Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 43

Jèhófà Fẹ́ Kó O Ní Ọgbọ́n Tòótọ́

Jèhófà Fẹ́ Kó O Ní Ọgbọ́n Tòótọ́

“Ọgbọ́n tòótọ́ ń ké jáde ní ojú ọ̀nà. Ó ń gbé ohùn rẹ̀ sókè ní àwọn ojúde ìlú.”​—ÒWE 1:20.

ORIN 88 Mú Mi Mọ Àwọn Ọ̀nà Rẹ

OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒ *

1. Kí ni ọ̀pọ̀ máa ń ṣe tá a bá ń wàásù ìmọ̀ràn ọlọgbọ́n tó wà nínú Bíbélì fún wọn? (Òwe 1:20, 21)

 NÍ Ọ̀PỌ̀ orílẹ̀-èdè, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà sábà máa ń wàásù láwọn ibi térò pọ̀ sí, a sì máa ń fún àwọn èèyàn láwọn ìwé wa. Ṣé ìwọ náà ti wàásù níbẹ̀ rí? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, á jẹ́ pé ìwọ náà ti ronú nípa àpèjúwe tó wà nínú ìwé Òwe, ìyẹn àpèjúwe ọgbọ́n tó ń ké jáde ní ojúde ìlú pé káwọn èèyàn wá tẹ́tí sí ìmọ̀ràn òun. (Ka Òwe 1:20, 21.) “Ọgbọ́n tòótọ́,” ìyẹn ọgbọ́n Jèhófà wà nínú Bíbélì àtàwọn ìwé ètò Ọlọ́run. Ọgbọ́n yìí gan-an làwọn èèyàn nílò kí wọ́n lè rí ìyè àìnípẹ̀kun. Torí náà, inú wa máa ń dùn tẹ́nì kan bá gba àwọn ìwé wa. Àmọ́ kì í ṣe gbogbo èèyàn ló máa ń gbà á. Àwọn kan máa ń sọ pé ohun tó wà nínú Bíbélì ò kan àwọn. Àwọn míì sì máa ń fi wá ṣe yẹ̀yẹ́ torí wọ́n rò pé Bíbélì ò bóde mu mọ́. A tún rí àwọn kan tó ń sọ pé ìmọ̀ràn tí Bíbélì fún wa nípa bó ṣe yẹ ká máa gbé ìgbé ayé wa ò bọ́gbọ́n mu, kódà wọ́n máa ń sọ pé èèyàn burúkú làwọn tó ń tẹ̀ lé ìlànà Bíbélì, wọ́n sì máa ń dáni lẹ́jọ́. Láìka gbogbo ìyẹn sí, Jèhófà ń fún gbogbo èèyàn láǹfààní láti ní ọgbọ́n tòótọ́ torí pé ó nífẹ̀ẹ́ wa. Báwo ló ṣe ń ṣe é?

2. Ibo la ti lè rí ọgbọ́n tòótọ́ lónìí, àmọ́ kí ni ọ̀pọ̀ pinnu pé àwọn máa ṣe?

2 Bíbélì wà lára ohun tí Jèhófà fi ń kọ́ wa ní ọgbọ́n tòótọ́. Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ gbogbo èèyàn ló ní Bíbélì lónìí. Àmọ́ àwọn ìwé ètò Ọlọ́run ńkọ́? Jèhófà ti bù kún wa débi pé àwọn ìwé náà ti wà ní èdè tó ju ẹgbẹ̀rún kan (1,000) lọ báyìí. Ó dájú pé àwọn tó bá ń tẹ́tí sí ọgbọ́n tòótọ́, ìyẹn àwọn tó ń ka Bíbélì àtàwọn ìwé wa, tí wọ́n sì ń fi ohun tí wọ́n ń kọ́ sílò máa jàǹfààní gan-an. Àmọ́, ó ṣeni láàánú pé ọ̀pọ̀ ló kọ̀ láti tẹ́tí sí ọgbọ́n tòótọ́ lónìí. Ìdí ni pé tí wọ́n bá fẹ́ ṣe ìpinnu, ọgbọ́n tara wọn ni wọ́n máa ń gbára lé tàbí ohun táwọn ẹlòmíì bá sọ fún wọn. Wọ́n tiẹ̀ lè máa fojú burúkú wò wá torí pé ìmọ̀ràn Bíbélì làwa ń tẹ̀ lé. Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa rí ìdí táwọn kan fi ń hu irú ìwà yìí. Àmọ́, ẹ jẹ́ ká kọ́kọ́ sọ̀rọ̀ nípa bá a ṣe lè ní ọgbọ́n tòótọ́ tó wá látọ̀dọ̀ Jèhófà.

