Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ta Ló Ń Darí Èrò Rẹ?

Ta Ló Ń Darí Èrò Rẹ?

‘Ẹ jáwọ́ nínú dídáṣà ní àfarawé ètò àwọn nǹkan yìí.’ ​RÓÒMÙ 12:2.

ORIN: 88, 45

1, 2. (a) Èsì wo ni Jésù fún Pétérù nígbà tí Pétérù sọ fún un pé kó ṣàánú ara rẹ̀? (Wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.) (b) Kí nìdí tí Jésù fi dáhùn bẹ́ẹ̀?

NÍGBÀ tí Jésù sọ fáwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé òun máa jìyà, òun sì máa tó kú, ẹnu yà wọ́n gan-an torí wọ́n rò pé Jésù ló máa dá orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn tó ń ṣàkóso lé wọn lórí. Ara Pétérù kò gbà á, ló bá sọ fún Jésù pé: “Ṣàánú ara rẹ, Olúwa; ìwọ kì yóò ní ìpín yìí rárá.” Àmọ́ Jésù fún un lésì pé: “Dẹ̀yìn lẹ́yìn mi, Sátánì! Ohun ìkọ̀sẹ̀ ni ìwọ jẹ́ fún mi, nítorí kì í ṣe àwọn ìrònú Ọlọ́run ni ìwọ ń rò, bí kò ṣe ti ènìyàn.”​—Mát. 16:​21-23; Ìṣe 1:6.

2 Ohun tí Jésù sọ yìí jẹ́ ká rí ìyàtọ̀ tó wà láàárín èrò Ọlọ́run àti èrò tí ayé Sátánì ń gbé lárugẹ. (1 Jòh. 5:19) Ọ̀pọ̀ nínú ayé gbà pé kò yẹ kéèyàn máa fìyà jẹ ara ẹ̀, irú èrò yìí sì ni Pétérù náà ní. Àmọ́ Jésù mọ̀ pé èrò Jèhófà yàtọ̀ pátápátá síyẹn. Ó mọ̀ pé Ọlọ́run fẹ́ kóun múra tán láti jìyà, kóun sì kú. Torí náà, èsì tí Jésù fún Pétérù fi hàn kedere pé èrò Jèhófà ni Jésù ní, kì í ṣe ti ayé.

3. Kí nìdí tí kò fi rọrùn láti ní èrò Jèhófà?

3 Àwa náà ńkọ́? Ṣé èrò Ọlọ́run ló ń darí wa àbí èrò táyé ń gbé lárugẹ? Lóòótọ́, a lè má ṣe ohun tó lòdì sí ìfẹ́ Ọlọ́run, àmọ́ àwọn ohun tá à ń rò lọ́kàn wa ńkọ́? Ṣé ohun tá à ń rò lọ́kàn bá ohun tí Jèhófà fẹ́ mu? Tá a bá fẹ́ kí èrò wa bá ti Jèhófà mu, àfi ká dìídì sapá láti ṣe bẹ́ẹ̀. Lọ́wọ́ kejì, ó rọrùn gan-an láti máa ronú bíi tàwọn èèyàn ayé, kì í sì í pẹ́ tó fi máa ń mọ́ọ̀yàn lára. Ìdí ni pé àwọn tí ẹ̀mí ayé ń darí ló yí wa ká. (Éfé. 2:2) Yàtọ̀ síyẹn, ìmọtara-ẹni-nìkan ni ayé ń gbé lárugẹ, torí náà ó lè máa wù wá pé ká ṣe bíi tiwọn. Ká sòótọ́, kò rọrùn láti ní èrò Jèhófà, àmọ́ ó rọrùn gan-an láti máa ronú bíi tàwọn èèyàn ayé.

4. (a) Kí ló lè ṣẹlẹ̀ tá a bá jẹ́ kí èrò ayé máa darí wa? (b) Kí la máa gbé yẹ̀ wò nínú àpilẹ̀kọ yìí?

