ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 22
Mọyì Àwọn Ìṣúra Tí Kò Ṣeé Fojú Rí
“Tẹ ojú [rẹ] mọ́ àwọn ohun tí a kò rí. . . . Nítorí àwọn ohun tí à ń rí wà fún ìgbà díẹ̀, àmọ́ àwọn ohun tí a kò rí máa wà títí ayérayé.”—2 KỌ́R. 4:18.
ORIN 45 Àṣàrò Ọkàn Mi
OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒ *
1. Kí ni Jésù sọ nípa ìṣúra tá a tò pa mọ́ sí ọ̀run?
KÌ Í ṣe gbogbo ìṣúra ló ṣeé fojú rí. Kódà, ọ̀pọ̀ ìṣúra tó ṣeyebíye jù lọ ni kò ṣeé fojú rí. Nínú Ìwàásù Lórí Òkè, Jésù sọ̀rọ̀ nípa àwọn ohun tá a fi ṣúra sí ọ̀run, ó sì jẹ́ kó ṣe kedere pé wọ́n ṣe pàtàkì ju ohun ìní èyíkéyìí lọ. Ó wá fi kún un pé: “Ibi tí ìṣúra yín bá wà, ibẹ̀ ni ọkàn yín náà máa wà.” (Mát. 6:19-21) Ká sòótọ́, téèyàn bá ka ohun kan sí pàtàkì, tọkàntọkàn ló fi máa wá a. Téèyàn bá sì ní orúkọ rere lọ́dọ̀ Jèhófà, ńṣe lonítọ̀hún ń “to ìṣúra pa mọ́ fún ara [rẹ̀] ní ọ̀run.” Jésù sọ pé irú ìṣura bẹ́ẹ̀ ò lè bà jẹ́, olè ò sì lè jí i.
2. (a) Bó ṣe wà nínú 2 Kọ́ríńtì 4:17, 18, kí ni Pọ́ọ̀lù rọ̀ wá pé ká tẹjú mọ́? (b) Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí?
2 Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù rọ̀ wá pé ká “tẹ ojú wa mọ́ àwọn ohun tí a kò rí.” (Ka 2 Kọ́ríńtì 4:17, 18.) Lára ohun tí a kò rí yìí làwọn ìbùkún tá a máa gbádùn nínú ayé tuntun. Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa sọ̀rọ̀ nípa ìṣúra mẹ́rin tí a kò lè fojú rí àmọ́ tá à ń jàǹfààní wọn báyìí. Àwọn ìṣúra náà ni bá a ṣe jẹ́ ọ̀rẹ́ Jèhófà, bá a ṣe ń gbàdúrà sí i, bí ẹ̀mí mímọ́ ṣe ń ràn wá lọ́wọ́ àti bí Jèhófà, Jésù àtàwọn áńgẹ́lì ṣe ń tì wá lẹ́yìn lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù. A tún máa sọ̀rọ̀ nípa bá a ṣe lè fi hàn pé a mọyì àwọn ìṣúra náà.
A JẸ́ Ọ̀RẸ́ JÈHÓFÀ
3. Ìṣúra tí a kò lè fojú rí wo ló ṣeyebíye jù lọ, kí ló sì mú ká ní ìṣúra náà?
3 Ìṣúra tí a kò lè fojú rí tó ṣeyebíye jù lọ ni bá a ṣe jẹ́ ọ̀rẹ́ Jèhófà Ọlọ́run. (Sm. 25:14) Báwo ni Ọlọ́run mímọ́ ṣe lè bá èèyàn tó jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀ ṣọ̀rẹ́ kó sì wà láìní àbàwọ́n? Ohun tó mú kó lè ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé ẹbọ ìràpadà Jésù ti “kó ẹ̀ṣẹ̀ ayé lọ.” (Jòh. 1:29) Kódà kí Jésù tó wá sáyé ni Jèhófà ti mọ̀ pé Jésù máa jẹ́ olóòótọ́ títí dójú ikú, á sì tipa bẹ́ẹ̀ gba aráyé là. Èyí ló mú kó ṣeé ṣe fún Jèhófà láti bá àwọn tó gbáyé ṣáájú ikú Jésù ṣọ̀rẹ́.—Róòmù 3:25.