ÌMỌ̀ JÈHÓFÀ LÓ MÁA JẸ́ KÁ GBỌ́N

3. Kí la gbọ́dọ̀ ṣe ká tó lè ní ọgbọ́n tòótọ́?

3 Ẹni tó bá gbọ́n máa ń lo ìmọ̀ tó ní láti ṣe ìpinnu tó dáa. Àmọ́ ká tó lè ní ọgbọ́n tòótọ́, àwọn nǹkan míì wà tá a gbọ́dọ̀ ṣe. Bíbélì sọ pé: “Ìbẹ̀rù Jèhófà ni ìbẹ̀rẹ̀ ọgbọ́n, ìmọ̀ Ẹni Mímọ́ Jù Lọ sì ni òye.” (Òwe 9:10) Torí náà, tá a bá fẹ́ ṣe ìpinnu pàtàkì, ó yẹ ká lo ìmọ̀ Jèhófà, ìyẹn “ìmọ̀ Ẹni Mímọ́ Jù Lọ” láti ṣe ìpinnu náà. A lè ṣe bẹ́ẹ̀ tá a bá ń ka Bíbélì tá a sì ń ṣèwádìí nínú àwọn ìwé ètò Ọlọ́run. Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, á fi hàn pé a ní ọgbọ́n tòótọ́.​—Òwe 2:5-7.

4. Kí nìdí tó fi jẹ́ pé Jèhófà nìkan ló lè fún wa ní ọgbọ́n tòótọ́?

4 Jèhófà nìkan ló lè fún wa ní ọgbọ́n tòótọ́. (Róòmù 16:27) Kí nìdí tó fi jẹ́ pé òun ni Orísun ọgbọ́n? Ìdí àkọ́kọ́ ni pé òun ni Ẹlẹ́dàá wa, ó sì ní ìmọ̀ àti òye nípa gbogbo nǹkan tó dá. (Sm. 104:24) Ìkejì, gbogbo nǹkan tí Jèhófà ń ṣe ló fi hàn pé ọlọ́gbọ́n ni. (Róòmù 11:33) Ìkẹta, gbogbo àwọn tó bá ń tẹ̀ lé ìmọ̀ràn ọlọgbọ́n tí Jèhófà ń fún wa máa ń jàǹfààní. (Òwe 2:10-12) Torí náà, tá a bá fẹ́ ní ọgbọ́n tòótọ́, a gbọ́dọ̀ gbà pé òótọ́ làwọn nǹkan mẹ́ta tá a sọ yẹn, ká sì jẹ́ kí wọ́n máa darí wa tá a bá fẹ́ ṣèpinnu.