4 Tá a bá jẹ́ kí èrò ayé máa darí wa, a lè di onímọtara-ẹni-nìkan, ká sì fẹ́ máa ṣe ohun tó wù wá. (Máàkù 7:​21, 22) Torí náà, ó ṣe pàtàkì pé ká ní ‘èrò Ọlọ́run,’ ká má sì fàyè gba èrò èèyàn, àpilẹ̀kọ yìí sì máa ràn wá lọ́wọ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀. A máa rí ìdí tó fi yẹ ká máa fojú tí Jèhófà fi ń wo nǹkan wò ó. Bákan náà, a máa rí i pé àwọn ìlànà Jèhófà kì í ká wa lọ́wọ́ kò, kàkà bẹ́ẹ̀ ó máa ń ṣe wá láǹfààní. Yàtọ̀ síyẹn, a tún máa rí ohun tó yẹ ká ṣe tá ò fi ní máa ronú bíi tàwọn èèyàn ayé. Àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé e máa jẹ́ ká mọ bá a ṣe lè mọ ojú tí Jèhófà fi ń wo àwọn nǹkan kan àti báwa náà ṣe lè máa fojú yẹn wò wọ́n.

ÈRÒ JÈHÓFÀ Ń ṢE WÁ LÁǸFÀÀNÍ

5. Kí nìdí táwọn kan kò fi fẹ́ kẹ́nì kankan dá sí ọ̀rọ̀ wọn?

5 Àwọn kan kì í fẹ́ kí ẹnikẹ́ni dá sọ́rọ̀ wọn tàbí kí wọ́n sọ ohun tí wọ́n máa ṣe fún wọn. Wọ́n máa ń sọ pé: “Ohun tó bá wù mí ni màá ṣe.” Wọ́n gbà pé àwọn lè ṣèpinnu láìsí pé ẹnì kan ń yẹ àwọn lọ́wọ́ wò. Yàtọ̀ síyẹn, wọn kì í fẹ́ kí ẹnikẹ́ni darí wọn, kódà wọn kì í fẹ́ fara wé ẹnikẹ́ni. *

6. (a) Irú òmìnira wo ni Jèhófà fún wa? (b) Ibo ni òmìnira wa mọ?

6 Ká fi sọ́kàn pé bá a ṣe ń jẹ́ kí Jèhófà darí èrò wa kò túmọ̀ sí pé a ò lómìnira láti pinnu ohun tá a fẹ́. 2 Kọ́ríńtì 3:17 sọ pé: “Níbi tí ẹ̀mí Jèhófà bá sì wà, níbẹ̀ ni òmìnira wà.” Bí àpẹẹrẹ, a lómìnira láti yan irú ẹni tó wù wá láti jẹ́. A lè yan ohun tó wù wá, a sì lè pinnu ohun tá a máa ṣe. Jèhófà fúnra rẹ̀ ló fún wa lómìnira yìí, síbẹ̀ ká fi sọ́kàn pé ó níbi tí òmìnira wa mọ. (Ka 1 Pétérù 2:16.) Tó bá dọ̀rọ̀ ohun tó tọ́ àtohun tí kò tọ́, Jèhófà fẹ́ ká gbé ìpinnu wa ka èrò rẹ̀ tó wà nínú Bíbélì. Ṣé àwọn ìlànà Jèhófà ń ká wa lọ́wọ́ kò ni àbí wọ́n ń ṣe wá láǹfààní?

7, 8. Kí nìdí tá a fi lè sọ pé àwọn ìlànà Jèhófà ò le koko jù? Ṣàpèjúwe.

7 Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ yìí. Àwọn òbí máa ń sapá láti kọ́ àwọn ọmọ wọn kí wọ́n lè níwà ọmọlúàbí. Wọ́n máa ń kọ́ wọn láti jẹ́ olóòótọ́, kí wọ́n máa ṣiṣẹ́ kára, kí wọ́n sì máa gba tàwọn míì rò. Kì í ṣe pé àwọn òbí náà le koko jù, kàkà bẹ́ẹ̀ ohun tí wọ́n fẹ́ ni pé káwọn ọmọ náà yàn, kí wọ́n yanjú, káyé wọn sì dáa lẹ́yìnwá ọ̀la. Táwọn ọmọ náà bá tójú bọ́, tí wọ́n sì kúrò ńlé, wọ́n á lómìnira láti pinnu ohun tí wọ́n fẹ́. Tí wọ́n bá gbẹ̀kọ́ dáadáa, tí wọ́n sì fi ohun tí wọ́n kọ́ sílò, ó ṣeé ṣe kí wọ́n ṣe àwọn ìpinnu tí wọn ò ní kábàámọ̀. Wọn ò sì ní tọrùn bọ wàhálà àtàwọn ìṣòro táwọn míì máa ń kó sí.

