Ọ̀rọ̀ Àpọ́nlé Tó Ń Tuni Lára!
JÉSÙ máa ń lo ọ̀rọ̀ náà “obìnrin” nígbà míì tó bá fẹ́ pọ́n àwọn obìnrin lé. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tó rí aláìsàn kan tí ẹ̀yìn rẹ̀ ti ká kò fún ọdún méjìdínlógún [18] tó sì fẹ́ wò ó sàn, Jésù sọ pé: “Obìnrin, a tú ọ sílẹ̀ kúrò nínú àìlera rẹ.” (Lúùkù 13:10-13) Àwọn Júù máa ń lo èdè àpọ́nlé yìí fáwọn obìnrin lásìkò tí wọ́n ń kọ Bíbélì. Ìdí nìyẹn tí Jésù náà fi lo èdè yìí fún ìyá rẹ̀. (Jòh. 19:26; 20:13) Àmọ́ ọ̀rọ̀ míì wà tó tuni lára ju èdè àpọ́nlé yìí lọ.
Bíbélì lo ọ̀rọ̀ tó ń tuni lára yìí nígbà tó ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn obìnrin kan. Jésù náà sì lò ó nígbà tó ń bá obìnrin kan sọ̀rọ̀, obìnrin yìí ti ní àìsàn ìsun ẹ̀jẹ̀ fún ọdún méjìlá. Ọ̀nà tí obìnrin náà gbà yọ sí Jésù kò bá Òfin Mósè mu torí pé Òfin yẹn sọ pé ẹni tó bá ní ìsun ẹ̀jẹ̀ jẹ́ aláìmọ́. Òótọ́ ni pé kò yẹ kí obìnrin yìí wá sáàárín èrò torí irú àìsàn tó ní. (Léf. 15:19-27) Àmọ́, àìsàn yẹn ti sú u. Kódà, ‘ọ̀pọ̀ oníṣègùn ti mú ọ̀pọ̀ ìrora bá a, ó sì ti ná gbogbo ohun àmúṣọrọ̀ rẹ̀, kò sì ṣe é láǹfààní ṣùgbọ́n, kàkà bẹ́ẹ̀, ó burú sí i.’—Máàkù 5:25, 26.
Obìnrin náà rọra yọ́ wọ àárín èrò, ó sún mọ́ Jésù látẹ̀yìn, ó sì fọwọ́ kan etí aṣọ rẹ̀. Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ìsun ẹ̀jẹ̀ náà dáwọ́ dúró! Obìnrin náà wá rò pé òun lè yọ́ kúrò níbẹ̀ láìjẹ́ kí ẹnikẹ́ni mọ̀, àmọ́ Jésù béèrè pé: “Ta ni ẹni tí ó fọwọ́ kàn mí?” (Lúùkù 8:45-47) Ẹ̀rù ba obìnrin náà, ló bá sáré wólẹ̀ síwájú Jésù, ó sì jẹ́wọ́ fún un.—Máàkù 5:33.
Kí ọkàn obìnrin náà lè balẹ̀, Jésù sọ fún un pé: “Mọ́kànle, ọmọbìnrin.” (Mát. 9:22) Àwọn ọ̀mọ̀wé Bíbélì kan sọ pé ọ̀rọ̀ Hébérù àti Gíríìkì tí wọ́n tú sí “ọmọbìnrin” jẹ́ “ọ̀rọ̀ onínúure àti ọ̀rọ̀ jẹ̀lẹ́ńkẹ́.” Jésù tún fi obìnrin náà lọ́kàn balẹ̀ nígbà tó sọ fún un pé: “Ìgbàgbọ́ rẹ ti mú ọ lára dá. Máa lọ ní àlàáfíà, kí o sì ní ìlera kúrò lọ́wọ́ àìsàn burúkú tí ń ṣe ọ́.”—Máàkù 5:34.
Bákan náà, Bóásì tó jẹ́ ọmọ Ísírẹ́lì pe Rúùtù tó jẹ́ ọmọ Móábù ní “ọmọbìnrin.” Ó ṣeé ṣe kẹ́rù máa ba Rúùtù torí pé inú oko ọkùnrin tí kò mọ̀ rí ló ti wá pèéṣẹ́. Àmọ́ nígbà tí Bóásì fẹ́ bá a sọ̀rọ̀, ó ní: “Gbọ́, ọmọbìnrin mi.” Ó wá ní kí Rúùtù máa pèéṣẹ́ nìṣó lóko òun. Rúùtù wá wólẹ̀ níwájú Bóásì, ó sì béèrè ìdí tí Bóásì fi ń ṣàánú òun láìka ti pé àjèjì lòun. Bóásì fi í lọ́kàn balẹ̀, ó sọ fún un pé: “A ròyìn fún mi ní kíkún nípa gbogbo ohun tí o ṣe fún ìyá ọkọ rẹ [ìyẹn Náómì tó jẹ́ opó] . . . Kí Jèhófà san ọ́ lẹ́san fún bí o ṣe hùwà.”—Rúùtù 2:8-12.
Àpẹẹrẹ àtàtà ni Jésù àti Bóásì fi lélẹ̀ fáwọn alàgbà lónìí. Nígbà míì, àwọn alàgbà méjì lè ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ arábìnrin kan tó nílò ìṣírí àti ìtọ́sọ́nà látinú Ìwé Mímọ́. Á dáa káwọn alàgbà náà gbàdúrà pé kí Jèhófà tọ́ àwọn sọ́nà, lẹ́yìn náà kí wọ́n fetí sílẹ̀ dáadáa sí ohun tí arábìnrin náà bá sọ. Èyí á mú kí wọ́n lè fi arábìnrin náà lọ́kàn balẹ̀, wọ́n á sì lè sọ̀rọ̀ ìtùnú fún un látinú Ìwé Mímọ́.—Róòmù 15:4.