ILÉ ÌṢỌ́ No. 3 2019 | Ṣé Ìgbésí Ayé Ẹ̀dá Kò Jù Báyìí Náà Lọ?

Ibéèrè tí ọ̀pọ̀ èèyàn máa ń béèrè ni, ìdáhùn tí èèyàn bá sì fara mọ́ lè pinnu bí ìgbésí ayé ṣe máa rí.

Ikú Ò Ṣeé Yẹ̀ Sílẹ̀

Kò sí bá a ṣe lè gbìyànjú tó, a ò lè gba ara wa lọ́wọ́ ọjọ́ ogbó àti ikú. Ṣé ìgbésí ayé ẹ̀dá kò jù báyìí náà lọ?

Àwọn Èèyàn Ń Wá Ẹ̀mí Gígùn

Àwọn onímọ̀ nípa ohun alààyè àti àbùdá èèyàn ń sapá láti wádìí ohun tó ń fà á téèyàn fi ń darúgbó. Kí ni wọ́n ti ṣàwárí?

Ọlọ́run Ò Dá Wa Pé Ká Máa Kú

Ta ni kò wù pé kó máa gbádùn ayé rẹ̀ pẹ̀lú ayọ̀ àti àlàáfíà?

Kí Nìdí Tá A Fi Ń Darúgbó Tá A Sì Ń Kú?

Ọlọ́run ò ní in lọ́kan pé kí àwa èèyàn máa kú. Nígbà tó dá àwọn òbí wa àkọ́kọ́, Ádámù àti Éfà, ó fún wọn ní ọpọlọ pípé àti ara pípé. Wọn ì bá wà títí dòní.

Báwo La Ṣe Máa Ṣẹ́gun Ikú?

Ọlọ́run fìfẹ́ ṣètò láti gba aráyé lọ́wọ́ ikú nípasẹ̀ ìràpadà tó san.

Bó O Ṣe Lè Gbé Ìgbé Ayé Tó Dára Jù Lọ

“Ọ̀nà” kan wà tó o lè gbà tó o bá fẹ́ gbádùn irú ìgbé ayé tí Ọlọ́run ń ṣètò fún àwọn tó nífẹ̀ẹ́ rẹ̀.

Bó O Ṣe Lè Gbádùn Ayé Rẹ Ní Báyìí

Báwo ni ìlànà Bíbélì ṣe lè jẹ́ kó o ní ìtẹ́lọ́rùn, láti mú kí ìgbéyàwó rẹ lágbára sí i àti láti fara da àìlera?

Kí Ló Máa Ṣẹlẹ̀ sí Àwọn Tó Ti Kú?

Bíbélì dáhùn ìbéèrè yìí.