Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ta Ni Ọlọ́run?

Ta Ni Ọlọ́run?

Ọ̀pọ̀ èèyàn máa ń sọ pé àwọn gba Ọlọ́run gbọ́. Ṣùgbọ́n tó o bá bi wọ́n pé ta ni Ọlọ́run, oríṣiríṣi ìdáhùn ni wọ́n á fún ẹ. Àwọn kan gbà pé Ọlọ́run jẹ́ adájọ́ tó burú tí kò mọ̀ ju kó máa fi ìyà ẹ̀ṣẹ̀ jẹni. Àmọ́, àwọn míì kà á sí ẹlẹ́yinjú àánú tó kàn ṣáà máa ń dárí jini láìka ẹ̀ṣẹ̀ téèyàn bá dá sí. Síbẹ̀ àwọn míì gbà pé Ọlọ́run jìnnà sí wa, kò sì rí tiwa rò. Pẹ̀lú oríṣiríṣi èrò táwọn èèyàn ní yìí, ọ̀pọ̀ gbà pé kò ṣeé ṣe láti mọ Ọlọ́run.

Kí nìdí tó fi yẹ kó o mọ Ọlọ́run? Ìdí ni pé tó o bá mọ irú ẹni tí Ọlọ́run jẹ́, á jẹ́ kí ìgbé ayé ẹ túbọ̀ dáa, wàá sì nírètí. (Ìṣe 17:26-28) Bó o bá ṣe sún mọ́ Ọlọ́run tó, bẹ́ẹ̀ lòun náà á ṣe nífẹ̀ẹ́ rẹ tó, á sì ràn ẹ́ lọ́wọ́. (Jémíìsì 4:8) Èyí tó wá ṣe pàtàkì jù ni pé ìmọ̀ pípéye nípa Ọlọ́run máa jẹ́ kó o ní ìyè ayérayé.​—Jòhánù 17:3.

Báwo lo ṣe lè mọ Ọlọ́run? Ronú nípa ẹnì kan tó o mọ̀ dáadáa, bóyá ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ kan. Báwo lẹ ṣe di ọ̀rẹ́? Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé orúkọ ẹ̀ lo kọ́kọ́ mọ̀, lẹ́yìn náà o bẹ̀rẹ̀ sí í mọ ìwà ẹ̀, ohun tó fẹ́, ohun tí kò fẹ́, ohun tó ti gbé ṣe, àwọn nǹkan tó fẹ́ ṣe lọ́jọ́ iwájú àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Lọ́rọ̀ kan, ohun tó jẹ́ kó o sún mọ́ ọn ni pé, o mọ irú ẹni tó jẹ́.

Bákan náà, a lè mọ Ọlọ́run tá a bá wá ìdáhùn àwọn ìbéèrè yìí:

A dìídì ṣe ìwé yìí kó o lè rí bí Bíbélì ṣe dáhùn àwọn ìbéèrè yẹn. Àwọn àpilẹ̀kọ yìí máa jẹ́ kó o mọ irú ẹni tí Ọlọ́run jẹ́ àti àǹfààní tí wàá rí tó o bá sún mọ́ ọn.