Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 20

Má Jẹ́ Kó Sú Ẹ Tó Bá Ṣòro Láti Wàásù Lágbègbè Yín

Má Jẹ́ Kó Sú Ẹ Tó Bá Ṣòro Láti Wàásù Lágbègbè Yín

“Fún irúgbìn rẹ . . . má sì dẹwọ́.”​—ONÍW. 11:6.

ORIN 70 Ẹ Wá Àwọn Ẹni Yíyẹ Kàn

OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒ *

Lẹ́yìn tí Jésù pa dà sọ́run, àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ fìtara wàásù ní Jerúsálẹ́mù àtàwọn agbègbè míì (Wo ìpínrọ̀ 1)

1. Àpẹẹrẹ wo ni Jésù fi lélẹ̀ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀, kí làwọn náà sì ṣe? (Wo àwòrán iwájú ìwé.)

ỌWỌ́ gidi ni Jésù fi mú iṣẹ́ ìwàásù nígbà tó wà láyé, ohun tó sì fẹ́ káwọn ọmọlẹ́yìn ẹ̀ ṣe náà nìyẹn. (Jòh. 4:35, 36) Nígbà tí Jésù ṣì wà pẹ̀lú àwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀, tìtaratìtara làwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ fi wàásù. (Lúùkù 10:1, 5-11, 17) Àmọ́ lẹ́yìn táwọn alátakò mú Jésù tí wọ́n sì pa á, àwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ dẹwọ́ fúngbà díẹ̀. (Jòh. 16:32) Lẹ́yìn tí Jésù jíǹde, ó gba àwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ níyànjú pé kí wọ́n tẹra mọ́ iṣẹ́ ìwàásù. Lẹ́yìn tí Jésù pa dà sọ́run, àwọn ọmọ ẹ̀yìn fìtara wàásù débi táwọn alátakò fi sọ pé: “Ẹ wò ó! ẹ ti fi ẹ̀kọ́ yín kún Jerúsálẹ́mù.”​—Ìṣe 5:28.

2. Báwo ni Jèhófà ṣe bù kún iṣẹ́ ìwàásù táwọn ọmọlẹ́yìn ṣe?

2 Jésù ló darí iṣẹ́ ìwàásù táwọn Kristẹni ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní ṣe, Jèhófà sì bù kún wọn débi pé ọ̀pọ̀ èèyàn dara pọ̀ mọ́ wọn. Bí àpẹẹrẹ, ní Pẹ́ńtíkọ́sì 33 S.K., nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́ta (3,000) ló ṣèrìbọmi. (Ìṣe 2:41) Bọ́jọ́ ṣe ń gorí ọjọ́, bẹ́ẹ̀ ni iye àwọn ọmọlẹ́yìn ń pọ̀ sí i. (Ìṣe 6:7) Síbẹ̀, Jésù sọ tẹ́lẹ̀ pé iṣẹ́ ìwàásù náà máa dé ọ̀pọ̀ ibi láyé láwọn ọjọ́ ìkẹyìn, ọ̀pọ̀ èèyàn sì máa di ọmọlẹ́yìn.​—Jòh. 14:12; Ìṣe 1:8.

3-4. Kí nìdí tó fi ṣòro láti wàásù láwọn ibì kan, kí la sì máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí?

3 Ó máa ń wu gbogbo wa láti kópa tó jọjú lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù. Láwọn ilẹ̀ kan, ó máa ń rọrùn láti wàásù. Kí nìdí? Ìdí ni pé láwọn ilẹ̀ yẹn, ọ̀pọ̀ èèyàn ló fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Kódà, àwọn tó fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì máa ń pọ̀ débi pé àwọn akéde kì í lè kárí wọn. Àmọ́ láwọn ibòmíì, kò rọrùn láti wàásù. Ìdí ni pé àwọn èèyàn kì í sábà sí nílé, àwọn tó bá sì wà nílé lè má nífẹ̀ẹ́ sọ́rọ̀ wa.

