ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 23
“Kí Orúkọ Rẹ Di Mímọ́”
“Jèhófà, orúkọ rẹ wà títí láé.”—SM. 135:13.
ORIN 10 Ẹ Yin Jèhófà Ọlọ́run Wa!
OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒ *
1-2. Àwọn nǹkan wo ló ṣe pàtàkì gan-an sáwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà?
OHUN méjì kan wà tó ṣe pàtàkì gan-an sí wa lónìí, ìyẹn ni bí Jèhófà ṣe máa fi hàn pé òun ni Ọba Aláṣẹ Ayé Àtọ̀run àti bó ṣe máa dá orúkọ rẹ̀ láre. Ó máa ń yá àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà lára láti sọ̀rọ̀ nípa kókó yìí. Àmọ́, bí Jèhófà ṣe máa fi hàn pé òun ni Ọba Aláṣẹ Ayé Àtọ̀run àti bó ṣe máa sọ orúkọ rẹ̀ di mímọ́ jọra. Torí náà, a ò lè sọ̀rọ̀ ọ̀kan ká fi èkejì sílẹ̀.
2 Gbogbo wa pátá la gbà pé ó yẹ kí Jèhófà mú ẹ̀gàn kúrò lórí orúkọ rẹ̀. A sì ti kẹ́kọ̀ọ́ pé Jèhófà gbọ́dọ̀ fi hàn pé ìṣàkóso òun ló dára jù lọ. Kò sí àní-àní pé àwọn nǹkan yìí ṣe pàtàkì gan-an.
3. Kí ni orúkọ náà Jèhófà wé mọ́?
3 Ká sòótọ́, orúkọ náà Jèhófà kan Ẹni tó ń jẹ́ orúkọ yẹn títí kan bó ṣe ń ṣàkóso. Torí náà, tá a bá sọ pé ọ̀rọ̀ tó ṣe pàtàkì jù ni bí Jèhófà ṣe máa mú ẹ̀gàn kúrò lórí orúkọ rẹ̀, ohun tá a tún ń sọ ni pé á jẹ́ kí aráyé mọ̀ pé ìṣàkóso òun ló dára jù lọ. Ìyẹn fi hàn pé kò sí bá a ṣe lè sọ̀rọ̀ nípa orúkọ Jèhófà tá ò ní ronú kan bó ṣe ń ṣàkóso láyé àti lọ́run.—Wo àpótí náà, “ Àwọn Nǹkan Míì Tó Wé Mọ́ Ọ̀rọ̀ Pàtàkì Yìí.”
4. Kí ni Sáàmù 135:13 sọ nípa orúkọ Ọlọ́run, àwọn ìbéèrè wo la sì máa dáhùn nínú àpilẹ̀kọ yìí?
4 Orúkọ Jèhófà ṣàrà ọ̀tọ̀ gan-an, kò sì lẹ́gbẹ́. (Ka Sáàmù 135:13.) Kí ló mú kí orúkọ náà ṣàrà ọ̀tọ̀? Báwo làwọn kan ṣe tàbùkù sórúkọ náà níbẹ̀rẹ̀? Báwo ni Jèhófà ṣe sọ orúkọ rẹ̀ di mímọ́? Kí nìwọ náà lè ṣe táá jẹ́ káwọn èèyàn mọ irú ẹni tí Ọlọ́run jẹ́ gan-an? Ẹ jẹ́ ká wá ìdáhùn sáwọn ìbéèrè yìí.