8 Bíi ti òbí kan tó nífẹ̀ẹ́ ọmọ rẹ̀, Jèhófà náà fẹ́ káyé wa ládùn kó lóyin. (Aísá. 48:​17, 18) Ìdí nìyẹn tó fi fún wa láwọn ìlànà nípa bó ṣe yẹ ká máa hùwà àti bó ṣe yẹ ká máa ṣe sáwọn míì. Ó fẹ́ ká máa fojú tóun fi ń wo nǹkan wò ó, ká sì máa fi àwọn ìlànà rẹ̀ sílò. Àwọn ìlànà yìí ò ká wa lọ́wọ́ kò rárá, kàkà bẹ́ẹ̀ wọ́n ń jẹ́ ká lè ronú jinlẹ̀, ká sì lo làákàyè wa. (Sm. 92:5; Òwe 2:​1-5; Aísá. 55:9) Èyí máa jẹ́ ká ṣe àwọn ìpinnu táá fún wa láyọ̀, táá sì jẹ́ ká gbádùn ayé wa. (Sm. 1:​2, 3) Ká sòótọ́, àá jàǹfààní tá a bá ń jẹ́ kí èrò Jèhófà darí wa.

ÈRÒ JÈHÓFÀ GA JU TAYÉ LỌ

9, 10. Kí ló fi hàn pé èrò Jèhófà ga ju tayé lọ?

9 Ìdí míì táwa ìránṣẹ́ Jèhófà fi ń jẹ́ kí èrò Jèhófà darí wa ni pé èrò Jèhófà ga ju tayé lọ fíìfíì. Onírúurú ìmọ̀ràn làwọn èèyàn ayé máa ń fúnni nípa ìdílé, béèyàn ṣe lè gbádùn iṣẹ́ rẹ̀, bó ṣe yẹ kéèyàn máa hùwà àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Àmọ́ ọ̀pọ̀ nínú ìmọ̀ràn wọn ni kò bá èrò Jèhófà mu rárá. Bí àpẹẹrẹ, ohun táyé ń gbé lárugẹ ni kéèyàn máa wá ipò àti ògo fún ara rẹ̀. Wọn ò sì ka ìṣekúṣe sí nǹkan burúkú. Yàtọ̀ síyẹn, wọ́n máa ń gba àwọn tọkọtaya nímọ̀ràn pé tọ́rọ̀ wọn ò bá ti wọ̀ mọ́, kò sóhun tó burú tí wọ́n bá pínyà tàbí kọ ara wọn sílẹ̀, wọ́n ní ìyẹn ló máa jẹ́ kí wọ́n láyọ̀. Àwọn ìmọ̀ràn yìí ò bá Ìwé Mímọ́ mu rárá. Ẹ gbọ́ ná, nínú ìmọ̀ràn táyé ń fúnni àti ti Bíbélì, èwo ló máa ṣe wá láǹfààní lónìí?

10 Jésù sọ pé “A fi ọgbọ́n hàn ní olódodo nípasẹ̀ àwọn iṣẹ́ rẹ̀.” (Mát. 11:19) Ká sòótọ́, ìtẹ̀síwájú ti bá ìmọ̀ ẹ̀rọ torí pé ojoojúmọ́ ni wọ́n ń gbé àwọn nǹkan tuntun jáde. Síbẹ̀, wọn ò lè yanjú ọ̀pọ̀ ìṣòro tó ń fa ìbànújẹ́ lónìí, irú bí ogun, kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà àti ìwà ọ̀daràn. Yàtọ̀ síyẹn, wọn ò rí ohun tó burú nínú ìṣekúṣe. Àmọ́ ọ̀pọ̀ gbà pé ìṣekúṣe ti ba nǹkan jẹ́ gan-an, torí pé ó ń tú ìdílé ká, ó sì ń fa onírúurú àrùn àtàwọn ìṣòro míì. Lọ́wọ́ kejì, àwa Kristẹni tá à ń tẹ̀ lé àwọn ìlànà Ọlọ́run máa ń gbádùn ìdílé aláyọ̀, ìlera tó dáa, a sì tún ń gbádùn àlàáfíà àti ìṣọ̀kan pẹ̀lú àwọn ará wa kárí ayé. (Aísá. 2:4; Ìṣe 10:​34, 35; 1 Kọ́r. 6:​9-11) Ǹjẹ́ èyí ò fi hàn kedere pé èrò Jèhófà ga ju tayé lọ fíìfíì?

11. Èrò ta ni Mósè jẹ́ kó darí òun, kí ló sì yọrí sí?

