Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÌTÀN ÌGBÉSÍ AYÉ

Inú Mi Dùn Pé Mo Bá Àwọn Tó Nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ṣiṣẹ́

Inú Mi Dùn Pé Mo Bá Àwọn Tó Nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ṣiṣẹ́

ỌMỌ orílẹ̀-èdè Scotland làwọn òbí mi, ìyẹn James àti Jessie Sinclair. Láwọn ọdún 1930, wọ́n kó wá sí ìlú Bronx, ní New York City. Ọdún mélòó kan lẹ́yìn náà ni wọ́n bí mi. Lára àwọn tí wọ́n kọ́kọ́ pàdé nígbà tí wọ́n dé ìlú Bronx ni Willie Sneddon tóun náà wá láti Scotland. Láàárín ìṣẹ́jú mélòó kan tí wọ́n pàdé, àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta ti dọ̀rẹ́, wọ́n sì jọ ń sọ̀rọ̀ nípa ara wọn àti ìdílé wọn.

Màámi sọ fún Willie pé kí Ogun Àgbáyé Kìíní tó bẹ̀rẹ̀, bàbá òun àti ẹ̀gbọ́n òun ọkùnrin kú sómi nígbà tí ọkọ̀ ojú omi tí wọ́n fi ń pẹja kọlu bọ́ǹbù kan tó wà nísàlẹ̀ òkun North Sea. Ni Willie tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà bá sọ pé, “Bàbá rẹ ń bẹ ní hẹ́ẹ̀lì!” Ọ̀rọ̀ yẹn ká màámi lára, àmọ́ òótọ́ Bíbélì tí wọ́n kọ́kọ́ gbọ́ nìyẹn.

Willie àti Liz Sneddon

Ohun tí Willie sọ bí màámi nínú gan-an torí wọ́n gbà pé èèyàn dáadáa ni bàbá àwọn. Willie wá sọ pé, “Ṣé inú yín máa dùn tí mo bá sọ fún yín pé Jésù náà lọ sí hẹ́ẹ̀lì?” Ohun tó sọ yìí mú kí màámi rántí ẹ̀kọ́ ṣọ́ọ̀ṣì kan tó sọ pé Jésù lọ sí hẹ́ẹ̀lì, Ọlọ́run sì gbé e dìde ní ọjọ́ kẹta. Màámi wá ronú pé, ‘Tó bá jẹ́ pé ibi tí wọ́n ti ń finá dá àwọn èèyàn burúkú lóró ni hẹ́ẹ̀lì, kí nìdí tí Jésù fi lọ síbẹ̀?’ Èyí ló mú kí màámi bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í lọ sípàdé, wọ́n sì ń dara pọ̀ mọ́ Ìjọ Bronx. Nígbà tó dọdún 1940, wọ́n ṣèrìbọmi.

Èmi àti màámi rèé, èmi àti bàbá mi la wà nísàlẹ̀

Nígbà yẹn, wọn kì í sábà sọ fáwọn òbí Kristẹni pé kí wọ́n kọ́ àwọn ọmọ wọn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ìgbà tí mo ṣì kéré, bàbá mi ló máa ń tọ́jú mi tí màámi bá lọ sípàdé tàbí tí wọ́n bá lọ sóde ẹ̀rí lópin ọ̀sẹ̀. Lẹ́yìn ọdún díẹ̀, èmi àti bàbá mi náà bẹ̀rẹ̀ sí í lọ sípàdé. Màámi nítara gan-an, wọ́n sì ń darí ọ̀pọ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ìgbà kan tiẹ̀ wà tí wọ́n máa ń pe àwọn ìkẹ́kọ̀ọ́ wọn tí kò jìnnà síra, wọ́n á kó wọn jọ, wọ́n á sì kọ́ wọn pa pọ̀. Tí n bá wà ní ọlidé, mo máa ń tẹ̀ lé wọn lọ sóde ẹ̀rí. Èyí mú kí n mọ Bíbélì gan-an, mo sì mọ bí mo ṣe lè fi kọ́ àwọn míì.

