Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 41

O Lè Ní Ayọ̀ Tòótọ́

O Lè Ní Ayọ̀ Tòótọ́

“Aláyọ̀ ni gbogbo ẹni tó bẹ̀rù Jèhófà, tó ń rìn ní àwọn ọ̀nà Rẹ̀.”—SM. 128:1.

ORIN 110 “Ìdùnnú Jèhófà”

OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒ *

1. Tá a bá ń wá “ìtọ́sọ́nà Ọlọ́run,” báwo nìyẹn ṣe máa jẹ́ ká ní ayọ̀ tòótọ́?

 Ọ̀PỌ̀ nǹkan ló ń fún àwọn èèyàn láyọ̀ lónìí, àmọ́ ayọ̀ náà kì í tọ́jọ́. Ayọ̀ tòótọ́ máa ń wà pẹ́ títí ni. Kí nìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀? Nígbà tí Jésù ń sọ̀rọ̀ nínú Ìwàásù orí Òkè, ó sọ pé: “Aláyọ̀ ni àwọn tó ń wá ìtọ́sọ́nà Ọlọ́run.” (Mát. 5:3) Jésù mọ̀ pé ìdí tí Jèhófà fi dá wa ni pé ká lè mọ Jèhófà, ká sì máa jọ́sìn ẹ̀. Ohun tí Ọlọ́run fẹ́ ká máa ṣe gan-an nìyẹn. Torí pé “Ọlọ́run aláyọ̀” ni Jèhófà, àwọn tó ń jọ́sìn ẹ̀ náà gbọ́dọ̀ máa láyọ̀.​—1 Tím. 1:11.

“Aláyọ̀ ni àwọn tí wọ́n ṣe inúnibíni sí nítorí òdodo.”​—Mát. 5:10 (Wo ìpínrọ̀ 2-3) *

2-3. (a) Àwọn wo ni Jésù tún sọ pé wọ́n lè láyọ̀? (b) Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí, kí sì nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká ṣe bẹ́ẹ̀?

2 Ṣé ó dìgbà tí gbogbo nǹkan bá ń lọ dáadáa fún wa ká tó lè láyọ̀? Rárá o. Nínú Ìwàásù orí Òkè, Jésù sọ nǹkan kan tó yani lẹ́nu, ó ní. “Àwọn tó ń ṣọ̀fọ̀” náà lè láyọ̀, ìyẹn àwọn tó kábàámọ̀ ẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n dá tàbí àwọn tí ìdààmú bá. Jésù tún sọ pé “àwọn tí wọ́n ṣe inúnibíni sí nítorí òdodo” tàbí àwọn tí wọ́n ń “pẹ̀gàn” wọn torí pé wọ́n jẹ́ ọmọlẹ́yìn Kristi náà lè láyọ̀. (Mát. 5:4, 10, 11) Àmọ́ kí ló máa jẹ́ ká ṣì láyọ̀ tá a bá bá ara wa nírú àwọn ipò yìí?

3 Ohun tí Jésù ń kọ́ wa ni pé kò dìgbà tí nǹkan bá ń lọ dáadáa fún wa ká tó lè láyọ̀, àmọ́ ohun tó máa jẹ́ ká láyọ̀ tòótọ́ ni pé ká sún mọ́ Ọlọ́run, ká sì máa wá ìtọ́sọ́nà ẹ̀. (Jém. 4:8) Báwo la ṣe lè ṣe é? Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa sọ̀rọ̀ nípa nǹkan mẹ́ta tó yẹ ká máa ṣe ká lè ní ayọ̀ tòótọ́.

