Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ | BÍ ỌLỌ́RUN ṢE PA​—BÍBÉLÌ MỌ́

Ìdí Tí Bíbélì Fi Wà Títí Dòní

Ìdí Tí Bíbélì Fi Wà Títí Dòní

Bíbélì kò mà pa run. Ìdí nìyẹn tó o fi lè ra Bíbélì kó o sì kà á. Tó bá tún wá jẹ́ èyí tí ìtúmọ̀ rẹ̀ péye lò ń kà, á jẹ́ pé ojúlówó Bíbélì tó ṣe é gbára lé bíi ti ìpilẹ̀ṣẹ̀ lò ń kà yẹn. * Àmọ́ kí nìdí tí Bíbélì ṣì fi wà títí dòní láìka onírúurú ìṣòro tó ti là kọjá sí, irú bíi kó fúnra rẹ̀ bà jẹ́, àtakò gbígbóná táwọn kan ṣe àti bí àwọn kan ṣe gbìyànjú láti yí ọ̀rọ̀ inú rẹ̀ pa dà? Kí ló mú kí ìwé yìí ṣàrà ọ̀tọ̀?

“Ó ti wá dá mi lójú pé ẹ̀bùn látọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni Bíbélì tí mo ní”

Ọ̀pọ̀ àwọn tó ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ló fara mọ́ ohun tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Gbogbo Ìwé Mímọ́ ni Ọlọ́run mí sí.” (2 Tímótì 3:16) Wọ́n gbà pé ohun tó jẹ́ kí Bíbélì wà títí dòní ni pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni àti pé Ọlọ́run fúnra rẹ̀ ló pa á mọ́ tí kò jẹ́ kó pa run. Faizal, tá a fa ọ̀rọ̀ rẹ̀ yọ nínú àpilẹ̀kọ tó bẹ̀rẹ̀ ìwé yìí pinnu láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì fúnra rẹ̀, kó lè mọ ohun tó wà nínú rẹ̀. Ohun tó sì rí yà á lẹ́nu. Kò pẹ́ tó fi rí i pé ọ̀pọ̀ ẹ̀kọ́ èké tí àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì fi ń kọ́ni kò sí nínú Bíbélì rárá. Láfikún sí i, nígbà tó kẹ́kọ̀ọ́ nípa bí Ọlọ́run ṣe máa tún ayé yìí ṣe láìpẹ́, ó wọ̀ ọ́ lọ́kàn gan-an.

Ó sọ pé: “Ó ti wá dá mi lójú pé ẹ̀bùn látọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni Bíbélì tí mo ní. Ó ṣe tán, tí Ọlọ́run bá lè dá ayé àti ọ̀run, ṣé kò wá ní lágbára láti fún wa ní ìwé kan, kó sì pa á mọ́ fún wa? Tá a bá ní èrò tó yàtọ̀ síyẹn, á jẹ́ pé à ń fojú kéré agbára Ọlọ́run tó jẹ́ Olódùmarè nìyẹn! Ta wá lèmi tí màá fi fojú kéré agbára Ọlọ́run?”—Aísáyà 40:8.

^ ìpínrọ̀ 3 Wo àpilẹ̀kọ náà “Báwo Lo Ṣe Lè Mọ Bíbélì Tí Wọ́n Túmọ̀ Lọ́nà Tó Dára?” nínú Ilé Ìṣọ́ May 1, 2008.