Ẹ Máa Fìfẹ́ Gbé Àwọn Míì Ró
“Ìfẹ́ a máa gbéni ró.”—1 KỌ́R. 8:1.
1. Ọ̀rọ̀ pàtàkì wo ni Jésù bá àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ sọ lálẹ́ ọjọ́ tó lò kẹ́yìn?
LÁLẸ́ ọjọ́ tí Jésù lò kẹ́yìn pẹ̀lú àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ìgbà ọgbọ̀n (30) tí Jésù mẹ́nu kan ìfẹ́. Ó dìídì tẹnu mọ́ ọn fáwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé kí wọ́n “nífẹ̀ẹ́ ara [wọn] lẹ́nì kìíní-kejì.” (Jòh. 15:12, 17) Ìfẹ́ tó ṣàrà ọ̀tọ̀ yìí ló máa jẹ́ kó hàn kedere pé ọmọlẹ́yìn Jésù ni wọ́n. (Jòh. 13:34, 35) Ìfẹ́ tí Jésù ń sọ yìí kì í ṣe ìfẹ́ oréfèé lásán àmọ́ ó jẹ́ ìfẹ́ tó máa ń mú kéèyàn fara ẹ̀ jìn fáwọn míì. Abájọ tí Jésù fi sọ pé: “Kò sí ẹni tí ó ní ìfẹ́ tí ó tóbi ju èyí lọ, pé kí ẹnì kan fi ọkàn rẹ̀ lélẹ̀ nítorí àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀. Ọ̀rẹ́ mi ni yín, bí ẹ bá ń ṣe ohun tí mo ń pa láṣẹ fún yín.”—Jòh. 15:13, 14.
2. (a) Kí la fi ń dá àwa ìránṣẹ́ Ọlọ́run mọ̀ lónìí? (b) Àwọn ìbéèrè wo la máa dáhùn nínú àpilẹ̀kọ yìí?
2 Lónìí, ohun táwọn èèyàn fi ń dá àwa ìránṣẹ́ Jèhófà mọ̀ ni pé a nífẹ̀ẹ́ ara wa dénú, a wà níṣọ̀kan, a sì máa ń fi ara wa jìn fáwọn míì. (1 Jòh. 3:10, 11) Inú wa dùn gan-an pé láìka ẹ̀yà, àwọ̀, èdè àti ibi tá a ti wá sí, ìfẹ́ tòótọ́ làwa èèyàn Jèhófà ní sí ara wa. Àmọ́ a lè máa ronú pé: ‘Kí nìdí tó fi yẹ ká nífẹ̀ẹ́ ara wa gan-an nísinsìnyí ju ti ìgbàkígbà rí lọ? Báwo ni Jèhófà àti Jésù ṣe ń fìfẹ́ gbé wa ró? Báwo lẹnì kọ̀ọ̀kan wa ṣe lè fìfẹ́ hàn sáwọn ará wa, ká sì gbé wọn ró?’—1 Kọ́r. 8:1.
ÌDÍ TÍ ÌFẸ́ FI ṢE PÀTÀKÌ NÍSINSÌNYÍ JU TI ÌGBÀKÍGBÀ RÍ LỌ
3. Kí ni wàhálà tá à ń bá yí ní “àwọn àkókò lílekoko” yìí ti mú káwọn kan ṣe?
3 “Àwọn àkókò lílekoko” là ń gbé, wàhálà àti “ìdààmú” tí ọ̀pọ̀ sì ń bá yí kọjá àfẹnusọ. (Sm. 90:10; 2 Tím. 3:1-5) Èyí ti mú kí ayé sú ọ̀pọ̀ èèyàn. Kódà ìwádìí kan fi hàn pé ohun tó ju ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rùn-ún mẹ́jọ (800,000) èèyàn ló ń gbẹ̀mí ara wọn lọ́dọọdún, ìyẹn fi hàn pé ó kéré tán èèyàn kan ń gbẹ̀mí ara rẹ̀ láàárín ìṣẹ́jú kan. Ó bani nínú jẹ́ pé àwọn Kristẹni kan lónìí náà ti gbẹ̀mí ara wọn torí ìṣòro tí wọ́n ní.
4. Àwọn wo nínú Bíbélì ló ronú pé ó sàn káwọn kú?