4 Tó bá jẹ́ pé ibi tí iṣẹ́ ìwàásù ò ti rọrùn lò ń gbé, àwọn ohun tá a máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí máa jẹ́ kó o mọ ohun tó o lè ṣe. A máa sọ ohun táwọn kan ti ṣe kí wọ́n lè rí ọ̀pọ̀ èèyàn bá sọ̀rọ̀. A tún máa sọ̀rọ̀ nípa ohun tí ò ní jẹ́ ká rẹ̀wẹ̀sì yálà àwọn èèyàn tẹ́tí sí wa tàbí wọn ò ṣe bẹ́ẹ̀.

MÁ JẸ́ KÓ SÚ Ẹ TÓ BÁ ṢÒRO LÁTI RÍ ÀWỌN ÈÈYÀN BÁ SỌ̀RỌ̀

5. Ìṣòro wo làwọn ará kan ní?

5 Ó túbọ̀ ń nira gan-an fún ọ̀pọ̀ àwọn ará wa láti bá àwọn èèyàn nílé. Ilé tó ní àwọn ẹ̀ṣọ́ lẹ́nu géètì tàbí àwọn àdúgbò tí wọ́n máa ń ti géètì rẹ̀ pọ̀ ní ìpínlẹ̀ ìwàásù àwọn akéde kan. Láwọn agbègbè yìí, àwọn ẹ̀ṣọ́ kì í jẹ́ kí ẹnikẹ́ni wọlé àfi tí onítọ̀hún bá ní àdéhùn pẹ̀lú ẹnì kan tó ń gbé ibẹ̀. Ní ti àwọn akéde míì, wọ́n lè lọ láti ilé kan sí òmíì láìsí ìdíwọ́, àmọ́ wọn kì í sábà bá àwọn èèyàn nílé. Àwọn akéde míì sì ń wàásù láwọn ìgbèríko tàbí agbègbè táwọn èèyàn ò fi bẹ́ẹ̀ pọ̀ sí. Nígbà míì, àwọn akéde yìí lè rin ìrìn àrìnwọ́dìí láti wá ẹnì kan lọ, síbẹ̀ kí wọ́n má bá a nílé. Ìṣòro yòówù ká máa kojú lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù, ẹ má jẹ́ kó sú wa. Kí la lè ṣe táá jẹ́ ká máa rí ọ̀pọ̀ èèyàn bá sọ̀rọ̀?

6. Báwo làwa tá à ń wàásù ṣe dà bí àwọn apẹja?

6 Jésù fi iṣẹ́ ìwàásù wé iṣẹ́ ẹja pípa. (Máàkù 1:17) Nígbà míì, àwọn apẹja lè wà lójú omi fún ọ̀pọ̀ ọjọ́ kí wọ́n má sì rí ẹja pa. Àmọ́ wọn kì í jẹ́ kó sú wọn. Ṣe ni wọ́n máa ń dá àwọn ọgbọ́n míì. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n lè lọ ní àkókò tó yàtọ̀, kí wọ́n lọ sí apá ibòmíì lórí omi tàbí kí wọ́n yí ọ̀nà tí wọ́n ń gbà pẹja pa dà. Àwa náà lè ṣe àwọn àyípadà kan bíi tàwọn apẹja. Ní báyìí, ẹ jẹ́ ká jíròrò àwọn àbá tó tẹ̀ lé e yìí.

Tó bá jẹ́ pé àdúgbò táwọn èèyàn kì í sábà sí nílé lo ti ń wàásù, gbìyànjú láti lọ lásìkò tí wọ́n máa wà nílé tàbí kó o lọ síbi tó ṣeé ṣe kó o ti rí àwọn èèyàn. O sì lè wàásù láwọn ọ̀nà míì (Wo ìpínrọ̀ 7-10) *