11 Àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà láyé àtijọ́ náà gbà pé èrò Jèhófà ga ju tayé lọ. Bí àpẹẹrẹ, bó tilẹ̀ jẹ́ pé “a fún [Mósè] ní ìtọ́ni nínú gbogbo ọgbọ́n àwọn ará Íjíbítì,” síbẹ̀ ó gbà pé ọ̀dọ̀ Ọlọ́run nìkan lèèyàn ti lè “jèrè ọkàn-àyà ọgbọ́n.” (Ìṣe 7:22; Sm. 90:12) Bákan náà, ó bẹ Jèhófà pé: “Jẹ́ kí n mọ àwọn ọ̀nà rẹ.” (Ẹ́kís. 33:13) Torí pé Mósè jẹ́ kí èrò Jèhófà máa darí òun, Jèhófà lò ó gan-an láti mú àwọn ohun tó ní lọ́kàn ṣẹ. Yàtọ̀ síyẹn, Jèhófà buyì kún un nígbà tó pè é ní ọkùnrin tí ìgbàgbọ́ rẹ̀ tayọ.​—Héb. 11:​24-27.

12. Kí ni Pọ́ọ̀lù gbé èrò rẹ̀ kà?

12 Ọ̀mọ̀wé ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù, ó kéré tán ó gbọ́ èdè méjì. (Ìṣe 5:34; 21:​37, 39; 22:​2, 3) Síbẹ̀, tó bá kan ọ̀rọ̀ ohun tó tọ́ àtohun tí kò tọ́, Pọ́ọ̀lù ò fàyè gba èrò ayé rárá. Kàkà bẹ́ẹ̀, ìlànà Ìwé Mímọ́ ló máa ń gbé èrò rẹ̀ kà. (Ka Ìṣe 17:2; 1 Kọ́ríńtì 2:​6, 7, 13.) Ìyẹn jẹ́ kí Pọ́ọ̀lù gbádùn iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ gan-an, ó sì tún fojú sọ́nà fún ìyè àìnípẹ̀kun.​—2 Tím. 4:8.

13. Tí èrò wa bá máa bá ti Jèhófà mu, ọwọ́ ta ló wà?

13 Ó dájú pé èrò Jèhófà ga ju tayé lọ fíìfíì. Tá a bá ń jẹ́ kí èrò rẹ̀ máa darí wa, a máa láyọ̀, ayé wa á sì nítumọ̀. Àmọ́ Jèhófà ò ní fipá mú wa pé ká fara mọ́ èrò rẹ̀. Bákan náà, “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” kì í fipá mú wa ṣe nǹkan, àwọn alàgbà náà ò sì ní ṣe bẹ́ẹ̀. (Mát. 24:45; 2 Kọ́r. 1:24) Kristẹni kọ̀ọ̀kan ló máa sapá láti mú kí èrò rẹ̀ bá ti Jèhófà mu. Àmọ́ báwo la ṣe lè ṣe bẹ́ẹ̀?

MÁ ṢE JẸ́ KÍ ÈRÒ AYÉ DARÍ RẸ

14, 15. (a) Kí èrò wa lè bá ti Jèhófà mu, kí ló yẹ ká máa ronú lé? (b) Bí Róòmù 12:2 ṣe sọ, kí nìdí tí kò fi yẹ ká fàyè gba èrò ayé? Ṣàpèjúwe.

14 Róòmù 12:2 gbà wá níyànjú pé: “Ẹ sì jáwọ́ nínú dídáṣà ní àfarawé ètò àwọn nǹkan yìí, ṣùgbọ́n ẹ para dà nípa yíyí èrò inú yín padà, kí ẹ lè ṣàwárí fúnra yín ìfẹ́ Ọlọ́run tí ó dára, tí ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà, tí ó sì pé.” Ó ṣe kedere pé ọ̀nà yòówù ká máa gbà ronú kó tó di pé a kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́, a lè mú èrò wa bá ti Ọlọ́run mu. Òótọ́ ni pé ibi tá a gbé dàgbà àtàwọn nǹkan tó ti ṣẹlẹ̀ sí wa lè nípa lórí bá a ṣe ń ronú. Àmọ́, Ọlọ́run dá wa lọ́nà táá mú kó ṣeé ṣe láti yí èrò wa pa dà. Síbẹ̀, ká fi sọ́kàn pé ká tó lè ṣe ìyípadà yìí, àfi ká ṣọ́ ohun tá à ń jẹ́ kó wọnú ọkàn wa àtohun tá à ń ronú lé. Torí náà, tá a bá ń ronú nípa ojú tí Jèhófà fi ń wo nǹkan, á túbọ̀ dá wa lójú pé ojú tí Jèhófà fi ń wo nǹkan ló tọ̀nà. Ìyẹn á sì mú kó rọrùn láti máa fojú tí Jèhófà fi ń wo nǹkan wò ó.