4 Láyé ìgbà tí wọ́n ń kọ Bíbélì, àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run kan wà tí ìṣòro mu wọ́n lómi débi tí wọ́n fi ronú pé á sàn káwọn kú. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí ìdààmú bá Jóòbù, ó ké jáde pé: ‘Mo kọ ẹ̀mí mi; èmi kì yóò wà láàyè fún àkókò tí ó lọ kánrin.’ (Jóòbù 7:16; 14:13) Nígbà tí nǹkan ò rí bí Jónà ṣe rò lẹ́nu iṣẹ́ tí Jèhófà fún un, ìrẹ̀wẹ̀sì bá a, ó wá sọ pé: “Wàyí o, Jèhófà, jọ̀wọ́, gba ọkàn mi kúrò lọ́dọ̀ mi, nítorí, kí n kú sàn ju kí n wà láàyè.” (Jónà 4:3) Bákan náà, ìgbà kan wà tí nǹkan tojú sú wòlíì Èlíjà débi tó fi ronú pé á sàn kóun kú. Ó sọ pé: “Ó tó gẹ́ẹ́! Wàyí o, Jèhófà, gba ọkàn mi kúrò.” (1 Ọba 19:4) Àmọ́ Jèhófà mọyì àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ olóòótọ́ yìí, kò sì fẹ́ kí wọ́n kú. Dípò tí Jèhófà fi máa bínú torí ohun tí wọ́n sọ, ṣe ló fìfẹ́ gbé wọn ró, ó sì ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wọ́n lè borí ẹ̀dùn ọkàn wọn, kí wọ́n sì máa sìn ín nìṣó.
5. Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì ká fìfẹ́ hàn sáwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin pàápàá jù lọ lásìkò tá a wà yìí?
5 Ọ̀pọ̀ àwọn ará wa lọ́kùnrin àti lóbìnrin ló ń kojú àwọn ìṣòro tó ń tánni lókun, ó sì yẹ ká gbé wọn ró tìfẹ́tìfẹ́. Àwọn kan ń kojú àtakò àti ìfiniṣẹ̀sín. Wọ́n ń fìtínà àwọn míì ní ibiṣẹ́. Yàtọ̀ síyẹn, iṣẹ́ àṣelàágùn táwọn kan ń ṣe ti mú kí wọ́n ṣàárẹ̀. Ìṣòro ìdílé làwọn míì ń bá yí, bóyá torí pé ọkọ tàbí aya wọn kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Àwọn ìṣòro yìí ti mú kí àárẹ̀ bá àwọn kan nínú ìjọ, kí wọ́n sì rẹ̀wẹ̀sì. Ta ló máa wá ran irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ lọ́wọ́?
ÌFẸ́ TÍ JÈHÓFÀ NÍ MÁA Ń GBÉ WA RÓ
6. Báwo ni Jèhófà ṣe ń fìfẹ́ gbé àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ ró?
6 Jèhófà fi àwa ìránṣẹ́ rẹ̀ lọ́kàn balẹ̀ pé títí láé lòun á máa nífẹ̀ẹ́ wa. Ó dájú pé ọkàn àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó jẹ́ olóòótọ́ máa balẹ̀ nígbà tí Jèhófà sọ fún wọn pé: “Nítorí òtítọ́ náà pé ìwọ ṣe iyebíye ní ojú mi, a kà ọ́ sí ẹni tí ó ní ọlá, èmi fúnra mi sì nífẹ̀ẹ́ rẹ. . . . Má fòyà, nítorí pé mo wà pẹ̀lú rẹ”! (Aísá. 43:4, 5) Jẹ́ kó dá ìwọ náà lójú pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ rẹ, kò sì ní fi ẹ́ sílẹ̀ láé. * Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣèlérí fáwọn tó ń fòótọ́ inú sin Jèhófà pé: “Bí Ẹni tí ó ní agbára ńlá, òun yóò gbà là. Òun yóò yọ ayọ̀ ńláǹlà lórí rẹ pẹ̀lú ayọ̀ yíyọ̀.”—Sef. 3:16, 17.
7. Báwo ni ìfẹ́ tí Jèhófà ní sí wa ṣe dà bí ti ìyá tó ń tọ́mọ lọ́wọ́? (Wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.)