MÁA KA BÍBÉLÌ DÉÉDÉÉ, KÓ O SÌ MÁA KẸ́KỌ̀Ọ́ Ẹ̀

4. Kí ló yẹ ká kọ́kọ́ ṣe tá a bá fẹ́ láyọ̀ tòótọ́? (Sáàmù 1:1-3)

4 ÀKỌ́KỌ́: Tá a bá fẹ́ láyọ̀ tòótọ́, a gbọ́dọ̀ máa kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run déédéé. Àwa èèyàn àti ẹranko nílò oúnjẹ ká má bàa kú, àmọ́ àwa èèyàn nìkan la lè kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Ohun tó sì yẹ ká máa ṣe nìyẹn. Ìdí nìyẹn tí Jésù fi sọ pé: “Kì í ṣe oúnjẹ nìkan ṣoṣo ló ń mú kí èèyàn wà láàyè, àmọ́ gbogbo ọ̀rọ̀ tó ń ti ẹnu Jèhófà jáde ni èèyàn fi ń wà láàyè.” (Mát. 4:4) Torí náà, kò yẹ ká jẹ́ kí ọjọ́ kan kọjá láì ka Bíbélì Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Onísáàmù kan sọ pé: ‘Aláyọ̀ ni ẹni tí òfin Jèhófà máa ń mú inú rẹ̀ dùn, tó sì máa ń ka òfin Rẹ̀ tọ̀sántòru.’​—Ka Sáàmù 1:1-3.

5-6. (a) Àwọn nǹkan wo ni Bíbélì jẹ́ ká mọ̀? (b) Báwo ni Bíbélì kíkà ṣe lè ràn wá lọ́wọ́?

5 Torí pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa, ó ti sọ àwọn nǹkan tó máa jẹ́ ká láyọ̀ fún wa nínú Bíbélì. Ó sọ ìdí tó fi dá wa. Ó tún sọ bá a ṣe lè sún mọ́ òun àti bá a ṣe lè rí ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ wa gbà. Kódà, ó jẹ́ ká mọ àwọn ohun rere tó máa ṣe fún wa lọ́jọ́ iwájú. (Jer. 29:11) Àwọn nǹkan tí Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ yìí ń fún wa láyọ̀, ó sì jẹ́ ká mọ̀ pé ọ̀la ń bọ̀ wá dáa!

6 Bíbélì tún fún wa láwọn ìmọ̀ràn tó dáa tá a lè máa tẹ̀ lé nígbèésí ayé wa. Tá a bá ń tẹ̀ lé àwọn ìmọ̀ràn yẹn, a máa láyọ̀. Ìgbàkigbà tí ìṣòro bá ń kó ẹ lọ́kàn sókè, ṣe ni kó o tẹra mọ́ Bíbélì kíkà, kó o sì máa ronú lórí ohun tó o kà. Jésù sọ pé: “Aláyọ̀ ni àwọn tó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, tí wọ́n sì ń pa á mọ́!”​—Lúùkù 11:28.

7. Kí ló máa jẹ́ kó o túbọ̀ jàǹfààní nígbà tó o bá ń ka Bíbélì?

7 Tó o bá ń ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, rí i pé o fara balẹ̀, kó o lè gbádùn ohun tó ò ń kà. Bí àpẹẹrẹ, ká sọ pé ẹnì kan se oúnjẹ tó o fẹ́ràn gan-an, àmọ́ torí pé ò ń kánjú tàbí torí pé ibòmíì lọkàn ẹ wà, ṣe lo kàn sáré kó oúnjẹ náà mì. Àmọ́ lẹ́yìn tó o parí oúnjẹ náà, ó wá ń ṣe ẹ́ bíi pé o ò bá ti fara balẹ̀ jẹ ẹ́ kó o lè gbádùn ẹ̀. Ṣé irú ẹ̀ ti ṣẹlẹ̀ sí ẹ rí? Wá bi ara ẹ pé, ṣé ìgbà kan wà tó o sáré ka Bíbélì, dípò kó o fara balẹ̀ ronú nípa ohun tó o kà kó o lè gbádùn ẹ̀? Torí náà, máa fara balẹ̀ ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, fojú inú wo ohun tó ń ṣẹlẹ̀ níbẹ̀, wò ó bíi pé ò ń gbọ́ àwọn ìró tó ń jáde níbẹ̀, kó o sì ronú lórí ohun tó o kà. Tó o bá ń ka Bíbélì bẹ́ẹ̀, wàá túbọ̀ láyọ̀.

8. Kí ni “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” ń pèsè fún wa? (Tún wo àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé.)

