Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ILÉ ÌṢỌ́ No. 1 2018 | Ṣé Bíbélì Ṣì Wúlò Lóde Òní?

Ṣé Bíbélì Wúlò Lóde Òní?

Tá a bá wo bí àwọn ẹ̀rọ ìgbàlódé ṣe mú kó rọrùn láti rí ìsọfúnni lóde òní, ṣé o rò pé Bíbélì ṣì wúlò fún wa? Bíbélì sọ pé:

“Gbogbo Ìwé Mímọ́ ni Ọlọ́run mí sí, ó sì ṣàǹfààní.”​—2 Tímótì 3:16.

Ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ yìí máa jẹ́ kó o mọ̀ bóyá lóòótọ́ ni Bíbélì lè tọ́ wa sọ́nà ní gbogbo apá ìgbésí ayé wa.

 

Ṣé Ọ̀rọ̀ Inú Bíbélì Wúlò Lóde Òní?

Kí ni ìwúlò Bíbélì tó ti wà láti nǹkan bíi ẹgbẹ̀rún ọdún méjì [2,000] sẹ́yìn, nígbà téèyàn lè rí àwọn ìsọfúnni lóríṣiríṣi lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀?

Ìlànà Bíbélì Wúlò Títí Láé

Òótọ́ ni pé àwọn èèyàn ń lóye àwọn nǹkan tuntun, àmọ́ ìyẹn ò sọ Bíbélì di ìwé tí kò bóde mu mọ́, torí pé àwọn ẹ̀kọ́ inú rẹ̀ dá lórí àwọn ìlànà tó wúlò títí láé.

Ṣé Bíbélì Bá Àkókò Wa Mu Àbí Kò Wúlò Mọ́ Rárá?

Bíbélì kì í ṣe ìwé sáyẹ́ǹsì, àmọ́ ohun tó sọ nípa sáyẹ́ǹsì máa yà ẹ́ lẹ́nu.

1 Ó Ń Jẹ́ Ká Yẹra fún Ìṣòro

Wo bí ọgbọ́n Ọlọ́run ṣe ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ láti tètè jáwọ́ nínú àṣà tó burú jáì.

2 Ó Ń Jẹ́ Ká Borí Ìṣòro

Bíbélì sọ ọgbọ́n téèyàn lè dá tó máa jẹ́ kó borí àwọn ìṣòro tí kò lọ bọ̀rọ̀ tó sì ń tán ni lókun, irú bí àníyàn tó pọ̀ lápọ̀jù, fífi nǹkan falẹ̀ àti ìdánìkanwà.

3 Ó Ń Jẹ́ Ká Fara Da Ìṣòro

Àwọn ìṣòro kan wà tá ò lè yẹra fún, kò sì sí ohun tá a lè ṣe láti yanjú wọn báyìí, irú bí ikú èèyàn wa kan tàbí àìsàn tó le gan-an.

Bíbélì Sọ Nípa Ọjọ́ Ọ̀la Rẹ

Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lè ràn wá lọ́wọ́ láti kojú àwọn ìṣòro tó wà níwájú wa, ìyẹn àwọn ìṣòro tí à ń dojú kọ lójoojúmọ́ nínú ayé burúkú yìí. Àmọ́ Bíbélì tún ń ṣe jù bẹ́ẹ̀ lọ. Ó tún máa ń tànmọ́lẹ̀ sáwọn ohun tó wà lọ́jọ́ iwájú.

Kí Lèrò Rẹ?

Kà nípa ohun táwọn kan gbà gbọ́ àti ohun tí Bíbélì gangan sọ nípa ìbéèrè yẹn.