7 Jèhófà ṣèlérí pé òun máa dúró ti àwọn ìránṣẹ́ òun láìka ìṣòro yòówù tí wọ́n bá ń kojú sí. Bíbélì sọ pé: “Ìhà ni a óò gbé yín sí, orí eékún sì ni a ó ti máa ṣìkẹ́ yín. Bí ènìyàn tí ìyá rẹ̀ ń tù nínú, bẹ́ẹ̀ ni èmi fúnra mi yóò ṣe máa tù yín nínú.” (Aísá. 66:12, 13) Ẹ fojú inú wo bó ṣe máa rí lára ọmọ kan tí ìyá rẹ̀ gbé sórí itan, tó ń ṣìkẹ́, tó sì ń pasẹ̀ fún! Jèhófà lo àfiwé yẹn ká lè mọ bó ṣe nífẹ̀ẹ́ àwa ìránṣẹ́ rẹ̀ tó. Jẹ́ kó dá ẹ lójú pé o ṣeyebíye gan-an lójú Jèhófà, ó mọyì rẹ, títí láé lá sì máa nífẹ̀ẹ́ rẹ.—Jer. 31:3.
8, 9. Báwo ni ìfẹ́ tí Jésù ní ṣe lè fún wa lókun?
8 Ohun míì wà tó mú káwa Kristẹni tòótọ́ gbà pé lóòótọ́ ni Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa gan-an. Bíbélì sọ pé: “Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ ayé tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí ó fi fi Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo fúnni, kí olúkúlùkù ẹni tí ó bá ń lo ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀ má bàa pa run, ṣùgbọ́n kí ó lè ní ìyè àìnípẹ̀kun.” (Jòh. 3:16) Kò sí àní-àní pé Jésù náà nífẹ̀ẹ́ wa, ìdí nìyẹn tó fi gbà láti kú nítorí tiwa. Ó dájú pé ìfẹ́ yìí máa ń jẹ́ kọ́kàn wa balẹ̀. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tiẹ̀ ṣèlérí pé ‘ìpọ́njú tàbí wàhálà’ ò lè “yà wá kúrò nínú ìfẹ́ Kristi.”—Róòmù 8:35, 38, 39.
9 Nígbà míì, àwọn ìṣòro kan lè máa kó ẹ̀dùn ọkàn bá wa tàbí kó má jẹ́ ká láyọ̀ lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà. Àmọ́, tá a bá ronú lórí bí Jésù ṣe nífẹ̀ẹ́ wa tó, a máa ní okun láti fara da àwọn ìṣòro náà. (Ka 2 Kọ́ríńtì 5:14, 15.) Kódà tó bá jẹ́ àwọn ìṣòro tó lékenkà irú bí àjálù, àtakò, ìjákulẹ̀ tàbí ìdààmú ọkàn là ń kojú, ìfẹ́ tí Kristi ní sí wa lè fún wa lókun tá a nílò ká má bàa sọ̀rètí nù.
Ó YẸ KÁ MÁA FÌFẸ́ HÀN SÁWỌN ARÁ WA
10, 11. Ṣé àwọn alàgbà nìkan ló yẹ kó máa tu àwọn tó ní ìsoríkọ́ nínú? Ṣàlàyé.
10 Jèhófà tún ń lo ìjọ Kristẹni láti jẹ́ ká mọ̀ pé òun nífẹ̀ẹ́ wa. Torí náà, àwa náà lẹ́nì kọ̀ọ̀kan lè fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ Jèhófà nígbà tá a bá ń fìfẹ́ hàn sáwọn ará wa, tá a sì ń ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti gbé wọn ró nípa tẹ̀mí, ká sì ràn wọ́n lọ́wọ́ nígbà tí wọ́n bá ní ẹ̀dùn ọkàn. (1 Jòh. 4:19-21) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Ẹ máa tu ara yín nínú lẹ́nì kìíní-kejì, kí ẹ sì máa gbé ara yin ró lẹ́nì kìíní-kejì, gan-an gẹ́gẹ́ bí ẹ ti ń ṣe ní tòótọ́.” (1 Tẹs. 5:11) Ìyẹn fi hàn pé gbogbo wa yálà a jẹ́ alàgbà tàbí a kì í ṣe alàgbà ló yẹ ká máa fara wé àpẹẹrẹ Jèhófà àti Jésù, ká sì máa tu àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa nínú.—Ka Róòmù 15:1, 2.
