ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 25
“Èmi Fúnra Mi Yóò Wá Àwọn Àgùntàn Mi”
“Èmi fúnra mi yóò wá àwọn àgùntàn mi, màá sì bójú tó wọn.”—ÌSÍK. 34:11.
ORIN 105 “Ọlọ́run Jẹ́ Ìfẹ́”
OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒ *
1. Kí nìdí tí Jèhófà fi fara ẹ̀ wé abiyamọ?
“ṢÉ OBÌNRIN lè gbàgbé ọmọ rẹ̀ tó ṣì ń mu ọmú?” Ìbéèrè pàtàkì yìí ni Jèhófà béèrè nígbà ayé wòlíì Àìsáyà. Jèhófà wá sọ pé: “Tí àwọn obìnrin yìí bá tiẹ̀ gbàgbé, mi ò jẹ́ gbàgbé rẹ láé.” (Àìsá. 49:15) Jèhófà kì í sábà fi ara ẹ̀ wé abiyamọ, àmọ́ ó ṣe bẹ́ẹ̀ nínú ẹsẹ yìí. Jèhófà lo ìfẹ́ tí abiyamọ kan máa ń ní sí ọmọ rẹ̀ láti ṣàpèjúwe ìfẹ́ tóun ní sáwọn ìránṣẹ́ òun. Ọ̀pọ̀ abiyamọ ló máa gbà pé òótọ́ ni arábìnrin kan tó ń jẹ́ Jasmin sọ, pé: “Téèyàn bá ń tọ́mọ lọ́wọ́, èèyàn máa ń nífẹ̀ẹ́ ọmọ náà, ìfẹ́ yìí sì máa ń lágbára gan-an.”
2. Báwo ló ṣe máa ń rí lára Jèhófà tí ìránṣẹ́ rẹ̀ èyíkéyìí bá rẹ̀wẹ̀sì, tó sì fi í sílẹ̀?
2 Jèhófà máa ń kíyè sí i tí ọ̀kan lára àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ bá pa ìpàdé tì, tí kò sì lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ìwàásù mọ́. Ẹ wá wo bó ṣe máa dùn ún tó bó ṣe ń rí i tí ọ̀pọ̀ ìránṣẹ́ rẹ̀ ń dí aláìṣiṣẹ́mọ́ * lọ́dọọdún.
3. Kí ni Jèhófà fẹ́ káwọn ará wa yìí ṣe?
3 Ọ̀pọ̀ àwọn ará wa yìí ló ti pa dà sínú ìjọ, kódà wọ́n ń ṣe dáadáa, inú wa sì ń dùn sí wọn! Ó wu Jèhófà pé kí gbogbo wọn pa dà sọ́dọ̀ òun, ohun táwa náà sì fẹ́ nìyẹn. (1 Pét. 2:25) Kí la lè ṣe láti ràn wọ́n lọ́wọ́? Ká tó dáhùn ìbéèrè yìí, ẹ jẹ́ ká kọ́kọ́ sọ̀rọ̀ lórí ìdí táwọn kan fi pa ìpàdé tì, tí wọn ò sì lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ìwàásù mọ́.
KÍ NÌDÍ TÁWỌN KAN FI FÀ SẸ́YÌN?
4. Báwo ni ọ̀rọ̀ àtijẹ àtimu ṣe mú káwọn kan fà sẹ́yìn?
4 Ọ̀rọ̀ àtijẹ àtimu ló gba àwọn kan lọ́kàn. Arákùnrin Hung * tó ń gbé nílẹ̀ Éṣíà sọ pé: “Mo jẹ́ kí ọ̀rọ̀ àtijẹ àtimu gbà mí lọ́kàn ju bó ti yẹ lọ. Èrò mi ni pé tí mo bá rí towó ṣe, á rọrùn fún mi láti sin Jèhófà dáadáa. Ìyẹn ló mú kí n máa forí ṣe fọrùn ṣe débi pé mo bẹ̀rẹ̀ sí í pa ìpàdé jẹ. Nígbà tó yá, mi ò tiẹ̀ lọ ìpàdé mọ́, mi ò sì lọ sóde ẹ̀rí mọ́. Ó jọ pé ṣe ni Sátánì ń lo ayé yìí láti mú káwọn èèyàn máa jìnnà sí Jèhófà díẹ̀díẹ̀ títí táá fi mú kí wọ́n fi Jèhófà sílẹ̀ pátápátá.”