5. Kí ló máa ń ṣẹlẹ̀ táwọn èèyàn ò bá gbà pé ọ̀dọ̀ Jèhófà ni ọgbọ́n tòótọ́ ti ń wá?

5 Ọ̀pọ̀ èèyàn ló gbà pé àgbàyanu làwọn nǹkan tó wà láyé, síbẹ̀ wọn ò gbà pé Ọlọ́run ló dá àwọn nǹkan yẹn. Wọ́n gbà pé ńṣe làwọn nǹkan yẹn ṣàdédé wà. Àwọn míì gbà pé Ọlọ́run ló dá àwọn nǹkan, àmọ́ wọn ò gbà pé àwọn ìlànà Bíbélì ṣì bóde mu, torí náà ohun tó bá wù wọ́n ni wọ́n ń ṣe. Kí nìyẹn ti wá yọrí sí? Ṣé ayé yìí ti wá dáa sí i báwọn èèyàn ṣe ń ṣe ohun tó wù wọ́n dípò kí wọ́n máa lo ọgbọ́n Ọlọ́run? Ṣé wọ́n ní ayọ̀ tòótọ́, ṣé wọ́n sì gbà pé ọjọ́ ọ̀la ń bọ̀ wá dáa? Àwọn nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀ láyé yìí ti jẹ́ ká rí i pé òótọ́ lohun tí Bíbélì sọ pé: “Kò sí ọgbọ́n tàbí òye tàbí ìmọ̀ràn tó lòdì sí Jèhófà tó lè dúró.” (Òwe 21:30) Ẹ ò rí i pé ó yẹ kí èyí mú ká gbára lé Jèhófà tó jẹ́ Orísun ọgbọ́n! Àmọ́, ó ṣeni láàánú pé ọ̀pọ̀ èèyàn kì í ṣe bẹ́ẹ̀. Kí nìdí?

ÌDÍ TÁWỌN ÈÈYÀN FI KỌ ỌGBỌ́N TÒÓTỌ́

6. Àwọn wo ni Òwe 1:22-25 sọ pé wọ́n kọ etí dídi sí ọgbọ́n tòótọ́?

6 Ọ̀pọ̀ ló kọ etí dídi sí ọgbọ́n tòótọ́ nígbà tó “ń ké jáde ní ojú ọ̀nà.” Àwọn mẹ́ta kan ni Bíbélì sọ pé wọ́n kọ ọgbọ́n tòótọ́: Àwọn “aláìmọ̀kan,” àwọn “afiniṣẹ̀sín” àtàwọn “òmùgọ̀.” (Ka Òwe 1:22-25.) Ní báyìí, ẹ jẹ́ ká wo ohun tó mú káwọn tá a sọ̀rọ̀ wọn yìí kọ ọgbọ́n Ọlọ́run àti ìdí tí kò fi yẹ ká fìwà jọ wọ́n.

7. Kí nìdí táwọn kan fi pinnu pé àwọn máa jẹ́ “aláìmọ̀kan”?

7 Àwọn “aláìmọ̀kan” làwọn tí kò ní ìrírí, tí wọ́n tètè máa ń gba ohun táwọn èèyàn bá sọ fún wọn gbọ́, ìyẹn sì máa ń mú káwọn èèyàn ṣì wọ́n lọ́nà. (Òwe 14:15, àlàyé ìsàlẹ̀) A sábà máa ń pàdé irú àwọn èèyàn bẹ́ẹ̀ tá a bá ń wàásù. Bí àpẹẹrẹ, ẹ ronú nípa ọ̀pọ̀ èèyàn táwọn olórí ẹ̀sìn àtàwọn olóṣèlú ń ṣì lọ́nà. Inú máa ń bí àwọn kan lẹ́yìn tí wọ́n bá mọ̀ pé wọ́n ti kó àwọn ṣìnà. Àmọ́ àwọn tí Òwe 1:22 sọ̀rọ̀ nípa wọn pinnu pé àwọn ṣì máa jẹ́ aláìmọ̀kan, kódà lẹ́yìn tí wọ́n rí i pé irọ́ ni wọ́n ń pa fáwọn. (Jer. 5:31) Ohun tó bá wù wọ́n ni wọ́n ń ṣe, wọn ò fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ ohun tí Bíbélì sọ, wọn ò sì fẹ́ tẹ̀ lé àwọn ìlànà tó wà nínú ẹ̀. Ọ̀pọ̀ ló máa ń ṣe bíi ti obìnrin ẹlẹ́sìn kan ní Quebec, lórílẹ̀-èdè Kánádà, ó sọ fún Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan tó wá wàásù nílé ẹ̀ pé, “Tí àlùfáà wa bá ṣì wá lọ́nà, òun ló máa jẹ̀bi ẹ̀, kì í ṣe àwa!” Torí náà, ó dájú pé a ò ní fẹ́ fìwà jọ àwọn tó mọ̀ọ́mọ̀ pinnu pé aláìmọ̀kan làwọn máa jẹ́!​—Òwe 1:32; 27:12.

