́tò ibi táwọn ọ̀rẹ́ mi ti ń gbádùn ara wọn lópin ọ̀sẹ̀ témi sì dá wà nínú ilé.”

14. Báwo ni ìmọ̀ràn tó wà nínú 1 Pétérù 3:8 ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ tá a bá ń lo ìkànnì àjọlò?

14 Ká sòótọ́, ìkànnì àjọlò wúlò láyè tiẹ̀, bí àpẹẹrẹ ó máa ń jẹ́ kó rọrùn láti kàn sí tẹbí-tọ̀rẹ́. Àmọ́, ǹjẹ́ o ti kíyè sí i pé torí káwọn èèyàn lè máa kan sáárá sí wọn làwọn kan ṣe ń gbé fọ́tò, fídíò àtàwọn nǹkan míì sórí ìkànnì? Ṣe ló dà bí ìgbà tí wọ́n ń sọ pé “Ẹ wò mí kẹ́ ẹ tún mi wò.” Àwọn kan máa ń sọ ọ̀rọ̀ àrífín àtàwọn ọ̀rọ̀ rírùn nípa fọ́tò wọn àtèyí táwọn míì gbé síbẹ̀. Torí pé àwa Kristẹni lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀, a sì máa ń gba tàwọn míì rò, a kì í sọ ọ̀rọ̀ tí kò bójú mu nípa àwọn míì.​—Ka 1 Pétérù 3:8.

Kí làwọn nǹkan tó ò ń gbé sórí ìkànnì ń fi hàn nípa ẹ? Ṣé ó fi hàn pé agbéraga ni ẹ́ tàbí onírẹ̀lẹ̀? (Wo ìpínrọ̀ 15)

15. Ìmọ̀ràn Bíbélì wo ni kò ní jẹ́ ká máa gbé ara wa ga?

15 Tó o bá ń lo ìkànnì àjọlò, ó yẹ kó o bi ara ẹ pé: ‘Ṣé àwọn ọ̀rọ̀, fọ́tò tàbí àwọn fídíò tí mò ń gbé síbẹ̀ fi hàn pé mò ń gbéra ga tàbí fọ́nnu? Ṣé àwọn míì kò ní máa jowú tí wọ́n bá rí àwọn nǹkan tí mo gbé síbẹ̀?’ Bíbélì sọ pé: “Gbogbo ohun tó wà nínú ayé​—ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara, ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ojú àti fífi ohun ìní ẹni ṣe àṣehàn​—kò wá látọ̀dọ̀ Baba, àmọ́ ó wá látọ̀dọ̀ ayé.” (1 Jòh. 2:16) Ìtumọ̀ Bíbélì kan sọ pé “fífi ohun ìní ẹni ṣe àṣehàn” túmọ̀ sí “kéèyàn fẹ́ káwọn míì ka òun sí pàtàkì.” Bẹ́ẹ̀ sì rèé, àwa Kristẹni ò fẹ́ káwọn èèyàn máa gbé wa gẹ̀gẹ̀. A máa ń fi ìmọ̀ràn Bíbélì yìí sọ́kàn pé: “Ẹ má ṣe jẹ́ kí a di agbéraga, kí a má ṣe máa bá ara wa díje, kí a má sì máa jowú ara wa.” (Gál. 5:26) Tá a bá lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀, a ò ní máa ṣe bíi tàwọn èèyàn ayé tí wọ́n ń gbéra ga tí wọ́n sì ń fẹ́ káwọn míì máa gbé wọn gẹ̀gẹ̀.

