TẸ̀ LÉ ÀPẸẸRẸ ÌGBÀGBỌ́ WỌN | DÁFÍDÌ
“Ti Jèhófà Ni Ìjà Ogun Náà”
DÁFÍDÌ dúró dáadáa kí àwọn ọmọ ogun tó ń sáré kọjá lára rẹ̀ má báa tì í ṣubú. Ẹ̀rù ń ba àwọn ọmọ ogun náà bí wọ́n ṣe ń sá kúrò lójú ogun. Kí ló ń bà wọ́n lẹ́rù? Dáfídì ń gbọ́ tí wọ́n ṣáà ń pe orúkọ ọkùnrin kan léraléra. Àṣé torí ọkùnrin gìrìwò kan ni wọ́n ṣe ń sá. Ọkùnrin ọ̀hún dúró sí pẹ̀tẹ́lẹ̀ náà, ó sì ga fíofío ju gbogbo wọn lọ. Ó ṣeé ṣe kí Dáfídì má tíì rí ẹni tó gá tó báyìí rí láyé rẹ̀.
Gòláyátì ni ọkùnrin náà! Dáfídì fojú ara rẹ̀ rí ohun tó fà á táwọn ọmọ ogun fi bẹ̀rù rẹ̀, ó ga gan-an, ó sì rí fìrìgbọ̀n. Kódà láìgbé aṣọ ogun wọ̀, ó wúwo ju àpapọ̀ ọkùnrin ńlá méjì lọ. Àmọ́ báyìí ó ti dira ogun, akínkanjú jagunjagun ni, ó sì lágbára. Gòláyátì pè wọ́n níjà pẹ̀lú ohùn rara. Fojú inú wo bó ṣe ń bú ramúramù táwọn ọmọ ogun á sì máa gbóhùn rẹ̀ bó ṣe ń pe Ísírẹ́lì àti Sọ́ọ̀lù ọba wọn níjà. Ó ní kí ẹni tó bá láyà jáde wá ko òun lójú!—1 Sámúẹ́lì 17:4-10.
Ojora mú àwọn ọmọ ogun Ísírẹ́lì àti Sọ́ọ̀lù Ọba wọn. Dáfídì gbọ́ pé ó ti lé lóṣù kan tí wọ́n ti wà lẹ́nu wàhálà yìí! Ẹgbẹ́ ogun méjèèjì ò lè ṣe ohunkóhun, Gòláyátì sì ń ṣáátá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lójoojúmọ́. Ọ̀rọ̀ náà tojú sú Dáfídì. Kò tiẹ̀ ṣeé gbọ́ sétí pé ojora mú ọba Ísírẹ́lì àtàwọn ọmọ ogun rẹ̀, títí kan àwọn ẹ̀gbọ́n Dáfídì mẹ́tẹ̀ẹ̀ta! Lójú Dáfídì, ohun tí Gòláyátì abọ̀rìṣà yìí ń ṣe kọjá pé ó kàn ń pẹ̀gàn àwọn ọmọ ogun Ísírẹ́lì, Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì gangan ló ń ṣáátá! Àmọ́ kí ni Dáfídì, ọmọdé lásánlàsàn, lè ṣe sí i? Kí sì ni a lè rí kọ́ lára ìgbàgbọ́ tí Dáfídì ní?—1 Sámúẹ́lì 17:11-14.
“FÒRÓRÓ YÀN ÁN, NÍTORÍ PÉ ÒUN NÌYÍ!”
Ẹ jẹ́ ká pa dà sì ohun tó ṣẹlẹ̀ ní ọ̀pọ̀ oṣù sẹ́yìn. Ó ti ń tó ọwọ́ ìrọ̀lẹ́, Dáfídì ṣì wà níbí tó ti ń bójú tó àwọn àgùntàn bàbá rẹ̀ níbi òkè kan ní Bẹ́tílẹ́hẹ́mù. Dáfídì kò tíì pé ọmọ ogún ọdún, àmọ́ ó rẹwà lọ́kùnrin, ó mọ́ra, ojú rẹ̀ fani mọ́ra, ó sì gbọ́n. Ó sábà máa ń ta háàpù lásìkò tí nǹkan bá pa rọ́rọ́. Ó mọrírì àwọn nǹkan mèremère tí Ọlọ́run dá, bó sì ṣe máa ń fi orin kíkọ dánra wò lọ́pọ̀ ìgbà tí jẹ́ kó mọ ohun èlò ìkọrin lò dáadáa. Ni wọ́n bá ké sí Dáfídì nírọ̀lẹ́ ọjọ́ tá à ń wí yìí. Bàbá rẹ̀ fẹ́ rí i ní kíá mọ́sá.—1 Sámúẹ́lì 16:12.
