Ǹjẹ́ O Mọ Ohun Tí Aago Sọ?
TÓ O bá fẹ́ mọ ohun tí aago sọ, kí ni wàá ṣe? Ó ṣeé ṣe kó o wojú aago ọwọ́ rẹ tàbí kó o wo aago míì tó o ní. Tí ọ̀rẹ́ rẹ kan bá bi ẹ́ pé aago mélòó ló lù, báwo lo ṣe máa dá a lóhùn? Òótọ́ ibẹ̀ ni pé onírúurú ọ̀nà lèèyàn lè gbà ṣàlàyé ohun tí aago sọ.
Lọ́pọ̀ ìgbà, ibi téèyàn bá gbé dàgbà ló máa ń pinnu bó ṣe máa ṣàlàyé ohun tí aago sọ. Bí àpẹẹrẹ, ká sọ pé wákàtí kan ààbọ̀ ti kọjá lẹ́yìn aago méjìlá ọ̀sán. O lè sọ pé aago kan ààbọ̀ (1:30) ti lù, tàbí kẹ̀, ó ṣeé ṣe kó o sọ pé aago kan kọjá ọgbọ̀n (30) ìṣẹ́jú. Láwọn ibòmíì sì rèé, wọ́n lè sọ pé aago méjì ku ọgbọ́n (30) ìṣẹ́jú.
Ó ṣeé ṣe kó o máa ronú pé, báwo ni wọ́n ṣe máa ń mọ ohun tí aago sọ láyé ìgbà tí wọ́n ń kọ Bíbélì? Onírúurú ọ̀nà ni wọ́n máa ń gbà ṣe bẹ́ẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù mẹ́nu kan “òwúrọ̀,” “ọ̀sán gangan,” “ọjọ́kanrí” àti “ìrọ̀lẹ́.” (Jẹ́n. 8:11; 19:27; 43:16; Diu. 28:29; 1 Ọba 18:26) Nígbà míì sì rèé, wọ́n máa ń sọ àkókò pàtó tí nǹkan kan ṣẹlẹ̀.
Láyé ìgbà yẹn, wọ́n máa ń gba àwọn olùṣọ́ láti ṣọ́ ibi kan pàápàá láti alẹ́ títí di ọjọ́ kejì. Ní ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún kí wọ́n tó bí Jésù, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pín àkókò tó wà láàárín alẹ́ títí di àárọ̀ ọjọ́ kejì sí ọ̀nà mẹ́ta. (Sm. 63:6) Bí àpẹẹrẹ, Àwọn Onídàájọ́ 7:19 mẹ́nu kan “ìṣọ́ àárín òru.” Nígbà tó fi máa dìgbà ayé Jésù, àwọn Júù ti pín àkókò ìṣọ́ òru yìí sí ọ̀nà mẹ́rin bíi tàwọn Gíríìkì àtàwọn ará Róòmù.
Ọ̀pọ̀ ìgbà làwọn ìwé Ìhìn Rere mẹ́nu kan àwọn àkókò ìṣọ́ yìí. Bí àpẹẹrẹ, “ìṣọ́ kẹrin òru” ni Jésù rìn lórí omi nígbà tó lọ síbi ọkọ̀ ojú omi táwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ wà. (Mát. 14:25) Nínú àpèjúwe kan, Jésù sọ pé: “Ká ní baálé ilé mọ ìṣọ́ tí olè ń bọ̀ ni, ì bá wà lójúfò, kì bá sì ti yọ̀ǹda kí a fọ́ ilé rẹ̀.”—Mát. 24:43.
Jésù mẹ́nu kan àwọn àkókò ìṣọ́ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin nígbà tó sọ fáwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé: “Ẹ máa bá a nìṣó ní ṣíṣọ́nà, nítorí ẹ kò mọ ìgbà tí ọ̀gá ilé náà ń bọ̀, yálà nígbà tí alẹ́ ti lẹ́ tàbí ní ọ̀gànjọ́ òru tàbí ìgbà kíkọ àkùkọ tàbí ní kùtùkùtù òwúrọ̀.” (Máàkù 13:35) Ìṣọ́ àkọ́kọ́ ni “alẹ́,” èyí sì bẹ̀rẹ̀ láti àsìkò tí oòrùn bá ti wọ̀ títí di nǹkan bí aago mẹ́sàn-án alẹ́. Ìṣọ́ kejì ni “ọ̀gànjọ́ òru” tó bẹ̀rẹ̀ láti nǹkan bí aago mẹ́sàn-án alẹ́ sí aago méjìlá òru. Ìṣọ́ kẹta tí Jésù pè ní “ìgbà kíkọ àkùkọ” bẹ̀rẹ̀ láti aago méjìlá òru títí di nǹkan bí aago mẹ́ta òru. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé àsìkò yìí ni àkùkọ kọ lálẹ́ ọjọ́ tí wọ́n mú Jésù. (Máàkù 14:72) Ìṣọ́ kẹrin ni “kùtùkùtù òwúrọ̀,” èyí sì bẹ̀rẹ̀ láti nǹkan bí aago mẹ́ta òru títí di ìgbà tí oòrùn bá yọ.
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn èèyàn láyé ìgbà yẹn ò ní onírúurú aago táwa ní lónìí, síbẹ̀ wọ́n ní ọ̀nà tí wọ́n fi ń mọ ohun tí àkókò jẹ́ yálà ní ọ̀sán tàbí lálẹ́.