7. Kí ló lè ṣẹlẹ̀ tá a bá wàásù lákòókò tó yàtọ̀ síra?

7 Gbìyànjú láti wàásù lákòókò tó yàtọ̀ síra. A máa rí ọ̀pọ̀ èèyàn bá sọ̀rọ̀ tá a bá lọ lásìkò tá a mọ̀ pé wọ́n máa wà nílé. Ó ṣe tán, ilé làbọ̀ sinmi oko. Ọ̀pọ̀ àwọn ará máa ń lọ sóde ẹ̀rí ní ọ̀sán tàbí lọ́wọ́ ìrọ̀lẹ́ torí wọ́n mọ̀ pé ọ̀pọ̀ èèyàn máa wà nílé lásìkò yẹn. Yàtọ̀ síyẹn, ara máa ń tu àwọn èèyàn lásìkò yẹn, wọ́n sì máa ń fàyè sílẹ̀ ká lè bá wọn sọ̀rọ̀. Bákan náà, o lè fi ohun tí alàgbà kan tó ń jẹ́ David sọ sílò. Ó sọ pé lẹ́yìn tí òun àtẹni tí àwọn jọ ṣiṣẹ́ lóde ẹ̀rí bá parí iṣẹ́, àwọn tún máa ń pa dà sọ́dọ̀ àwọn táwọn ò bá nílé lọ́jọ́ yẹn kan náà. Ó fi kún un pé: “Ó máa ń yà mí lẹ́nu pé ọ̀pọ̀ àwọn tá ò bá nílé nígbà àkọ́kọ́ la máa ń bá nígbà tá a bá pa dà lọ.” *

Tó bá jẹ́ pé àdúgbò táwọn èèyàn kì í sábà sí nílé lo ti ń wàásù, gbìyànjú láti lọ lásìkò tí wọ́n máa wà nílé (Wo ìpínrọ̀ 7-8)

8. Báwo la ṣe lè fi ohun tó wà nínú Oníwàásù 11:6 sílò lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù wa?

8 Bó ti wù kó nira tó, a ò gbọ́dọ̀ jẹ́ kó sú wa láti máa wá àwọn èèyàn. Ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tá a gbé àpilẹ̀kọ yìí kà sọ ohun tó yẹ ká ṣe. (Ka Oníwàásù 11:6.) David tá a sọ̀rọ̀ ẹ̀ lẹ́ẹ̀kan ò jẹ́ kó sú òun. Lẹ́yìn tó pààrà ilé kan lọ́pọ̀ ìgbà, lọ́jọ́ kan, ó bá onílé náà. Inú ọkùnrin tó bá nílé dùn láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ọkùnrin náà sọ pé: “Ọdún kẹjọ mi rèé tí mo ti ń gbé níbí, àmọ́ mi ò rí i kí Ẹlẹ́rìí Jèhófà kankan wá sílé mi.” David wá sọ pé: “Àwọn tá a bá pa dà bá nílé lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn sábà máa ń nífẹ̀ẹ́ sí ọ̀rọ̀ wa.”

Tó bá jẹ́ pé àdúgbò táwọn èèyàn kì í sábà sí nílé lo ti ń wàásù, lọ síbi tó ṣeé ṣe kó o ti rí àwọn èèyàn (Wo ìpínrọ̀ 9)

9. Kí làwọn ará wa kan ti ṣe kí wọ́n lè wàásù fáwọn tó ṣòro bá nílé?

9 Wá wọn lọ síbòmíì. Káwọn ará wa lè wàásù fáwọn tó ṣòro bá nílé, wọ́n ṣètò láti lọ wàásù níbi tí wọ́n ti lè bá àwọn èèyàn pàdé. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n máa ń wàásù ní òpópónà tàbí kí wọ́n lo àwọn àtẹ ìwé, ìyẹn sì ti jẹ́ kí wọ́n lè wàásù fáwọn èèyàn tó ń gbé láwọn ibi tá ò ti lè wàásù láti ilé dé ilé. Bákan náà, ọ̀pọ̀ akéde ti rí i pé ó máa ń yá àwọn èèyàn lára láti gbọ́ ìwàásù tàbí láti gba ìwé wa tá a bá pàdé wọn níbi ìgbafẹ́, ní ọjà tàbí ibi táwọn ilé iṣẹ́ wà. Floiran tó jẹ́ alábòójútó àyíká ní Bòlífíà sọ pé: “A máa ń lọ wàásù ní ọjà àti láwọn ibi tí ilé iṣẹ́ wà láàárín aago kan sí mẹ́ta ọ̀sán torí pé àsìkò yẹn lọwọ́ àwọn ọlọ́jà máa ń dilẹ̀. Àwọn èèyàn sábà máa ń gbọ́ wa, kódà a máa ń bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú wọn.”

