Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 42

‘Aláyọ̀ Ni Àwọn Tó Jẹ́ Olóòótọ́ sí Jèhófà’

‘Aláyọ̀ Ni Àwọn Tó Jẹ́ Olóòótọ́ sí Jèhófà’

Aláyọ̀ ni àwọn tó ń pa ìwà títọ́ mọ́ . . . , tó ń rìn nínú òfin Jèhófà.”​—SM. 119:1, àlàyé ìsàlẹ̀.

ORIN 124 Jẹ́ Adúróṣinṣin

OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒ *

Díẹ̀ lára àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa tó nígboyà tí wọ́n ti wà lẹ́wọ̀n tipẹ́ àtàwọn tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ fi sẹ́wọ̀n nítorí ohun tí wọ́n gbà gbọ́ (Wo ìpínrọ̀ 1-2)

1-2. (a) Kí làwọn ìjọba kan ṣe sáwọn èèyàn Jèhófà, àmọ́ kí làwọn èèyàn Jèhófà ṣe? (b) Kí lá jẹ́ ká máa láyọ̀ tí wọ́n bá tiẹ̀ ń ṣe inúnibíni sí wa? (Kí lo lè sọ nípa àwòrán iwájú ìwé.)

 NÍ LỌ́WỌ́LỌ́WỌ́ báyìí, ó ju ọgbọ̀n (30) orílẹ̀-èdè lọ tí wọ́n ti ń dí iṣẹ́ wa lọ́wọ́ tàbí tí wọ́n ti fòfin de iṣẹ́ wa. Àwọn orílẹ̀-èdè kan lára àwọn orílẹ̀-èdè náà ń ju àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa sẹ́wọ̀n. Ṣé àwọn ará wa ṣe ohun tí ò dáa ni? Rárá o, kódà Jèhófà náà mọ̀ pé wọn ò ṣohun tí ò dáa. Gbogbo ohun tí wọ́n ń ṣe ò ju pé kí wọ́n ka Bíbélì, kí wọ́n wàásù, kí wọ́n sì lọ sípàdé láti jọ́sìn Jèhófà pẹ̀lú àwọn ará wọn. Wọn ò tún dá sọ́rọ̀ òṣèlú. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé wọ́n gbógun tì wọ́n gan-an, àwọn ará wa yìí jẹ́ olóòótọ́ sí Ọlọ́run, * wọ́n sì ń sin Jèhófà tọkàntọkàn. Ìyẹn sì ń jẹ́ kí wọ́n máa láyọ̀!

2 Ó ṣeé ṣe kó o ti rí fọ́tò díẹ̀ lára àwọn ará tó nígboyà yìí, tí inú wọn ń dùn, tí wọ́n sì ń rẹ́rìn ín. Wọ́n ń láyọ̀ torí wọ́n mọ̀ pé inú Jèhófà ń dùn sí àwọn torí pé wọ́n jẹ́ olóòótọ́. (1 Kíró. 29:17a) Jésù sọ pé: “Aláyọ̀ ni àwọn tí wọ́n ṣe inúnibíni sí nítorí òdodo . . . Ẹ máa yọ̀, kí inú yín sì dùn gidigidi, torí èrè yín pọ̀.”​—Mát. 5:10-12.

ÀPẸẸRẸ TÓ YẸ KÁ TẸ̀ LÉ

Pétérù àti Jòhánù fi àpẹẹrẹ tó dáa lélẹ̀ fáwọn Kristẹni tó ń lọ sílé ẹjọ́ láti gbèjà ìgbàgbọ́ wọn lákòókò wa yìí (Wo ìpínrọ̀ 3-4)

3.Ìṣe 4:19, 20 ṣe sọ, kí làwọn àpọ́sítélì nígbà ayé àwọn Kristẹni àkọ́bẹ̀rẹ̀ ṣe nígbà tí wọ́n ṣenúnibíni sí wọn, kí sì nìdí?