ORÚKỌ ṢE PÀTÀKÌ
5. Kí làwọn kan lè béèrè tí wọ́n bá gbọ́ pé kí orúkọ Ọlọ́run di mímọ́?
5 “Kí orúkọ rẹ di mímọ́.” (Mát. 6:9) Ohun tí Jésù sọ pé ó yẹ kó gbawájú nínú àdúrà wa nìyí. Àmọ́ kí ni Jésù ní lọ́kàn? Láti sọ ohun kan di mímọ́ túmọ̀ sí pé kéèyàn ya ohun náà sọ́tọ̀, kó sì jẹ́ mímọ́ láìní àbàwọ́n kankan. Àwọn kan lè wá béèrè pé, ‘Ṣebí mímọ́ lorúkọ Jèhófà, kò sì lábàwọ́n?’ Bẹ́ẹ̀ ni, àmọ́ ká lè dáhùn ìbéèrè yìí ní kíkún, ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa ohun tí orúkọ dúró fún.
6. Kí nìdí tí orúkọ fi ṣe pàtàkì?
6 Wọ́n máa ń kọ orúkọ sílẹ̀ tàbí pè é jáde láti fi dá ẹnì kan mọ̀. Bó ti wù kó rí, orúkọ kọjá ọ̀rọ̀ téèyàn wulẹ̀ kọ sílẹ̀ tàbí pè jáde. Bíbélì sọ pé: “Orúkọ rere ló yẹ kéèyàn yàn dípò ọ̀pọ̀ ọrọ̀.” (Òwe 22:1; Oníw. 7:1) Kí nìdí tí orúkọ fi ṣe pàtàkì tó bẹ́ẹ̀? Ìdí ni pé táwọn èèyàn bá gbọ́ orúkọ ẹnì kan, irú ẹni tónítọ̀hún jẹ́ ló máa wá sí wọn lọ́kàn. Torí náà, kì í ṣe bí wọ́n ṣe kọ orúkọ kan sílẹ̀ tàbí bí wọ́n ṣe ń pè é ló ṣe pàtàkì jù bí kò ṣe irú ẹni tónítọ̀hún jẹ́ àtohun táwọn èèyàn ń rò nípa ẹ̀.
7. Báwo làwọn èèyàn ṣe ń tàbùkù sí orúkọ Ọlọ́run?
7 Nígbàkigbà táwọn èèyàn bá sọ ohun tí kò jóòótọ́ nípa Jèhófà, ṣe ni wọ́n ń tàbùkù sí orúkọ rẹ̀. Tí wọ́n bá sì tàbùkù sórúkọ rẹ̀, ṣe ni wọ́n ń bà á lórúkọ jẹ́. Ọgbà Édẹ́nì lẹnì kan ti kọ́kọ́ sọ ohun tí kò jóòótọ́ nípa Ọlọ́run tó sì tipa bẹ́ẹ̀ tàbùkù sí orúkọ rẹ̀. Kí lohun tó ṣẹlẹ̀ gan-an, kí la sì rí kọ́ nínú ẹ̀?
BÍ ẸNÌ KAN ṢE KỌ́KỌ́ BA ỌLỌ́RUN LÓRÚKỌ JẸ́
8. Kí ni Ádámù àti Éfà mọ̀ nípa Jèhófà, àwọn ìbéèrè wo ló sì jẹ yọ?
8 Ádámù àti Éfà mọ̀ pé Jèhófà ni orúkọ Ọlọ́run, wọ́n sì tún mọ àwọn nǹkan pàtàkì míì nípa rẹ̀. Wọ́n mọ̀ pé òun ni Ẹlẹ́dàá àwọn, Òun ló jẹ́ kí àwọn wà láàyè, òun ló fún àwọn ní Párádísè ẹlẹ́wà táwọn ń gbé tó sì mú kí àwọn di tọkọtaya. Jẹ́n. 1:26-28; 2:18) Pẹ̀lú bí Jèhófà ṣe fún Ádámù àti Éfà ní ọpọlọ pípé, ǹjẹ́ wọ́n máa ronú jinlẹ̀ nípa gbogbo nǹkan tí Jèhófà ṣe fún wọn? Ṣéyẹn máa mú kí wọ́n túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà tó fún wọn láwọn ẹ̀bùn náà, ṣé wọ́n á sì mọyì rẹ̀? Ìdáhùn sáwọn ìbéèrè yìí túbọ̀ ṣe kedere nígbà tẹ́nì kan tó jẹ́ ọ̀tá Ọlọ́run wá sọ́dọ̀ wọn tó sì dán wọn wò.