8 Jésù yan “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” kó lè máa fi Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run bọ́ wa dáadáa lákòókò tó yẹ. * (Mát. 24:45) Ẹrú olóòótọ́ máa ń rí i dájú pé gbogbo ìwé àti fídíò tí wọ́n ń ṣe dá lórí Bíbélì. (1 Tẹs. 2:13) Àwọn nǹkan yẹn ló ń jẹ́ ká mọ èrò Jèhófà bó ṣe wà nínú Bíbélì. Ìdí nìyẹn tá a fi máa ń ka ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! àtàwọn àpilẹ̀kọ míì tó wà lórí ìkànnì jw.org. Yàtọ̀ síyẹn, a tún máa ń múra àwọn ìpàdé àárín ọ̀sẹ̀ àti ti òpin ọ̀sẹ̀ sílẹ̀, a sì máa ń wo ètò oṣooṣù JW Broadcasting®. Tá a bá ń ka Bíbélì, tá a sì ń kẹ́kọ̀ọ́ ẹ̀ déédéé, ó máa rọrùn fún wa láti ṣe nǹkan kejì tó máa jẹ́ ká láyọ̀.

MÁA TẸ̀ LÉ ÀWỌN ÌLÀNÀ JÈHÓFÀ

9. Nǹkan kejì wo ló yẹ ká ṣe táá mú ká ní ayọ̀ tòótọ́?

9 ÌKEJÌ: Tá a bá fẹ́ ní ayọ̀ tòótọ́, a gbọ́dọ̀ máa tẹ̀ lé àwọn ìlànà Jèhófà. Onísáàmù kan sọ pé: “Aláyọ̀ ni gbogbo ẹni tó bẹ̀rù Jèhófà, tó ń rìn ní àwọn ọ̀nà Rẹ̀.” (Sm. 128:1) Tẹ́nì kan bá bẹ̀rù Jèhófà, ẹni náà á máa bọ̀wọ̀ fún un, kò sì ní ṣe ohun tó máa bà á nínú jẹ́. (Òwe 16:6) Torí náà, ó yẹ ká máa tẹ̀ lé àwọn ìlànà Ọlọ́run tó bá dọ̀rọ̀ ohun tó tọ́ àtohun tí kò tọ́ tí Bíbélì sọ. (2 Kọ́r. 7:1) A máa láyọ̀ tá a bá ń ṣe ohun tí Jèhófà fẹ́, tá a sì kórìíra ohun tó kórìíra.​—Sm. 37:27; 97:10; Róòmù 12:9.

10. Kí ni Róòmù 12:2 sọ pé ká máa ṣe?

10 Ka Róòmù 12:2. Ẹnì kan lè mọ̀ pé Jèhófà lẹ́tọ̀ọ́ láti fún wa ní ìlànà nípa ohun tó tọ́ àtohun tí kò tọ́, àmọ́ ẹni náà tún gbọ́dọ̀ máa tẹ̀ lé ìlànà Ọlọ́run. Bí àpẹẹrẹ, ẹnì kan lè mọ òfin tí ìjọba ṣe nípa bó ṣe yẹ kéèyàn fi mọ́tò ẹ̀ sáré tó lójú pópó, àmọ́ ó lè má fẹ̀ tẹ̀ lé òfin yẹn, kó wá máa sáré àsápajúdé. Lọ́nà kan náà, ìwà tá a bá ń hù ló máa fi hàn pé a gbà lóòótọ́ pé àwọn ìlànà Jèhófà máa ṣe wá láǹfààní. (Òwe 12:28) Èrò tí Dáfídì náà ní nìyẹn torí ó sọ nípa Jèhófà pé: “O jẹ́ kí n mọ ọ̀nà ìyè. Ayọ̀ púpọ̀ wà ní iwájú rẹ, ìdùnnú sì wà ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ títí láé.”​—Sm. 16:11.

11-12. (a) Tí ohun kan bá ń kó wa lọ́kàn sókè tàbí tá a rẹ̀wẹ̀sì, kí ni ò yẹ ká ṣe? (b) Báwo lohun tó wà nínú Fílípì 4:8 ṣe lè jẹ́ ká yan eré ìnàjú tó dáa?

11 Tí ohun kan bá ń kó wa lọ́kàn sókè tàbí tá a rẹ̀wẹ̀sì, ó máa ń wù wá ká ṣe ohun tá a máa fi pàrònú rẹ́. Bó ṣe yẹ kó rí nìyẹn, àmọ́ a gbọ́dọ̀ ṣọ́ra, kó má lọ jẹ́ ohun tínú Jèhófà ò dùn sí la máa fi pàrònú rẹ́.​—Éfé. 5:10-12, 15-17.