3 Nígbà ayé àwọn Kristẹni àkọ́bẹ̀rẹ̀, wọ́n ṣenúnibíni sáwọn àpọ́sítélì torí pé wọ́n ń wàásù nípa Jésù, àmọ́ wọ́n fara dà á. Bákan náà lónìí, wọ́n ń ṣenúnibíni sáwọn ará wa, àwọn náà sì ń fara dà á. Léraléra làwọn adájọ́ tó wà ní ilé ẹjọ gíga jù lọ àwọn Júù “pàṣẹ fún wọn pé kí wọ́n má sọ̀rọ̀ nípa orúkọ Jésù mọ́.” (Ìṣe 4:18; 5:27, 28, 40) Kí làwọn àpọ́sítélì wá ṣe? (Ka Ìṣe 4:19, 20.) Wọ́n mọ̀ pé ẹni tó láṣẹ jù lọ ló ‘pàṣẹ fún wọn pé káwọn wàásù fún àwọn èèyàn kí wọ́n sì jẹ́rìí kúnnákúnná’ nípa Kristi. (Ìṣe 10:42) Torí náà, Pétérù àti Jòhánù tó ṣojú fáwọn Kristẹni yòókù fìgboyà sọ pé Ọlọ́run làwọn máa fetí sí dípò àwọn adájọ́ yẹn àti pé àwọn ò ní yéé wàásù nípa Jésù. Lédè míì, ṣe ló dà bí ìgbà táwọn àpọ́sítélì yẹn ń bi àwọn adájọ́ yẹn pé, ‘Ṣé ohun tẹ́ ẹ̀ ń sọ ni pé ẹ láṣẹ lórí wa ju Ọlọ́run lọ?’

4. Bó ṣe wà nínú Ìṣe 5:27-29, àpẹẹrẹ wo làwọn àpọ́sítélì fi lélẹ̀ fáwa Kristẹni tòótọ́, báwo la sì ṣe lè fara wé wọn?

4 Àwọn àpọ́sítélì fi àpẹẹrẹ tó dáa lélẹ̀ fáwa Kristẹni lónìí pé ká máa “ṣègbọràn sí Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí alákòóso dípò èèyàn.” (Ka Ìṣe 5:27-29.) Lẹ́yìn táwọn Júù yẹn nà wọ́n tán, àwọn àpọ́sítélì kúrò nílé ẹjọ gíga jù lọ àwọn Júù, “wọ́n ń yọ̀ nítorí a ti kà wọ́n yẹ láti jìyà nítorí orúkọ Jésù,” wọn ò sì dáwọ́ iṣẹ́ ìwàásù dúró!​—Ìṣe 5:40-42.

5. Àwọn ìbéèrè wo la máa dáhùn?

5 Àpẹẹrẹ táwọn àpọ́sítélì fi lélẹ̀ mú ká bi ara wa láwọn ìbéèrè kan. Ìbéèrè àkọ́kọ́ ni pé, ṣé ìpinnu tí wọ́n ṣe pé àwọn máa gbọ́ràn sí Ọlọ́run dípò àwọn èèyàn ò ta ko àṣẹ Ọlọ́run tó wà nínú Ìwé Mímọ́ pé ká “máa tẹrí ba fún àwọn aláṣẹ onípò gíga”? (Róòmù 13:1) Ìkejì, bí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣe sọ, báwo la ṣe lè “máa tẹrí ba fún ìjọba àti àwọn aláṣẹ,” ká sì tún jẹ́ olóòótọ́ sí Ọlọ́run tó jẹ́ Alákòóso tó ga jù lọ?​—Títù 3:1.

“ÀWỌN ALÁṢẸ ONÍPÒ GÍGA”

6. (a) Àwọn wo ni Róòmù 13:1 pè ní “aláṣẹ onípò gíga,” kí ló sì yẹ ká máa ṣe fún wọn? (b) Báwo ni agbára àwọn aláṣẹ ayé yìí ṣe pọ̀ tó tá a bá fi wé ti Ọlọ́run?