4. Sọ díẹ̀ lára àwọn tó di ọ̀rẹ́ Ọlọ́run kí Jésù tó wá sáyé.
4 Ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa díẹ̀ lára àwọn tó di ọ̀rẹ́ Ọlọ́run kí Jésù tó wá sáyé. Ábúráhámù lo ìgbàgbọ́ tó lágbára nínú Jèhófà. Lẹ́yìn ohun tó lé ní ẹgbẹ̀rún (1,000) ọdún kan tí Ábúráhámù kú, Jèhófà pè é ní “ọ̀rẹ́ mi.” (Àìsá. 41:8) Èyí jẹ́ ká rí i pé kò sóhun tó lè ya Jèhófà àtàwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀, kódà ikú ò lè yà wọ́n. Lójú Jèhófà, Ábúráhámù ṣì wà láàyè. (Lúùkù 20:37, 38) Àpẹẹrẹ ẹlòmíì ni Jóòbù. Ìṣojú ọ̀kẹ́ àìmọye áńgẹ́lì ni Jèhófà ti fi Jóòbù yangàn. Jèhófà sọ pé “olódodo àti olóòótọ́ èèyàn ni, ó bẹ̀rù Ọlọ́run, ó sì kórìíra ohun tó burú.” (Jóòbù 1:6-8) Kí ni Jèhófà sọ nípa Dáníẹ́lì, tóun náà sin Jèhófà nílẹ̀ àwọn abọ̀rìṣà fún nǹkan bí ọgọ́rin (80) ọdún? Ẹ̀ẹ̀mẹta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ làwọn áńgẹ́lì sọ fún un pé ó “ṣeyebíye gan-an” lójú Ọlọ́run. (Dán. 9:23; 10:11, 19) Ó dá wa lójú pé Jèhófà ń fojú sọ́nà de ìgbà tó máa jí àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ dìde.—Jóòbù 14:15.
5. Kí lá jẹ́ ká lè di ọ̀rẹ́ Jèhófà?
5 Ṣé Jèhófà láwọn ọ̀rẹ́ lórí ilẹ̀ ayé lónìí? Bẹ́ẹ̀ ni, kódà wọ́n lé ní mílíọ̀nù mẹ́jọ. Ohun tó jẹ́ ká sọ bẹ́ẹ̀ ni pé ọ̀pọ̀ èèyàn lọ́mọdé àti lágbà, lọ́kùnrin àti lóbìnrin ló ń fi hàn nínú ìwà wọn pé àwọn jẹ́ ọ̀rẹ́ Ọlọ́run. Bíbélì sì sọ pé “àwọn adúróṣinṣin ni ọ̀rẹ́ Rẹ̀ tímọ́tímọ́.” (Òwe 3:32) Ìgbàgbọ́ tí wọ́n ní nínú ẹbọ ìràpadà Jésù ló mú kí wọ́n di ọ̀rẹ́ Jèhófà. Ìyẹn ló mú kí Jèhófà fún wa láǹfààní láti yara wa sí mímọ́ fún òun, ká sì ṣèrìbọmi. Tẹ́nì kan bá gbé àwọn ìgbésẹ̀ yìí, á dara pọ̀ mọ́ àwọn mílíọ̀nù èèyàn tó ti yara wọn sí mímọ́, tí wọ́n ṣèrìbọmi, tí wọ́n sì ti di ‘ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́’ pẹ̀lú Ẹni tó ga jù lọ láyé àti lọ́run.
