Ayé Máa Tó Di Párádísè!
Ọlọ́run dá ayé káwọn olódodo lè máa gbé inú ẹ̀ títí láé. (Sáàmù 37:29) Ó fi tọkọtaya àkọ́kọ́, Ádámù àti Éfà sínú ọgbà kan tó rẹwà tó ń jẹ́ Édẹ́nì. Ó ní kí àwọn àtàwọn ọmọ wọn máa tọ́jú ẹ̀, kí wọ́n sì sọ gbogbo ayé di Párádísè.—Jẹ́nẹ́sísì 1:28; 2:15.
Ọlọ́run fẹ́ kí ayé di Párádísè, àmọ́ báyé ṣe rí lónìí yàtọ̀ pátápátá sí ohun tí Ọlọ́run fẹ́. Ṣùgbọ́n Ọlọ́run ò tíì yí ohun tó ní lọ́kàn pa dà. Báwo ló ṣe máa wá ṣe ohun tó ní lọ́kàn níbẹ̀rẹ̀? Gẹ́gẹ́ bá a ṣe rí i nínú àwọn ẹ̀kọ́ tó ṣáájú, Ọlọ́run kò ní pa ayé run. Kàkà kó pa á run, ńṣe ló máa jẹ́ káwọn olódodo máa gbé inú rẹ̀. Tí Ọlọ́run bá ṣe ohun tó ní lọ́kàn, báwo ni ayé ṣe máa rí?
Ìjọba kan ṣoṣo á máa ṣàkóso gbogbo ayé
Láìpẹ́, tí ìjọba Ọlọ́run bá bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso gbogbo aráyé, ayé máa di ibi tí gbogbo èèyàn á máa gbé pa pọ̀ níṣọ̀kan, wọ́n á sì máa ṣiṣẹ́ tó ń fúnni láyọ̀. Ọlọ́run ti yan Jésù Kristi láti ṣàkóso ayé. Lóde òní, àwọn aláṣẹ ayé ò bìkítà nípa àwọn èèyàn, àmọ́ ìgbà gbogbo ni Jésù á máa ṣohun tó dáa fáwọn èèyàn. Jésù máa fi ìfẹ́ ṣàkóso àwọn èèyàn, ó máa jẹ́ Ọba olóore tó lójú àánú, ó sì máa dá ẹjọ́ àwọn èèyàn bó ṣe tọ́.—Àìsáyà 11:4.
Gbogbo èèyàn máa wà níṣọ̀kan
Nínú ayé tuntun, àwọn èèyàn ò ní máa bára wọn jà torí pé ẹ̀yà wọn yàtọ̀ tàbí torí pé orílẹ̀-èdè wọn yàtọ̀ síra, bó ṣe máa ń ṣẹlẹ̀ lónìí. Ńṣe ni gbogbo aráyé máa wà níṣọ̀kan. (Ìfihàn 7:9, 10) Gbogbo àwọn tó máa wà láyé á nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run, wọ́n á nífẹ̀ẹ́ ọmọnìkejì wọn, wọ́n á sì fọwọ́ sowọ́ pọ̀ láti máa tọ́jú ayé bí Ọlọ́run ṣe fẹ́ níbẹ̀rẹ̀.—Sáàmù 115:16.
Àjálù ò ní ṣẹlẹ̀ mọ́
Nígbà tí Ìjọba Ọlọ́run bá bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso ayé, Ẹlẹ́dàá wa máa rí sí i pé àwọn àjálù ò ní sí mọ́, irú bíi ìmìtìtì ilẹ̀, ìjì líle àti àkúnya omi. (Sáàmù 24:1, 2) Nígbà tí Jésù wà láyé, ó fi díẹ̀ lára agbára tí Ọlọ́run fún un hàn nígbà tó mú kí ìjì líle pa rọ́rọ́. (Máàkù 4:39, 41) Nígbà àkóso Kristi, àwọn èèyàn ò ní máa bẹ̀rù pé àjálù lè ṣẹlẹ̀. Ìjọba Ọlọ́run tún máa mú kí àlàáfíà wà láàárín èèyàn àti ẹranko bó ṣe rí níbẹ̀rẹ̀, àwọn èèyàn ò sì ní ṣe ohun tó máa ba ayé àti àyíká rẹ̀ jẹ́ mọ́.—Hósíà 2:18.