6 Ka Róòmù 13:1. Nínú ẹsẹ Bíbélì yìí, gbólóhùn náà, “àwọn aláṣẹ onípò gíga” ń tọ́ka sí àwọn èèyàn tó ń ṣàkóso, tí wọ́n sì ń lo agbára wọn láti darí àwọn èèyàn. Àwa Kristẹni tòótọ́ náà wà lára àwọn tó gbọ́dọ̀ máa ṣègbọràn sáwọn aláṣẹ ìjọba yìí. Ìdí ni pé wọ́n máa ń ṣe ipa tiwọn kí àlàáfíà lè wà nílùú, wọ́n máa ń rí i dájú pé àwọn èèyàn ń pa òfin ìlú mọ́, nígbà míì sì rèé, wọ́n máa ń gbèjà àwa èèyàn Ọlọ́run. (Ìfi. 12:16) Torí náà, Bíbélì rọ̀ wá pé ká máa san owó orí fún wọn, ká máa fún wọn ní ìṣákọ́lẹ̀, ká máa bẹ̀rù wọn bó ṣe yẹ, ká sì máa bọlá fún wọn. (Róòmù 13:7) Àmọ́ torí pé Jèhófà fàyè gba àwọn aláṣẹ ìjọba yìí ni wọ́n ṣe ń lo àṣẹ wọn lórí àwọn èèyàn. Jésù jẹ́ ká mọ̀ bẹ́ẹ̀ nígbà tí gómìnà Róòmù kan tó ń jẹ́ Pọ́ńtíù Pílátù ń bi í láwọn ìbéèrè kan. Nígbà tí Pílátù ń sọ fún Jésù pé òun láṣẹ láti sọ pé kí wọ́n pa á tàbí kí wọ́n dá a sílẹ̀, Jésù sọ fún un pé: “O ò lè ní àṣẹ kankan lórí mi àfi tí a bá fún ọ láṣẹ látòkè.” (Jòh. 19:11) Bákan náà ló rí lónìí, bíi ti Pílátù, ó níbi tí agbára àwọn aláṣẹ ayé yìí mọ.

7. Àwọn ìgbà wo la ò ní ṣègbọràn sáwọn aláṣẹ, kí ló sì yẹ káwọn aláṣẹ yẹn mọ̀ dájú?

7 Àwa Kristẹni máa ń ṣe ohun tí àwọn aláṣẹ bá sọ, tí ò bá ṣáà ti ta ko òfin Ọlọ́run. Àmọ́, tí wọ́n bá ní ká ṣe ohun tí Jèhófà ní ká má ṣe tàbí tí wọ́n bá ní ká má ṣe ohun tí Jèhófà ní a gbọ́dọ̀ máa ṣe, a ò ní ṣègbọràn. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n lè ní káwọn ọ̀dọ́kùnrin lọ dara pọ̀ mọ́ àwọn tó ń jagun fún orílẹ̀-èdè wọn. * Yàtọ̀ síyẹn, wọ́n lè fòfin de Bíbélì àtàwọn ìwé ètò Ọlọ́run, wọ́n sì lè ní ká má wàásù tàbí lọ sípàdé mọ́. Táwọn èèyàn tó ń ṣàkóso bá ṣi agbára wọn lò, irú bíi kí wọ́n ṣenúnibíni sáwa ọmọlẹ́yìn Kristi, ó dájú pé wọ́n máa jíhìn fún Ọlọ́run torí pé Jèhófà ń rí gbogbo ohun tí wọ́n ń ṣe!​—Oníw. 5:8.

8. Ìyàtọ̀ wo ló wà nínú “aláṣẹ onípò gíga” àti “onípò àjùlọ,” kí sì nìdí tó fi yẹ ká mọ ìyàtọ̀ tó wà láàárín wọn?