Nígbà tó dé, ó rí Jésè bàbá rẹ̀ tó ń bá bàbá arúgbó kan sọ̀rọ̀. Wòlíì Sámúẹ́lì tó jẹ́ olóòótọ́ ni. Jèhófà ló rán an pé kó lọ yan ẹni tó máa jọba Ísírẹ́lì lẹ́yìn tí Sọ́ọ̀lù bá kú lára àwọn ọmọkùnrin Jésè! Sámúẹ́lì ti rí àwọn ẹ̀gbọ́n méje tí Dáfídì ní, àmọ́ Jèhófà sọ fún un pé òun kò yan èyíkéyìí lára wọn. Nígbà tí Dáfídì wọlé dé, Jèhófà sọ fún Sámúẹ́lì pé: “Fòróró yàn án, nítorí pé òun nìyí!” Lójú gbogbo àwọn ẹ̀gbọ́n Dáfídì, Sámúẹ́lì gbé ìwo kan tí àkànṣe òróró kún inú rẹ̀, ó sì da díẹ̀ sí Dáfídì lórí. Bí ìgbésí ayé Dáfídì ṣe yí pa dà nìyẹn o. Bíbélì sọ pé: “Ẹ̀mí Jèhófà sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣiṣẹ́ lára Dáfídì láti ọjọ́ yẹn lọ.”—1 Sámúẹ́lì 16:1, 5-11, 13.
Ṣé Dáfídì wá bẹ̀rẹ̀ sí í gbéra ga torí pé ó ti di ọba lọ́la? Rárá, ó dúró de ìgbà tí ẹ̀mí Jèhófà máa darí rẹ̀ láti gba iṣẹ́ tó gbé lé e lọ́wọ́. Ní gbogbo àkókò yẹn, ó ń bá iṣẹ́ olùṣọ́ àgùntàn tó ń ṣe lọ. Tọkàntọkàn ló fi ń ṣe iṣẹ́ náà, ó sì ní ìgboyà. Ìgbà 1 Sámúẹ́lì 17:34-36; Aísáyà 31:4.
méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ làwọn ẹranko ẹhànnà fẹ́ pa àwọn àgùntàn bàbá rẹ̀ jẹ. Kìnnìún ló kọ́kọ́ wá, ẹ̀yìn náà ni béárì wá. Dáfídì ò kàn dúró sí ọ̀ọ́kán kó sì fọgbọ́n lé àwọn ẹranko ẹhànnà náà lọ. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ló bá wọn wọ̀yá ìjà kó lè gba àwọn àgùntàn bàbá rẹ̀ sílẹ̀. Nígbà méjèèjì, ó pa àwọn ẹranko ẹhànnà náà!—Lọ́jọ́ kan, wọ́n tún wá pe Dáfídì. Ìròyìn rẹ̀ ti kàn dé ọ̀dọ̀ Sọ́ọ̀lù Ọba. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ṣì jẹ́ akínkanjú ológun, Sọ́ọ̀lù ti pàdánù ojúure Jèhófà torí pé kò tẹ̀ lé ìtọ́ni tí Ọlọ́run fún un. Jèhófà ti gba ẹ̀mí rẹ̀ lára Sọ́ọ̀lù, ẹ̀mí burúkú sì ń dárí rẹ̀, èyí mú kó máa bínú sódì, ó máa ń fura òdì, ó sì ń hùwà ipá. Tí ẹ̀mí burúkú yìí bá ti bẹ̀rẹ̀ sí í darí rẹ̀, orin nìkan ló lè mára tù ú. Àwọn kan lára àwọn ìránṣẹ́ Sọ́ọ̀lù ti gbọ́ pé Dáfídì mọ orin kọ, ó sì jẹ́ akínkanjú. Èyí ló mú kí wọ́n pe Dáfídì wá sí ààfin, ó ń kọrin fún Sọ́ọ̀lù, ó sì ń bá a gbé ohun ìjà rẹ̀.—1 Sámúẹ́lì 15:26-29; 16:14-23.