8. Kí ló máa jẹ́ ká di ọlọ́gbọ́n?

8 Ó nídìí tí Bíbélì fi gbà wá níyànjú pé ká má ṣe jẹ́ aláìmọ̀kan, dípò bẹ́ẹ̀ ṣe ló yẹ ká “dàgbà di géńdé nínú òye.” (1 Kọ́r. 14:20) A máa ní òye tó yẹ ká ní tá a bá ń fi àwọn ìlànà Bíbélì sílò. Bọ́jọ́ ṣe ń gorí ọjọ́, àá rí báwọn ìlànà yẹn ò ṣe ní jẹ́ ká kó síṣòro àti bí wọ́n ṣe ń jẹ́ ká ṣe àwọn ìpinnu tó bọ́gbọ́n mu. Torí náà, ó yẹ ká bi ara wa pé, ṣé ìlànà Bíbélì ni mo fi ń ṣe àwọn ìpinnu tí mò ń ṣe? Tó bá sì ti pẹ́ díẹ̀ tí mo ti ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tí mo sì ti ń wá sípàdé, kí ló dé tí mi ò tíì ya ara mi sí mímọ́ fún Jèhófà, kí n sì ṣèrìbọmi? Tí mo bá sì ti ṣèrìbọmi, ṣé mò ń já fáfá sí i lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù àti kíkọ́ni? Ṣé àwọn ìpinnu tí mò ń ṣe fi hàn pé ìlànà Bíbélì ló ń darí mi? Ṣé bí Jésù ṣe máa ń ṣe sáwọn èèyàn lèmi náà máa ń ṣe sí wọn? Tá a bá rí i pé àwọn ibì kan wà tó yẹ ká ti ṣàtúnṣe, ẹ jẹ́ ká gba ìmọ̀ràn Jèhófà torí pé ìyẹn ló máa ‘ń sọ aláìmọ̀kan di ọlọ́gbọ́n.’​—Sm. 19:7.

9. Báwo làwọn “afiniṣẹ̀sín” ṣe ń fi hàn pé àwọn kọ ọgbọ́n Ọlọ́run?

9 Àwọn kejì tí wọ́n kọ ọgbọ́n Ọlọ́run ni àwọn “afiniṣẹ̀sín.” A sábà máa ń pàdé irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ tá a bá ń wàásù. Wọ́n sì máa ń fi wá ṣe yẹ̀yẹ́. (Sm. 123:4) Bíbélì ti sọ tẹ́lẹ̀ pé tó bá dọjọ́ ìkẹyìn, àwọn tó ń fini ṣẹlẹ́yà máa pọ̀ gan-an. (2 Pét. 3:3, 4) Bíi tàwọn ọkọ ọmọ Lọ́ọ̀tì, àwọn kan lónìí ò gba ìkìlọ̀ tí Ọlọ́run ń fún wọn. (Jẹ́n. 19:14) Ọ̀pọ̀ ló máa ń fi àwa tá à ń tẹ̀ lé ìlànà Bíbélì ṣe yẹ̀yẹ́. Àwọn afiniṣẹ̀sín ń ṣohun tí wọ́n ń ṣe yìí torí ‘ohun tí kò bá ìfẹ́ Ọlọ́run mu ló ń wù wọ́n.’ (Júùdù 7, 17, 18) Ẹ ò rí i pé ohun tí Bíbélì sọ nípa àwọn afiniṣẹ̀sín yìí bá ìwà àwọn apẹ̀yìndà mu torí pé wọ́n ti fi Jèhófà sílẹ̀!

