Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ṣé Ayé Yìí Máa Pa Run Ni?

Ṣé Ayé Yìí Máa Pa Run Ni?

Ó ṣeé ṣe kó o ti kà á rí nínú Bíbélì pé òpin ayé máa dé. (1 Jòhánù 2:17) Ṣé ohun tí Bíbélì ń sọ ni pé kò ní sí èèyàn kankan mọ́ láyé? Ṣé ayé máa pa run pátápátá tí kò sì ní sóhun alààyè kankan níbẹ̀ ni?

BÍBÉLÌ JẸ́ KÁ MỌ̀ PÉ RÁRÁ NI ÌDÁHÙN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ MÉJÈÈJÌ YÌÍ.

Awọn Nǹkan Wo Ni Kò Ní Pa Run?

ÌRAN ÈÈYÀN

Ohun tí Bíbélì sọ: ‘Ọlọ́run ò kàn dá ayé lásán, àmọ́ ó dá a ká lè máa gbé inú rẹ̀.’​—ÀÌSÁYÀ 45:18.

AYÉ

Ohun tí Bíbélì sọ: “Ìran kan ń lọ, ìran kan sì ń bọ̀, àmọ́ ayé wà títí láé.”​—ONÍWÀÁSÙ 1:4.

OHUN TÓ TÚMỌ̀ SÍ: Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé ayé yìí ò ní pa run àti pé títí láé làwọn èèyàn á máa gbénú ẹ̀. Tó bá rí bẹ́ẹ̀, kí ni òpin ayé?

RONÚ LÓRÍ KÓKÓ YÌÍ: Bíbélì fi òpin ayé tó ń bọ̀ wé ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà ayé Nóà. Nígbà yẹn, “ìwà ipá” ló kún gbogbo ayé. (Jẹ́nẹ́sísì 6:13) Àmọ́, olódodo ni Nóà. Torí náà Ọlọ́run dá Nóà àti ìdílé rẹ̀ sí, àmọ́ ó fi ìkún omi pa àwọn èèyàn burúkú run. Nígbà tí Bíbélì ń sọ̀rọ̀ nípa ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà yẹn, ó ní: ‘Ayé ìgbà yẹn pa run nígbà tí ìkún omi bò ó mọ́lẹ̀.’ (2 Pétérù 3:6) Bí ayé ìgbà yẹn ṣe dópin nìyẹn. Àmọ́ kí ló pa run? Àwọn èèyàn burúkú tó wà láyé nígbà yẹn ló pa run, kì í ṣe ayé. Torí náà, nígbà tí Bíbélì sọ pé ayé máa dópin, kì í ṣe ayé fúnra ẹ̀ ló ń sọ pé ó máa pa run. Kàkà bẹ́ẹ̀, òpin àwọn èèyàn burúkú àti gbogbo iṣẹ́ ọwọ́ wọn ló ń sọ.

Àwọn Nǹkan Wo Ló Máa Dópin?

ÌṢÒRO ÀTI ÌWÀ BURÚKÚ

Ohun tí Bíbélì sọ: “Láìpẹ́, àwọn ẹni burúkú ò ní sí mọ́; wàá wo ibi tí wọ́n wà tẹ́lẹ̀. Wọn ò ní sí níbẹ̀. Àmọ́ àwọn oníwà pẹ̀lẹ́ ni yóò jogún ayé, inú wọn yóò sì máa dùn jọjọ nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ àlàáfíà.”​—SÁÀMÙ 37:​10, 11.

OHUN TÓ TÚMỌ̀ SÍ: Ìkún Omi tó ṣẹlẹ̀ nígbà ayé Nóà fòpin sí ìwà burúkú tó ń ṣẹlẹ̀ láyé nígbà yẹn. Àmọ́ nígbà tó yá àwọn kan tún bẹ̀rẹ̀ sí í hùwà burúkú, wọ́n sì ń ni àwọn èèyàn lára. Ṣùgbọ́n láìpẹ́, Ọlọ́run máa fòpin sí gbogbo ìwà burúkú pátápátá. Bí onísáàmù yẹn ṣe sọ: “Àwọn ẹni burúkú ò ní sí mọ́.” Ọlọ́run máa lo Ìjọba rẹ̀ láti fòpin sí gbogbo ìwà burúkú. Látọ̀run ni Ìjọba náà á ti máa ṣàkóso ayé. Gbogbo àwọn tó máa wà láyé nígbà yẹn ló sì máa jẹ́ olódodo.