5. Báwo làwọn ìṣòro tó ń rọ́ lura ṣe mú kí arábìnrin kan fà sẹ́yìn?
5 Ìṣòro táwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin kan ní ló mú kí wọ́n fà sẹ́yìn. Àpẹẹrẹ kan ni ti arábìnrin kan tó ń gbé nílẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, Anne lorúkọ ẹ̀, ọmọ márùn-ún ló sì ní. Ó sọ pé: “Abirùn ni ọ̀kan lára àwọn ọmọkùnrin mi, nígbà tó yá wọ́n yọ ọmọbìnrin mi kan lẹ́gbẹ́, èyí ọkùnrin kejì sì ní àrùn ọpọlọ. Ọ̀rọ̀ yìí kó ẹ̀dùn ọkàn bá mi débi pé mo bẹ̀rẹ̀ sí í pa ìpàdé jẹ, mi ò sì kì í ṣe déédéé lóde ẹ̀rí mọ́. Nígbẹ̀yìngbẹ́yín, mo di aláìṣiṣẹ́mọ́.” Ó dùn wá gan-an pé irú nǹkan yìí ṣẹlẹ̀ sí Arábìnrin Anne àti ìdílé rẹ̀, a sì bá àwọn míì tó láwọn ìṣòro bí èyí kẹ́dùn gan-an!
6. Báwo lẹnì kan ṣe lè fà sẹ́yìn torí pé kò fi ìlànà inú Kólósè 3:13 sílò?
6 Ka Kólósè 3:13. Ohun tẹ́nì kan ṣe ló mú káwọn míì fà sẹ́yìn nínú ìjọ. Kódà, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù gbà pé ó ṣeé ṣe kí ẹnì kan ní “ìdí láti fẹ̀sùn kan” ẹlòmíì nínú ìjọ. Bí àpẹẹrẹ, ẹnì kan lè rẹ́ wa jẹ. Tá ò bá sì kíyè sára, a lè di irú ẹni bẹ́ẹ̀ sínú, kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀ àá bẹ̀rẹ̀ sí í yẹra fáwọn ará. Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Arákùnrin Pablo tó ń gbé ní South America nìyẹn. Wọ́n parọ́ mọ́ ọn pé ó hùwà àìtọ́, ìyẹn sì mú kó pàdánù àǹfààní iṣẹ́ ìsìn tó ní. Báwo lọ̀rọ̀ náà ṣe rí lára rẹ̀? Arákùnrin Pablo sọ pé: “Inú bí mi burúkú burúkú ni mo bá bẹ̀rẹ̀ sí í pa ìpàdé jẹ. Kí n tó mọ̀, mi ò lọ sípàdé mọ́.”
7. Kí ló lè ṣẹlẹ̀ tí ẹ̀rí ọkàn bá ń da ẹnì kan láàmú?
7 Ẹ̀rí ọkàn lè máa da ẹnì kan láàmú torí pé ó rú òfin Ọlọ́run nígbà kan rí, ó sì lè ronú pé Ọlọ́run ò lè nífẹ̀ẹ́ òun mọ́. Kódà lẹ́yìn tó ti ronú pìwà dà tí wọ́n sì fàánú hàn sí i, ó ṣì lè máa ronú pé òun ò yẹ lẹ́ni tó ń sin Jèhófà. Bó ṣe rí lára arákùnrin kan tó ń jẹ́ Francisco nìyẹn. Ó sọ pé: “Wọ́n bá mi wí torí pé mo ṣèṣekúṣe. Níbẹ̀rẹ̀, mo máa ń lọ sípàdé déédéé, àmọ́ nígbà tó yá ìrẹ̀wẹ̀sì bá mi, mo sì gbà pé mi ò yẹ lẹ́ni tó ń sin Jèhófà. Ẹ̀rí ọkàn mi ń dà mí láàmú, ó wá ń ṣe mí bíi pé Jèhófà ò tíì dárí jì mí. Bó ṣe di pé mi ò lọ sípàdé mọ́ nìyẹn tí mi ò sì lọ sóde ẹ̀rí mọ́.” Báwo lọ̀rọ̀ àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin tá a sọ̀rọ̀ wọn yìí ṣe rí lára rẹ? Ó dájú pé ohun tó ṣẹlẹ̀ sí wọn dùn ẹ́, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́? Báwo lo ṣe rò pé ó máa rí lára Jèhófà?
