Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
Ṣé àwọn ànímọ́ mẹ́sàn-án tó wà nínú Gálátíà 5:22, 23 nìkan ni “èso ti ẹ̀mí”?
Ànímọ́ mẹ́sàn-án péré ni ẹsẹ Bíbélì yẹn sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀, ó ní: “Èso ti ẹ̀mí ni ìfẹ́, ayọ̀, àlàáfíà, sùúrù, inú rere, ìwà rere, ìgbàgbọ́, ìwà tútù, ìkóra-ẹni-níjàánu.” Àmọ́ kò yẹ ká wá ronú pé àwọn ànímọ́ yìí nìkan ni ẹ̀mí Ọlọ́run lè mú ká ní.
Ẹ kíyè sí ohun tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ ní ẹsẹ tó ṣáájú pé: “Àwọn iṣẹ́ ti ara . . . ni ìṣekúṣe, ìwà àìmọ́, ìwà àìnítìjú, ìbọ̀rìṣà, ìbẹ́mìílò, ìkórìíra, wàhálà, owú, inú fùfù, awuyewuye, ìpínyà, ẹ̀ya ìsìn, ìlara, ìmutíyó, àwọn àríyá aláriwo, àti irú àwọn nǹkan yìí.” (Gál. 5:19-21) Gbólóhùn tí Pọ́ọ̀lù sọ kẹ́yìn yìí fi hàn pé àwọn nǹkan míì wà tó jẹ́ “iṣẹ́ ti ara” bó ṣe wà nínú Kólósè 3:5. Bákan náà, lẹ́yìn tó mẹ́nu kan àwọn ànímọ́ mẹ́sàn-án tó para pọ̀ jẹ́ èso tẹ̀mí, ó sọ pé: “Kò sí òfin kankan tó lòdì sí irú àwọn nǹkan yìí.” Torí náà, kì í ṣe gbogbo ànímọ́ dáadáa tí ẹ̀mí Ọlọ́run lè mú ká ní ni Pọ́ọ̀lù mẹ́nu bà.
Kókó yìí túbọ̀ ṣe kedere tá a bá fi wé ohun tí Pọ́ọ̀lù sọ nínú lẹ́tà rẹ̀ sáwọn ará Éfésù, ó ní: “Oríṣiríṣi ohun rere àti òdodo àti òtítọ́ ló jẹ́ èso ìmọ́lẹ̀.” (Éfé. 5:8, 9) Àbí ẹ ò rí nǹkan, bí “ohun rere” tàbí ìwà rere, òdodo àti òtítọ́ ṣe jẹ́ apá kan “èso ìmọ́lẹ̀” náà ló jẹ́ apá kan “èso ti ẹ̀mí.”
Bákan náà, Pọ́ọ̀lù rọ Tímótì pé kó “máa wá òdodo, ìfọkànsin Ọlọ́run, ìgbàgbọ́, ìfẹ́, ìfaradà àti ìwà tútù.” (1 Tím. 6:11) Nínú àwọn ànímọ́ mẹ́fà tí Pọ́ọ̀lù mẹ́nu bà yìí, mẹ́ta péré (ìyẹn ìgbàgbọ́, ìfẹ́ àti ìwà tútù) ló jẹ́ apá kan “èso ti ẹ̀mí.” Ó dájú pé Tímótì máa nílò kí ẹ̀mí Ọlọ́run ràn án lọ́wọ́ kó lè ní àwọn ànímọ́ mẹ́ta tó kù náà, ìyẹn òdodo, ìfọkànsin Ọlọ́run àti ìfaradà.—Fi wé Kólósè 3:12; 2 Pétérù 1:5-7.
Torí náà, kì í ṣe àwọn ànímọ́ tó wà nínú Gálátíà 5:22, 23 nìkan ló yẹ kí Kristẹni ní. Kò sí àní-àní pé ẹ̀mí Ọlọ́run lè ràn wá lọ́wọ́ láti ní àwọn ànímọ́ mẹ́sàn-án tó para pọ̀ jẹ́ “èso ti ẹ̀mí.” Àmọ́ àwọn ànímọ́ míì wà tó yẹ ká ní bá a ṣe ń dàgbà nípa tẹ̀mí ká lè “gbé ìwà tuntun wọ̀, èyí tí a dá gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ Ọlọ́run nínú òdodo tòótọ́ àti ìdúróṣinṣin.”—Éfé. 4:24.