A Ó Bù Kún Ẹni Tí Ó Jẹ́ Ọ̀làwọ́
ỌJỌ́ pẹ́ táwọn olùjọsìn tòótọ́ ti máa ń rúbọ. Bí àpẹẹrẹ, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa ń fi ẹran rúbọ, ìgbà gbogbo làwọn Kristẹni náà sì máa ń rú “ẹbọ ìyìn.” Bó ti wù kó rí, àwọn ẹbọ míì wà tá a lè rú táá múnú Ọlọ́run dùn. (Héb. 13:15, 16) Nínú àwọn àpẹẹrẹ tá a fẹ́ gbé yẹ̀ wò báyìí, a máa rí i pé tá a bá ń rú àwọn ẹbọ yìí sí Jèhófà, àá láyọ̀, á sì bù kún wa.
Àpẹẹrẹ kan ni ti Hánà, tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà láyé àtijọ́. Ó wù ú gan-an pé kóun bímọ, àmọ́ kò rọ́mọ bí. Ó yíjú sí Jèhófà, ó sì ṣèlérí pé tí Jèhófà bá fún òun lọ́mọkùnrin, òun á “fi í fún Jèhófà ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀.” (1 Sám. 1:10, 11) Nígbà tó yá Hánà lóyún, ó bí ọmọkùnrin kan, ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Sámúẹ́lì. Lẹ́yìn tí Hánà já Sámúẹ́lì lẹ́nu ọmú, ó mú un lọ sí àgọ́ ìjọsìn bó ṣe jẹ́jẹ̀ẹ́ pé òun máa ṣe. Jèhófà bù kún Hánà torí pé ẹ̀mí rere tó ní ló mú kó yọ̀ǹda ọmọ rẹ̀. Jèhófà mú kó bí ọmọ márùn-ún míì, Sámúẹ́lì di wòlíì Ọlọ́run, ó sì tún wà lára àwọn tó kọ Bíbélì.—1 Sám. 2:21.
Bíi ti Hánà àti Sámúẹ́lì, àwa Kristẹni náà ti ya ara wa sí mímọ́ fún Jèhófà Ẹlẹ́dàá wa, a sì ń fayé wa sìn ín. Bákan náà, Jésù ṣèlérí pé kò sóhun tá a yááfì torí ìjọsìn Jèhófà tó máa gbé torí pé Jèhófà máa bù kún wa gan-an.—Máàkù 10:28-30.
Ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní, obìnrin kan wà nínú ìjọ tó ń jẹ́ Dọ́káàsì. Bíbélì sọ pé ó pọ̀ gidigidi nínú “àwọn iṣẹ́ rere àti àwọn ẹ̀bùn àánú,” ìyẹn ni pé ó jẹ́ ọ̀làwọ́. Àmọ́ nígbà tó yá, “ó dùbúlẹ̀ àìsàn, ó sì kú,” ìyẹn ba àwọn ará nínú jẹ́ gan-an. Nígbà tí wọ́n gbọ́ pé Pétérù wà lágbègbè wọn, wọ́n bẹ̀ ẹ́ pé kó tètè wá sọ́dọ̀ àwọn. Ẹ wo bí inú wọn ṣe máa dùn tó nígbà tí Pétérù dé tó sì jí Dọ́káàsì dìde! Èyí ni ìgbà àkọ́kọ́ tí ọ̀kan lára àwọn àpọ́sítélì Jésù máa jí òkú dìde. (Ìṣe 9:36-41) Ọlọ́run ò gbàgbé àwọn iṣẹ́ rere tí Dọ́káàsì ṣe. (Héb. 6:10) Yàtọ̀ síyẹn, ìwà ọ̀làwọ́ rẹ̀ tún wà lákọọ́lẹ̀ nínú Bíbélì káwa náà lè fara wé e.
Tó bá dọ̀rọ̀ kéèyàn jẹ́ ọ̀làwọ́, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fi àpẹẹrẹ tó dáa lélẹ̀ torí pé ó lo àkókò rẹ̀ àti okun rẹ̀ fáwọn míì. Nínú lẹ́tà tó kọ sáwọn ará ní Kọ́ríńtì, ó sọ pé: “Ní tèmi, ṣe ni èmi yóò máa fi ìyọ̀ṣẹ̀ṣẹ̀ gan-an náwó, a ó sì ná mi tán pátápátá fún ọkàn yín.” (2 Kọ́r. 12:15) Pọ́ọ̀lù kẹ́kọ̀ọ́ láti inú ìrírí ara rẹ̀ pé èèyàn á láyọ̀ téèyàn bá fi ara rẹ̀ jìn fún àwọn míì, ní pàtàkì jù lọ, èèyàn á rí ìbùkún àti ìtẹ́wọ́gbà Jèhófà.—Ìṣe 20:24, 35.
Kò sí àní-àní pé inú Jèhófà ń dùn bá a ṣe ń lo àkókò àti okun wa lẹ́nu iṣẹ́ Ìjọba Ọlọ́run, tá a sì tún ń ran àwọn ará wa lọ́wọ́. Àmọ́, ǹjẹ́ àwọn ọ̀nà míì wà tá a lè gbà ti iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba Ọlọ́run lẹ́yìn? Bẹ́ẹ̀ ni! Láfikún sí iṣẹ́ ìwàásù tá à ń ṣe, a tún lè fi ọrẹ àtinúwá bọlá fún Ọlọ́run. Ọrẹ yìí la fi ń bójú tó iṣẹ́ ìwàásù kárí ayé, òun náà la sì fi ń bójú tó àwọn míṣọ́nnárì àtàwọn míì tó wà lẹ́nu àkànṣe iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún. Yàtọ̀ síyẹn, ọrẹ àtinúwá yìí náà là ń lò bá a ṣe ń ṣe ìwé àtàwọn fídíò, tá à ń túmọ̀ wọn sáwọn èdè míì, tá à ń ṣèrànwọ́ fáwọn tí àjálù bá, tá a sì ń kọ́ àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba tuntun. Ó dá wa lójú pé “a óò mú ọkàn tí ó lawọ́ sanra.” Ju gbogbo ẹ̀ lọ, tá a bá ń fún Jèhófà láwọn ohun ìní wa tó níye lórí, ṣe là ń bọlá fún un.—Òwe 3:9; 11:25.