Tó bá jẹ́ pé àdúgbò táwọn èèyàn kì í sábà sí nílé lo ti ń wàásù, wá àwọn ọ̀nà míì tí wàá máa gbà wàásù fáwọn èèyàn (Wo ìpínrọ̀ 10)

10. Kí lohun míì tó o lè ṣe kó o lè rí àwọn èèyàn wàásù fún?

10 Lo ọ̀nà míì láti wàásù. Ká sọ pé o ti wá ẹnì kan lọ lọ́pọ̀ ìgbà tó o sì ti lọ láwọn àkókò tó yàtọ̀ síra, síbẹ̀ tó ò bá ẹni náà nílé, kí lo lè ṣe? Katarína sọ pé: “Mo máa ń kọ lẹ́tà sáwọn tí mo ti wá lọ lọ́pọ̀ ìgbà àmọ́ tí mi ò bá nílé. Ohun tí mo fẹ́ sọ fún wọn tí mo bá rí wọn ni mo máa ń kọ sínú lẹ́tà náà.” Ẹ̀kọ́ ibẹ̀ ni pé o lè lo onírúurú ọ̀nà láti kàn sáwọn tó wà ní ìpínlẹ̀ ìwàásù yín.

MÁ JẸ́ KÓ SÚ Ẹ TÁWỌN ÈÈYÀN Ò BÁ FẸ́ GBỌ́ ÌWÀÁSÙ

11. Kí nìdí táwọn kan kì í fẹ́ gbọ́ ìwàásù wa?

11 Àwọn kan kì í fẹ́ gbọ́ ìwàásù wa. Àwọn kan ò sì rídìí tó fi yẹ kí wọ́n mọ̀ nípa Ọlọ́run tàbí Bíbélì. Wọn ò gbà pé Ọlọ́run wà nítorí ìyà tó ń jẹ aráyé. Wọn ò gba Bíbélì gbọ́ torí wọ́n rí i pé ìwà àgàbàgebè ló kún ọwọ́ àwọn aṣáájú ẹ̀sìn tó sọ pé àwọn gba Bíbélì gbọ́. Ohun tó gba àwọn míì lọ́kàn ni ọ̀rọ̀ iṣẹ́ wọn, ìdílé wọn àtàwọn ìṣòro míì, wọn ò sì gbà pé Bíbélì lè ran àwọn lọ́wọ́. Kí ni ò ní jẹ́ káyọ̀ wa pẹ̀dín táwọn èèyàn ò bá tiẹ̀ fẹ́ gbọ́ ìwàásù wa?

12. Báwo lohun tó wà nínú Fílípì 2:4 ṣe lè mú ká túbọ̀ ráwọn èèyàn bá sọ̀rọ̀ lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù?

12 Fi hàn pé o nífẹ̀ẹ́ wọn. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn kan ò fẹ́ gbọ́rọ̀ wa lákọ̀ọ́kọ́, wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀ torí pé akéde tó fẹ́ bá wọn sọ̀rọ̀ fìfẹ́ hàn sí wọn. (Ka Fílípì 2:4.) Bí àpẹẹrẹ, David tá a sọ̀rọ̀ ẹ̀ lẹ́ẹ̀kan sọ pé: “Tẹ́nì kan bá sọ pé òun ò fẹ́ gbọ́rọ̀ wa, ṣe la máa ń fi Bíbélì wa àti ìwé tá a fẹ́ fún un sínú àpò pa dà. Àá wá bi í pé: ‘Ṣé ò sí tẹ́ ẹ fi sọ bẹ́ẹ̀.’ ” Àwọn èèyàn máa ń mọ̀ tẹ́nì kan bá nífẹ̀ẹ́ wọn lóòótọ́. Wọ́n lè má rántí ohun tá a sọ ní pàtó, àmọ́ wọn ò ní gbàgbé bá a ṣe fìfẹ́ hàn sí wọn. Kódà, bí ẹnì kan ò bá tiẹ̀ fẹ́ gbọ́rọ̀ wa rárá, a lè jẹ́ kó hàn nínú ojú wa àti ìṣesí wa pé a nífẹ̀ẹ́ rẹ̀.