(9. Bó ṣe wà nínú Jẹ́nẹ́sísì 2:16, 17 àti 3:1-5, kí ni Jèhófà sọ fún tọkọtaya àkọ́kọ́, báwo sì ni Sátánì ṣe yí ọ̀rọ̀ náà po?
9 Ka Jẹ́nẹ́sísì 2:16, 17 àti 3:1-5. Sátánì fi ejò bojú ó sì béèrè lọ́wọ́ Éfà pé: “Ṣé òótọ́ ni Ọlọ́run sọ pé ẹ kò gbọ́dọ̀ jẹ nínú èso gbogbo igi inú ọgbà?” Téèyàn bá wo ìbéèrè yẹn, á mọ̀ pé irọ́ wà ńbẹ̀, àfi bíi májèlé tẹ́nì kan rọra bù sínú oúnjẹ aládùn kan. Ohun tí Ọlọ́run sọ gan-an ni pé wọ́n lè jẹ èso gbogbo igi tó wà nínú ọgbà náà àyàfi ẹyọ kan péré. Ó dájú pé àìlóǹkà oúnjẹ ló wà fún Ádámù àti Éfà láti jẹ. (Jẹ́n. 2:9) Ìyẹn sì fi hàn pé ọ̀làwọ́ ni Jèhófà. Àmọ́ igi kan wà tí Ọlọ́run dìídì sọ fún Ádámù àti Éfà pé wọn ò gbọ́dọ̀ jẹ èso rẹ̀. Bó ti wù kó rí, ṣe ni Sátánì yí ọ̀rọ̀ Jèhófà po. Ohun tí Sátánì sọ mú kó dà bíi pé Jèhófà kì í ṣe ọ̀làwọ́. Èyí lè mú kí Éfà ronú pé, ‘Ṣé kì í ṣe pé Ọlọ́run ń fi ohun kan dù wá?’
10. Báwo ni Sátánì ṣe ba Ọlọ́run lórúkọ jẹ́ ní tààràtà, kí nìyẹn sì yọrí sí?
10 Nígbà tí Sátánì bi Éfà ní ìbéèrè yẹn, Éfà ṣì ka Jèhófà sí alákòóso tó yẹ kó fún òun lófin. Torí náà, ohun tí Jèhófà sọ gẹ́lẹ́ ló fi dá Sátánì lóhùn. Ó wá fi kún un pé Ọlọ́run ní àwọn ò gbọ́dọ̀ fọwọ́ kan igi náà. Ohun tí Ọlọ́run sọ yé e dáadáa pé táwọn bá ṣàìgbọràn, ikú ló máa gbẹ̀yìn rẹ̀. Ni Sátánì bá dáhùn pé: “Ó dájú pé ẹ ò ní kú.” (Jẹ́n. 3:2-4) Lọ́tẹ̀ yìí, Sátánì kò pẹ́ ọ̀rọ̀ sọ rárá. Ṣe ló kúkú ba Ọlọ́run lórúkọ jẹ́ ní tààràtà, tó sì tipa bẹ́ẹ̀ pe Jèhófà ní òpùrọ́. Ohun tí Sátánì ṣe yìí ló mú kó di èṣù tàbí abanijẹ́. Èṣù tan Éfà jẹ pátápátá, Éfà sì gba ohun tó sọ gbọ́. (1 Tím. 2:14) Éfà fọkàn tán Sátánì dípò Jèhófà, ìyẹn sì mú kó ṣe ìpinnu tó burú jù lọ. Ó ṣàìgbọràn sí Jèhófà, ó sì tàpá sí àṣẹ rẹ̀. Ló bá jẹ èso tí Jèhófà ní wọn ò gbọ́dọ̀ jẹ, nígbà tó yá ó fún Ádámù náà jẹ lára ẹ̀.—Jẹ́n. 3:6.