Kí n má parọ́, mi ò fọwọ́ pàtàkì mú ẹ̀kọ́ òtítọ́ nígbà tí mo wà ní kékeré. Àmọ́ nígbà tí mo pé nǹkan bí ọmọ ọdún méjìlá [12], mo di akéde Ìjọba Ọlọ́run, àtìgbà yẹn ni mo sì ti ń lọ sóde ẹ̀rí déédéé. Nígbà tí mo pé ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógún [16], mo ya ara mi sí mímọ́ fún Jèhófà, mo sì ṣèrìbọmi ní July 24, 1954 ní àpéjọ àgbègbè kan nílùú Toronto, lórílẹ̀-èdè Kánádà.

IṢẸ́ ÌSÌN BẸ́TẸ́LÌ

Ní ìjọ tí mo wà, àwọn ará kan wà níbẹ̀ tó ń sìn ní Bẹ́tẹ́lì, àwọn míì sì ti sìn rí ní Bẹ́tẹ́lì. Mo kẹ́kọ̀ọ́ gan-an lára wọn. Bí wọ́n ṣe máa ń sọ àsọyé, tí wọ́n sì máa ń ṣàlàyé àwọn òtítọ́ Bíbélì máa ń wú mi lórí gan-an. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé yunifásítì làwọn olùkọ́ mi níléèwé fẹ́ kí n lọ, Bẹ́tẹ́lì ni mo pinnu pé màá lọ. Torí náà, mo gba fọ́ọ̀mù Bẹ́tẹ́lì ní àpéjọ yẹn. Nígbà tó tún dọdún 1955, mo tún gba fọ́ọ̀mù Bẹ́tẹ́lì ní àpéjọ tá a ṣe ní pápá ìṣeré Yankee, ní New York City. Kò pẹ́ sígbà yẹn ni wọ́n pè mí sí Bẹ́tẹ́lì tó wà ní Brooklyn ní September 19, 1955. Ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógún [17] ni mí nígbà yẹn. Lọ́jọ́ kejì tí mo dé Bẹ́tẹ́lì, wọ́n ní kí n máa ṣiṣẹ́ ní ibi tí wọ́n ti ń di ìwé pọ̀ ní 117 Adams Street. Lẹ́yìn ìyẹn, mo bẹ̀rẹ̀ sí í ṣiṣẹ́ nídìí maṣíìnì tó máa ń to ìwé pọ̀, táá sì tì í lọ sídìí maṣíìnì táá rán an pa pọ̀.

Mo bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìsìn ní Bẹ́tẹ́lì tó wà ní Brooklyn lọ́mọ ọdún mẹ́tàdínlógún [17]

Lẹ́yìn tí mo ti lo nǹkan bí oṣù kan níbi tí wọ́n ti ń dìwé pọ̀, wọ́n gbé mi lọ sí Ẹ̀ka Ìwé Ìròyìn. Ìdí sì ni pé nígbà yẹn, wọ́n máa ń tẹ àdírẹ́sì àwọn èèyàn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣe ẹ̀dáwó Ilé Ìṣọ́ àti Jí! sára àpò ìwé. Èmi sì rèé, mo mọ bí wọ́n ṣe ń tẹ̀wé. Ní oṣù díẹ̀ lẹ́yìn náà, wọ́n gbé mi lọ sí Ẹ̀ka Ìkówèéránṣẹ́. Arákùnrin Klaus Jensen tó jẹ́ alábòójútó ẹ̀ka náà sọ pé kí n ṣiṣẹ́ pẹ̀lú awakọ̀ tó ń kó ìwé lọ sí èbúté níbi tí wọ́n á ti fi ránṣẹ́ sáwọn orílẹ̀-èdè míì. Yàtọ̀ síyẹn, a tún máa ń kó àwọn ìwé ìròyìn lọ sí ilé ìfìwéránṣẹ́, kí wọ́n lè fi ránṣẹ́ sáwọn ìjọ tó wà káàkiri orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. Arákùnrin Jensen sọ fún mi pé irú iṣẹ́ yìí ló dáa fún mi, ìdí sì ni pé mo rí lẹ́gẹ́lẹ́gẹ́. Bá a ṣe ń kó àwọn ìwé lọ sí èbúté àti sílé ìfìwéránṣẹ́ yẹn sì jẹ́ kí n lágbára gan-an lóòótọ́. Ó dájú pé Arákùnrin Jensen náà ti ro ọ̀rọ̀ yẹn dáadáa kí wọ́n tó sọ fún mi.