12 Nínú lẹ́tà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ sáwọn Kristẹni tó wà ní Fílípì, ó rọ̀ wọ́n pé kí wọ́n máa ronú nípa ohunkóhun tó jẹ́ ‘òdodo, tó jẹ́ mímọ́, tó yẹ ní fífẹ́ àti ohunkóhun tó bá dára.’ (Ka Fílípì 4:8.) Bó tiẹ̀ jẹ́ pé eré ìnàjú kọ́ ni Pọ́ọ̀lù ń sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀, ohun tó sọ lè ràn wá lọ́wọ́ láti yan eré ìnàjú tó dáa. Tó o bá ń ka ẹsẹ yìí, gbìyànjú kó o ṣe nǹkan yìí: Ibi tó o bá ti rí ọ̀rọ̀ náà “ohunkóhun,” fi “orin,” “fíìmù,” “ìwé” tàbí “géèmù orí kọ̀ǹpútà” rọ́pò ẹ̀. Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, á jẹ́ kó o lè mọ eré ìnàjú tí Ọlọ́run fẹ́ àtèyí tí kò fẹ́. Àwọn ìlànà gíga Jèhófà la fẹ́ máa tẹ̀ lé nígbèésí ayé wa. (Sm. 119:1-3) Tá a bá ń tẹ̀ lé àwọn ìlànà gíga yẹn, a máa ní ẹ̀rí ọkàn tó mọ́, ìyẹn á jẹ́ ká lè ṣe ohun kẹta tó máa jẹ́ ká ní ayọ̀ tòótọ́.​—Ìṣe 23:1.

ÌJỌSÌN JÈHÓFÀ NI KÓ O FI SÍPÒ ÀKỌ́KỌ́

13. Nǹkan kẹta wo ló yẹ ká ṣe táá mú ká ní ayọ̀ tòótọ́? (Jòhánù 4:23, 24)

13 ÌKẸTA: Rí i dájú pé o fi ìjọsìn Jèhófà sípò àkọ́kọ́. Torí pé Jèhófà ló dá wa, òun ló yẹ ká máa jọ́sìn. (Ìfi. 4:11; 14:6, 7) Torí náà, ohun tó yẹ kó ṣe pàtàkì jù sí wa ni bá a ṣe máa jọ́sìn Jèhófà lọ́nà tó tẹ́wọ́ gbà, ìyẹn “ní ẹ̀mí àti òtítọ́.” (Ka Jòhánù 4:23, 24.) Ká lè máa jọ́sìn Jèhófà lọ́nà tó fẹ́ bó ṣe wà nínú Ìwé Mímọ́, a gbọ́dọ̀ jẹ́ kí ẹ̀mí mímọ́ ẹ̀ máa tọ́ wa sọ́nà. Kódà tó bá jẹ́ orílẹ̀-èdè tí wọ́n ti dí iṣẹ́ wa lọ́wọ́ tàbí fòfin de iṣẹ́ wa là ń gbé, ìjọsìn Jèhófà la gbọ́dọ̀ fi sípò àkọ́kọ́. Ní bá a ṣe ń sọ̀rọ̀ yìí, àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa tó ju ọgọ́rùn-ún (100) lọ ló wà lẹ́wọ̀n torí pé wọ́n jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà. * Síbẹ̀, wọ́n ń láyọ̀, wọ́n sì ń ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe láti máa gbàdúrà, láti máa dá kẹ́kọ̀ọ́, wọ́n sì ń wàásù nípa Ọlọ́run àti Ìjọba ẹ̀ fáwọn èèyàn. Táwọn èèyàn bá ń pẹ̀gàn wa tí wọ́n sì ń ṣe inúnibíni sí wa, inú wa máa ń dùn torí a mọ̀ pé Jèhófà wà pẹ̀lú wa àti pé ó máa san wá lérè.​—Jém. 1:12; 1 Pét. 4:14.