13. Kí la lè ṣe tí ọ̀rọ̀ wa fi máa wọ onírúurú èèyàn lọ́kàn?

13 A lè fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn tá a bá jẹ́ kí ọ̀rọ̀ wa bá ipò wọn mu. Bí àpẹẹrẹ, ǹjẹ́ a rí àmì tó fi hàn pé àwọn ọmọ kéékèèké wà nínú ilé náà? O ò ṣe jíròrò ohun tí Bíbélì sọ nípa bá a ṣe lè tọ́ àwọn ọmọ yanjú tàbí bí ìdílé ṣe lè túbọ̀ láyọ̀, ó ṣeé ṣe kíyẹn wọ àwọn òbí wọn lọ́kàn. Ṣé o kíyè sí i pé kì í ṣe àgádágodo kan péré ni wọ́n fi ti ilẹ̀kùn wọn? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, a lè sọ̀rọ̀ nípa bí ìwà ọ̀daràn ṣe gbilẹ̀ kárí ayé àti ohun tí Ọlọ́run máa ṣe sí i, ó ṣeé ṣe kíyẹn wọ ẹni náà lọ́kàn. Ẹni yòówù kó tẹ́tí sí wa, ẹ jẹ́ ká rí i dájú pé a jẹ́ kí wọ́n mọ bí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣe lè ràn wọ́n lọ́wọ́. Katarína tá a sọ̀rọ̀ ẹ̀ lẹ́ẹ̀kan sọ pé: “Mo máa ń rántí bí òtítọ́ ṣe tún ayé mi ṣe.” Ìyẹn máa ń jẹ́ kó fi ìdánilójú sọ̀rọ̀, àwọn tó sì ń bá sọ̀rọ̀ máa ń rí i pé ohun tó sọ dá a lójú lóòótọ́.

14. Bó ṣe wà nínú Òwe 27:17, báwo làwọn tí wọ́n jọ ṣiṣẹ́ lóde ẹ̀rí ṣe lè ran ara wọn lọ́wọ́?

14 Jẹ́ káwọn míì ràn ẹ́ lọ́wọ́. Ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní, Pọ́ọ̀lù jẹ́ kí Tímótì mọ bí òun ṣe ń wàásù àti bí òun ṣe ń kọ́ni, ó sì gba Tímótì níyànjú pé kóun náà máa wàásù kó sì máa kọ́ni lọ́nà yẹn. (1 Kọ́r. 4:17) Bíi ti Tímótì, àwa náà lè kẹ́kọ̀ọ́ látọ̀dọ̀ àwọn tó nírìírí nínú ìjọ wa. (Ka Òwe 27:17.) Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ arákùnrin kan tó ń jẹ́ Shawn. Ìgbà kan wà tó ṣiṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà ní abúlé kan tí ọ̀pọ̀ ti gbà pé ìsìn táwọn ń ṣe tẹ́ àwọn lọ́rùn. Kí ni ò jẹ́ kí ayọ̀ ẹ̀ pẹ̀dín? Ó sọ pé: “Nígbàkigbà tó bá ṣeé ṣe, mo máa ń bá àwọn míì ṣiṣẹ́ lóde ẹ̀rí. A máa ń lo àkókò tá a fi ń rìn láti ilé kan sí òmíì láti jíròrò ohun tá a lè ṣe táá jẹ́ káwọn èèyàn tẹ́tí sí wa. Bí àpẹẹrẹ, a máa jíròrò ohun tí onílé yẹn sọ àti èsì tá a fún un. Lẹ́yìn náà, àá wá jíròrò ohun tá a lè sọ tá a bá tún bá irú ẹ̀ pàdé.”

15. Kí nìdí tó fi yẹ ká fọ̀rọ̀ iṣẹ́ ìwàásù wa sádùúrà?

15 Bẹ Jèhófà pé kó ràn ẹ́ lọ́wọ́. Gbàdúrà pé kí Jèhófà tọ́ ẹ sọ́nà ní gbogbo ìgbà tó o bá lọ sóde ẹ̀rí. Kò sí ohun tá a lè dá ṣe láìsí ìrànlọ́wọ́ ẹ̀mí mímọ́. (Sm. 127:1; Lúùkù 11:13) Tó o bá ń gbàdúrà pé kí Jèhófà ràn ẹ́ lọ́wọ́, sọ ohun tó o fẹ́ kó ṣe fún ẹ ní pàtó. Bí àpẹẹrẹ, bẹ̀ ẹ́ pé kó darí ẹ lọ sọ́dọ̀ àwọn tó fẹ́ mọ òtítọ́ tí wọ́n sì ṣe tán láti gbọ́. Kó o wá fi iṣẹ́ ti àdúrà náà lẹ́yìn, kó o sì wàásù fún gbogbo àwọn tó o bá pàdé.