Ẹ̀ka Ìwé Ìròyìn ló máa ń ṣiṣẹ́ lórí fọ́ọ̀mù táwọn ìjọ fi ń béèrè fún ìwé ìròyìn. Iṣẹ́ tí mò ń ṣe níbẹ̀ ló jẹ́ kí n mọ onírúurú èdè tá a fi ń tẹ àwọn ìwé ìròyìn wa ní Brooklyn. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé mi ò gbọ́ nípa ọ̀pọ̀ àwọn èdè yìí rí, inú mi dùn pé ẹgbẹẹgbẹ̀rún ìwé ìròyìn la fi ń ránṣẹ́ sáwọn orílẹ̀-èdè tó wà káàkiri ayé. Mi ò mọ̀ nígbà yẹn pé mo ṣì máa láǹfààní láti dé ọ̀pọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè yìí.

Èmi pẹ̀lú Robert Wallen, Charles Molohan, àti Don Adams

Lọ́dún 1961, wọ́n ní kí n máa ṣiṣẹ́ ní Ọ́fíìsì Akápò, Arákùnrin Grant Suiter sì ni alábòójútó ibẹ̀. Lẹ́yìn tí mo lo ọdún díẹ̀ níbẹ̀, Arákùnrin Nathan Knorr tó ń múpò iwájú lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù pè mí sí ọ́fíìsì rẹ̀. Ó sọ fún mi pé ọ̀kan lára àwọn arákùnrin tó ń ṣiṣẹ́ ní ọ́fíìsì òun ń lọ sí Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ fún oṣù kan, tó bá sì pa dà dé, Ẹ̀ka Iṣẹ́ Ìsìn láá ti máa ṣiṣẹ́. Torí náà, wọ́n ní kí n máa ṣe iṣẹ́ rẹ̀. Lára àwọn tá a jọ ń ṣiṣẹ́ ni Don Adams, mo rántí pé òun ni mo fún ní fọ́ọ̀mù Bẹ́tẹ́lì tí mo gbà ní àpéjọ ọdún 1955. Àwọn arákùnrin míì tá a jọ ṣiṣẹ́ ni Robert Wallen àti Charles Molohan. Àwa mẹ́rẹ̀ẹ̀rin sì jọ ṣiṣẹ́ pọ̀ fún ohun tó lé ní àádọ́ta [50] ọdún. Inú mi dùn pé àwọn arákùnrin tó nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run ni mo bá ṣiṣẹ́.​—Sm. 133:1.

Èmi rèé ní Fẹnẹsúélà lọ́dún 1970, ìgbà àkọ́kọ́ tí wọ́n rán mi lọ sí ẹ̀ka míì

Àtọdún 1970 ni wọ́n ti ní kí n máa ṣèbẹ̀wò sáwọn ẹ̀ka ọ́fíìsì tó wà láwọn orílẹ̀-èdè míì. Ìrìn àjò yìí máa ń gba ọ̀sẹ̀ mélòó kan, ó sì lè jẹ́ ẹ̀ẹ̀kan lọ́dún tàbí ẹ̀ẹ̀kan lọ́dún méjì ni mo máa ń lọ. Mo máa ń ṣàyẹ̀wò àwọn àkọsílẹ̀ wọn, mo sì máa ń fún àwọn tó ń sìn ní Bẹ́tẹ́lì àtàwọn míṣọ́nnárì níṣìírí. Inú mi máa ń dùn gan-an tí mo bá rí àwọn míṣọ́nnárì tí wọ́n kẹ́kọ̀ọ́ yege ní Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì nígbà tí ilé ẹ̀kọ́ náà ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀, síbẹ̀ tí wọ́n ṣì ń fòótọ́ sìn lórílẹ̀-èdè tí wọ́n rán wọn lọ. Mo láyọ̀ gan-an torí pé iṣẹ́ yìí ti fún mi láǹfààní láti ṣèbẹ̀wò sí orílẹ̀-èdè tó ju àádọ́rùn-ún [90] lọ.