10.Sáàmù 1:1 ṣe sọ, kí nìdí tí kò fi yẹ ká fìwà jọ àwọn afiniṣẹ̀sín?

10 Kí la lè ṣe tá ò bá fẹ́ fìwà jọ àwọn afiniṣẹ̀sín? Ohun tá a lè ṣe ni pé ká yẹra fún àwọn èèyàn tó bá ń ṣàríwísí ṣáá nípa gbogbo nǹkan. (Ka Sáàmù 1:1.) Ìyẹn ni pé a ò ní máa tẹ́tí sí àwọn apẹ̀yìndà, a ò sì ní máa ka ìwé wọn. A mọ̀ pé tá ò bá ṣọ́ra, a lè bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàríwísí gbogbo nǹkan, ká má fọkàn tán Jèhófà mọ́, ká sì máa kọminú sí ohun tí ètò ẹ̀ bá ń sọ fún wa. Torí náà, tá ò bá fẹ́ fìwà jọ àwọn afiniṣẹ̀sín, ó yẹ ká bi ara wa pé: ‘Ṣé mo máa ń ṣàríwísí tí ètò Ọlọ́run bá fún wa ní ìtọ́ni tuntun kan tàbí tí wọ́n ṣàlàyé òye tuntun kan? Ṣé kì í ṣe ibi táwọn tó ń ṣàbójútó wa kù sí ni mo máa ń wò ṣáá?’ Torí náà, tá a bá tètè ṣàtúnṣe láti mú èrò tí ò tọ́ yìí kúrò lọ́kàn wa, inú Jèhófà máa dùn sí wa.​—Òwe 3:34, 35.

11. Ojú wo làwọn “òmùgọ̀” fi ń wo àwọn ìlànà ìwà rere tí Jèhófà fún wa?

11 Àwọn kẹta tí wọ́n kọ ọgbọ́n Ọlọ́run ni àwọn “òmùgọ̀.” Òmùgọ̀ ni wọ́n torí wọn kì í tẹ̀ lé àwọn ìlànà ìwà rere tí Ọlọ́run fún wa. Ohun tó tọ́ lójú wọn ni wọ́n ń ṣe. (Òwe 12:15) Irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ kọ Jèhófà tó jẹ́ Orísun ọgbọ́n sílẹ̀. (Sm. 53:1) Tá a bá bá irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ pàdé lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù, wọ́n máa ń bú wa gan-an torí pé à ń tẹ̀ lé àwọn ìlànà Bíbélì. Àmọ́ ọ̀rọ̀ ẹnu wọn ò lè ṣe ẹnikẹ́ni láǹfààní. Bíbélì sọ pé: “Ọgbọ́n tòótọ́ ga ju ohun tí ọwọ́ òmùgọ̀ lè tẹ̀; kò ní ohun kankan láti sọ ní ẹnubodè ìlú.” (Òwe 24:7) Torí náà, kò sí ọ̀rọ̀ ọgbọ́n kankan tó lè ti ẹnu òmùgọ̀ jáde. Abájọ tí Jèhófà fi kìlọ̀ fún wa pé ká “jìnnà sí òmùgọ̀ èèyàn”!​—Òwe 14:7.

12. Kí ló yẹ ká ṣe tá ò bá fẹ́ fìwà jọ àwọn òmùgọ̀?

12 Àwa Kristẹni tòótọ́ kì í hùwà bí àwọn tí kì í tẹ̀ lé ìlànà Ọlọ́run, kàkà bẹ́ẹ̀ ohun tí Ọlọ́run fẹ́ la máa ń ṣe, a sì máa ń pa àwọn òfin ẹ̀ mọ́. A lè mú kí ìfẹ́ tá a ní fún Ọlọ́run túbọ̀ lágbára tá a bá ń ronú nípa ohun tó máa ń ṣẹlẹ̀ sáwọn tí kì í tẹ̀ lé ìlànà Ọlọ́run àtàwọn tó ń tẹ̀ lé ìlànà rẹ̀. O lè kíyè sí ohun táwọn òmùgọ̀ tó kọ ọgbọ́n Jèhófà máa ń fọwọ́ ara wọn fà sórí ara wọn, kó o wá fi wé bí ìgbésí ayé ẹ ṣe dáa torí pé ò ń tẹ̀ lé àwọn ìlànà Ọlọ́run.​—Sm. 32:8, 10.

