Àwọn Nǹkan Wo Ni Ọlọ́run Máa Ṣe?
Tó o bá níṣòro, ó máa wù ẹ́ pé kí ọ̀rẹ́ ẹ ràn ẹ́ lọ́wọ́. Ó ṣe tán, ìgbà ìpọ́njú là ń mọ ọ̀rẹ́. Ohun táwọn kan rò nìyẹn tí wọ́n fi sọ pé Ọlọ́run kì í ṣe ọ̀rẹ́ àwọn, torí wọ́n gbà pé Ọlọ́run kò ṣe nǹkan kan sí ìṣòro àwọn. Àmọ́ ká sọ̀rọ̀ síbi tọ́rọ̀ wà, Ọlọ́run ti ṣe ọ̀pọ̀ nǹkan ribiribi fún wa. Ó máa tó mú gbogbo ìṣòro wa kúrò, á sì fòpin sí gbogbo ìyà tó ń jẹ aráyé. Kí ni Ọlọ́run máa ṣe?
Ó MÁA MÚ GBOGBO ÌWÀ IBI KÚRÒ
Bí Ọlọ́run ṣe máa fòpin sí ìwà ibi ni pé ó máa pa olórí àwọn ẹni ibi run. Bíbélì jẹ́ ká mọ onítọ̀hún nígbà tó sọ pé: “Gbogbo ayé wà lábẹ́ agbára ẹni burúkú náà.” (1 Jòhánù 5:19) Sátánì Èṣù ni “ẹni burúkú náà.” Òun ni Jésù pè ní “alákòóso ayé yìí.” (Jòhánù 12:31) Ọ̀dọ̀ Sátánì gangan ni ìwà ibi ti bẹ̀rẹ̀, òun ló fojú pa mọ́ tó ń da wàhálà sí ọmọ aráyé lágbada. Kí ni Ọlọ́run máa ṣe?
Jèhófà Ọlọ́run máa lo Jésù Kristi láti “pa ẹni tó lè fa ikú run, ìyẹn Èṣù.” (Hébérù 2:14; 1 Jòhánù 3:8) Kódà, Bíbélì fi hàn pé Èṣù fúnra ẹ̀ mọ̀ pé “ìgbà díẹ̀ ló kù” tóun máa pa run. (Ìfihàn 12:12) Ọlọ́run tún máa pa gbogbo àwọn tó ń hùwà burúkú run pátápátá.—Sáàmù 37:9; Òwe 2:22.
Ó MÁA SỌ AYÉ DI PÁRÁDÍSÈ
Lẹ́yìn tí gbogbo ìwà ibi bá dópin táwọn ẹni ibi sì pa run, Ẹlẹ́dàá wa máa rí i dájú pé àwọn èèyàn rere nìkan ló ṣẹ́ kù sáyé, ayé sì máa di Párádísè bó ṣe fẹ́ kó rí níbẹ̀rẹ̀. Kí ni ká máa fojú sọ́nà fún?
Àlàáfíà àti ààbò máa gbilẹ̀ títí láé. “Àwọn oníwà pẹ̀lẹ́ ni yóò jogún ayé, inú wọn yóò sì máa dùn jọjọ nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ àlàáfíà.”—Sáàmù 37:11.
Oúnjẹ aṣaralóore á pọ̀ yanturu. “Ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ oúnjẹ máa wà lórí ilẹ̀; ó máa kún àkúnwọ́sílẹ̀ lórí àwọn òkè.”—Sáàmù 72:16.
A máa ní ilé tó dáa àti iṣẹ́ tó ń tẹ́ni lọ́rùn. “Wọ́n á kọ́ ilé, wọ́n sì máa gbé inú wọn, wọ́n á gbin ọgbà àjàrà, wọ́n sì máa jẹ èso wọn. . . . Àwọn àyànfẹ́ mi sì máa gbádùn iṣẹ́ ọwọ́ wọn dé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́.”—Àìsáyà 65:21, 22.