Àwọn ọ̀dọ́ lè kẹ́kọ̀ọ́ látara ìgbàgbọ́ tí Dáfídì ní. Àwọn nǹkan tó máa mú kó túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà ló máa ń ṣe ní àkókò tí ọwọ́ rẹ̀ bá dilẹ̀. Láfikún sí i, ó kọ́ iṣẹ́ ọwọ́ tó wúlò tó sì mú kí wọ́n tètè gbà á síṣẹ́. Èyí tó ṣe pàtàkì jù ni pé ó jẹ́ kí ẹ̀mí Jèhófà darí òun. Ẹ ò rí i pé ẹ̀kọ́ pàtàkì lèyí jẹ́ fún gbogbo wa!—Oníwàásù 12:1.
“MÁ ṢE JẸ́ KÍ ỌKÀN-ÀYÀ ỌKÙNRIN ÈYÍKÉYÌÍ RẸ̀WẸ̀SÌ NÍNÚ RẸ̀”
Bí Dáfídì ṣe ń ṣiṣẹ́ lọ́dọ̀ Sọ́ọ̀lù, ó ṣì tún máa ń pa dà sílé láti lọ bójú tó àwọn àgùntàn, ó tiẹ̀ máa ń pẹ́ kó tó pa dà sí ààfin nígbà míì. Lọ́jọ́ kan tí Dáfídì lọ sílé, Jésè bàbá rẹ̀ rán an pé kó lọ wo àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ mẹ́ta tí wọ́n wà lára ọmọ ogun Sọ́ọ̀lù. Dáfídì jẹ́ iṣẹ́ tí bàbá rẹ̀ rán an, ó kó ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹrù, ó sì forí lé Pẹ̀tẹ́lẹ̀ Éláhì. Nígbà tó débẹ̀, inú rẹ̀ bàjẹ́ bó ṣe rí ẹgbẹ́ ọmọ ogun Ísírẹ́lì àtàwọn Filísínì tí wọn ò lè ṣe ohunkóhun, bá a ṣe ṣàpèjúwe rẹ̀ níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí. Wọ́n wà lórí àwọn òkè méjì tó dojú kọ ara wọn, àfonífojì ńlá kan sì là wọ́n láàárín.—1 Sámúẹ́lì 17:1-3, 15-19.
Àmọ́ ojú Dáfídì kò gbà á. Ó ronú pé báwo làwọn ọmọ ogun Jèhófà, Ọlọ́run alààyè ṣe lè máa sá fún ọkùnrin kan tó jẹ́ kèfèrí lásánlàsàn? Dáfídì wò ó pé Jèhófà ni Gòláyátì ń ṣáátá. Ló bá bẹ̀rẹ̀ sí í fi ìtara bá àwọn ọmọ ogun sọ̀rọ̀ nípa bí wọ́n ṣe máa ṣẹ́gun Gòláyátì. Kò pẹ́ tí ọ̀rọ̀ yìí fi dé etígbọ̀ọ́ Élíábù ẹ̀gbọ́n Dáfídì. Ó fìkanra mọ́ Dáfídì, ó ní ṣe ló wá wòran ogun. Àmọ́ Dáfídì dá a lóhùn pé: “Kí ni mo tíì ṣe báyìí? Kì í ha ṣe ọ̀rọ̀ kan lásán ni bí?” Ló bá tún ń fi ìgboyà sọ̀rọ̀ lọ nípa bí wọ́n ṣe máa ṣẹ́gun Gòláyátì, títí tẹ́nì kan fi sọ̀rọ̀ náà létí Sọ́ọ̀lù. Lọ́ba bá pàṣẹ pé kí wọ́n mú Dáfídì wá.—1 Sámúẹ́lì 17:23-31.