Ara wa máa jí pépé, ọ̀pọ̀ oúnjẹ sì máa wà
Ara gbogbo èèyàn máa jí pépé. Àwọn èèyàn ò ní máa ṣàìsàn, wọn ò ní darúgbó, wọn ò sì ní kú mọ́. (Àìsáyà 35:5, 6) Àwọn èèyàn máa gbádùn àyíká tó rẹwà tó sì mọ́ tónítóní bí irú èyí tí Ádámù àti Éfà gbádùn nínú ọgbà Édẹ́nì. Nínú ayé tuntun, ilẹ̀ máa mú ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ oúnjẹ jáde bó ṣe rí ní ọgbà Édẹ́nì, gbogbo èèyàn á sì ní oúnjẹ tó pọ̀ láti jẹ. (Jẹ́nẹ́sísì 2:9) Gbogbo àwọn èèyàn tó máa wà ní Párádísè máa “jẹun ní àjẹyó” bíi ti àwọn èèyàn Ọlọ́run ní Ísírẹ́lì àtijọ́.—Léfítíkù 26:4, 5.
Àlàáfíà àti ààbó tó dájú
Nígbà tí ìjọba Ọlọ́un bá ń ṣàkóso ayé, gbogbo èèyàn máa wà ní àlàáfíà, wọ́n á sì má hùwà tó dáa sí ara wọn. Kò ní sí ogun mọ́, àwọn èèyàn ò ní máa ṣi agbára lò mọ́, gbogbo èèyàn á ní ohun tó yẹ kí wọ́n ní. Bíbélì sọ pé: “Kálukú wọn máa jókòó lábẹ́ àjàrà rẹ̀ àti lábẹ́ igi ọ̀pọ̀tọ́ rẹ̀, ẹnì kankan ò sì ní dẹ́rù bà wọ́n.”—Míkà 4:3, 4.
Gbogbo èèyàn máa ní ilé àti iṣẹ́ tó dáa
Ìdílé kọ̀ọ̀kan ló máa ní ilé tiwọn, ẹ̀rù ò ní máa bà wọ́n pé wọ́n á lé wọn kúrò níbẹ̀, a sì máa jadùn iṣẹ́ ọwọ́ wa. Bíbélì sọ pé àwọn tó máa wà nínú ayé tuntun tí Ọlọ́run ṣèlérí “ò ní ṣiṣẹ́ kára lásán.”—Àìsáyà 65:21-23.
Ẹ̀kọ́ tó dára jù lọ làwọn èèyàn á máa kọ́
Bíbélì sọ pé: “Ó dájú pé ìmọ̀ Jèhófà máa bo ayé, bí omi ṣe ń bo òkun.” (Àìsáyà 11:9) Àwọn tó máa wà nínú ayé tuntun máa kẹ́kọ̀ọ́ lára ọgbọ́n tí kò lópin tí Ẹlẹ́dàá wa Jèhófà ní. Wọ́n á tún kẹ́kọ̀ọ́ lára àwọn nǹkan tó rẹwà tí Ọlọ́run dá. Wọn ò ní lo ìmọ̀ wọn láti fi ṣe àwọn ohun ìjà, wọn ò sì ní lo ìmọ̀ náà láti fi pa àwọn èèyàn lára. (Àìsáyà 2:4) Kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n á kọ́ bí wọ́n á ṣe máa gbé ní àlàáfíà pẹ̀lú ara wọn àti bí wọ́n á ṣe máa ṣètọ́jú ayé.—Sáàmù 37:11.
Àwọn èèyàn máa wà láàyè títí láé
Ọlọ́run fara balẹ̀ dá ayé fún àwa èèyàn ká lè máa gbádùn ara wa lójoojúmọ́. Ohun tó fẹ́ ni pé káwa èèyàn máa gbé ayé títí láé. (Sáàmù 37:29; Àìsáyà 45:18) Kí ohun tí Ọlọ́run ní lọ́kàn bàa lè ṣẹ, ó “máa gbé ikú mì títí láé.” (Àìsáyà 25:8) Bíbélì sọ pé, “Ikú ò ní sí mọ́, kò ní sí ọ̀fọ̀ tàbí ẹkún tàbí ìrora mọ́.” (Ìfihàn 21:4) Ọlọ́run máa dáàbò bo àwọn onígbọràn nígbà tó bá pa àwọn èèyàn burúkú run, ó sì máa jí àìmọye èèyàn tó ti kú dìde sínú ayé tuntun. Àwọn yìí ni Ọlọ́run máa fún láǹfààní láti máa gbé ayé títí láé.—Jòhánù 5:28, 29; Ìṣe 24:15.
A rọ̀ ẹ́ pé kó o kẹ́kọ̀ọ́ sí i nípa bó o ṣe lè la òpin ayé já, kó o sì máa gbé inú ayé tuntun tó máa dé láìpẹ́. Sọ fún Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan pé kó jẹ́ kẹ́ ẹ jọ máa jíròrò Bíbélì lọ́fẹ̀ẹ́ nínú ìwé Gbádùn Ayé Rẹ Títí Làé!