“MÁA RONÚ LỌ́NÀ TÓ FI HÀN PÉ O LÁRÒJINLẸ̀”

16. Kí nìdí tí kò fi yẹ ká máa gbéra ga?

16 Ó yẹ ká lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀ torí pé àwọn agbéraga ò “láròjinlẹ̀.” (Róòmù 12:3) Àwọn agbéraga máa ń fọ́nnu, wọ́n sì máa ń bá àwọn míì díje. Ìrònú wọn àti ìwà wọn máa ń mú kí wọ́n ṣàkóbá fún ara wọn àtàwọn míì. Tí wọn ò bá yí pa dà, Sátánì máa fọ́ ojú inú wọn, á sì sọ wọ́n dìbàjẹ́. (2 Kọ́r. 4:4; 11:3) Àmọ́ onírẹ̀lẹ̀ èèyàn máa ń ní àròjinlẹ̀. Kì í ro ara ẹ̀ pin, bẹ́ẹ̀ sì ni kì í ro ara ẹ̀ ju bó ṣe yẹ lọ torí ó mọ̀ pé àwọn míì sàn ju òun lọ lónírúurú ọ̀nà. (Fílí. 2:3) Bákan náà, ó mọ̀ pé “Ọlọ́run dojú ìjà kọ àwọn agbéraga, àmọ́ ó ń fi inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí hàn sí àwọn onírẹ̀lẹ̀.” (1 Pét. 5:5) Àwọn tó láròjinlẹ̀ ò ní fẹ́ ṣe ohunkóhun tó máa sọ wọ́n di ọ̀tá Jèhófà.

17. Kí ló yẹ ká ṣe tá ò bá fẹ́ di agbéraga?

17 Tá ò bá fẹ́ di agbéraga, a gbọ́dọ̀ fi ìmọ̀ràn Bíbélì sílò tó ní ká “bọ́ ìwà àtijọ́ sílẹ̀ pẹ̀lú àwọn àṣà rẹ̀, [ká] sì fi ìwà tuntun wọ ara [wa] láṣọ.” Ìyẹn ò rọrùn, àmọ́ á ṣeé ṣe tá a bá ń fara balẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jésù tá a sì ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ̀. (Kól. 3:​9, 10; 1 Pét. 2:21) Bó ti wù kó rí, ìsapá wa tó bẹ́ẹ̀ ó jù bẹ́ẹ̀ lọ. Tá a bá ń fẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ ṣe nǹkan, ìdílé wa á túbọ̀ láyọ̀, àlàáfíà àti ìṣọ̀kan á gbilẹ̀ nínú ètò Ọlọ́run, a ò sì ní máa lo ìkànnì àjọlò nílòkulò. Ju gbogbo ẹ̀ lọ, àá rí ìbùkún àti ojúure Jèhófà.

ORIN 117 Ìwà Rere

^ ìpínrọ̀ 5 Àwọn agbéraga àti onímọtara-ẹni-nìkan ló kúnnú ayé lónìí. A gbọ́dọ̀ ṣọ́ra kí wọ́n má bàa kéèràn ràn wá. Torí náà nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa jíròrò bá ò ṣe ní máa ro ara wa ju bó ṣe yẹ lọ nínú ìgbéyàwó wa, nínú ètò Ọlọ́run àti nígbà tá a bá ń lo ìkànnì àjọlò.

^ ìpínrọ̀ 2 ÀLÀYÉ Ọ̀RỌ̀: Agbéraga èèyàn máa ń ro ara rẹ̀ ju bó ṣe yẹ lọ, ó sì máa ń fojú pa àwọn míì rẹ́. Torí náà, onímọtara-ẹni-nìkan ni. Lọ́wọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ máa ń jẹ́ ká gba tàwọn míì rò. Ẹni tó lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀ kì í gbéra ga, bẹ́ẹ̀ sì ni kì í jọra ẹ̀ lójú.

^ ìpínrọ̀ 56 ÀWÒRÁN: Alàgbà kan tó máa ń sọ àsọyé ní àpéjọ agbègbè tó sì tún jẹ́ alábòójútó láwọn ẹ̀ka míì nínú ètò Ọlọ́run mọ bó ti ṣe pàtàkì tó pé kóun máa lọ sóde ẹ̀rí, kóun sì máa tún Gbọ̀ngàn Ìjọba ṣe.