13. Ṣé Jèhófà máa ń fipá mú wa láti tẹ̀ lé ìmọ̀ràn ọlọgbọ́n tó fún wa?

13 Gbogbo èèyàn ni Jèhófà fẹ́ kó jàǹfààní ọgbọ́n òun, àmọ́ kò fipá mú ẹnikẹ́ni nínú wa láti ṣe bẹ́ẹ̀. Síbẹ̀, ó sọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sáwọn tí ò bá fetí sí ìmọ̀ràn ọlọgbọ́n. (Òwe 1:29-32) Àwọn tí ò ṣègbọràn sí Jèhófà máa “jìyà ọ̀nà tí wọ́n yàn.” Tó bá yá, ìgbésí ayé tí wọ́n ń gbé á kó ìdààmú àti ìyọnu bá wọn, níkẹyìn wọ́n á pa run. Àmọ́ Jèhófà ṣèlérí fáwọn tó ń fetí sí ìmọ̀ràn ọlọgbọ́n tó fún wa, tí wọ́n sì ń ṣe ohun tó fẹ́ pé: “Ẹni tó ń fetí sí mi á máa gbé lábẹ́ ààbò, ìbẹ̀rù àjálù kò sì ní yọ ọ́ lẹ́nu.”​—Òwe 1:33.

ỌGBỌ́N ỌLỌ́RUN MÁA Ń ṢE WÁ LÁǸFÀÀNÍ

Tá a bá ń dáhùn nípàdé, á jẹ́ kí àjọse wa pẹ̀lú Jèhófà dáa sí i (Wo ìpínrọ̀ 15)

14-15. Kí la rí kọ́ nínú Òwe 4:23?

14 Gbogbo ìgbà tá a bá ń lo ọgbọ́n Ọlọ́run la máa ń jàǹfààní ẹ̀. Bá a ṣe sọ níṣàájú, gbogbo èèyàn ni Jèhófà fẹ́ kó jàǹfààní ìmọ̀ràn ọlọgbọ́n tó ń fún wa. Bí àpẹẹrẹ, jálẹ̀ ìwé Òwe, Jèhófà fún wa láwọn ìmọ̀ràn tó máa ṣe wá láǹfààní, táá sì jẹ́ káyé wa túbọ̀ dáa tá a bá ń tẹ̀ lé wọn. Ní báyìí, ẹ jẹ́ ká gbé mẹ́rin lára ìmọ̀ràn ọlọgbọ́n náà yẹ̀ wò.

15 Dáàbò bo ọkàn rẹ. Bíbélì sọ pé: “Ju gbogbo ohun mìíràn tí ò ń dáàbò bò, dáàbò bo ọkàn rẹ, nítorí inú rẹ̀ ni àwọn ohun tó ń fúnni ní ìyè ti ń wá.” (Òwe 4:23) Ẹ wo bá a ṣe máa ń sapá tó ká tó lè dáàbò bo ọkàn wa. Ó gba pé ká jẹ oúnjẹ tó ń ṣara lóore, ká máa ṣeré ìmárale, ká sì yẹra fáwọn nǹkan tó lè kó bá ìlera wa. Ohun kan náà ló yẹ ká ṣe tá a bá fẹ́ dáàbò bo irú ẹni tá a jẹ́ nínú lọ́hùn-ún. Ó gba pé ká máa kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lójoojúmọ́, ká máa múra ìpàdé sílẹ̀, ká máa lọ sípàdé déédéé, ká sì máa dáhùn nípàdé. Tá a bá ń lo okun wa lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù déédéé, ńṣe là ń dáàbò bo ọkàn wa, ìyẹn irú ẹni tá a jẹ́ nínú lọ́hùn-ún. Torí náà, tá a bá ń yẹra fún ohunkóhun tó lè kó bá èrò inú wa, irú bí eré ìnàjú tó ń gbé ìṣekúṣe lárugẹ àti ẹgbẹ́ búburú, a ò ní hùwà tí ò bójú mu.