11. Kí ló yẹ kí Ádámù àti Éfà ṣe nígbà tí Sátánì dán wọn wò, àmọ́ kí ni wọn ò ṣe?
11 Kí lo rò pé Éfà ì bá ti sọ fún Sátánì? Jẹ́ ká wò ó báyìí ná, ká ní Éfà sọ fún un pé: “Mi ò mọ̀ ẹ́, àmọ́ mo mọ Jèhófà Baba mi, mo nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, mo sì gba ohun tó sọ gbọ́. Òun ló fún èmi àti ọkọ mi ní gbogbo ohun tá a ní. Kí lo fi ara ẹ pè ná, àyà mà kò ẹ́ o? Kó bó ti ń ṣe ẹ́ kúrò lọ́dọ̀ mi!” Ẹ wo bí inú Jèhófà ṣe máa dùn tó pé ọmọbìnrin òun nífẹ̀ẹ́ òun dénú, kò sì gbàgbàkugbà láyè! (Òwe 27:11) Àmọ́ Éfà ò nífẹ̀ẹ́ Jèhófà dénú, bọ́rọ̀ Ádámù náà sì ṣe rí nìyẹn. Torí pé Ádámù àti Éfà ò nífẹ̀ẹ́ Jèhófà tí wọn ò sì jẹ́ adúróṣinṣin sí i, wọn ò gbèjà Jèhófà nígbà tí Sátánì ta kò ó.
12. Báwo ni Sátánì ṣe mú kí Éfà ṣiyèméjì, kí sì ni òun àti ọkọ rẹ̀ kò ṣe?
12 Bá a ṣe rí i, ohun tí Sátánì kọ́kọ́ ṣe ni pé ó mú kí Éfà ṣiyèméjì. Ó mú kí Éfà ronú pé bóyá ni Jèhófà jẹ́ Ẹni rere. Nígbà tó wá gbé irọ́ kalẹ̀, kàkà kí Ádámù àti Éfà já irọ́ náà, ṣe ni wọ́n gbà á gbọ́. Ìyẹn mú kó rọrùn fún Sátánì láti tàn wọ́n jẹ, wọ́n sì ṣọ̀tẹ̀ sí Jèhófà Baba wọn ọ̀run. Ọgbọ́n kan náà ni Sátánì ń dá lónìí. Ó máa ń ba Jèhófà lórúkọ jẹ́. Ṣe làwọn tó bá sì gba irọ́ rẹ̀ gbọ́ máa ń kọ ìṣàkóso Jèhófà sílẹ̀ pátápátá.
JÈHÓFÀ SỌ ORÚKỌ ARA RẸ̀ DI MÍMỌ́
13. Báwo ni Ìsíkíẹ́lì 36:23 ṣe tẹnu mọ́ ohun tí Bíbélì dá lé?
13 Ṣé Jèhófà kàn fọwọ́ lẹ́rán láìṣe nǹkan kan sí ẹ̀sùn tí Sátánì fi kàn án ni? Rárá kò ṣe bẹ́ẹ̀! Láti Jẹ́nẹ́sísì dé Ìfihàn la ti rí àwọn ohun tí Jèhófà ṣe kó lè jẹ́ kó ṣe kedere pé irọ́ ni gbogbo ẹ̀sùn tí Sátánì fi kan òun lọ́gbà Édẹ́nì. (Jẹ́n. 3:15) Kódà, a lè ṣàkópọ̀ ohun tí Bíbélì dá lé lọ́nà yìí pé: Jèhófà sọ orúkọ rẹ̀ di mímọ́ nípasẹ̀ Ìjọba rẹ̀ tí Jésù máa ṣàkóso, èyí ló sì máa mú kí òdodo àti àlàáfíà gbilẹ̀ láyé. Àwọn àkọsílẹ̀ inú Bíbélì ló jẹ́ ká túbọ̀ lóye bí Jèhófà ṣe sọ orúkọ rẹ̀ di mímọ́.—Ka Ìsíkíẹ́lì 36:23.