15 Àmọ́ ká tó lè mú èrò wa bá ti Jèhófà mu, a gbọ́dọ̀ “jáwọ́ nínú dídáṣà ní àfarawé ètò àwọn nǹkan yìí.” A ò gbọ́dọ̀ fàyè gba èrò èyíkéyìí tí kò bá ti Ọlọ́run mu nínú ọkàn wa. Ẹ jẹ́ ká fi oúnjẹ ṣàpẹẹrẹ ohun tá à ń sọ yìí. Tẹ́nì kan bá fẹ́ kí ìlera òun túbọ̀ dáa sí i, ó lè pinnu pé òun á máa jẹ oúnjẹ aṣaralóore. Àmọ́ báwo ni ìlera ẹ̀ ṣe máa rí tó bá tún ń jẹ àwọn oúnjẹ tó ti bà jẹ́? Lọ́nà kan náà, tẹ́nì kan bá ń sapá láti gba èrò Jèhófà, àmọ́ tó tún ń fàyè gba èrò ayé, asán ni gbogbo ìsapá rẹ̀ máa já sí.

16. Ó yẹ ká dáàbò bo ara wa lọ́wọ́ kí ni?

16 Ṣé a lè yẹra pátápátá fún èrò ayé? Kò ṣeé ṣe, inú ayé yìí làwa náà ń gbé, torí náà kò sí bá a ṣe lè yẹra pátápátá fún èrò wọn. (1 Kọ́r. 5:​9, 10) Bí àpẹẹrẹ, lóde ẹ̀rí a máa ń pàdé àwọn tó ń sọ ohun tó yàtọ̀ pátápátá sí ẹ̀kọ́ Bíbélì. Àmọ́ ti pé a ò lè yẹra pátápátá kò túmọ̀ sí pé a gbọ́dọ̀ fàyè gba àwọn èrò náà nínú ọkàn wa. Bíi ti Jésù, ẹsẹ̀kẹsẹ̀ la gbọ́dọ̀ kọ èrò èyíkéyìí tó bá jẹ́ ti Sátánì. Yàtọ̀ síyẹn, a gbọ́dọ̀ dáàbò bo ọkàn wa, ká má ṣe fàyè gba èrò ayé.​—Ka Òwe 4:23.

17. Kí ló yẹ ká ṣe ká má bàa fàyè gba èrò ayé?

17 Ó yẹ ká fara balẹ̀ dáadáa ká tó yan àwọn tá a máa bá ṣọ̀rẹ́. Bíbélì kìlọ̀ fún wa pé tá a bá ń kẹ́gbẹ́ pẹ̀lú àwọn tí kò sin Jèhófà, kò ní pẹ́ tá a fi máa bẹ̀rẹ̀ sí í ronú bíi tiwọn, ó ṣe tán àwọn èèyàn máa ń sọ pé àgùntàn tó bá ń bá ajá rìn, á jẹ̀gbẹ́. (Òwe 13:20; 1 Kọ́r. 15:​12, 32, 33) Ó tún yẹ ká ṣọ́ra tó bá kan eré ìnàjú tá à ń wò. A gbọ́dọ̀ yẹra fún èyíkéyìí tó bá ń gbé ẹ̀kọ́ ẹfolúṣọ̀n, ìwà ipá àti ìṣekúṣe lárugẹ. A ò gbọ́dọ̀ jẹ́ kí èrò tó “lòdì sí ìmọ̀ nípa Ọlọ́run” sọ ọkàn wa di ẹlẹ́gbin.​—2 Kọ́r. 10:5.

Ṣé a máa ń kọ́ àwọn ọmọ wa káwọn náà lè máa yẹra fáwọn eré ìnàjú tí kò dáa? (Wo ìpínrọ̀ 18, 19)

18, 19. (a) Kí nìdí tó fi yẹ ká wà lójúfò? (b) Àwọn ìbéèrè wo ló yẹ ká bi ara wa, kí sì nìdí?