Torí pé a kì í lépa owó, ohun tá a ní tẹ́ wa lọ́rùn (Wo ìpínrọ̀ 16)

16. Báwo ni ohun tó wà ní Òwe 23:4, 5 ṣe lè ṣe wá láǹfààní lónìí?

16 Jẹ́ kí ohun tó o ní tẹ́ ẹ lọ́rùn. Bíbélì fún wa ní ìmọ̀ràn yìí pé: “Má fi wàhálà pa ara rẹ torí kí o lè kó ọrọ̀ jọ. . . . Nígbà tí o bá bojú wò ó, kò ní sí níbẹ̀, torí ó dájú pé ó máa hu ìyẹ́ bí ẹyẹ idì, á sì fò lọ sójú ọ̀run.” (Òwe 23:4, 5) Ìgbàkigbà lèèyàn lè pàdánù ọrọ̀ àti ohun ìní tó kó jọ. Àmọ́ lónìí àtolówó àti tálákà ló ń ṣiṣẹ́ kára kí wọ́n lè di ọlọ́rọ̀. Bí wọ́n ṣe ń fi gbogbo ọjọ́ ayé wọn lépa owó yìí ti mú kí wọ́n ba ara wọn lórúkọ jẹ́. Ó ti mú kí àjọṣe àárín wọn àtàwọn èèyàn bà jẹ́, ó sì ti kó bá ìlera wọn. (Òwe 28:20; 1 Tím. 6:9, 10) Àmọ́, torí pé àwa Kristẹni tòótọ́ ní ọgbọ́n Ọlọ́run, a kì í lépa owó, ìyẹn ni ò sì jẹ́ ká di oníwọra. A máa ń jẹ́ kí ohun tá a ní tẹ́ wa lọ́rùn, a sì ń láyọ̀.​—Oníw. 7:12.

Tá a bá ń ronú ká tó sọ̀rọ̀, ọ̀rọ̀ ẹnu wa ò ní pa àwọn èèyàn lára (Wo ìpínrọ̀ 17)

17.Òwe 12:18 ṣe sọ, báwo la ṣe lè ní “ahọ́n ọlọ́gbọ́n”?

17 Máa ronú kó o tó sọ̀rọ̀. Tá ò bá ṣọ́ra, ọ̀rọ̀ ẹnu wa lè kó bá wa. Bíbélì sọ pé: “Ọ̀rọ̀ téèyàn sọ láìronú dà bí ìgbà tí idà gúnni, àmọ́ ahọ́n ọlọ́gbọ́n ń woni sàn.” (Òwe 12:18) Àárín àwa àtàwọn èèyàn máa dáa tá ò bá sọ kùdìẹ̀-kudiẹ wọn fáwọn ẹlòmíì. (Òwe 20:19) Tá a bá fẹ́ kí ọ̀rọ̀ ẹnu wa tu àwọn èèyàn lára dípò táá fi máa múnú bí wọn, ó yẹ ká máa ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run déédéé, ká sì máa ronú lórí ohun tá a kà. (Lúùkù 6:45) Torí náà, tá a bá ń ronú nípa ohun tí Bíbélì sọ, ọ̀rọ̀ ẹnu wa máa dà bí “orísun ọgbọ́n” tó ń tu àwọn èèyàn lára.​—Òwe 18:4.