14. Báwo ni bí Jèhófà ṣe bójú tó ọ̀rọ̀ tó wáyé nínú ọgbà Édẹ́nì ṣe sọ orúkọ rẹ̀ di mímọ́?
14 Gbogbo ọ̀nà ni Sátánì gbà kó lè dí Jèhófà lọ́wọ́, kí ohun tí Jèhófà ní lọ́kàn má bàa ṣẹ. Àmọ́ pàbó ni gbogbo ìsapá rẹ̀ já sí. Àkọsílẹ̀ Bíbélì jẹ́ ká mọ bí Jèhófà ṣe bójú tó ọ̀rọ̀ náà, èyí sì mú kó hàn gbangba-gbàǹgbà pé kò sẹ́ni tó dà bíi Jèhófà Ọlọ́run wa. Ká sòótọ́, ohun tí Sátánì àtàwọn alátìlẹ́yìn rẹ̀ ṣe dun Jèhófà gan-an. (Sm. 78:40) Àmọ́ bí Jèhófà ṣe yanjú ọ̀rọ̀ náà fi hàn pé ó jẹ́ ọlọ́gbọ́n, onísùúrù àti onídàájọ́ òdodo. Ọ̀pọ̀ ìgbà ló sì fi hàn pé kò sẹ́ni tó lágbára bíi tòun. Ju gbogbo ẹ̀ lọ, ìfẹ́ rẹ̀ hàn nínú gbogbo ohun tó ń ṣe. (1 Jòh. 4:8) Ó ṣe kedere pé àtìgbà yẹn ni Jèhófà ti ń sọ orúkọ ara rẹ̀ di mímọ́.
15. Báwo ni Sátánì ṣe ń ba Jèhófà lórúkọ jẹ́ lónìí, kí nìyẹn sì ti yọrí sí?
15 Títí dòní, Sátánì ṣì ń ba Jèhófà lórúkọ jẹ́. Ó ń mú káwọn èèyàn máa ronú pé bóyá ni Ọlọ́run jẹ́ alágbára, onídàájọ́ òdodo, ọlọ́gbọ́n àti onífẹ̀ẹ́. Bí àpẹẹrẹ, Sátánì ń mú káwọn èèyàn gbà pé kì í ṣe Jèhófà ló dá ayé yìí àtàwọn nǹkan míì. Tó bá sì ráwọn tó gbà pé Ọlọ́run wà, ó máa ń fẹ́ mú kí wọ́n gbà pé àwọn òfin Ọlọ́run ti le jù àti pé kò lójú àánú. Kódà, ó tún ń kọ́ àwọn èèyàn pé ìkà àti òṣónú ni Jèhófà, pé ó máa jó àwọn èèyàn nínú iná ọ̀run àpáàdì. Tí wọ́n bá sì ti gba irọ́ yìí gbọ́, ṣe ni wọ́n máa kẹ̀yìn sí Jèhófà. Ó dìgbà tí Jèhófà bá pa Sátánì run kó tó dẹ́kun àtimáa ṣi àwọn èèyàn lọ́nà. Torí náà, ó fẹ́ kíwọ náà kẹ̀yìn sí Jèhófà. Ṣé wàá gbà fún un?