ÀPẸẸRẸ ARÁKÙNRIN KAN

14. Kí ló ṣẹlẹ̀ sí arákùnrin ọ̀dọ́ kan lórílẹ̀-èdè Tajikistan, kí sì nìdí?

14 Àwọn nǹkan tó ṣẹlẹ̀ sáwọn ará wa ti jẹ́ ká rí i pé nǹkan mẹ́ta tá a ti gbé yẹ̀ wò yìí máa ń jẹ́ ká ní ayọ̀ tòótọ́, láìka ìṣòro tá a ní sí. Ẹ jẹ́ ká wo ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Arákùnrin Jovidon Bobojonov torí pé ó kọ̀ láti wọṣẹ́ ológun. Ọmọ ọdún mọ́kàndínlógún (19) ni, orílẹ̀-èdè Tajikistan ló sì ti wá. Ní October 4, 2019, wọ́n fipá mú un kúrò nílé ẹ̀, ọ̀pọ̀ oṣù ló fi wà látìmọ́lé, wọ́n sì fìyà jẹ ẹ́ bíi pé ọ̀daràn ni. Àwọn oníròyìn gbé ìròyìn náà títí kan àwọn oníròyìn láti orílẹ̀-èdè míì, wọ́n ròyìn ìwà ìkà tí wọ́n hù sí arákùnrin wa yìí. Àwọn oníròyìn náà sọ pé wọ́n nà án kó lè tọwọ́ bọ̀wé pé òun máa ṣiṣẹ́ ológun, kódà wọ́n fẹ́ fipá mú kó wọṣọ ológun. Nígbà tó yá, wọ́n dá a lẹ́bi, wọ́n sì jù ú sẹ́wọ̀n níbi tó ti ń ṣiṣẹ́ àṣekára títí dìgbà tí ààrẹ orílẹ̀-èdè náà fi fagi lé ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn án, ó sì ní kí wọ́n dá a sílẹ̀. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé wọ́n fojú Jovidon rí màbo, kò rẹ̀wẹ̀sì, ó jẹ́ olóòótọ́, ó sì ń láyọ̀. Kí ló ràn án lọ́wọ́? Ohun tó ràn án lọ́wọ́ ni pé gbogbo àkókò yẹn ló fi ń ṣe ohun tó jẹ́ kí àjọṣe ẹ̀ pẹ̀lú Jèhófà dáa sí i.

Jovidon máa ń kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run déédéé, ó ń tẹ̀ lé àwọn ìlànà Ọlọ́run, ó sì fi ìjọsìn Jèhófà sípò àkọ́kọ́ (Wo ìpínrọ̀ 15-17)

15. Báwo ni Jovidon ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run nígbà tó wà lẹ́wọ̀n?

15 Nígbà tí Jovidon wà lẹ́wọ̀n, ó ṣì ń kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, bó tiẹ̀ jẹ́ pé kò ní Bíbélì àtàwọn ìwé ètò Ọlọ́run. Báwo ló ṣe ṣe é? Àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin tó máa ń gbé oúnjẹ wá fún un máa ń kọ ọ̀rọ̀ ẹsẹ ojúmọ́ kọ̀ọ̀kan sára báàgì tí wọ́n fi ń gbé oúnjẹ wá fún un. Ìyẹn jẹ́ kó lè máa ka Bíbélì lójoojúmọ́, kó sì máa ṣàṣàrò lórí ẹ̀. Lẹ́yìn tí wọ́n dá a sílẹ̀ lẹ́wọ̀n, ó gba àwọn tí ò tíì dojú kọ àdánwò tó le gan-an nímọ̀ràn pé: “Ó ṣe pàtàkì pé ká lo àǹfààní tá a ní báyìí tí ò tíì sí ohun tó ń dí wa lọ́wọ́ láti máa ka Bíbélì àtàwọn ìwé ètò Ọlọ́run, ká lè túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà.”

16. Kí ni Jovidon gbájú mọ́ nígbà tó wà lẹ́wọ̀n?

16 Arákùnrin Jovidon tẹ̀ lé ìlànà Jèhófà. Dípò kó máa ro èròkerò tàbí kó máa hùwà burúkú lọ́gbà ẹ̀wọ̀n, ohun tó gbájú mọ́ ni bó ṣe máa ṣe ohun táá múnú Jèhófà dùn. Gbogbo ìgbà ni Jovidon máa ń ronú nípa bí àwọn nǹkan tí Jèhófà dá ṣe rẹwà tó. Tó bá jí láàárọ̀, ó máa ń gbọ́ ohùn àwọn ẹyẹ àti orin aládùn tí wọ́n ń kọ. Tó bá di alẹ́, ó máa ń wo òṣùpá àtàwọn ìràwọ̀. Ó sọ pé: “Àwọn nǹkan tí Jèhófà dá yìí máa ń fún mi láyọ̀, ó sì máa ń mórí mi yá gágá.” Tá a bá mọyì Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àtàwọn nǹkan tó dá, àá máa láyọ̀, ìyẹn á sì jẹ́ ká lè máa fara dà á nìṣó.