Inú mi dùn pé mo ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ àwọn ará ní ohun tó lé ní 90 orílẹ̀-èdè!

MO RÍ AYA RERE

Àwọn ìjọ tó wà lágbègbè New York City ni wọ́n yan gbogbo àwa tá à ń sìn ní Bẹ́tẹ́lì sí. Àgbègbè Bronx ni ìjọ tí wọ́n yàn mí sí wà. Ìjọ tó kọ́kọ́ wà lágbègbè yẹn ti gbèrú gan-an, ó sì ti bí àwọn ìjọ míì. Upper Bronx ni orúkọ ìjọ yẹn báyìí, ìjọ yẹn sì ni mò ń dara pọ̀ mọ́.

Láwọn ọdún 1960, ìdílé kan tó wá láti orílẹ̀-èdè Latvia kó wá sí àgbègbè Bronx. Apá gúúsù àgbègbè Bronx ni wọ́n ti kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́. Livija ni ọmọ wọn obìnrin tó dàgbà jù, bó ṣe parí ilé ẹ̀kọ́ rẹ̀ ló bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà déédéé. Oṣù díẹ̀ lẹ́yìn náà, ó lọ sìn níbi tí àìní gbé pọ̀ ní ìpínlẹ̀ Massachusetts. Èmi àti ẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í kọ lẹ́tà síra wa, mo máa ń sọ bí nǹkan ṣe ń lọ níjọ wa, òun náà sì máa ń sọ bí iṣẹ́ náà ṣe ń tẹ̀ síwájú lágbègbè Boston.

Èmi àti Livija

Lẹ́yìn ọdún díẹ̀, Livija di aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe. Síbẹ̀, ó wù ú láti ṣe púpọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ Ọlọ́run, torí náà ó gba fọ́ọ̀mù Bẹ́tẹ́lì. Nígbà tó dọdún 1971, wọ́n pè é wá sí Bẹ́tẹ́lì. Ṣe ló ń ṣe mí bíi pé Jèhófà ń darí rẹ̀ sọ́dọ̀ mi. Torí náà, ní October 27, 1973, a ṣègbéyàwó, inú mi sì dùn pé Arákùnrin Knorr ló sọ àsọyé ìgbéyàwó wa. Òwe 18:22 sọ pé: “Ẹnì kan ha ti rí aya rere bí? Ẹni náà ti rí ohun rere, ẹni náà sì ti rí ìfẹ́ rere gbà láti ọ̀dọ̀ Jèhófà.” Àǹfààní gbáà ló jẹ́ pé èmi àti Livija ti jọ sìn ní Bẹ́tẹ́lì fún ohun tó lé lógójì [40] ọdún báyìí. A sì tún wà níjọ kan tó wà lágbègbè Bronx.