8 Tá a bá pe ẹnì kan ní “aláṣẹ onípò gíga,” ó túmọ̀ sí pé ó “dáa ju àwọn kan lọ, ó ga ju àwọn kan lọ, ó sì nípò ju àwọn kan lọ.” Àmọ́ ìyẹn ò túmọ̀ sí pé “òun ló dáa jù lọ, òun ló ga jù lọ tàbí pé òun ló wà nípò tó ga jù lọ.” Ọ̀rọ̀ tá a ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ tán yìí la máa fi ń dá ẹni tó wà “nípò àjùlọ” mọ̀. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Bíbélì pe àwọn èèyàn tó ń ṣàkóso ní “aláṣẹ onípò gíga,” ẹnì kan wà tó láṣẹ ju gbogbo wọn lọ. Jèhófà lẹni náà, kódà ẹ̀ẹ̀mẹrin ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni Bíbélì pe Jèhófà ní “Onípò Àjùlọ.”​—Dán. 7:18, 22, 25, 27.

“ONÍPÒ ÀJÙLỌ”

9. Kí ni wòlíì Dáníẹ́lì rí nínú àwọn ìran tí Jèhófà fi hàn án?

9 Wòlíì Dáníẹ́lì rí àwọn ìran kan tó jẹ́ ká rí i kedere pé Jèhófà láṣẹ ju gbogbo àwọn aláṣẹ ayé lọ. Dáníẹ́lì kọ́kọ́ rí ẹranko ńlá mẹ́rin tó ṣàpẹẹrẹ àwọn ìjọba tó ti ṣàkóso ayé kọjá, ìyẹn Bábílónì, Mídíà àti Páṣíà, Gíríìsì pẹ̀lú Róòmù. Àmọ́, ìjọba Gẹ̀ẹ́sì àti Amẹ́ríkà ló ń ṣàkóso ayé lákòókò wa yìí. (Dán. 7:1-3, 17) Lẹ́yìn náà, Dáníẹ́lì rí Jèhófà tó jókòó sórí ìtẹ́ ní kọ́ọ̀tù lọ́run. (Dán. 7:9, 10) Ohun tí wòlíì olóòótọ́ yìí rí nínú ìran lẹ́yìn ìyẹn jẹ́ ìkìlọ̀ fáwọn tó ń ṣàkóso lákòókò wa yìí.

10.Dáníẹ́lì 7:13, 14, 27 ṣe sọ, àwọn wo ni Jèhófà gbé agbára àti àṣẹ láti ṣàkóso ayé lé lọ́wọ́, kí nìyẹn sì fi hàn pé Ọlọ́run jẹ́?

10 Ka Dáníẹ́lì 7:13, 14, 27. Ọlọ́run gba agbára àti àṣẹ kúrò lọ́wọ́ àwọn èèyàn tó ń ṣàkóso, ó sì gbé e fún àwọn míì tó lágbára, tó sì dáa jù wọ́n lọ. Àwọn wo ló gbé e fún? Ó gbé e fún “ẹnì kan bí ọmọ èèyàn,” ìyẹn Jésù Kristi àti àwọn “ẹni mímọ́ ti Onípò Àjùlọ,” ìyẹn àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì (144,000) tó máa ṣàkóso “títí láé àti láéláé.” (Dán. 7:18) Ó dájú pé Jèhófà ni “Onípò Àjùlọ” torí pé òun nìkan ló láṣẹ láti ṣe irú nǹkan yìí.

11. Nǹkan míì wo ni Dáníẹ́lì sọ tó fi hàn pé Jèhófà láṣẹ ju gbogbo àwọn alákòóso ayé lọ?

11 Ohun tí Dáníẹ́lì rí nínú ìran bá ohun tó sọ ṣáájú ìgbà yẹn mu. Dáníẹ́lì sọ pé: “Ọlọ́run ọ̀run . . .  ń mú ọba kúrò, ó sì ń fi ọba jẹ.” Ó tún sọ pé: “Ẹni Gíga Jù Lọ ni Alákòóso nínú ìjọba aráyé, ẹni tó bá wù ú ló ń gbé e fún.” (Dán. 2:19-21; 4:17) Ǹjẹ́ àwọn ìgbà kan tiẹ̀ wà tí Jèhófà mú àwọn ọba kúrò tàbí tó fi àwọn ọba jẹ? Bẹ́ẹ̀ ni!

Jèhófà gba ìjọba lọ́wọ́ Bẹliṣásárì, ó sì gbé e fún àwọn ará Mídíà àti Páṣíà (Wo ìpínrọ̀ 12)

12. Sọ àpẹẹrẹ bí Jèhófà ṣe mú àwọn ọba kúrò lórí ìtẹ́ wọn nígbà àtijọ́. (Wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)

12 Jèhófà ti fi hàn gbangba-gbàǹgbà pé òun lágbára ju àwọn “aláṣẹ onípò gíga” lọ. Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ mẹ́ta kan. Fáráò ọba Íjíbítì mú àwọn èèyàn Jèhófà lẹ́rú, ó sì kọ̀ láti tú wọn sílẹ̀. Àmọ́ Ọlọ́run dá wọn sílẹ̀, ó sì pa Fáráò sínú Òkun Pupa. (Ẹ́kís. 14:26-28; Sm. 136:15) Nígbà tí Bẹliṣásárì ọba Bábílónì se àsè ńlá kan, ‘ó gbé ara rẹ̀ ga sí Olúwa ọ̀run, ó sì ń yin àwọn ọlọ́run tí wọ́n fi fàdákà àti wúrà’ ṣe dípò Jèhófà. (Dán. 5:22, 23) Àmọ́ Ọlọ́run rẹ ọba agbéraga yìí wálẹ̀. “Òru ọjọ́ yẹn gan-an” ni wọ́n pa Bẹliṣásárì, Jèhófà sì gbé ìjọba ẹ̀ fún àwọn ará Mídíà àti Páṣíà. (Dán. 5:28, 30, 31) Ọba Hẹ́rọ́dù Àgírípà Kìíní ti ilẹ̀ Palẹ́sìnì pa àpọ́sítélì Jémíìsì. Ó tún fi àpọ́sítélì Pétérù sẹ́wọ̀n kí wọ́n lè pa á, àmọ́ Jèhófà ò jẹ́ kí Hẹ́rọ́dù rí i ṣe. Torí náà Bíbélì sọ pé, “áńgẹ́lì Jèhófà kọ lù ú,” ó sì kú.​—Ìṣe 12:1-5, 21-23.

13. Sọ àpẹẹrẹ ìgbà tí Jèhófà ṣẹ́gun àgbájọ àwọn ọba orílẹ̀-èdè.

13 Jèhófà fi hàn pé òun tún lágbára ju àgbájọ àwọn ọba orílẹ̀-èdè lọ. Jèhófà jà fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì, ó jẹ́ kí wọ́n ṣẹ́gun àwọn ọba Kénáánì mọ́kànlélọ́gbọ̀n (31), wọ́n sì gba èyí tó pọ̀ jù lára Ilẹ̀ Ìlérí. (Jóṣ. 11:4-6, 20; 12:1, 7, 24) Jèhófà tún ṣẹ́gun Ọba Bẹni-hádádì àti àwọn ọba Síríà méjìlélọ́gbọ̀n (32) tó bá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jà.​—1 Ọba 20:1, 26-29.

14-15. (a) Kí ni Ọba Nebukadinésárì àti Dáríúsì sọ nípa àkóso Jèhófà? (b) Kí ni onísáàmù kan sọ nípa Jèhófà àtàwọn èèyàn Ọlọ́run?