17. Báwo ni 1 Pétérù 1:6, 7 ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ tá a bá bá ara wa ní ipò tó jọ ti Jovidon?

17 Arákùnrin Jovidon fi ìjọsìn Jèhófà sípò àkọ́kọ́. Ó mọ̀ pé ó ṣe pàtàkì kóun jẹ́ olóòótọ́ sí Ọlọ́run. Jésù sọ pé: “Jèhófà Ọlọ́run rẹ ni o gbọ́dọ̀ jọ́sìn, òun nìkan ṣoṣo sì ni o gbọ́dọ̀ ṣe iṣẹ́ ìsìn mímọ́ fún.” (Lúùkù 4:8) Àwọn ọ̀gá ológun àtàwọn sójà ò fẹ́ kí Jovidon sin Jèhófà mọ́. Àmọ́, ojoojúmọ́ àti ní alaalẹ́ ni Jovidon máa ń gbàdúrà tọkàntọkàn pé kí Jèhófà ran òun lọ́wọ́ kóun lè jẹ́ olóòótọ́. Ìwà ìkà tí wọ́n hù sí Jovidon pọ̀ gan-an, síbẹ̀ ó jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé wọ́n fipá mú Arákùnrin Jovidon kúrò nílé ẹ̀, tí wọ́n nà án, tí wọ́n sì jù ú sẹ́wọ̀n, inú ẹ̀ ń dùn torí àwọn nǹkan yẹn ti dán ìgbàgbọ́ ẹ̀ wò, ó sì kógo já.​—Ka 1 Pétérù 1:6, 7.

18. Kí lá jẹ́ ká máa láyọ̀ nìṣó?

18 Jèhófà ti jẹ́ ká mọ àwọn nǹkan tó máa jẹ́ ká ní ayọ̀ tòótọ́. Tó o bá ń ṣe àwọn nǹkan mẹ́ta tó máa jẹ́ kó o láyọ̀ tòótọ́ bá a ṣe sọ nínú àpilẹ̀kọ yìí, wàá máa láyọ̀ bó o tiẹ̀ ń dojú kọ àwọn ìṣòro tó le. Ìwọ náà á lè sọ bíi ti onísáàmù pé: “Aláyọ̀ ni àwọn tí Jèhófà jẹ́ Ọlọ́run wọn!”​—Sm. 144:15.

ORIN 89 Gbọ́, Ṣègbọràn, Kó O sì Gba Ìbùkún

^ Ó ṣòro fún ọ̀pọ̀ èèyàn láti ní ayọ̀ tòótọ́ torí ohun tó ń fúnni láyọ̀ tòótọ́ kọ́ ni wọ́n ń fayé wọn ṣe. Wọ́n ń lépa ìgbádùn, ọrọ̀, òkìkí àti bí wọ́n ṣe máa di alágbára. Àmọ́ nígbà tí Jésù wà láyé, ó sọ bí àwọn èèyàn ṣe lè ní ayọ̀ tòótọ́. Torí náà nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa sọ̀rọ̀ nípa nǹkan mẹ́ta táá jẹ́ ká ní ayọ̀ tòótọ́.

^ Wo àpilẹ̀kọ náà, “Ṣé Ò Ń Rí Oúnjẹ Gbà ‘Ní Àkókò Tí Ó Bẹ́tọ̀ọ́ Mu’?” nínú Ilé Ìṣọ́ August 15, 2014.

^ Kó o lè mọ púpọ̀ sí i, wo àpilẹ̀kọ náà “Wọ́n Fi Wọ́n Sẹ́wọ̀n Torí Ohun Tí Wọ́n Gbà Gbọ́” lórí ìkànnì jw.org.

^ ÀWÒRÁN: Àwòrán yìí ń sọ nípa ìgbà tí wọ́n fàṣẹ ọba mú arákùnrin kan, tí wọ́n gbé e lọ sílé ẹjọ́ kí wọ́n lè fẹ̀sùn kàn án. Àmọ́ àwọn ará dúró tì í gbágbáágbá.