6. Báwo la ṣe lè fi hàn pé a mọyì bá a ṣe jẹ́ ọ̀rẹ́ Ọlọ́run?
6 Báwo la ṣe lè fi hàn pé a mọyì bá a ṣe jẹ́ ọ̀rẹ́ Ọlọ́run? Bíi ti Ábúráhámù àti Jóòbù tí wọ́n jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà fún ohun tó lé lọ́gọ́rùn-ún ọdún, àwa náà gbọ́dọ̀ jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà láìka iye ọdún tá a ti ń sin Jèhófà bọ̀ nínú ayé burúkú yìí. Bíi ti Dáníẹ́lì, a gbọ́dọ̀ mọyì bá a ṣe jẹ́ ọ̀rẹ́ Ọlọ́run, kó sì ṣe pàtàkì sí wa ju ẹ̀mí wa lọ. (Dán. 6:7, 10, 16, 22) Ó dájú pé Jèhófà máa ràn wá lọ́wọ́ láti fara da àdánwò èyíkéyìí, ìyẹn á sì mú kí okùn ọ̀rẹ́ wa túbọ̀ lágbára.—Fílí. 4:13.
A LÈ GBÀDÚRÀ SÍ ỌLỌ́RUN
7. (a) Bó ṣe wà nínú Òwe 15:8, báwo ni àdúrà wa ṣe máa ń rí lára Jèhófà? (b) Báwo ni Jèhófà ṣe máa ń dáhùn àdúrà wa?
7 Ìṣúra míì tá ò lè fojú rí ni àdúrà. Àwọn ọ̀rẹ́ tó mọwọ́ ara wọn máa ń bára wọn sọ̀rọ̀, wọ́n sì máa ń finú han ara wọn. Ṣé bí àárín àwa àti Jèhófà náà ṣe rí nìyẹn? Bẹ́ẹ̀ ni! Jèhófà máa ń bá wa sọ̀rọ̀ nípasẹ̀ Bíbélì Ọ̀rọ̀ rẹ̀, ibẹ̀ la sì ti mọ èrò rẹ̀ àti bí nǹkan ṣe máa ń rí lára rẹ̀. Àwa náà máa ń bá a sọ̀rọ̀ nínú àdúrà, kódà a máa ń sọ ohun tó ń jẹ wá lọ́kàn àti bọ́rọ̀ ṣe rí lára wa fún un. Inú Jèhófà Òwe 15:8.) Kì í ṣe pé Jèhófà máa ń tẹ́tí sí àdúrà wa nìkan, ó tún máa ń dáhùn wọn torí pé ọ̀rẹ́ wa ni. Ó máa ń tètè dáhùn àdúrà wa nígbà míì. Ó sì lè gba pé ká gbàdúrà léraléra fún ohun kan náà. Síbẹ̀, ó dá wa lójú pé ó máa dáhùn àdúrà wa lásìkò tó tọ́, ohun tó dáa jù ló sì máa ṣe fún wa. Àmọ́ o, láwọn ìgbà míì ó lè ṣe ohun tó yàtọ̀ sí ohun tá a gbàdúrà fún. Bí àpẹẹrẹ, dípò kó mú àdánwò kan kúrò, ó lè fún wa lọ́gbọ́n àti okun táá jẹ́ ká “lè fara dà á.”—1 Kọ́r. 10:13.
máa ń dùn láti gbọ́ àdúrà wa. (Ka8. Báwo la ṣe lè fi hàn pé a mọyì àǹfààní tá a ní láti gbàdúrà?
8 Báwo la ṣe lè fi hàn pé a mọyì àǹfààní tó ṣeyebíye tá a ní láti gbàdúrà sí Jèhófà? A lè ṣe bẹ́ẹ̀ tá a bá ń ṣe ohun tí Jèhófà sọ, pé ká “máa gbàdúrà nígbà gbogbo.” (1 Tẹs. 5:17) Kì í fipá mú wa pé ká gbàdúrà sí òun. Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ló ń rọ̀ wá pé ká “tẹra mọ́ àdúrà gbígbà.” (Róòmù 12:12) Torí náà, a lè fi hàn pé a mọyì àǹfààní yìí tá a bá ń gbàdúrà lóòrèkóòrè jálẹ̀ ọjọ́ kọ̀ọ̀kan. Àmọ́ o, ká má gbàgbé láti máa dúpẹ́ ká sì máa yin Jèhófà nínú àdúrà wa.—Sm. 145:2, 3.