16. Kí nìdí tí ìdákẹ́kọ̀ọ́ fi ṣe pàtàkì ká tó lè ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa láṣeyanjú?

16 Máa dá kẹ́kọ̀ọ́ déédéé. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ pé: ‘Fúnra rẹ ṣàwárí ìfẹ́ Ọlọ́run tí ó dára, tí ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà, tí ó sì pé.’ (Róòmù 12:2) Bí òtítọ́ tá a mọ̀ nípa Ọlọ́run bá ṣe dá wa lójú tó, bẹ́ẹ̀ làá máa fìgboyà wàásù fáwọn èèyàn. Katarína tá a sọ̀rọ̀ ẹ̀ lẹ́ẹ̀kan sọ pé: “Lẹ́nu àìpẹ́ yìí, mo rí i pé ó yẹ kí n jẹ́ kí àwọn òtítọ́ Bíbélì kan túbọ̀ dá mi lójú. Torí náà, mo fara balẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ kó lè túbọ̀ dá mi lójú pé Ẹlẹ́dàá kan wà, pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni Bíbélì lóòótọ́ àti pé Ọlọ́run ní ètò kan tó ń lò lónìí.” Katarína sọ pé bóun ṣe dá kẹ́kọ̀ọ́ yẹn jẹ́ kí ìgbàgbọ́ òun túbọ̀ lágbára, kóun sì túbọ̀ láyọ̀ lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù.

ÌDÍ TÁ Ò FI JẸ́ KÓ SÚ WA

17. Kí nìdí tí Jésù ò fi ṣíwọ́ àtimáa wàásù?

17 Jésù ò ṣíwọ́ àtimáa wàásù bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn kan ò tẹ́tí sí i. Kí nìdí? Ìdí ni pé ó mọ bó ti ṣe pàtàkì tó pé káwọn èèyàn mọ òtítọ́, ó sì fẹ́ ràn wọ́n lọ́wọ́. Ó mọ̀ pé àwọn kan tí wọn ò tẹ́tí sí òun nígbà yẹn ṣì máa pa dà nígbàgbọ́ nínú òun. Bọ́rọ̀ àwọn àbúrò ẹ̀ sì ṣe rí gẹ́lẹ́ nìyẹn. Ní gbogbo ọdún mẹ́ta àtààbọ̀ tó fi wàásù, kò sí ìkankan lára wọn tó di ọmọlẹ́yìn rẹ̀. (Jòh. 7:5) Àmọ́ lẹ́yìn tí Jésù jíǹde, wọ́n di Kristẹni.​—Ìṣe 1:14.

18. Kí nìdí tí kò fi yẹ káwa náà ṣíwọ́ àtimáa wàásù?

18 A ò mọ ẹni tó ṣì máa wá kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ tó sì máa di ìránṣẹ́ Jèhófà. Ó lè pẹ́ káwọn kan tó gbà pé òtítọ́ la fi ń kọ́ni kí wọ́n sì gbé ìgbésẹ̀. Kódà, àwọn tí ò fetí sí wa lè kíyè sí ìwà rere wa kí wọ́n sì wá “yin Ọlọ́run lógo” nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín.​—1 Pét. 2:12.