11 Nígbà míì, àwọn kan nínú ìjọ lè ní ìsoríkọ́ tó lékenkà, èyí sì lè gba pé kí wọ́n lọ rí dókítà. (Lúùkù 5:31) Ó yẹ káwọn alàgbà àtàwọn míì nínú ìjọ fi sọ́kàn pé àwọn kì í ṣe dókítà tó lè tọ́jú irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀. Síbẹ̀, ó ṣe pàtàkì kí gbogbo wa ran irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ lọ́wọ́ yálà a jẹ́ alàgbà tàbí a kì í ṣe bẹ́ẹ̀. Bíbélì gbà wá níyànjú pé: “Ẹ máa sọ̀rọ̀ ìtùnú fún àwọn ọkàn tí ó soríkọ́, ẹ máa ṣètìlẹyìn fún àwọn aláìlera, ẹ máa ní ìpamọ́ra fún gbogbo ènìyàn.” (1 Tẹs. 5:14) Gbogbo wa pátá ló yẹ ká máa fìfẹ́ hàn sí àwọn tó ní ìsoríkọ́, ká mú sùúrù fún wọn, ká máa gba tiwọn rò, ká sì máa bá wọn sọ̀rọ̀ lọ́nà pẹ̀lẹ́. Ṣé o máa ń tu irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ nínú, ṣé o sì máa ń gbé wọn ró? Ǹjẹ́ o mọ ohun tó o lè ṣe tó o bá fẹ́ ràn wọ́n lọ́wọ́?
12. Sọ àpẹẹrẹ ẹnì kan tó rí ìtùnú nítorí pé àwọn ará ìjọ fìfẹ́ hàn sí i.
12 Tá a bá fìfẹ́ hàn sáwọn tó ní ìsoríkọ́, báwo nìyẹn ṣe lè gbé wọn ró? Arábìnrin kan ní Yúróòpù sọ pé: “Nígbà míì, ó máa ń ṣe mí bíi pé kí n pa ara mi. Àmọ́ àwọn ará nínú ìjọ dúró tì mí, wọn ò sì jẹ́ kí n gbẹ̀mí ara mi. Gbogbo ìgbà làwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin máa ń fìfẹ́ hàn sí mi, wọ́n sì máa ń mú kára tù mí. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn díẹ̀ nínú ìjọ ló mọ̀ pé mo ní ìsoríkọ́, síbẹ̀ gbogbo ìjọ pátá ló dúró tì mí. Tọkọtaya kan tiẹ̀ wà tó mú mi bí ọmọ. Ẹ ò lè mọ̀ pé àwọn kọ́ ló bí mi torí pé wọ́n máa ń tọ́jú mi gan-an, kódà ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé ojoojúmọ́ ni wọ́n máa ń wà pẹ̀lú mi látàárọ̀ ṣúlẹ̀.” Òótọ́ ni pé, ohun tí kálukú wa lè ṣe láti ran àwọn míì lọ́wọ́ yàtọ̀ síra. Síbẹ̀, ká fi sọ́kàn pé ohunkóhun tá a bá fi tinútinú ṣe fáwọn tó ní ẹ̀dùn ọkàn lè mú kára tù wọ́n, kó sì gbé wọn ró. *
BÁ A ṢE LÈ FÌFẸ́ HÀN SÁWỌN ARÁ WA
13. Kí ló yẹ ká ṣe tá a bá fẹ́ gbé àwọn míì ró?
13 Máa fara balẹ̀ tẹ́tí sí wọn. (Ják. 1:19) Tá a bá ń fara balẹ̀ tẹ́tí sẹ́nì kan, ṣe là ń fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ ẹni náà. Bí àpẹẹrẹ, tá a bá wà pẹ̀lú ẹnì kan tó ní ẹ̀dùn ọkàn, a lè fọgbọ́n béèrè àwọn ìbéèrè táá jẹ́ ká mọ bí nǹkan ṣe rí lára rẹ̀. Ìyẹn á jẹ́ ká mọ bá a ṣe lè gba tiẹ̀ rò, ká sì fìfẹ́ hàn sí i. Bákan náà, jẹ́ kó hàn lójú rẹ pé o nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, ọ̀rọ̀ ẹ̀ sì ń jẹ ẹ́ lọ́kàn. Tí ẹni náà bá ń ṣàlàyé ohun tó ń ṣe é tàbí tó ń tú ọkàn rẹ̀ jáde, má ṣe dá ọ̀rọ̀ mọ́ ọn lẹ́nu, ńṣe ni kó o ṣe sùúrù títí táá fi bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ délẹ̀. Tó o bá fara balẹ̀ tẹ́tí sí i, wàá túbọ̀ lóye bí ọ̀rọ̀ náà ṣe rí lára rẹ̀. Yàtọ̀ síyẹn, ẹni náà máa fọkàn tán ẹ, á sì tẹ́tí sí àwọn ìmọ̀ràn tó o bá fún un torí pé ìwọ náà fara balẹ̀ tẹ́tí sí i nígbà tó ń sọ̀rọ̀. Tẹ́ni tó ní ẹ̀dùn ọkàn bá rí i pé lóòótọ́ lo nífẹ̀ẹ́ òun, ìyẹn á mú kára tù ú.
14. Kí nìdí tí kò fi yẹ ká máa ṣàríwísí àwọn míì?
14 Má ṣe máa ṣàríwísí. Tó o bá ń ṣàríwísí ẹni tó ní ẹ̀dùn ọkàn, ṣe lo tún ń dá kún ìṣòro ẹ̀ dípò kó o máa gbé e ró. Bíbélì sọ pé: “Ẹnì kan wà tí ń sọ̀rọ̀ láìronú bí ẹni pé pẹ̀lú àwọn ìgúnni idà, ṣùgbọ́n ahọ́n ọlọ́gbọ́n jẹ́ ìmúniláradá.” (Òwe 12:18) A lè má dìídì fọ̀rọ̀ gún ẹni tó ní ẹ̀dùn ọkàn lára, síbẹ̀ tá a bá ń sọ̀rọ̀ láìronú jinlẹ̀, a lè fọ̀rọ̀ gún ẹni náà lára láìmọ̀, ọ̀rọ̀ náà sì máa dùn ún. Torí náà, ká lè fìfẹ́ hàn sí ẹnì kan, ká sì gbé e ró, a gbọ́dọ̀ máa fọ̀rọ̀ ro ara wa wò, ká fira wa sípò ẹni náà, ká lè mọ bọ́rọ̀ kan ṣe máa rí lára ẹ̀.—Mát. 7:12.
15. Kí la lè lo láti gbé àwọn míì ró?
15 Máa fi Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tu àwọn míì nínú. (Ka Róòmù 15:4, 5.) Àwọn ọ̀rọ̀ tó wà nínú Bíbélì máa ń tuni nínú, ìyẹn ò sì jọni lójú torí pé àtọ̀dọ̀ “Ọlọ́run tí ń pèsè ìfaradà àti ìtùnú” ni Bíbélì ti wá. Yàtọ̀ sáwọn ẹsẹ Bíbélì tó ń tuni nínú, àwọn ìtẹ̀jáde míì wà táá jẹ́ ká rí àwọn ọ̀rọ̀ tó ń fini lọ́kàn balẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, a ní ìwé atọ́ka Watch Tower Publications Index àti Ìwé Ìwádìí fún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Àwọn ìtẹ̀jáde yìí máa jẹ́ ká rí àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ àtàwọn ìsọfúnni míì tó lè ràn wá lọ́wọ́ láti kojú ìṣòro yòówù tó lè dé bá wa. A sì lè lo àwọn ìsọfúnni yìí láti gbé àwọn míì ró, ká sì tù wọ́n nínú nígbà tí wọ́n bá níṣòro.
16. Àwọn ànímọ́ wo ló yẹ ká ní tá a bá fẹ́ ran Kristẹni kan tó ní ẹ̀dùn ọkàn lọ́wọ́?
16 Máa ṣìkẹ́ wọn, kó o sì máa bá wọn lò lọ́nà jẹ̀lẹ́ńkẹ́. Àwọn ànímọ́ àtàtà yìí máa ń jẹ́ ká lè mára tu ẹni tó bá rẹ̀wẹ̀sì, ká sì gbé e ró. Bíbélì sọ pé Jèhófà jẹ́ “Baba àánú oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ àti Ọlọ́run ìtùnú gbogbo,” ó sì máa ń fi “ìyọ́nú oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́” hàn sáwọn ìránṣẹ́ rẹ̀. (Ka 2 Kọ́ríńtì 1:3-6; Lúùkù 1:78; Róòmù 15:13) Pọ́ọ̀lù fi àpẹẹrẹ tó dáa lélẹ̀ lórí ọ̀rọ̀ yìí, ó sọ pé: “Àwa di ẹni pẹ̀lẹ́ láàárín yín, bí ìgbà tí abiyamọ ń ṣìkẹ́ àwọn ọmọ tirẹ̀. Nítorí náà, ní níní ìfẹ́ni oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ fún yín, ó dùn mọ́ wa nínú jọjọ láti fún yín, kì í ṣe ìhìn rere Ọlọ́run nìkan, ṣùgbọ́n ọkàn àwa fúnra wa pẹ̀lú, nítorí ẹ di olùfẹ́ ọ̀wọ́n fún wa.” (1 Tẹs. 2:7, 8) Táwa náà bá ń ṣìkẹ́ àwọn ará wa, tá a sì ń bá wọn lò lọ́nà jẹ̀lẹ́ńkẹ́, Jèhófà lè lò wá láti tu ẹnì kan tó ní ẹ̀dùn ọkàn nínú.