JÈHÓFÀ NÍFẸ̀Ẹ́ ÀWỌN ÀGÙNTÀN RẸ̀
8. Ṣé Jèhófà máa ń gbàgbé àwọn tó ti fìgbà kan jọ́sìn rẹ̀ àmọ́ tí wọ́n ṣáko lọ? Ṣàlàyé.
8 Jèhófà kì í gbàgbé àwọn tó ti fìgbà kan rí ṣe dáadáa tí wọ́n wá fà sẹ́yìn nígbà tó yá. Yàtọ̀ síyẹn, kò gbàgbé ohun tí wọ́n ṣe nínú ìjọsìn rẹ̀. (Héb. 6:10) Wòlíì Àìsáyà lo àpèjúwe kan láti jẹ́ ká mọ bí Jèhófà ṣe nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn rẹ̀ tó. Ó ní: “Ó máa bójú tó agbo ẹran rẹ̀ bíi ti olùṣọ́ àgùntàn. Ó máa fi apá rẹ̀ kó àwọn ọ̀dọ́ àgùntàn jọ, ó sì máa gbé wọn sí àyà rẹ̀.” (Àìsá. 40:11) Báwo ló ṣe máa ń rí lára Jèhófà tó jẹ́ Olùṣọ́ Àgùntàn Ńlá nígbà tí ọ̀kan lára àgùntàn rẹ̀ bá ṣáko lọ? Jésù jẹ́ ká mọ bó ṣe máa ń rí lára Jèhófà nígbà tó bi àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Kí lèrò yín? Tí ọkùnrin kan bá ní ọgọ́rùn-ún (100) àgùntàn, tí ọ̀kan nínú wọn sì sọ nù, ṣebí ó máa fi mọ́kàndínlọ́gọ́rùn-ún (99) yòókù sílẹ̀ lórí òkè ni, kó sì bẹ̀rẹ̀ sí í wá èyí tó sọ nù? Tó bá sì rí i, mò ń sọ fún yín, ó dájú pé ó máa yọ̀ gidigidi torí rẹ̀ ju mọ́kàndínlọ́gọ́rùn-ún (99) tí kò tíì sọ nù.”—Mát. 18:12, 13.
9. Láyé àtijọ́, ọwọ́ wo làwọn olùṣọ́ àgùntàn tó mọṣẹ́ wọn níṣẹ́ fi máa ń mú àwọn àgùntàn wọn? (Wo àwòrán iwájú ìwé.)
9 Kí nìdí tá a fi lè fi Jèhófà wé olùṣọ́ àgùntàn? Ìdí ni pé láyé àtijọ́, àwọn olùṣọ́ àgùntàn tó mọṣẹ́ wọn níṣẹ́ máa ń bójú tó àwọn àgùntàn wọn dáadáa. Bí àpẹẹrẹ, Dáfídì bá kìnnìún àti bíárì jà kó lè dáàbò bo àwọn àgùntàn rẹ̀. (1 Sám. 17:34, 35) Olùṣọ́ àgùntàn tó nífẹ̀ẹ́ àwọn àgùntàn rẹ̀ máa ń wà lójú fò, ó sì máa ń mọ̀ bí ọ̀kan lára àgùntàn rẹ̀ bá sọ nù. (Jòh. 10:3, 14) Irú olùṣọ́ àgùntàn bẹ́ẹ̀ máa fi àgùntàn mọ́kàndínlọ́gọ́rùn-ún (99) yòókù sílẹ̀ sínú ọgbà tàbí kó ní kí olùṣọ́ àgùntàn míì máa bá òun bójú tó wọn kóun lè lọ wá ẹyọ kan tó sọ nù. Jésù lo àpèjúwe yìí ká lè lóye ẹ̀kọ́ pàtàkì kan pé: “Kò wu Baba mi tó wà ní ọ̀run pé kí ọ̀kan péré nínú àwọn ẹni kékeré yìí ṣègbé.”—Mát. 18:14.
JÈHÓFÀ MÁA Ń WÁ ÀWỌN ÀGÙNTÀN RẸ̀
10. Bó ṣe wà nínú Ìsíkíẹ́lì 34:11-16, kí ni Jèhófà sọ pé òun máa ṣe fáwọn àgùntàn tó sọ nù?
10 Gbogbo wa ni Jèhófà nífẹ̀ẹ́ títí kan àwọn tí Bíbélì pè ní “àwọn ẹni kékeré” tó ti ṣáko lọ. Jèhófà gba ẹnu wòlíì Ìsíkíẹ́lì sọ pé òun máa wá àwọn àgùntàn òun tó sọ nù, òun á sì mú wọn pa dà sínú agbo. Ó tún sọ àwọn ìgbésẹ̀ tó máa gbé láti mú Ìsíkíẹ́lì 34:11-16.) Lákọ̀ọ́kọ́, olùṣọ́ àgùntàn yìí máa wá àgùntàn náà lọ, ìyẹn sì máa ń gba ọ̀pọ̀ àkókò àti ìsapá. Tó bá ti rí i, á gbé e pa dà sínú agbo. Tí àgùntàn náà bá ṣèṣe, á tọ́jú rẹ̀, tí ebi bá ń pa á, á gbé e mọ́ra, á sì fún un lóúnjẹ. Ìgbésẹ̀ yìí kan náà ló yẹ kí ẹ̀yin alàgbà tẹ́ ẹ jẹ́ olùṣọ́ àgùntàn “agbo Ọlọ́run” máa gbé kẹ́ ẹ lè ṣèrànwọ́ fún gbogbo àwọn tó ti ṣáko lọ. (1 Pét. 5:2, 3) Ẹ wá wọn lọ, ẹ ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wọ́n lè pa dà sínú ìjọ, kẹ́ ẹ sì fìfẹ́ bójú tó wọn nípa tẹ̀mí. *
wọn pa dà sínú agbo, àwọn ìgbésẹ̀ yìí kan náà ni olùṣọ́ àgùntàn kan ní Ísírẹ́lì máa gbé tí àgùntàn rẹ̀ bá sọ nù. (Ka11. Kí ni olùṣọ́ àgùntàn mọ̀ pé ó lè ṣẹlẹ̀?
11 Olùṣọ́ àgùntàn tó mọṣẹ́ rẹ̀ níṣẹ́ mọ̀ pé àgùntàn lè sọ nù. Tí àgùntàn kan bá sì ṣáko lọ, olùṣọ́ àgùntàn náà kò ní lù ú. Àpẹẹrẹ àtàtà ni Jèhófà fi lélẹ̀ lórí ọ̀rọ̀ yìí. Ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa ohun tó ṣe nígbà táwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ kan láyé àtijọ́ rẹ̀wẹ̀sì.
12. Báwo ni Jèhófà ṣe ran Jónà lọ́wọ́?
12 Wòlíì Jónà ò lọ síbi tí Jèhófà rán an lọ. Síbẹ̀, Jèhófà ò jẹ́ kí ọ̀rọ̀ rẹ̀ sú òun. Torí pé olùṣọ́ àgùntàn tó nífẹ̀ẹ́ àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ ni Jèhófà, ó dá Jónà nídè, ó sì fún un lókun tó mú kó lè ṣiṣẹ́ tó gbé fún un. (Jónà 2:7; 3:1, 2) Nígbà tó yá, Jèhófà lo ewéko akèrègbè kan láti kọ́ Jónà lẹ́kọ̀ọ́ kó lè mọ̀ pé ẹ̀mí èèyàn ṣe pàtàkì. (Jónà 4:10, 11) Kí la rí kọ́? Ẹ̀yin alàgbà ò gbọ́dọ̀ jẹ́ kí ọ̀rọ̀ àwọn tó ṣáko lọ sú yín. Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ni kẹ́ ẹ sapá láti lóye ohun tó mú kí wọ́n kúrò nínú agbo. Tí wọ́n bá sì ti pa dà sọ́dọ̀ Jèhófà, ẹ máa fìfẹ́ hàn sí wọn, kẹ́ ẹ sì jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé ọ̀rọ̀ wọn jẹ yín lógún.
13. Kí la rí kọ́ látinú ojú tí Jèhófà fi wo ẹni tó kọ Sáàmù 73?
13 Ìrẹ̀wẹ̀sì bá ẹni tó kọ Sáàmù 73 nígbà tó rí bí àwọn ẹni burúkú ṣe ń gbádùn. Ìyẹn mú kó bẹ̀rẹ̀ sí i ronú pé ṣé àǹfààní kankan tiẹ̀ wà nínú kéèyàn máa sin Ọlọ́run. (Sm. 73:12, 13, 16) Kí ni Jèhófà wá ṣe? Kò dá a lẹ́bi. Kódà, ṣe ni Jèhófà jẹ́ kí ọ̀rọ̀ ẹ̀ wà lákọọ́lẹ̀ nínú Bíbélì. Nígbẹ̀yìngbẹ́yín, onísáàmù náà wá rí i pé kò sóhun tó dà bíi kéèyàn jẹ́ ọ̀rẹ́ Jèhófà. (Sm. 73:23, 24, 26, 28) Kí la rí kọ́? Ó ṣeé ṣe káwọn kan nínú ìjọ máa ṣiyèméjì pé bóyá làǹfààní wà nínú báwọn ṣe ń sin Jèhófà. Tó bá rí bẹ́ẹ̀, ẹ̀yin alàgbà ò gbọ́dọ̀ dá wọn lẹ́bi tàbí kẹ́ ẹ pa wọ́n tì. Dípò bẹ́ẹ̀, ṣe ni kẹ́ ẹ sapá láti mọ ìdí tí wọ́n fi ń ṣiyèméjì. Ìgbà yẹn lẹ tó lè mọ ẹsẹ Ìwé Mímọ́ táá ràn wọ́n lọ́wọ́ táá sì fún wọn níṣìírí.
14. Kí ló ṣẹlẹ̀ sí Èlíjà, báwo sì ni Jèhófà ṣe ràn án lọ́wọ́?
14 Wòlíì Èlíjà sá lọ nítorí Ayaba Jésíbẹ́lì. (1 Ọba 19:1-3) Ó ronú pé kò sí wòlíì Jèhófà kankan mọ́ nílẹ̀ Ísírẹ́lì àti pé asán ni gbogbo iṣẹ́ tóun ṣe. Ẹ̀dùn ọkàn bá Èlíjà débi tó fi gbàdúrà pé kóun kú. (1 Ọba 19:4, 10) Jèhófà ò dá Èlíjà lẹ́bi, kàkà bẹ́ẹ̀ ṣe ló fi dá a lójú pé òun nìkan kọ́ ló ń sin Jèhófà nílẹ̀ Ísírẹ́lì, pé àwọn míì ṣì wà. Yàtọ̀ síyẹn, ó sọ fún un pé òun máa tì í lẹ́yìn àti pé iṣẹ́ ṣì pọ̀ fún un láti ṣe. Jèhófà tẹ́tí sí gbogbo ohun tí Èlíjà sọ, ó sì gbé iṣẹ́ míì fún un. (1 Ọba 19:11-16, 18) Kí la rí kọ́? Gbogbo wa, ní pàtàkì àwọn alàgbà ló yẹ kó máa fìfẹ́ hàn sáwọn àgùntàn Jèhófà. Ohun yòówù kẹ́nì kan sọ tàbí ṣe, kódà tó bá tiẹ̀ sọ pé Jèhófà kò lè dárí ji òun, tàbí kẹ̀ tí inú ń bí i, ó yẹ kẹ́yin alàgbà fara balẹ̀ tẹ́tí sí i. Lẹ́yìn náà, kẹ́ ẹ fi dá a lójú pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ gan-an, ó sì mọyì rẹ̀.
OJÚ WO LÓ YẸ KÁ FI MÁA WO ÀWỌN ÀGÙNTÀN JÈHÓFÀ TÓ ṢÁKO LỌ?
15. Bó ṣe wà nínú Jòhánù 6:39, ọwọ́ wo ni Jésù fi mú àwọn àgùntàn Jèhófà?
15 Ọwọ́ wo ni Jèhófà fẹ́ ká fi mú àwọn àgùntàn òun tó ṣáko lọ? A lè kẹ́kọ̀ọ́ látinú ohun tí Jésù ṣe. Ó mọ̀ pé gbogbo àgùntàn Jèhófà ló ṣeyebíye lójú rẹ̀, ìdí nìyẹn tó fi ṣe gbogbo ohun tó lè ṣe kí “àwọn àgùntàn ilé Ísírẹ́lì tó sọ nù” lè pa dà sọ́dọ̀ Jèhófà. (Mát. 15:24; Lúùkù 19:9, 10) Torí pé olùṣọ́ àgùntàn àtàtà ni Jésù, ó tún ṣe gbogbo ohun tó lè ṣe kí èyíkéyìí lára àgùntàn Jèhófà má bàa sọ nù.—Ka Jòhánù 6:39.
16-17. Ojú wo ló yẹ kẹ́yin alàgbà fi máa wo àwọn àgùntàn Jèhófà tó ṣáko lọ? (Wo àpótí náà “ Bí Nǹkan Ṣe Máa Ń Rí Lára Àwọn Àgùntàn Tó Sọ Nù.”)