9. Kí ni arákùnrin kan sọ nípa àdúrà, báwo ló sì ṣe máa ń rí lára rẹ tó o bá ń gbàdúrà?
9 Bá a ṣe ń pẹ́ sí i nínú ètò Jèhófà, tá a sì ń kíyè sí bó ṣe ń dáhùn àdúrà wa, bẹ́ẹ̀ ló ṣe yẹ ká túbọ̀ mọyì àǹfààní tá a ní láti gbàdúrà. Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ Arákùnrin Chris tó ti wà lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún fún ọdún mẹ́tàdínláàádọ́ta (47). Ó sọ pé: “Inú mi máa ń dùn gan-an láti gbàdúrà sí Jèhófà láàárọ̀ kùtù, ojú kì í sì í kán mi tí mo bá ń bá a sọ̀rọ̀. Mo sábà máa ń kíyè sáwọn ohun àrà tí Jèhófà dá àti bójú ọjọ́ ṣe máa ń mọ́lẹ̀ rekete tí oòrùn bá yọ tó sì tàn sára ewéko. Èyí máa ń mú kí n dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà fáwọn nǹkan tó fún wa, títí kan àǹfààní tá a ní láti gbàdúrà. Tó bá wá dalẹ́ tí mo sì gbàdúrà,
ọkàn mi máa ń balẹ̀ pé mo ní ẹ̀rí ọkàn tó mọ́.”Ẹ̀BÙN Ẹ̀MÍ MÍMỌ́
10. Kí nìdí tó fi yẹ ká mọyì ẹ̀bùn ẹ̀mí mímọ́?
10 Ìṣúra míì tá ò lè fojú rí tó yẹ ká mọyì ni ẹ̀bùn ẹ̀mí mímọ́. Jésù rọ̀ wá pé ká máa gbàdúrà pé kí Ọlọ́run fún wa ní ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀. (Lúùkù 11:9, 13) Jèhófà máa ń tipasẹ̀ ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ yìí fún wa ní agbára, àní “agbára tó kọjá ti ẹ̀dá.” (2 Kọ́r. 4:7; Ìṣe 1:8) Ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run máa ràn wá lọ́wọ́ láti fara da àdánwò èyíkéyìí.
11. Báwo ni ẹ̀mí mímọ́ ṣe máa ń ràn wá lọ́wọ́?
11 Ẹ̀mí mímọ́ máa ń jẹ́ ká lè ṣe ojúṣe wa nínú ètò Ọlọ́run. Ẹ̀mí mímọ́ máa ń jẹ́ ká túbọ̀ já fáfá nínú àwọn ohun tá a mọ̀ ọ́n ṣe. Ká sòótọ́, ẹ̀mí mímọ́ Jèhófà ló ń jẹ́ ká lè gbé onírúurú nǹkan ṣe nínú ìjọsìn rẹ̀, kì í ṣe agbára wa.
12. Bó ṣe wà nínú Sáàmù 139:23, 24, kí la lè bẹ Jèhófà pé kó ṣe fún wa?
12 Ọ̀nà míì tá a lè gbà fi hàn pé a mọyì ẹ̀mí mímọ́ ni pé ká máa bẹ Jèhófà pé kó jẹ́ ká mọ̀ tá a bá ti ń ní èrò tí kò tọ́ nínú ọkàn wa. (Ka Sáàmù 139:23, 24.) Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, Jèhófà máa fi ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ ràn wá lọ́wọ́ ká lè mọ̀ bóyá èrò tí kò tọ́ ti ń gbilẹ̀ lọ́kàn wa. Tá a bá sì wá rí i pé èrò tí kò tọ́ wà lọ́kàn wa, ká bẹ Jèhófà pé kó fún wa ní ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ ká lè fa èrò tí kò tọ́ náà tu. Èyí á fi hàn pé a ò fẹ́ kí ohunkóhun dí Jèhófà lọ́wọ́ àtimáa fi ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ ràn wá lọ́wọ́.—Éfé. 4:30.
