Ayé Tuntun Là Ń Fẹ́!
Ọ̀gbẹ́ni António Guterres, tó jẹ́ akọ̀wé àgbà fún Àjọ Ìṣọ̀kan Àgbáyé sọ pé: “Ayé yìí ti dojú rú gan-an.” Ṣé o gbà pé òótọ́ lohun tí ọ̀gbẹ́ni yẹn sọ?
Àwọn nǹkan tó ń bani lọ́kàn jẹ́ là ń gbọ́ nínú ìròyìn
Àìsàn àti àjàkálẹ̀ àrùn
Ìmìtìtì ilẹ̀, omíyalé àtàwọn àjálù míì
Ipò òṣì àti ebi
Bíba àyíká jẹ́ àti kí ayé máa gbóná ju bó ṣe yẹ lọ
Ìwà ọ̀daràn àti ìwà ìbàjẹ́ àwọn aláṣẹ
Ogun
Ó ti wá hàn kedere báyìí pé, ayé tuntun là ń fẹ́. Àwọn nǹkan tí aráyé ń fẹ́ ni
Ara tó jí pépé
Ààbò àti ìfọ̀kànbalẹ̀ fún gbogbo èèyàn
Oúnjẹ tó pọ̀ rẹpẹtẹ
Àyíká tó tura
Ìdájọ́ òdodo fún gbogbo èèyàn
Àlàáfíà kárí ayé
Kí ni ayé tuntun?
Kí ló máa ṣẹlẹ̀ sí ayé tá a wà yìí?
Kí ló yẹ ká ṣe tá a bá fẹ́ máa gbénú ayé tuntun?
Nínú ìwé yìí, Bíbélì máa dáhùn àwọn ìbéèrè yìí àtàwọn ìbéèrè míì bí irú èyí lọ́nà tó ń fini lọ́kàn balẹ̀.