Ṣé ó wù ẹ́ kó o wà níbẹ̀ nígbà táwọn nǹkan yìí bá ṣẹlẹ̀? Láìpẹ́, àwọn ohun tá ò máa gbádùn lójoojúmọ́ ayé wa nìyẹn.
Ó MÁA MÚ ÀÌSÀN ÀTI IKÚ KÚRÒ
Ọmọ aráyé ti kàgbákò àìsàn àti ikú. Àmọ́ láìpẹ́, ìyẹn máa di ohun ìgbàgbé. Ọlọ́run máa wo ọlá ikú ìrúbọ tí Jésù kú láti ra aráyé pa dà, kí “gbogbo ẹni tó bá ń ní ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀ má bàa pa run, ṣùgbọ́n kó lè ní ìyè àìnípẹ̀kun.” (Jòhánù 3:16) Kí ló máa wá ṣẹlẹ̀?
Àìsàn kò ní sí mọ́. “Kò sí ẹnì kankan tó ń gbé ibẹ̀ tó máa sọ pé: ‘Ara mi ò yá.’ A ti máa dárí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn èèyàn tó ń gbé ilẹ̀ náà jì wọ́n.”—Àìsáyà 33:24.
Ikú ò ní máa pọ́n ọmọ aráyé lójú mọ́. “Ó máa gbé ikú mì títí láé, Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sì máa nu omijé kúrò ní ojú gbogbo èèyàn.”—Àìsáyà 25:8.
Àwọn èèyàn máa wà láàyè títí láé. “Ìyè àìnípẹ̀kun ni ẹ̀bùn tí Ọlọ́run ń fúnni nípasẹ̀ Kristi Jésù Olúwa wa.”—Róòmù 6:23.
Àwọn tó ti kú máa jíǹde. “Àjíǹde àwọn olódodo àti àwọn aláìṣòdodo yóò wà.” (Ìṣe 24:15) Ìràpadà Jésù máa mú kó ṣeé ṣe fáwọn tó ti kú láti jíǹde.
Báwo ni Ọlọ́run ṣe máa ṣe gbogbo nǹkan yìí?
Ó MÁA MÚ KÍ ÌJỌBA PÍPÉ ṢÀKÓSO AYÉ
Ìjọba ọ̀run ni Ọlọ́run máa lò láti mú ohun tó ní lọ́kàn ṣẹ fún ayé yìí àti àwa èèyàn, Ọlọ́run sì ti yan Jésù Kristi láti jẹ́ Ọba Ìjọba náà. (Sáàmù 110:1, 2) Ìjọba yẹn ni Jésù kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ láti máa gbàdúrà fún nígbà tó sọ pé: “Baba wa tí ń bẹ ní ọ̀run, . . . kí Ìjọba rẹ dé.”—Mátíù 6:9, 10.
Ìjọba Ọlọ́run máa ṣàkóso ayé, á sì mú gbogbo wàhálà àti ìyà kúrò. Torí náà, Ìjọba yìí gangan ló máa mú ìtura bá aráyé! Ìdí nìyẹn tí Jésù ṣe fìtara wàásù “ìhìn rere Ìjọba náà” nígbà tó wà láyé, ó sì sọ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ pé káwọn náà ṣe bẹ́ẹ̀.—Mátíù 4:23; 24:14.
Torí pé Jèhófà Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ àwa èèyàn ló ṣe ṣèlérí pé òun máa ṣe gbogbo àwọn ohun àgbàyanu yìí fún wa. Ṣé ó wù ẹ́ láti mọ Ọlọ́run yìí, kó o sì sún mọ́ ọn? Tó o bá sún mọ́ Ọlọ́run, àǹfààní wo ló máa ṣe ẹ́? Àpilẹ̀kọ tó kàn máa ṣàlàyé.
ÀWỌN NǸKAN WO NI ỌLỌ́RUN MÁA ṢE? Ọlọ́run máa mú àìsàn àti ikú kúrò, ó máa lo Ìjọba rẹ̀ láti mú kí aráyé wà níṣọ̀kan, ó sì máa sọ ayé di Párádísè