Ọ̀RỌ̀ TÓ WÀ NÍLẸ̀ YÌÍ KÀN Ẹ́
16. Kí lo lè ṣe tí Ádámù àti Éfà ò ṣe?
16 Jèhófà fún àwa èèyàn aláìpé láǹfààní láti sọ orúkọ rẹ̀ di mímọ́. Torí náà, ohun kan wà tí Ádámù àti Éfà ò ṣe àmọ́ tí ìwọ lè ṣe. Lóòótọ́ inú ayé táwọn èèyàn ti ń tàbùkù sí Jèhófà tí wọ́n sì ń bà á lórúkọ jẹ́ lò ń gbé, síbẹ̀ o lè jẹ́ káwọn míì mọ òótọ́ nípa Jèhófà, pé ẹni mímọ́ ni, ó jẹ́ olódodo, ẹni rere, ó sì nífẹ̀ẹ́ àwa èèyàn. (Àìsá. 29:23) O lè fi hàn pé ìṣàkóso Jèhófà lo fara mọ́. O lè jẹ́ káwọn míì mọ̀ pé Ìjọba Jèhófà nìkan ló máa tẹ́ aráyé lọ́rùn, òun ló sì máa mú àlàáfíà àti ayọ̀ wá fún aráyé.—Sm. 37:9, 37; 146:5, 6, 10.
17. Báwo ni Jésù ṣe mú káwọn èèyàn mọ orúkọ Baba rẹ̀?
17 Àpẹẹrẹ Jésù là ń tẹ̀ lé tá a bá jẹ́ káwọn míì mọ òótọ́ nípa Jèhófà. (Jòh. 17:26) Yàtọ̀ sí pé Jésù sọ orúkọ Baba rẹ̀ fáwọn èèyàn, ó tún jẹ́ kí wọ́n mọ irú ẹni tí Jèhófà jẹ́ gan-an. Bí àpẹẹrẹ, ìwà àwọn Farisí àtohun tí wọ́n fi ń kọ́ni mú káwọn èèyàn máa wo Jèhófà bí ẹni tó le koko jù, tí kì í gba tẹni rò, tí kò ṣeé sún mọ́, tí kò sì láàánú. Àmọ́ Jésù fi hàn pé Jèhófà ò rí bẹ́ẹ̀ rárá. Ó kọ́ni pé Jèhófà máa ń gba tàwọn èèyàn rò, ó jẹ́ Ọlọ́run ìfẹ́, ó máa ń mú sùúrù, ó sì ń dárí jini. Ó tún jẹ́ káwọn èèyàn mọ irú ẹni tí Jèhófà jẹ́ nínú ìwà rẹ̀ torí pé ó gbé ànímọ́ Baba rẹ̀ yọ lọ́nà tó pé pérépéré.—Jòh. 14:9.
18. Báwo la ṣe lè fi hàn pé irọ́ làwọn ọ̀tá Jèhófà ń pa mọ́ ọn?
Éfé. 5:1, 2) Tá a bá jẹ́ káwọn èèyàn mọ irú ẹni tí Jèhófà jẹ́ gan-an nínú ọ̀rọ̀ àti ìṣe wa, ṣe là ń sọ orúkọ rẹ̀ di mímọ́. A lè dá orúkọ Jèhófà láre tá a bá jẹ́ káwọn èèyàn lóye ẹ̀kọ́ òtítọ́ tó wà nínú Bíbélì. * Ìyẹn á sì tún fi hàn pé èèyàn aláìpé lè jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà.—Jóòbù 27:5.
18 Bíi ti Jésù, àwa náà lè jẹ́ káwọn èèyàn mọ irú ẹni tí Jèhófà jẹ́, pé Ọlọ́run ìfẹ́ ni, ó sì jẹ́ onínúure. Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, à ń fi hàn pé irọ́ làwọn ọ̀tá Jèhófà ń pa mọ́ ọn. A lè sọ orúkọ Jèhófà di mímọ́ tá a bá ń jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé ẹni mímọ́ ni. Àwa náà lè fara wé Jèhófà bá a tiẹ̀ jẹ́ aláìpé. (19. Báwo lọ̀rọ̀ inú Àìsáyà 63:7 ṣe jẹ́ ká rí ohun tó yẹ ká máa tẹnu mọ́ tá a bá ń kọ́ni?