13. Báwo la ṣe lè túbọ̀ mọyì ẹ̀mí mímọ́?
13 A lè túbọ̀ fi hàn pé a mọyì ẹ̀mí mímọ́ tá a bá ń ronú nípa àwọn nǹkan ribiribi tó ń gbé ṣe lákòókò wa yìí. Kí Jésù tó pa dà sọ́run, ó sọ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Ẹ ó gba agbára nígbà tí ẹ̀mí mímọ́ bá bà lé yín, ẹ ó sì jẹ́ ẹlẹ́rìí mi . . . títí dé ibi tó jìnnà jù lọ ní ayé.” (Ìṣe 1:8) Ohun tó sì ń ṣẹlẹ̀ gan-an lákòókò wa yìí nìyẹn. Bí àpẹẹrẹ, ẹ̀mí mímọ́ ti mú kí àwọn mílíọ̀nù mẹ́jọ ààbọ̀ èèyàn máa jọ́sìn Jèhófà níbi gbogbo láyé. A tún ń gbádùn Párádísè tẹ̀mí torí ẹ̀mí mímọ́ mú ká ní àwọn ànímọ́ bí ìfẹ́, ayọ̀, àlàáfíà, sùúrù, inú rere, ìwà rere, ìgbàgbọ́, ìwà tútù àti ìkóra-ẹni-níjàánu. Àwọn ànímọ́ yìí ló para pọ̀ di “èso ti ẹ̀mí.” (Gál. 5:22, 23) Ẹ ò rí i pé ẹ̀bùn tó ṣeyebíye ni ẹ̀mí mímọ́!
JÈHÓFÀ, JÉSÙ ÀTÀWỌN ÁŃGẸ́LÌ Ń TÍ WÀ LẸ́YÌN
14. Àwọn tá ò lè fojú rí wo ló ń tì wá lẹ́yìn lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù?
14 Àǹfààní ńlá ló jẹ́ pé à ń bá Jèhófà, Jésù àtàwọn áńgẹ́lì ṣiṣẹ́. (2 Kọ́r. 6:1) Gbogbo ìgbà tá a bá wà lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù là ń bá wọn ṣiṣẹ́. Pọ́ọ̀lù sọ nípa ara rẹ̀ àtàwọn míì tó ń wàásù pé: “Alábàáṣiṣẹ́ pẹ̀lú Ọlọ́run ni wá.” (1 Kọ́r. 3:9) A tún ń bá Jésù ṣiṣẹ́ nígbàkigbà tá a bá wà lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù àti sísọni di ọmọ ẹ̀yìn. Ẹ rántí ohun tí Jésù sọ lẹ́yìn tó pàṣẹ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé kí wọ́n “máa sọ àwọn èèyàn gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ ẹ̀yìn,” ó ní: “Mo wà pẹ̀lú yín.” (Mát. 28:19, 20) Àwọn áńgẹ́lì náà ńkọ́? Bíbélì fi hàn pé wọ́n ń darí wa bá a ṣe ń kéde “ìhìn rere àìnípẹ̀kun . . . fún àwọn tó ń gbé ayé.” A mà dúpẹ́ o!—Ìfi. 14:6.
15. Sọ àpẹẹrẹ kan nínú Bíbélì tó fi hàn pé ohun kékeré kọ́ ni Jèhófà ń ṣe láti ràn wá lọ́wọ́ lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù.
15 Àwọn nǹkan wo la ti gbé ṣe torí pé Jèhófà ń ràn wá lọ́wọ́? Bá a ṣe ń fúnrúgbìn ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run, àwọn kan ń bọ́ sí ọkàn rere, wọ́n sì ń hù. (Mát. 13:18, 23) Ta ló ń mú kí irúgbìn òtítọ́ náà hù kó sì so èso? Jésù jẹ́ kó ṣe kedere pé kò sẹ́ni tó lè di ọmọ ẹ̀yìn òun láìjẹ́ pé “Baba . . . fà á.” (Jòh. 6:44) A rí àpẹẹrẹ ohun tí Jésù sọ yìí nínú Bíbélì. Ẹ rántí ìgbà tí Pọ́ọ̀lù wàásù fáwọn obìnrin kan lẹ́yìn odi ìlú Fílípì. Ẹ kíyè sóhun tí Bíbélì sọ nípa ọ̀kan lára wọn tó ń jẹ́ Lìdíà, ó ní: “Jèhófà . . . ṣí ọkàn rẹ̀ sílẹ̀ láti fiyè sí ohun tí Pọ́ọ̀lù ń sọ.” (Ìṣe 16:13-15) Bíi ti Lìdíà, ẹgbẹẹgbẹ̀rún èèyàn ni Jèhófà ti fà wá sọ́dọ̀ ara rẹ̀.