MO BÁ ÀWỌN ARÁKÙNRIN KRISTI ṢIṢẸ́

Inú mi dùn gan-an pé mo láǹfààní láti bá Arákùnrin Knorr ṣiṣẹ́. Arákùnrin Knorr máa ń ṣiṣẹ́ kára gan-an, ó sì mọyì àwọn míṣọ́nnárì tó ń sìn kárí ayé. Ọ̀pọ̀ àwọn míṣọ́nnárì yìí ni Ẹlẹ́rìí àkọ́kọ́ ní orílẹ̀-èdè tí wọ́n rán wọn lọ. Àmọ́ lọ́dún 1976, ó bani nínú jẹ́ pé àìsàn jẹjẹrẹ ṣe Arákùnrin Knorr. Nígbà tó wà ní ìdùbúlẹ̀ àìsàn, ó pè mí lọ́jọ́ kan, ó kó àwọn ìwé kan tí wọ́n máa tó tẹ̀ fún mi, ó sì ní kí n kà á sí òun létí. Ó tún ní kí n pe Arákùnrin Frederick Franz, kóun náà lè máa gbọ́ bí mo ṣe ń kà wọ́n. Ìgbà tó yá ni mo mọ̀ pé Arákùnrin Knorr ti máa ń ka àwọn ìwé tí wọ́n máa tẹ̀ jáde fún Arákùnrin Franz torí ojú rẹ̀ tó ti di bàìbàì.

Èmi àti Daniel pẹ̀lú Marina Sydlik rèé lọ́dún 1977 nígbà tá a lọ bẹ ẹ̀ka ọ́fíìsì kan wò

Arákùnrin Knorr kú lọ́dún 1977. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ikú rẹ̀ dùn wá, síbẹ̀ a láyọ̀ pé ó jẹ́ olóòótọ́ títí dójú ikú, ó sì ti gba èrè rẹ̀ lọ́run. (Ìṣí. 2:10) Lẹ́yìn náà, Arákùnrin Franz bẹ̀rẹ̀ sí í múpò iwájú.

Akọ̀wé Arákùnrin Milton Henschel ni mí nígbà yẹn, ọ̀pọ̀ ọdún lòun náà sì fi bá Arákùnrin Knorr ṣiṣẹ́. Arákùnrin Henschel sọ fún mi pé iṣẹ́ tó gbawájú fún mi báyìí ni pé kí n máa ran Arákùnrin Franz lọ́wọ́. Màá máa ka àwọn ìwé wa sí i létí kí wọ́n tó tẹ̀ wọ́n jáde. Arákùnrin Franz máa ń tètè rántí nǹkan, ó sì máa ń pọkàn pọ̀ sórí nǹkan téèyàn bá kà fún un. Inú mi dùn gan-an pé mo ràn án lọ́wọ́ títí tó fi kú ní December 1992!

124 Columbia Heights níbi tí mo ti ṣiṣẹ́ fún ọ̀pọ̀ ọdún

Ọdún mọ́kànlélọ́gọ́ta [61] rèé tí mo ti wà ní Bẹ́tẹ́lì, síbẹ̀ ṣe ló dà bí àná lójú mi. Àwọn òbí mi fòótọ́ sin Jèhófà títí wọ́n fi kú, mo sì ń fojú sọ́nà láti rí wọn nínú ayé tuntun. (Jòh. 5:28, 29) Kò sí ohun tí mo lè rí nínú ayé yìí tí mo lè fi wé àǹfààní tí mo ní láti ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwọn tó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà lọ́kùnrin àti lóbìnrin kárí ayé. Kò sígbà tí èmi àti Livija ronú nípa àwọn ọdún tá a ti wà lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún tí a kì í gbà pé “ìdùnnú Jèhófà ni odi agbára [wa].”​—Neh. 8:10.

Kò sẹ́ni tó lè sọ pé ọpẹ́lọpẹ́ òun ni ètò Jèhófà fi ń tẹ̀ síwájú, torí pé Jèhófà fúnra rẹ̀ ló ń mú kí iṣẹ́ náà máa tẹ̀ síwájú. Àǹfààní ńlá ni mo ní bí mo ṣe bá àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin olóòótọ́ ṣiṣẹ́ látọdún yìí wá. Ọ̀pọ̀ lára àwọn ẹni àmì òróró tá a jọ ṣiṣẹ́ kò sí láyé mọ́. Àmọ́, inú mi dùn pé mo bá irú àwọn olóòótọ́ bẹ́ẹ̀ ṣiṣẹ́ lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà.