Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
Báwo ni Kristẹni kan ṣe máa mọ̀ bóyá ó tọ́ kí òun fún òṣìṣẹ́ ìjọba kan ní owó tàbí ẹ̀bùn?
Ọ̀rọ̀ yìí gba àròjinlẹ̀ gan-an. Ó ṣe tán, àwa Kristẹni gbọ́dọ̀ jẹ́ olóòótọ́. A gbọ́dọ̀ máa pa òfin ìjọba mọ́ bí kò bá ti ta ko òfin Jèhófà. (Mát. 22:21; Róòmù 13:1, 2; Héb. 13:18) Á tún máa ń sapá láti bọ̀wọ̀ fún àṣà ìbílẹ̀ ibi tá à ń gbé, a sì máa ń ‘nífẹ̀ẹ́ àwọn aládùúgbò wa gẹ́gẹ́ bí ara wa.’ (Mát. 22:39; Róòmù 12:17, 18; 1 Tẹs. 4:11, 12) Àwọn ìlànà yìí làwọn Kristẹni níbi gbogbo máa fi sọ́kàn kí wọ́n lè mọ̀ bóyá káwọn fún òṣìṣẹ́ lówó tàbí ẹ̀bùn.
Ní ọ̀pọ̀ ibi láyé, kò dìgbà téèyàn bá fún àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba lówó kéèyàn tó rí ẹ̀tọ́ ẹ̀ gbà. Wọ́n ń ṣe iṣẹ́ tí ìjọba ń torí ẹ sanwó fún wọn, wọn kì í sì í béèrè tàbí retí pé kí ẹnikẹ́ni fún àwọn lówó tàbí ẹ̀bùn èyíkéyìí. Ní ọ̀pọ̀ ilẹ̀, kò bófin mu fáwọn òṣìṣẹ́ ìjọba láti béèrè tàbí gba owó àti ẹ̀bùn kódà bí wọ́n bá tiẹ̀ ń ṣe iṣẹ́ wọn bí iṣẹ́. Ní irú àwọn ilẹ̀ bẹ́ẹ̀, àbẹ̀tẹ́lẹ̀ ni wọ́n máa ka irú owó bẹ́ẹ̀ sí, kódà bó bá tiẹ̀ ti parí iṣẹ́ náà kó tó gbà á. Níbi tí irú òfin bẹ́ẹ̀ bá wà, ọ̀rọ̀ bóyá kí Kristẹni kan fáwọn òṣìṣẹ́ ìjọba lówó tàbí kó má fún wọn ò tún sí mọ́. Àbẹ̀tẹ́lẹ̀ ni irú owó tàbí ẹ̀bùn bẹ́ẹ̀.
Àmọ́ láwọn ibi tí irú òfin bẹ́ẹ̀ kò ti sí tàbí tí ìjọba ò fọwọ́ pàtàkì mú òfin náà, àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba tó wà níbẹ̀ kì í wo irú owó bẹ́ẹ̀ bí àbẹ̀tẹ́lẹ̀. Láwọn ilẹ̀ kan, àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba máa ń fi ipò wọn kó àwọn èèyàn nífà tàbí kí wọ́n gba owó lọ́wọ́ wọn kí wọ́n tó ṣiṣẹ́ tó yẹ kí wọ́n ṣe, wọ́n á sì takú pé àwọn ò ní ṣiṣẹ́ náà tẹ́ni náà ò bá fáwọn lówó. Bí àpẹẹrẹ, àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba máa ń gba owó tàbí ẹ̀bùn lọ́wọ́ àwọn èèyàn kí wọ́n tó forúkọ ìgbéyàwó sílẹ̀, kí wọ́n tó gba owó orí lọ́wọ́ ẹnì kan, kí wọ́n tó fúnni ní ìwé àṣẹ láti kọ́lé àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Èyí tó tiẹ̀ burú ńbẹ̀ ni pé bí ẹnì kan ò bá fáwọn òṣìṣẹ́ yìí lówó, wọ́n lè mọ̀ọ́mọ̀ dínà ẹ̀tọ́ rẹ̀ tàbí kí wọ́n tiẹ̀ má jẹ́ kó rí ohun tó wá fún ṣe, àfi tó bá fún wọn ní nǹkan. Ní orílẹ̀-èdè kan, a gbọ́ pé táwọn panápaná bá dé ibi tí wọ́n ti fẹ́ lọ paná, wọn ò ní bẹ̀rẹ̀ sí í paná náà àfi tí wọ́n bá kọ́kọ́ fún wọn lówó tó jọjú.
Ẹ́kís. 23:8; Diu. 16:19; Òwe 17:23.
Nírú àwọn ilẹ̀ tírú ìwà bẹ́ẹ̀ ti wọ́pọ̀, àwọn kan gbà pé kò sí báwọn ò ṣe ní máa fáwọn òṣìṣẹ́ ìjọba lówó tàbí ẹ̀bùn. Ní irú ipò bẹ́ẹ̀, Kristẹni kan lè kà á sí ara owó tó yẹ kóun san kí òun tó lè rí ẹ̀tọ́ òun gbà. Àmọ́ torí ìwà jẹgúdújẹrá tó gbòde kan, Kristẹni kan gbọ́dọ̀ kíyè sára kó lè fi ìyàtọ̀ sáàárín ohun tó tọ́ àtèyí tí kò tọ́ lójú Ọlọ́run. Ọ̀tọ̀ ni kéèyàn fúnni lówó tàbí lẹ́bùn kó lè rí ẹ̀tọ́ rẹ̀ gbà, ọ̀tọ̀ sì ni kéèyàn máa fúnni ní ẹ̀gúnjẹ tàbí rìbá kó lè rí nǹkan tí ò lẹ́tọ̀ọ́ sí gbà. Níbi tí irú ìwà ìbàjẹ́ bẹ́ẹ̀ ti pọ̀, àwọn kan máa ń fún òṣìṣẹ́ ìjọba tàbí ọlọ́pàá ní “ẹ̀gúnjẹ” kí wọ́n lè rí ohun tí wọn ò lẹ́tọ̀ọ́ sí gbà tàbí torí kí wọ́n má bàa jìyà ẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n dá tàbí san owó ìtanràn torí pé wọ́n rúfin. Torí náà, kò ní dáa ká máa fún àwọn èèyàn ní ẹ̀gúnjẹ tàbí rìbá tàbí káwa fúnra wa máa gba ẹ̀gúnjẹ. Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, ohun tá a ṣe ò bófin mu nìyẹn.—Ọ̀pọ̀ àwọn Kristẹni tó ti fi Bíbélì kọ́ ẹ̀rí ọkàn wọn kì í fẹ́ fún àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba lówó pàápàá tí wọ́n bá béèrè fún un. Wọ́n ronú pé táwọn bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, àwọn á máa kọ́wọ́ ti ìwà ìbàjẹ́ wọn nìyẹn. Torí náà, bí ẹnikẹ́ni bá ní kí wọ́n fún òun lówó, wọn ò ní fún un.
Àwọn Kristẹni tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú wọn mọ̀ pé táwọn bá fún ẹnì kan lówó tàbí ẹ̀bùn káwọn lè rí nǹkan táwọn ò lẹ́tọ̀ọ́ sí gbà, àbẹ̀tẹ́lẹ̀ nìyẹn, síbẹ̀ àdúgbò táwọn kan ń gbé àti ohun tó wọ́pọ̀ níbẹ̀ lè mú káwọn kan fún àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba lówó tàbí ẹ̀bùn ráńpẹ́ kí wọ́n lè rí ẹ̀tọ́ wọn gbà tàbí kí wọ́n lè tètè rí i gbà. Bí àpẹẹrẹ, lẹ́yìn táwọn Kristẹni kan bá gba ìtọ́jú ọ̀fẹ́ ní ilé ìwòsàn ìjọba, wọ́n máa ń fún àwọn nọ́ọ̀sì tàbí dókítà ní owó tàbí ẹ̀bùn láti fi hàn pé àwọn mọ rírì ìtọ́jú tí wọ́n fáwọn. Wọ́n sábà máa ń ṣe bẹ́ẹ̀ lẹ́yìn tí wọ́n bá ti gbàtọ́jú tán kì í ṣe kí wọ́n tó gbàtọ́jú kó má bàa di pé wọ́n mọ̀ọ́mọ̀ dami síwájú kí wọ́n lè tẹ ilẹ̀ tútù.
Kò ṣeé ṣe láti sọ gbogbo ipò téèyàn lè bá ara rẹ̀ nínú àpilẹ̀kọ yìí. Àmọ́ ipò yòówù ká bá ara wa ní ibikíbi, àwa Kristẹni gbọ́dọ̀ ṣe ìpinnu táá jẹ́ ká ní ẹ̀rí ọkàn rere. (Róòmù 14:1-6) A gbọ́dọ̀ yẹra fáwọn ohun tí kò bófin mu. (Róòmù 13:1-7) A sì gbọ́dọ̀ yẹra fún ohunkóhun tó lè kó ẹ̀gàn bá orúkọ Jèhófà tàbí tó lè mú kí ẹlòmíì kọsẹ̀. (Mát. 6:9; 1 Kọ́r. 10:32) Àwọn ìpinnu tá a bá sì ń ṣe gbọ́dọ̀ fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ àwọn aládùúgbò wa.—Máàkù 12:31.
Báwo ni àwọn ará nínú ìjọ ṣe lè fi ayọ̀ wọn hàn nígbà tí wọ́n bá ṣèfilọ̀ pé a ti gba ẹnì kan tá a yọ lẹ́gbẹ́ pa dà?