16. Ta ló yẹ ká dúpẹ́ lọ́wọ́ ẹ̀ fáwọn àṣeyọrí tá à ń ṣe lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù?
16 Ta ló ń mú ká ṣàṣeyọrí lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù àti sísọni dọmọ ẹ̀yìn? Pọ́ọ̀lù dáhùn ìbéèrè yìí nínú lẹ́tà tó kọ sáwọn ará ní Kọ́ríńtì, ó ní: “Èmi gbìn, Àpólò bomi rin, àmọ́ Ọlọ́run ló mú kó máa dàgbà, tó fi jẹ́ pé kì í ṣe ẹni tó ń gbìn ló ṣe pàtàkì tàbí ẹni tó ń bomi rin, bí kò ṣe Ọlọ́run tó ń mú kó dàgbà.” (1 Kọ́r. 3:6, 7) Bíi ti Pọ́ọ̀lù, Jèhófà ló yẹ ká máa dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀, ká sì máa fìyìn fún tá a bá ṣe àṣeyọrí èyíkéyìí lẹ́nu iṣẹ́ náà.
17. Báwo la ṣe lè fi hàn pé a mọyì bá a ṣe ń bá Jèhófà, Jésù àtàwọn áńgẹ́lì ṣiṣẹ́?
17 Báwo la ṣe lè fi hàn pé a mọyì àǹfààní tá a ní láti bá Jèhófà, Jésù àtàwọn áńgẹ́lì ṣiṣẹ́? A lè ṣe bẹ́ẹ̀ tá a bá ń lo gbogbo àǹfààní tá a ní láti bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ Jèhófà. Onírúurú ọ̀nà la lè gbà ṣe bẹ́ẹ̀, a lè wàásù “ní gbangba àti láti ilé dé ilé.” (Ìṣe 20:20) Ọ̀pọ̀ gbádùn kí wọ́n máa wàásù lọ́nà àìjẹ́-bí-àṣà. Tí wọ́n bá pàdé àwọn èèyàn, wọ́n á kí wọn tẹ̀rín-tọ̀yàyà, wọ́n á sì bẹ̀rẹ̀ sí í bá wọn sọ̀rọ̀. Tẹ́nì náà bá ṣe tán àtibá wọn sọ̀rọ̀, wọ́n á dọ́gbọ́n bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò Bíbélì pẹ̀lú ẹ̀.
18-19. (a) Báwo la ṣe ń bomi rin irúgbìn òtítọ́? (b) Sọ ìrírí kan tó jẹ́ ká rí bí Jèhófà ṣe ran akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kan lọ́wọ́.