16 Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù gba àwọn alàgbà ìjọ Éfésù níyànjú pé kí wọ́n fara wé ọwọ́ tí Jésù fi mú agbo, ó ní: “Ẹ gbọ́dọ̀ ṣèrànwọ́ fún àwọn tó jẹ́ aláìlera, ẹ sì gbọ́dọ̀ fi àwọn ọ̀rọ̀ Jésù Olúwa sọ́kàn, nígbà tí òun fúnra rẹ̀ sọ pé: ‘Ayọ̀ púpọ̀ wà nínú fífúnni ju èyí tó wà nínú rírígbà lọ.’ ” (Ìṣe 20:17, 35) Kò sí àní-àní pé iṣẹ́ ńlá làwọn alàgbà ní bí ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí ṣe sọ. Alàgbà kan tó ń jẹ́ Salvador láti orílẹ̀-èdè Sípéènì sọ pé: “Tí n bá ronú lórí bó ṣe máa ń rí lára Jèhófà tí àgùntàn rẹ̀ bá sọ nù àti bó ṣe máa ń ràn wọ́n lọ́wọ́, ó máa ń wu èmi náà láti ṣe gbogbo ohun tí mo lè ṣe kí n lè ràn wọ́n lọ́wọ́. Mo mọ̀ pé Jèhófà fẹ́ kí n ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wọ́n lè pa dà sínú agbo.”
17 Gbogbo àwọn tá a mẹ́nu kàn nínú àpilẹ̀kọ yìí ni wọ́n ràn lọ́wọ́, tí wọ́n sì pa dà sọ́dọ̀ Jèhófà. Ó dá wa lójú pé ọ̀pọ̀ àwọn míì ló ṣì wà tó fẹ́ pa dà sínú ìjọ. Torí náà nínú àpilẹ̀kọ tó kàn, a máa túbọ̀ jíròrò bá a ṣe lè ràn wọ́n lọ́wọ́ láti pa dà sọ́dọ̀ Jèhófà.
ORIN 139 Fojú Inú Wo Ìgbà Tí Gbogbo Nǹkan Máa Di Tuntun
^ ìpínrọ̀ 5 Àwọn kan tí wọ́n ti ń fòótọ́ ọkàn sin Jèhófà fún ọ̀pọ̀ ọdún ti ń rẹ̀wẹ̀sì báyìí, kódà àwọn míì ti fi ètò Ọlọ́run sílẹ̀. Kí ló fà á? Báwo lọ̀rọ̀ wọn ṣe rí lára Jèhófà? A máa dáhùn àwọn ìbéèrè yìí nínú àpilẹ̀kọ yìí. A tún máa sọ̀rọ̀ nípa bí Jèhófà ṣe ran àwọn olóòótọ́ kan lọ́wọ́ láyé àtijọ́ nígbà tí wọ́n rẹ̀wẹ̀sì, àá sì rí ohun tíyẹn kọ́ wa.
^ ìpínrọ̀ 2 ÀLÀYÉ Ọ̀RỌ̀: Aláìṣiṣẹ́mọ́ ni akéde kan tí kò lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ìwàásù àti sísọni di ọmọ ẹ̀yìn fún odindi oṣù mẹ́fà tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ. Síbẹ̀, arákùnrin àti arábìnrin wa làwọn akéde yìí, a sì nífẹ̀ẹ́ wọn gan-an.
^ ìpínrọ̀ 4 A ti yí orúkọ rẹ̀ pa dà.
^ ìpínrọ̀ 10 Nínú àpilẹ̀kọ tó kàn, a máa jíròrò bí ẹ̀yin alàgbà ṣe lè gbé àwọn ìgbésẹ̀ mẹ́ta yìí.
^ ìpínrọ̀ 60 ÀWÒRÁN: Olùṣọ́ àgùntàn kan nílẹ̀ Ísírẹ́lì ń wá àgùntàn rẹ̀ tó sọ nù, nígbà tó rí i, ó gbé e pa dà sínú agbo. Ohun táwọn alàgbà náà ń ṣe lónìí nìyẹn.
^ ìpínrọ̀ 64 ÀWÒRÁN: Arábìnrin kan tó jẹ́ aláìṣiṣẹ́mọ́ rí àwọn Ẹlẹ́rìí méjì tí wọ́n ń fayọ̀ wàásù fún ọkùnrin kan nídìí ìpàtẹ ìwé.