Nínú Lúùkù orí 15, a rí àkàwé tó fakíki tí Jésù sọ nípa ọkùnrin kan tó ní ọgọ́rùn-ún [100] àgùntàn. Nígbà tí ọ̀kan nínú àwọn àgùntàn náà sọnù, ọkùnrin náà fi mọ́kàndínlọ́gọ́rùn-ún [99] tó kù sílẹ̀ nínú aginjù, ó sì wá èyí tó sọnù lọ ‘títí tó fi rí i.’ Jésù ń bá àkàwé náà lọ, ó ní: “Nígbà tí ó bá sì ti rí i, a gbé e lé èjìká rẹ̀, a sì yọ̀. Nígbà tí ó bá sì dé ilé, a pe àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ àti àwọn aládùúgbò rẹ̀ jọ, a sì sọ fún wọn pé, ‘Ẹ bá mi yọ̀, nítorí mo ti rí àgùntàn mi tí ó sọnù.’” Ní ìparí àkàwé náà, Jésù sọ pé: “Mo sọ fún yín pé báyìí ni ìdùnnú púpọ̀ yóò ṣe wà ní ọ̀run lórí ẹlẹ́ṣẹ̀ kan tí ó ronú pìwà dà ju lórí mọ́kàndínlọ́gọ́rùn-ún [99] àwọn olódodo tí wọn kò nílò ìrònúpìwàdà.”—Lúùkù 15:4-7.
Ohun tó ṣẹlẹ̀ ṣáájú kí Jésù tó sọ àkàwé yìí jẹ́ ká rí i pé ńṣe ni Jésù fẹ́ tún èrò àwọn Farisí àti àwọn akọ̀wé òfin ṣe. Wọ́n ń bẹnu àtẹ́ lu Jésù torí pé ó máa ń kó àwọn agbowó orí àtàwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ mọ́ra. (Lúùkù 15:1-3) Jésù wá fi yé wọn pé ayọ̀ púpọ̀ máa ń wà lọ́run tí ẹlẹ́ṣẹ̀ kan bá ronú pìwà dà. Èyí lè mú ká béèrè pé, ‘Táwọn tó wà lọ́run bá ń yọ̀, ṣé kò yẹ kí àwọn tó wà lórí ilẹ̀ ayé náà máa yọ̀ tí ẹlẹ́ṣẹ̀ kan bá ronú pìwà dà, tó yí pa dà, tó sì ṣe ipa ọ̀nà títọ́ fún ẹsẹ̀ rẹ̀?’—Héb. 12:13.
Ọ̀pọ̀ ìdí wà fún wa láti yọ̀ nígbà tí wọ́n bá gba ẹnì kan tí wọ́n yọ lẹ́gbẹ́ pa dà sínú ìjọ. Ẹni náà ní láti máa bá a lọ ní jíjẹ́ olóòótọ́ sí Ọlọ́run, àmọ́ torí ó ronú pìwà dà la ṣe gbà á pa dà, inú wa sì dùn pé ó ṣe bẹ́ẹ̀. Torí náà, nígbà táwọn alàgbà bá ṣèfilọ̀ pé a ti gba ẹnì kan pa dà, kò burú tá a bá pa àtẹ́wọ́ tó tọkàn wá.
Kí ló máa ń mú kí adágún omi Bẹtisátà tó wà ní Jerúsálẹ́mù “dà rú”?
Nígbà ayé Jésù, àwọn olùgbé Jerúsálẹ́mù kan rò pé adágún omi Bẹtisátà máa ń woni sàn tó bá “dà rú.” (Jòh. 5:1-7) Ìyẹn ló mú káwọn tó ń wá ìwòsàn máa pé jọ síbẹ̀.
Àwọn Júù máa ń wá ṣe ààtò ìwẹ̀nùmọ́ nínú omi yìí. Tí omi náà bá ti ń lọ sílẹ̀, wọ́n á ṣí omi tó wà nínú ìkùdu ńlá kan tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ adágún omi náà, omi tó wà nínú ìkùdu ńlá náà á sì ṣàn wá sínú adágún omi yìí. Ìwádìí táwọn awalẹ̀pìtàn ṣe fi hàn pé odi kan pààlà sáàárín ìkùdu ńlá àti adágún omi yìí. Wọ́n máa ń ṣí ihò kan tó wà lára odi yìí kí omi lè gba abẹ́ ṣàn wọ inú adágún omi náà. Ó ní láti jẹ́ pé omi tó ń ya wọnú adágún omi yìí láti abẹ́ ló ń mú kí ojú omi náà máa dà rú.
Nínú àwọn Bíbélì kan, Jòhánù 5:4 sọ pé áńgẹ́lì kan ló ń mú kí omi náà dà rú, àmọ́ èyí kò sí nínú àwọn ìwé àfọwọ́kọ Gírí ìkì ìgbàanì irú bí ìwé Codex Sinaiticus tí wọ́n kọ ní ọgọ́rùn-ún ọdún kẹrin. Lẹ́gbẹ̀ẹ́ adágún omi Bẹtisátà, Jésù wo ọkùnrin kan tó ti ń ṣàìsàn fún ọdún méjìdínlógójì [38] sàn. Ọkùnrin yẹn ò wọ inú omi náà rárá tí Jésù fi wò ó sàn.