RONÚ LÓRÍ KÓKÓ YÌÍ: Ṣé àwọn tó jẹ́ aláṣẹ ayé báyìí máa fara mọ́ ọn pé kí Ìjọba Ọlọ́run máa ṣàkóso? Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé wọn ò ní fara mọ́ ọn. Ohun tí wọ́n máa ṣe ò ní bọ́gbọ́n mu rárá, ńṣe ni wọ́n máa dojú ìjà kọ Ìjọba Ọlọ́run. (Sáàmù 2:2) Kí ló máa wá ṣẹlẹ̀? Ọlọ́run máa pa gbogbo ìjọba èèyàn run, Ìjọba Ọlọ́run “nìkan ló sì máa dúró títí láé.” (Dáníẹ́lì 2:44) Kí nìdí tó fi yẹ kí Ìjọba èèyàn dópin?

OHUN TÁ A FẸ́​—Kí Ìjọba Èèyàn Dópin

Ohun tí Bíbélì sọ: “Kò sí ní ìkáwọ́ èèyàn tó ń rìn láti darí ìṣísẹ̀ ara rẹ̀.”​—JEREMÁYÀ 10:23.

OHUN TÓ TÚMỌ̀ SÍ: Ọlọ́run ò dá àwa èèyàn pé ká máa ṣàkóso ara wa. Àwọn tó wà nípò àṣẹ ò ṣàkóso àwọn èèyàn lọ́nà tó dáa, wọn ò sì tún mọ bí wọ́n á ṣe yanjú ìṣòro àwọn èèyàn.

RONÚ LÓRÍ KÓKÓ YÌÍ: Ìwé Britannica Academic sọ pé ó jọ pé bí ìjọba orílẹ̀-èdè kọ̀ọ̀kan ṣe ń dá ṣe ìjọba tiẹ̀ ni kò jẹ́ ká lè “yanjú àwọn ìṣòro tó kan gbogbo ayé, bí ipò òṣì, ebi, àrùn, omíyalé, ìmìtìtì ilẹ̀ àtàwọn àjálù míì, títí kan ogun àti ìwà ọ̀daràn.” Ìwé yẹn tún sọ pé: “Àwọn kan . . . gbà pé káwọn ìṣòro yìí tó lè yanjú, àfi kí ìjọba kan ṣoṣo máa ṣàkóso gbogbo ayé.” Àmọ́, òótọ́ ibẹ̀ ni pé tí gbogbo ìjọba èèyàn bá tiẹ̀ fìmọ̀ ṣọ̀kan tí wọ́n sì yan ẹnì kan ṣoṣo láti máa ṣàkóso ayé, àwọn èèyàn aláìpé láá ṣì máa wà nípò àṣẹ, bẹ́ẹ̀ sì rèé kò sí bí èèyàn aláìpé ṣe lè yanjú àwọn ìṣòro tá a sọ yẹn. Ìjọba Ọlọ́run nìkan ló lè yanjú gbogbo ìṣòro ayé, táwọn ìṣòro náà ò sì tún ní gbérí mọ́ láé!

Torí náà, nígbà tí Bíbélì ń sọ̀rọ̀ nípa òpin ayé, ohun tó ń sọ ni òpin àwọn èèyàn burúkú àti gbogbo iṣẹ́ ọwọ́ wọn. Èyí jẹ́ ká rí i pé òpin ayé kì í ṣohun tó yẹ káwọn èèyàn rere máa bẹ̀rù rárá. Kàkà bẹ́ẹ̀, ohun tó yẹ ká máa retí ni, torí pé ńṣe ni ayé burúkú yìí máa dópin, tí Ìjọba Ọlọ́run sì máa sọ ayé di tuntun!

Ìgbà wo ni gbogbo nǹkan yìí máa ṣẹlẹ̀? Wàá rí ohun tí Bíbélì sọ ní orí tó kàn.