18 Torí pé “alábàáṣiṣẹ́ pẹ̀lú Ọlọ́run ni wá,” a máa ń bomi rin irúgbìn òtítọ́ tá a gbìn sọ́kàn àwọn èèyàn. Tẹ́nì kan bá tẹ́tí
sọ́rọ̀ wa, a máa ń pa dà lọ sọ́dọ̀ ẹ̀ tàbí ká ṣètò pé kí ẹlòmíì lọ sọ́dọ̀ ẹ̀ kó lè bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Bí ìkẹ́kọ̀ọ́ náà ṣe ń tẹ̀ síwájú, inú wa máa ń dùn bá a ṣe ń rí i tí Jèhófà ń ran ẹni náà lọ́wọ́ láti ṣe àwọn ìyípadà tó yẹ nígbèésí ayé ẹ̀.19 Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ ọkùnrin kan lórílẹ̀-èdè South Africa tó ń jẹ́ Raphalalani tó fìgbà kan rí jẹ́ babaláwo. Ó fẹ́ràn ohun tó kọ́ látinú Bíbélì. Àmọ́ ó ṣòro fún un láti fara mọ́ ohun tí Bíbélì sọ pé kò yẹ ká máa bá òkú sọ̀rọ̀. (Diu. 18:10-12) Bọ́jọ́ ṣe ń gorí ọjọ́, ó jẹ́ kí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run yí òun lérò pa dà. Nígbẹ̀yìngbẹ́yín, kò ṣe iṣẹ́ babaláwo mọ́ bó tiẹ̀ jẹ́ pé ìyẹn gba ìjẹ lẹ́nu ẹ̀. Ní báyìí, Raphalalani ti pé ẹni ọgọ́ta (60) ọdún, ó sọ pé: “Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn ará tí wọ́n bámi wáṣẹ́ tí wọ́n sì tún ṣe àwọn nǹkan míì fún mi. Ju gbogbo ẹ̀ lọ, mo dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà tó bá mi tún ìgbésí ayé mi ṣe, torí pé ní báyìí mo ti ń wàásù fáwọn ẹlòmíì, mo ti ṣèrìbọmi, mo sì ti di ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà.”
20. Kí lo pinnu pé wàá ṣe?
20 Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a ti sọ̀rọ̀ nípa àwọn ìṣúra mẹ́rin tá ò lè fojú rí. Èyí tó ṣe pàtàkì jù nínú wọn ni bá a ṣe jẹ́ ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Jèhófà. Èyí ló mú kó ṣeé ṣe fún wa láti ní àwọn ìṣúra míì, ìyẹn bá a ṣe ń bá a sọ̀rọ̀ nínú àdúrà, bí ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ ṣe ń darí wa, tí Òun, Jésù àtàwọn áńgẹ́lì sì ń tì wá lẹ́yìn lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù. Torí náà, ẹ jẹ́ ká pinnu pé àá túbọ̀ mọyì àwọn ìṣúra tá ò lè fojú rí yìí. Ẹ sì jẹ́ ká máa fi gbogbo ọjọ́ ayé wa dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà tó jẹ́ ká lè máa bá òun ṣọ̀rẹ́.
ORIN 145 Ọlọ́run Ṣèlérí Párádísè
^ ìpínrọ̀ 5 Nínú àpilẹ̀kọ tó ṣáájú, a jíròrò díẹ̀ lára àwọn ìṣúra tí Jèhófà fún wa tá a lè fojú rí. Ní báyìí, a máa sọ̀rọ̀ nípa àwọn ìṣúra tá ò lè fojú rí àti bá a ṣe lè fi hàn pé a mọyì wọn. Bákan náà, àá sọ bá a ṣe lè túbọ̀ mọyì Jèhófà tó fún wa láwọn ìṣúra náà.
^ ìpínrọ̀ 58 ÀWÒRÁN Ojú Ìwé: (1) Arábìnrin kan ń wo àwọn nǹkan tí Jèhófà dá, ó sì ń ṣàṣàrò lórí bóun ṣe jẹ́ ọ̀rẹ́ Jèhófà.
^ ìpínrọ̀ 60 ÀWÒRÁN Ojú Ìwé: (2) Arábìnrin náà ń gbàdúrà pé kí Jèhófà jẹ́ kí òun ní ìgboyà láti wàásù.
^ ìpínrọ̀ 62 ÀWÒRÁN Ojú Ìwé: (3) Ẹ̀mí mímọ́ fún arábìnrin náà nígboyà láti wàásù lọ́nà àìjẹ́-bí-àṣà.
^ ìpínrọ̀ 64 ÀWÒRÁN Ojú Ìwé:(4) Arábìnrin náà ń kọ́ ẹni tó wàásù fún lọ́nà àìjẹ́-bí-àṣà lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Àwọn áńgẹ́lì ń ti arábìnrin náà lẹ́yìn bó ṣe ń wàásù tó sì ń sọni di ọmọ ẹ̀yìn.