14 Léraléra ni Jèhófà ti fi hàn pé òun ni Ẹni Tó Lágbára Jù Lọ! Ìgbà kan wà tí Nebukadinésárì ọba Bábílónì fọ́nnu nípa ‘agbára àti okun àti ògo ọlá ńlá’ tó ní dípò kó gbà pé Jèhófà ni Ẹni tí ìyìn yẹ, torí náà, Jèhófà mú kó ya wèrè. Lẹ́yìn tí ara Nebukadinésárì yá, ó “yin Ẹni Gíga Jù Lọ,” ó sì wá gbà pé “àkóso tó wà títí láé ni àkóso [Jèhófà].” Ó tún sọ pé: “Kò sí ẹni tó lè dá a dúró.” (Dán. 4:30, 33-35) Lẹ́yìn tí wọ́n dán Dáníẹ́lì wò, tí Jèhófà sì dá a nídè nínú ihò kìnnìún, Ọba Dáríúsì pàṣẹ pé: “Kí àwọn èèyàn máa bẹ̀rù Ọlọ́run Dáníẹ́lì gidigidi. Torí òun ni Ọlọ́run alààyè, ó sì máa wà títí láé. Ìjọba rẹ̀ ò ní pa run láé, àkóso rẹ̀ sì máa wà títí ayérayé.”​—Dán. 6:7-10, 19-22, 26, 27.

15 Onísáàmù kan sọ pé: “Jèhófà ti mú kí ohun tí àwọn orílẹ̀-èdè gbèrò já sí òfo; ó ti dojú ìmọ̀ràn àwọn èèyàn dé.” Ó tún sọ pé: “Aláyọ̀ ni orílẹ̀-èdè tí Jèhófà jẹ́ Ọlọ́run rẹ̀, àwọn èèyàn tí ó ti yàn láti jẹ́ ohun ìní rẹ̀.” (Sm. 33:10, 12) Ẹ ò rí i pé ó yẹ ká jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà nítorí àwọn nǹkan rere tó ń ṣe fún wa yìí!

OGUN ÀJÀKẸ́YÌN

Àgbájọ àwọn orílẹ̀-èdè ò ní lè kojú àwọn ọmọ ogun Jèhófà (Wo ìpínrọ̀ 16-17)

16. Kí ló dá wa lójú pé Jèhófà máa ṣe nígbà “ìpọ́njú ńlá,” kí sì nìdí? (Wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)

16 A ti rí bí Jèhófà ṣe fi agbára ẹ̀ hàn nígbà àtijọ́. Àmọ́, kí ló yẹ ká máa retí láìpẹ́? Ó dá wa lójú pé Jèhófà máa gba àwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ ẹ̀ sílẹ̀ nígbà “ìpọ́njú ńlá” tó ń bọ̀. (Mát. 24:21; Dán. 12:1) Jèhófà máa ṣe bẹ́ẹ̀ nígbà tí àgbájọ àwọn orílẹ̀-èdè tí Bíbélì pè ní Gọ́ọ̀gù ti ilẹ̀ Mágọ́gù bá gbéjà ko àwa olóòótọ́ ìránṣẹ́ Ọlọ́run. Kódà, tí gbogbo igba ó dín méje (193) orílẹ̀-èdè tó wà nínú Àjọ Ìṣọ̀kan Àgbáyé bá wà lára àwọn tó kóra jọ láti gbéjà ko àwa èèyàn Ọlọ́run, wọn ò ní lè kojú Ẹni Tó Lágbára Jù Lọ àtàwọn ọmọ ogun rẹ̀! Jèhófà ṣèlérí pé: “Ó dájú pé màá gbé ara mi ga, màá jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé ẹni mímọ́ ni mí, màá sì jẹ́ kí àwọn orílẹ̀-èdè mọ irú ẹni tí mo jẹ́; wọ́n á sì wá mọ̀ pé èmi ni Jèhófà.”​—Ìsík. 38:14-16, 23; Sm. 46:10.

