Ìgbà Wo Ni Jésù Sọ Pé Òpin Máa Dé?
Nínú ori tó ṣáájú èyí, a ti kẹ́kọ̀ọ́ pé tí Bíbélì bá sọ pé òpin ayé máa dé, kì í ṣe ohun tó ń sọ ni pé ayé fúnra ẹ̀ máa pa run, bẹ́ẹ̀ ni kò túmọ̀ sí pé ìran èèyàn máa pa run. Àmọ́, ohun tó ń sọ ni òpin ìjọba àwọn èèyàn burúkú, gbogbo iṣẹ́ ọwọ́ wọn àti gbogbo àwọn tó ń tì wọ́n lẹ́yìn. Ṣùgbọ́n, ṣé Bíbélì tiẹ̀ sọ ìgbà tí Ìjọba àwọn èèyàn tó ń ni aráyé lára yìí máa dópin?
WO OHUN MÉJÌ TÍ JÉSÙ SỌ NÍPA ÒPIN AYÉ:
“Torí náà, ẹ máa ṣọ́nà, torí pé ẹ ò mọ ọjọ́ tàbí wákàtí náà.”—MÁTÍÙ 25:13.
“Ẹ máa wọ̀nà, ẹ wà lójúfò, torí ẹ ò mọ ìgbà tí àkókò tí a yàn jẹ́.”—MÁÀKÙ 13:33.
Torí náà, kò sẹ́nì kankan láyé tó lè sọ pé ìgbà báyìí ni òpin ayé máa dé. Àmọ́, Ọlọ́run ti ‘yan àkókò kan,’ ìyẹn “ọjọ́ àti wákàtí” tí òpin máa dé. (Mátíù 24:36) Ṣé ìyẹn wá túmọ̀ sí pé kò sí bá a ṣe lè mọ̀ tí òpin bá ti ń sún mọ́lé ni? A lè mọ̀. Jésù sọ àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ kan tó máa jẹ́ káwọn ọmọlẹ́yìn ẹ̀ mọ̀ tí òpin bá ti sún mọ́lé.
ÀMÌ TÍ JÉSÙ SỌ
Àwọn ohun tí Jésù sọ pé ó máa ṣẹlẹ̀ yẹn ló máa jẹ́ àmì pé “ìparí ètò àwọn nǹkan” tàbí òpin ayé ti sún mọ́lé. Jésù sọ pé: “Orílẹ̀-èdè máa dìde sí orílẹ̀-èdè àti ìjọba sí ìjọba, àìtó oúnjẹ àti ìmìtìtì ilẹ̀ sì máa wà láti ibì kan dé ibòmíì.” (Mátíù 24:3, 7) Ó tún sọ pé “àjàkálẹ̀ àrùn” máa wà. (Lúùkù 21:11) Ṣé ò ń rí àwọn nǹkan tí Jésù sọ tẹ́lẹ̀ pé ó máa ṣẹ̀lẹ̀?
Lára àwọn nǹkan tó ti ṣọṣẹ́ gan-an lákòókò yìí ni ogun, ìyàn, ìmìtìtì ilẹ̀ àtàwọn àìsàn burúkú lórísiríṣi. Bí àpẹẹrẹ lọ́dún 2004, ìmìtìtì ilẹ̀ kan tó lágbára ṣẹlẹ̀ lábẹ́ Òkun Íńdíà. Èyí mú kí àkúnya omi ṣẹlẹ̀, ó sì pa nǹkan bíi ẹgbẹ̀rún lọ́nà igba ó lé mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (225,000) èèyàn. Láàárín ọdún mẹ́ta, àjàkálẹ̀ àrùn kòrónà (COVID-19) pa àwọn èèyàn tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó mílíọ́nù méje kárí ayé. Jésù sọ pé táwọn nǹkan yìí bá ti ń ṣẹlẹ̀, òpin ayé ti sún mọ́lé nìyẹn.
“ÀWỌN ỌJỌ́ ÌKẸYÌN”
Bíbélì pe àkókò tó máa ṣáájú òpin ayé ní “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn.” (2 Pétérù 3:3, 4) Tímótì kejì orí kẹta ẹsẹ kìíní sí ìkarùn-ún sọ pé ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn, ìwà burúkú àwọn èèyàn á máa pọ̀ sí i. (Wo àpótí náà “ Ohun Tó Máa Ṣẹlẹ̀ Kí Òpin Tó Dé.”) Ṣé ìwọ náà ń rí àwọn èèyàn tí wọn ò mọ̀ ju tara wọn nìkan lọ, tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ owó, tí wọ́n burú gan-an, tí wọn ò sì nífẹ̀ẹ́ àwọn ẹlòmíì? Ìwà táwọn èèyàn ń hù yìí náà tún jẹ́ ẹ̀rí pé a ti sún mọ́ òpin ayé gan-an.
Ìgbà wo làwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí máa parí? Bíbélì sọ pé “ìgbà díẹ̀ ló kù.” Lẹ́yìn náà, Ọlọ́run máa “run àwọn tó ń run ayé.”—Ìfihàn 11:15-18, àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé; 12:12.
AYÉ MÁA TÓ DI PÁRÁDÍSÈ!
Ọlọ́run ti dá ọjọ́ àti wákàtí tó máa pa àwọn èèyàn burúkú run. (Mátíù 24:36) Ṣùgbọ́n ìròyìn ayọ̀ míì tún ni pé Ọlọ́run “kò fẹ́ kí ẹnikẹ́ni pa run.” (2 Pétérù 3:9) Ìdí nìyẹn tó fi ń fún gbogbo èèyàn láǹfààní láti kẹ́kọ̀ọ́ nípa òun kí wọ́n sì máa tẹ̀ lé àwọn ìlànà òun. Èyí fi hàn pé Ọlọ́run fẹ́ ká là á já tí òpin ayé bá dé, ká sì máa gbé nínú ayé tuntun nígbà tí ayé bá di Párádísè.
Ọlọ́run ti ṣètò báwọn èèyàn kárí ayé ṣe máa kẹ́kọ̀ọ́ nípa ohun tó yẹ kí wọ́n ṣe, tí wọ́n bá fẹ́ wà lára àwọn táá máa gbé inú ayé tuntun lábẹ́ Ìjọba rẹ̀. Jésù sọ pé a máa wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run “ní gbogbo ilẹ̀ ayé tí à ń gbé.” (Mátíù 24:14) Lọ́dún 2019, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kárí ayé fi ohun tó lé ní bílíọ́nù méjì wákàtí wàásù ìhìn rere fáwọn èèyàn, wọ́n sì ń kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kí wọ́n lè mọ̀ pé ọ̀la ṣì ń bọ̀ wá dáa. Jésù sọ pé a máa ṣe iṣẹ́ ìwàásù kárí ayé kí òpin tó dé.
Ìjọba èèyàn ti fẹ́ẹ̀ dópin. Àmọ́, inú wa dùn pé a lè la òpin ayé já, ká sì wà lára àwọn táá máa gbé ayé nínú Párádísé tí Ọlọ́run ṣèlérí. Nínú orí tó kàn, a máa sọ̀rọ̀ nípa ohun tó yẹ ká ṣe ká lè wà lára àwọn táá máa gbé inú ayé tuntun.
Àsọtẹ́lẹ̀ tí Jésù sọ nípa “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” fi wá lọ́kàn balẹ̀ pé ọ̀la ń bọ̀ wá dáa