Tá a bá ń tẹ̀ lé ohun tí ètò Ọlọ́run ń sọ fún wa, àá túbọ̀ já fáfá lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù (Wo ìpínrọ̀ 18)

18. Báwo lohun tó wà nínú Òwe 24:6 ṣe máa jẹ́ ká ṣàṣeyọrí lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù àti kíkọ́ni?

18 Máa tẹ̀ lé ìtọ́sọ́nà ètò Ọlọ́run. Bíbélì fún wa ní ìmọ̀ràn kan tó máa jẹ́ ká ṣàṣeyọrí, ó ní: “Ìtọ́sọ́nà ọlọgbọ́n ni kí o fi ja ogun rẹ, nípasẹ̀ ọ̀pọ̀ agbani-nímọ̀ràn, àṣeyọrí á wà.” (Òwe 24:6, àlàyé ìsàlẹ̀) Ẹ jẹ́ ká wo bí ìlànà Bíbélì yìí ṣe ń jẹ́ ká ṣàṣeyọrí lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù àti kíkọ́ni tá à ń ṣe. Dípò ká máa ṣiṣẹ́ ìwàásù àti kíkọ́ni lọ́nà tó wù wá, à ń tẹ̀ lé àbá tí ètò Ọlọ́run ń fún wa. À ń rí ìtọ́sọ́nà ọlọgbọ́n gbà láwọn ìpàdé wa. Torí pé ibẹ̀ ni àwọn tó ní ìrírí ti máa ń sọ àsọyé tó dá lórí Bíbélì, a sì tún máa ń gbádùn àṣefihàn tó ń dá wa lẹ́kọ̀ọ́. Yàtọ̀ síyẹn, ètò Ọlọ́run máa ń ṣe àwọn ìwé àtàwọn fídíò tó wúlò láti fi kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ kí wọ́n lè mọ òtítọ́ Bíbélì. Ṣé ìwọ náà máa ń lo àwọn ìwé àtàwọn fídíò yìí bó ṣe yẹ?

19. Báwo ni ìmọ̀ràn ọlọgbọ́n tí Jèhófà fún wa ṣe rí lára ẹ? (Òwe 3:13-18)

19 Ka Òwe 3:13-18. A mà dúpẹ́ o pé àwọn ìmọ̀ràn tó ń ṣe wá láǹfààní wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run! Báwo layé wa ò bá ṣe rí ká sọ pé àwọn ìmọ̀ràn yìí ò sí nínú Bíbélì? Nínú àpilẹ̀kọ yìí a ti gbé àwọn àpẹẹrẹ kan yẹ̀ wò tó jẹ́ ká mọ bí ọ̀rọ̀ ọlọgbọ́n tó wà nínú ìwé Òwe ṣe lè ṣe wá láǹfààní. Ká sòótọ́, kò síbi tá a kà nínú Bíbélì tá ò ní rí ọ̀rọ̀ ọlọgbọ́n tí Jèhófà fún wa. Torí náà, ẹ jẹ́ ká pinnu pé jálẹ̀ ìgbésí ayé wa làá máa lo ọgbọ́n tí Jèhófà fún wa. Lónìí ọ̀pọ̀ èèyàn ni ò mọyì ọgbọ́n Ọlọ́run, àmọ́ ó dá àwa Kristẹni tòótọ́ lójú pé tá a bá ‘di ọgbọ́n Ọlọ́run mú ṣinṣin, àá máa láyọ̀.’

ORIN 36 À Ń Dáàbò Bo Ọkàn Wa

^ Ọgbọ́n tí Jèhófà máa ń fún wa ju ohunkóhun tí ayé yìí lè fún wa lọ. Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa sọ̀rọ̀ nípa àpèjúwe kan nínú ìwé Òwe tó dá lórí ọgbọ́n tòótọ́ tó ń ké jáde ní ojúde ìlú. Torí náà, a máa mọ bá a ṣe lè ní ọgbọ́n tòótọ́, ìdí táwọn kan fi kọ etí dídi sí ọgbọ́n tòótọ́ àti àǹfààní tá a máa rí tá a bá ní ọgbọ́n tòótọ́.