Àǹfààní Wo Lo Máa Rí Tó O Bá Mọ Ọlọ́run?
Àwọn àpilẹ̀kọ tá a ti gbé yẹ̀ wò nínú ìwé yìí ti jẹ́ ká rí ìdáhùn ìbéèrè náà, Ta ni Ọlọ́run? Ìdáhùn tá a kọ́kọ́ rí nínú Bíbélì ni pé Jèhófà ni orúkọ Ọlọ́run, ìfẹ́ ló sì ta yọ nínú àwọn ìwà àti ìṣe ẹ̀. A tún sọ̀rọ̀ nípa àwọn ohun tó ti ṣe àtàwọn nǹkan iyebíye tó ṣì máa ṣe fáwa èèyàn lọ́jọ́ iwájú. Ọ̀pọ̀ nǹkan ṣì wà tó o máa kọ́ nípa Ọlọ́run, àmọ́ o lè máa ronú pé, àǹfààní wo ló máa ṣe ẹ́ tó o bá kẹ́kọ̀ọ́ sí i nípa Ọlọ́run?
Jèhófà ṣèlérí pé ‘tá a bá wá òun, òun máa jẹ́ ká rí òun.’ (1 Kíróníkà 28:9) Ohun tíyẹn túmọ̀ sí ni pé bó o ṣe túbọ̀ ń mọ Ọlọ́run, wàá di “ọ̀rẹ́ rẹ̀ tímọ́tímọ́.” (Sáàmù 25:14) Oò rí i pé àǹfààní àrà ọ̀tọ̀ gbáà nìyẹn máa jẹ́! Àwọn àǹfààní wo là ń sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀?
Wàá ní ayọ̀ tòótọ́. Bíbélì pe Jèhófà ní “Ọlọ́run aláyọ̀.” (1 Tímótì 1:11) Torí náà, tó o bá sún mọ́ ọn, tó o sì ń fara wé e, wàá ní ayọ̀ tòótọ́. Ayọ̀ yìí á hàn lójú ẹ, wàá máa ronú lọ́nà tó tọ́, ọkàn ẹ á sì balẹ̀. (Sáàmù 33:12) Ọlọ́run tún máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ kí ayé ẹ lè ládùn kó sì lóyin. Kíyẹn lè ṣeé ṣe, á kọ́ ẹ láti yẹra fáwọn ìwà tó lè ba ayé ẹ jẹ́, á tọ́ ẹ sọ́nà láti máa hùwà rere àti bó o ṣe lè máa ṣe dáadáa sáwọn èèyàn. Níkẹyìn, ìwọ fúnra ẹ á lè sọ bíi ti onísáàmù náà pé: “Sísúnmọ́ Ọlọ́run dára fún mi.”—Sáàmù 73:28.
Ọlọ́run á bójú tó ẹ, á sì máa ṣìkẹ́ ẹ. Jèhófà ṣèlérí fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé: “Màá fún ọ ní ìmọ̀ràn pẹ̀lú ojú mi lára rẹ.” (Sáàmù 32:8) Ohun tí Jèhófà ń sọ ni pé òun máa fìfẹ́ bójú tó àwọn ìránṣẹ́ òun lẹ́nì kọ̀ọ̀kan, òun á sì pèsè ohun tí wọ́n nílò lẹ́nì kọ̀ọ̀kan. (Sáàmù 139:1, 2) Tó o bá sapá kí àárín ìwọ àti Ọlọ́run lè gún régé, wàá rí i pé á máa dúró tì ẹ́ nígbà gbogbo.
Ọjọ́ ọ̀la ẹ máa dáa. Yàtọ̀ sí pé Ọlọ́run máa jẹ́ kó o láyọ̀ kí ayé ẹ sì dáa ní báyìí, á tún mú kí ọjọ́ ọ̀la ẹ dáa gan-an. (Àìsáyà 48:17, 18) Bíbélì fi dá wa lójú pé: “Èyí túmọ̀ sí ìyè àìnípẹ̀kun, pé kí wọ́n wá mọ ìwọ Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo àti Jésù Kristi, ẹni tí o rán.” (Jòhánù 17:3) Nínú ayé tó kún fún wàhálà yìí, ńṣe ni ìrètí àgbàyanu yìí dà bí ìdákọ̀ró, ‘ó dájú, ó sì fìdí múlẹ̀.’—Hébérù 6:19.
Àwọn nǹkan tá a sọ yìí kàn jẹ́ díẹ̀ lára ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìdí tó fi yẹ ká túbọ̀ mọ Ọlọ́run ká sì sún mọ́ ọn. A rọ̀ ẹ́ pé kó o bá ọ̀kan lára àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà sọ̀rọ̀ tàbí kó o lọ sí ìkànnì jw.org/yo kó o lè rí àwọn ìsọfúnni síwájú sí i.