17. Tá a bá fẹ́ gbé àwọn ará wa ró, kí ló yẹ ká fi sọ́kàn?
17 Máa rántí pé aláìpé làwọn ará wa. Ó yẹ ká máa fi sọ́kàn pé àwọn ará wa lọ́kùnrin àti lóbìnrin kì í ṣe ẹni pípé torí náà kò sí bí wọn ò ṣe ní máa ṣàṣìṣe. (Oníw. 7:21, 22) Ká rántí pé Jèhófà kì í retí pé káwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ ṣe ohun tó ju agbára wọn lọ. Torí náà, ó yẹ ká máa fara wé Jèhófà, ká sì máa mú sùúrù fáwọn ará wa nígbà tí wọ́n bá ṣàṣìṣe. (Éfé. 4:2, 32) Dípò ká máa hùwà sí wọn bíi pé wọn ò ṣe dáadáa tó tàbí ká máa fi ohun tí wọ́n lè ṣe wé tàwọn míì, ṣe ló yẹ ká máa yìn wọ́n fún ohun tí wọ́n bá ṣe. Tá a bá ń gbóríyìn fún wọn látọkànwá, ọkàn wọn á balẹ̀, ohun tí wọ́n sì ń ṣe lẹ́nu iṣẹ́ Jèhófà á máa fún wọn láyọ̀.—Gál. 6:4.
18. Kí nìdí tó fi yẹ ká máa gbé ara wa ró, ká sì máa fìfẹ́ hàn síra wa?
18 Gbogbo àwa ìránṣẹ́ Jèhófà la ṣeyebíye lójú rẹ̀. Jésù náà sì nífẹ̀ẹ́ wa, ìdí nìyẹn tó fi fẹ̀mí rẹ̀ rà wá pa dà. (Gál. 2:20) Àwa náà nífẹ̀ẹ́ àwọn ará wa lọ́kùnrin àti lóbìnrin, a sì máa ń ṣìkẹ́ wọn. Torí náà, tá a bá fẹ́ kára tu àwọn ará, Bíbélì gbà wá níyànjú pé “kí a máa lépa àwọn ohun tí ń yọrí sí àlàáfíà àti àwọn ohun tí ń gbéni ró fún ara wa lẹ́nì kìíní-kejì.” (Róòmù 14:19) Ní báyìí ná, à ń fojú sọ́nà fún Párádísè tí Jèhófà ṣèlérí níbi tí ẹnikẹ́ni ò ti ní rẹ̀wẹ̀sì mọ́. Tó bá dìgbà yẹn, kò ní sí àìsàn mọ́, kò ní sí ogun, inúnibíni, ìṣòro ìdílé, ìjákulẹ̀ títí kan ikú tí ẹ̀ṣẹ̀ Ádámù fà. Nígbà tí Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso Kristi bá fi máa parí, gbogbo èèyàn pátápátá ti máa di pípé. Àwọn tó bá la ìdánwò ìkẹyìn já ni Jèhófà máa gbà ṣọmọ rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé, wọ́n á sì ní “òmìnira ológo ti àwọn ọmọ Ọlọ́run.” (Róòmù 8:21) Ǹjẹ́ kí gbogbo wa túbọ̀ máa fìfẹ́ hàn síra wa, ká sì máa gbé ara wa ró, ká lè jọ kọ́wọ̀ọ́ rìn wọnú ayé tuntun tí Jèhófà ṣèlérí.
^ ìpínrọ̀ 12 Tó o bá fẹ́ mọ ohun tó o lè ṣe tó bá ń ṣe ẹ́ bíi pé kó o pa ara ẹ, wo àwọn àpilẹ̀kọ tó wà nínú àwọn Jí! tá a mẹ́nu kàn yìí: “Má Ṣe Jẹ́ Káyé Sú Ẹ Ìdí Mẹ́ta Tó Fi Yẹ Kó O Ṣì Wà Láàyè” (May 2014); “Tó Bá Ń Ṣe Ẹ́ Bíi Pé Kó O Gbẹ̀mí Ara Rẹ” (April 2012); àti “Ìrànwọ́ fún Àwọn Obìnrin Tí Ọkọ Wọn Ń Lù” (November 8, 2001) ojú ìwé 13 sí 22.