18 A gbọ́dọ̀ wà lójúfò torí pé àwọn èrò kan wà táyé ń gbé lárugẹ lọ́nà tí kò fi bẹ́ẹ̀ hàn sójú táyé. Bí àpẹẹrẹ, àwọn oníròyìn kan lè fọgbọ́n gbè sẹ́yìn ẹgbẹ́ òṣèlú kan, kéèyàn má sì mọ̀. Àwọn ìròyìn míì máa ń dá lórí báwọn kan ṣe rí towó ṣe tẹ́nu wọn sì tólẹ̀ láwùjọ. Àwọn fíìmù àtàwọn ìwé kan máa ń kọ́ àwọn èèyàn pé ara wọn tàbí ìdílé wọn ló yẹ kí wọ́n fi ṣáájú ohunkóhun míì, wọ́n sì lè ṣe é lọ́nà táá fi dà bíi pé ohun tí wọ́n sọ yẹn mọ́gbọ́n dání. Àmọ́ èrò bẹ́ẹ̀ yàtọ̀ pátápátá sí ohun tí Ìwé Mímọ́ sọ. Bí àpẹẹrẹ, Bíbélì jẹ́ kó ṣe kedere pé téèyàn bá fi ti Jèhófà ṣáájú nìkan ló tó lè gbádùn ayé rẹ̀, kí ìdílé rẹ̀ sì láyọ̀. (Mát. 22:​36-39) Bákan náà, àwọn ìtàn ọmọdé kan wà tó máa ń dà bíi pé kò sóhun tó burú nínú rẹ̀, àmọ́ téèyàn bá wò ó dáadáa, wọ́n máa ń gbé ìṣekúṣe lárugẹ.

19 Èyí ò túmọ̀ sí pé a ò lè gbádùn eré ìnàjú. Síbẹ̀, ó yẹ ká bi ara wa pé: ‘Ǹjẹ́ mo tètè máa ń fura tí eré kan bá ń gbé èrò ayé lárugẹ kódà tí ò bá ṣe tààràtà? Ṣé mo máa ń ṣọ́ra fáwọn ìwé tàbí eré tó lè gbin èrò òdì sọ́kàn èmi àtàwọn ọmọ mi? Ṣé mo máa ń jẹ́ káwọn ọmọ mi mọ èrò Jèhófà dáadáa, débi pé èrò ayé tí wọ́n ń gbọ́ tí wọ́n sì ń rí kò ní nípa lórí wọn?’ Tá a bá ti mọ ìyàtọ̀ tó wà láàárín èrò Ọlọ́run àti èrò ayé, ó dájú pé èrò ayé ò ní lè darí wa.

ÈRÒ WO LÓ Ń DARÍ RẸ?

20. Kí ló ń pinnu èrò táá máa darí wa?

20 Ká rántí pé èrò méjì la lè gbà láyè nínú ọkàn wa, yálà ká gba èrò Jèhófà tàbí ti ayé Sátánì. Èwo là ń jẹ́ kó darí wa? Ní kúkúrú, èyí tá a bá jẹ́ kó jọba nínú ọkàn wa ni. Tá a bá jẹ́ kí èrò ayé jọba lọ́kàn wa, àwa náà á bẹ̀rẹ̀ sí í ronú bíi tiwọn, á sì máa wù wá láti ṣe bíi tiwọn. Ìdí nìyẹn tó fi ṣe pàtàkì pé ká ṣọ́ ohun tá à ń rò.

21. Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ tó kàn?

21 Bá a ṣe sọ ṣáájú, ká lè máa fojú tí Jèhófà fi ń wo nǹkan wò ó, a gbọ́dọ̀ yẹra fún èrò ayé. Káwa náà lè ní èrò Jèhófà, ó tún ṣe pàtàkì pé ká máa ṣàṣàrò nípa ojú tó fi ń wo nǹkan. Ohun tá a máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ tó kàn nìyẹn.

^ ìpínrọ̀ 5 Òótọ́ kan ni pé èrò àwọn míì ṣì máa ń nípa lórí irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, èrò àwọn míì máa ń nípa lórí wa tó bá kan ohun tá a gbà gbọ́ tàbí lórí àwọn ọ̀rọ̀ míì bí aṣọ tá a máa wọ̀. Àmọ́, àwa fúnra wa la máa pinnu ẹni tá a fẹ́ kó nípa lórí wa.