19. Kí ni 1 Kọ́ríńtì 3:6, 7 sọ tá a gbọ́dọ̀ fi sọ́kàn?

19 Bá a ṣe ń gbìn tá a sì ń bomi rin, a gbọ́dọ̀ fi sọ́kàn pé Ọlọ́run ló ń mú kó dàgbà. (Ka 1 Kọ́ríńtì 3:6, 7.) Arákùnrin Getahun tó ń gbé lórílẹ̀-èdè Etiópíà sọ pé: “Fún ohun tó lé ní ogún (20) ọdún, èmi nìkan ni Ẹlẹ́rìí lágbègbè tí mò ń gbé. Àmọ́ ní báyìí, àwa akéde mẹ́rìnlá (14) la wà níbí. Lára àwọn tó ṣèrìbọmi ni ìyàwó mi àtàwọn ọmọ mi mẹ́ta pẹ̀lú àwọn mẹ́sàn-án míì. Nígbà míì, a máa ń tó méjìlélọ́gbọ̀n (32) nípàdé.” Getahun ń fayọ̀ wàásù, kò sì jẹ́ kó sú òun títí Jèhófà fi fa àwọn tó nífẹ̀ẹ́ òtítọ́ sínú ètò rẹ̀.​—Jòh. 6:44.

20. Báwo la ṣe dà bí àwọn tó ń gbẹ̀mí là?

20 Gbogbo èèyàn ló ṣeyebíye lójú Jèhófà. Abájọ tó fi fún wa láǹfààní láti máa bá Ọmọ rẹ̀ ṣiṣẹ́ bó ṣe ń kó àwọn èèyàn jọ láti gbogbo orílẹ̀-èdè kí òpin tó dé. (Hág. 2:7) Ṣe ni iṣẹ́ ìwàásù wa dà bí iṣẹ́ àwọn tó ń gbẹ̀mí là. A dà bí àwùjọ àwọn tó ń gbẹ̀mí là tí wọ́n rán láti dóòlà ẹ̀mí àwọn tó wà nínú ọkọ̀ ojú omi tó ń rì. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ìwọ̀nba lára wọn ni wọ́n á lè dóòlà ẹ̀mí ẹ̀, iṣẹ́ gbogbo àwọn tó ń gbẹ̀mí là náà ò já sásán. Bákan náà lọ̀rọ̀ iṣẹ́ ìwàásù wa rí. A ò mọ bí àwọn tá a ṣì máa rí yọ nínú ayé Èṣù yìí ṣe máa pọ̀ tó. Ẹnikẹ́ni lára wa ni Jèhófà sì lè lò láti ràn wọ́n lọ́wọ́. Andreas tó ń gbé lórílẹ̀-èdè Bòlífíà sọ pé: “Mo gbà pé àjọṣe gbogbo wa ni tẹ́nì kan bá kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ tó sì ṣèrìbọmi.” Ká máa rántí pé àwa nìkan kọ́ là ń ṣiṣẹ́ yìí, torí náà ká má jẹ́ kó sú wa. Tá ò bá dẹwọ́, Jèhófà máa bù kún wa, àá sì máa láyọ̀ bá a ṣe ń ṣiṣẹ́ náà.

ORIN 66 Ẹ Kéde Ìhìn Rere Náà

^ ìpínrọ̀ 5 Kí la lè ṣe tí iṣẹ́ ìwàásù ò fi ní sú wa tó bá jẹ́ pé a kì í báwọn èèyàn nílé tàbí wọn kì í fẹ́ tẹ́tí sí wa? Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa jíròrò àwọn nǹkan tó máa ràn wá lọ́wọ́.

^ ìpínrọ̀ 7 Àbá yòówù tẹ́ ẹ bá pinnu láti tẹ̀ lé nínú àpilẹ̀kọ yìí, ẹ rí i dájú pé ó bá òfin mu tó bá kan ọ̀rọ̀ lílo ìsọfúnni ẹlòmíì.

^ ìpínrọ̀ 60 ÀWÒRÁN: (látòkèdélẹ̀): Tọkọtaya kan ń wàásù láwọn ibi tó ti ṣòro láti bá àwọn èèyàn nílé. Ẹni tó ń gbé ilé àkọ́kọ́ ti lọ síbi iṣẹ́, èkejì lọ sílé ìwòsàn, nígbà tí ẹ̀kẹta lọ rajà. Tọkọtaya náà wá ẹni àkọ́kọ́ lọ sílé lọ́wọ́ ìrọ̀lẹ́. Wọ́n bá ẹnì kejì pàdé níbi tí wọ́n pàtẹ ìwé wa sí nítòsí ilé ìwòsàn. Wọ́n sì pe ẹnì kẹta lórí fóònù.