19 Ohun míì tún wà tá a lè ṣe láti sọ orúkọ Jèhófà di mímọ́. Tá a bá ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́, a sábà máa ń tẹnu mọ́ ọn pé Jèhófà ló lẹ́tọ̀ọ́ láti ṣàkóso ayé àtọ̀run, òótọ́ sì ni. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé kò burú láti kọ́ àwọn èèyàn ní òfin Ọlọ́run, ohun tó ṣe pàtàkì jù ni pé ká jẹ́ kí wọ́n nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Baba wa ọ̀run, kí wọ́n sì jẹ́ adúróṣinṣin sí i. Torí náà, ó yẹ ká máa tẹnu mọ́ àwọn ànímọ́ rere tí Jèhófà ní, ká sì jẹ́ kí wọ́n mọ irú ẹni tó jẹ́. (Ka Àìsáyà 63:7.) Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, àwọn èèyàn á nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, wọ́n á sì máa ṣègbọràn sí i torí pé wọ́n fẹ́ jẹ́ adúróṣinṣin sí i.
20. Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ tó kàn?
20 Àmọ́ báwo la ṣe lè rí i dájú pé ìwà wa àtohun tá a fi ń kọ́ni ń sọ orúkọ Jèhófà di mímọ́, ó sì ń mú kó rọrùn fáwọn èèyàn láti sún mọ́ ọn? A máa dáhùn ìbéèrè yìí nínú àpilẹ̀kọ tó kàn.
ORIN 2 Jèhófà Ni Orúkọ Rẹ
^ ìpínrọ̀ 5 Ọ̀rọ̀ wo ló ṣe pàtàkì jù lọ sáwa èèyàn àtàwọn áńgẹ́lì? Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì tó bẹ́ẹ̀, báwo ló sì ṣe kàn wá? Tá a bá lóye ìdáhùn sáwọn ìbéèrè yìí àtàwọn ìbéèrè míì tó jẹ mọ́ ọn, á jẹ́ kí àjọṣe wa pẹ̀lú Jèhófà túbọ̀ lágbára.
^ ìpínrọ̀ 18 Àwọn ìgbà kan wà tá a sọ nínú àwọn ìwé wa pé kò tọ̀nà ká máa sọ pé ká dá orúkọ Jèhófà láre torí pé kò sẹ́ni tó nàka àbùkù sí i pé kò lẹ́tọ̀ọ́ láti jẹ́ orúkọ náà. Àmọ́, a ní òye tuntun nípa èyí níbi ìpàdé ọdọọdún tó wáyé lọ́dún 2017. Alága ìpàdé náà sọ pé: ‘Kókó náà ni pé, kò sóhun tó burú nínú kéèyàn gbàdúrà fún ìdáláre orúkọ Jèhófà torí pé Jèhófà ní láti jẹ́ káráyé mọ̀ pé èké lẹ̀sùn tí wọ́n fi kan òun.’—Wo ètò ti January 2018 lórí ìkànnì jw.org®. Wo abẹ́ OHUN TÁ A NÍ > JW BROADCASTING®.
^ ìpínrọ̀ 62 ÀWÒRÁN: Èṣù ba Ọlọ́run lórúkọ jẹ́, ó sọ fún Éfà pé òpùrọ́ ni Ọlọ́run. Àtìgbà yẹn ni Sátánì ti ń tan ẹ̀kọ́ èké kálẹ̀ pé ìkà ni Ọlọ́run àti pé kì í ṣe Òun ló dá àwa èèyàn.
^ ìpínrọ̀ 64 ÀWÒRÁN: Arákùnrin kan ń tẹnu mọ́ àwọn ànímọ́ Jèhófà bó ṣe ń kọ́ ẹnì kan lẹ́kọ̀ọ́.