17. Kí ni Bíbélì sọ pé ó máa ṣẹlẹ̀ sáwọn ọba ayé, kí ló sì máa ṣẹlẹ̀ sáwọn tó ń pa ìwà títọ́ mọ́?

17 Nígbà tí Gọ́ọ̀gù bá gbéjà ko àwa èèyàn Ọlọ́run, ìyẹn máa jẹ́ kí Jèhófà ja ogun àjàkẹ́yìn ní Amágẹ́dọ́nì, ó sì máa pa “àwọn ọba gbogbo ilẹ̀ ayé tí à ń gbé” run. (Ìfi. 16:14, 16; 19:19-21) Àmọ́, “àwọn adúróṣinṣin ló máa gbé ní ayé, àwọn tó ń pa ìwà títọ́ mọ́ ló sì máa ṣẹ́ kù sínú rẹ̀.”​—Òwe 2:21, àlàyé ìsàlẹ̀.

A GBỌ́DỌ̀ JẸ́ OLÓÒÓTỌ́ SÍ JÈHÓFÀ

18. Kí ni ọ̀pọ̀ àwa Kristẹni tòótọ́ ti pinnu pé a máa ṣe, kí sì nìdí? (Dáníẹ́lì 3:28)

18 Ọjọ́ pẹ́ táwọn Kristẹni tòótọ́ ti ń fi ẹ̀mí wọn wewu torí pé wọ́n nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, wọ́n sì gbà pé òun ni Ọba Aláṣẹ Ayé Àtọ̀run. Bíi tàwọn Hébérù mẹ́ta tí wọ́n jù sínú iná ìléru àmọ́ tí Ẹni Tó Lágbára Jù Lọ gbà wọ́n sílẹ̀ torí pé wọ́n jẹ́ olóòótọ́, bẹ́ẹ̀ náà làwa Kristẹni tòótọ́ ṣe pinnu pé Jèhófà la máa jẹ́ olóòótọ́ sí.​—Ka Dáníẹ́lì 3:28.

19. Kí ni Jèhófà máa fi dá àwọn èèyàn ẹ̀ lẹ́jọ́, kí nìyẹn sì gba pé ká ṣe báyìí?

19 Dáfídì sọ bó ti ṣe pàtàkì tó pé ká jẹ́ olóòótọ́ sí Ọlọ́run. Ó sọ pé: “Jèhófà yóò ṣe ìdájọ́ àwọn èèyàn. Ṣe ìdájọ́ mi, Jèhófà, gẹ́gẹ́ bí òdodo mi àti gẹ́gẹ́ bí ìwà títọ́ mi.” (Sm. 7:8) Dáfídì tún sọ pé: “Ìwà títọ́ àti ìdúróṣinṣin máa dáàbò bò mí.” (Sm. 25:21) Torí náà, ohun tó máa jẹ́ ká gbádùn ayé wa ni pé ká jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà, ká má fi í sílẹ̀ rárá bá a tiẹ̀ ń dojú kọ ọ̀pọ̀ ìṣòro! Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, àwa náà máa lè sọ bíi ti onísáàmù pé: “Aláyọ̀ ni àwọn tó ń pa ìwà títọ́ mọ́ . . . , tó ń rìn nínú òfin Jèhófà.”​—Sm. 119:1, àlàyé ìsàlẹ̀.

ORIN 122 Ẹ Fẹsẹ̀ Múlẹ̀ Ṣinṣin!

^ Bíbélì rọ̀ wá pé ká máa tẹrí ba fún àwọn aláṣẹ onípò gíga, ìyẹn àwọn ìjọba ayé yìí. Àmọ́ àwọn ìjọba kan máa ń ta ko Jèhófà àtàwọn èèyàn rẹ̀. Torí náà, báwo la ṣe lè máa tẹrí ba fáwọn alákòóso ayé, ká sì tún jẹ́ olóòótọ́ sí Ọlọ́run?

^ ÀLÀYÉ Ọ̀RỌ̀: Tẹ́nì kan bá jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà, kódà tí wọ́n bá tiẹ̀ dán ìgbàgbọ́ ẹni náà wò, ó ṣì máa jẹ́ adúróṣinṣin, á sì gbà pé Jèhófà nìkan ló lẹ́tọ̀ọ́ láti ṣàkóso ayé àtọ̀run.