Dáfídì sọ̀rọ̀ akínkanjú níwájú ọba, ó ní: “Má ṣe jẹ́ kí ọkàn-àyà ọkùnrin èyíkéyìí rẹ̀wẹ̀sì nínú rẹ̀.” Ọkàn Sọ́ọ̀lù àtàwọn ọmọ ogun rẹ̀ ti pami nítorí Gòláyátì. Ó ṣeé ṣe kí wọ́n ti ṣe àṣìṣe tí ọ̀pọ̀ èèyàn máa ń ṣe, ìyẹn ni bí wọ́n ṣe wo ara wọn lẹ́gbẹ̀ẹ́ ọkùnrin fìrìgbọ̀n yìí, pé àwọn ò tiẹ̀ dé àyà rẹ̀. Wọ́n gbà pé ọwọ́ kan ló máa pa àwọn danù. Ṣùgbọ́n, Dáfídì ò ronú bẹ́ẹ̀ ní tiẹ̀. Bá a ṣe máa rí i níwájú, ojú tí Dáfídì fi wo ọ̀rọ̀ náà yàtọ̀ pátápátá sí tiwọn. Ló bá sọ pé òun máa lọ bá Gòláyátì jà.—1 Sámúẹ́lì 17:32.
Sọ́ọ̀lù kò fara mọ́ ọn, ó ní: “Ìwọ kò lè lọ bá Filísínì yìí láti bá a jà, nítorí ọmọdékùnrin lásán-làsàn ni ọ́, òun sì jẹ́ ọkùnrin ogun láti ìgbà ọmọdékùnrin rẹ̀.” Ṣé ọmọdé ni Dáfídì lóòótọ́? Rárá o, àmọ́ ó ṣì kéré láti wọṣẹ́ ológun, ó sì lè jẹ́ pé ojú ọmọdé ló ní. Àmọ́ àwọn èèyàn ti mọ Dáfídì sí akínkanjú ọkùnrin, ó sì ṣeé ṣe kó ti fẹ́rẹ̀ẹ́ pé ọmọ ogun ọdún lásìkò yìí.—Dáfídì fi Sọ́ọ̀lù lọ́kàn balẹ̀, ó ṣàlàyé bó ṣe pa kìnnìún àti béárì fún un. Ṣé ó wá ń fọ́nnu ni? Rárá o. Dáfídì mọ ohun tó jẹ́ kó lè pa àwọn ẹranko yẹn. Ó sọ pé: “Jèhófà, ẹni tí ó dá mi nídè kúrò ní àtẹ́sẹ̀ kìnnìún náà àti kúrò ní àtẹ́sẹ̀ béárì náà, òun ni ẹni tí yóò dá mi nídè kúrò ní ọwọ́ Filísínì yìí.” Sọ́ọ̀lù wá jánu lórí ọ̀rọ̀ náà, ló bá fèsì pé: “Máa lọ, kí Jèhófà fúnra rẹ̀ sì wà pẹ̀lú rẹ.”—1 Sámúẹ́lì 17:37.
Ṣé ó wù ẹ́ láti ní irú ìgbàgbọ́ tí Dáfídì ní? Kíyè sí i pé ìgbàgbọ́ tí Dáfídì ní kì í ṣe ọ̀rọ̀ ẹnu lásán. Ìmọ̀ tó ní àtàwọn ohun tí Ọlọ́run ti ṣe fún un ló jẹ́ kí ìgbàgbọ́ rẹ̀ lágbára. Ó mọ̀ pé Jèhófà máa ń dáàbò boni, ó sì máa ń mú àwọn ìlérí rẹ̀ ṣẹ. Táwa náà bá fẹ́ nírú ìgbàgbọ́ bẹ́ẹ̀, a gbọ́dọ̀ máa bá a nìṣó láti máa kẹ́kọ̀ọ́ nípa Ọlọ́run tó ṣe Bíbélì. Bá a sì ṣe ń fi ohun tá a kọ́ ṣèwà hù, èyí máa ṣe wá láǹfààní, á sì mú kí ìgbàgbọ́ wa lágbára sí i.—Hébérù 11:1.
“JÈHÓFÀ YÓÒ FI Ọ́ LÉ MI LỌ́WỌ́”
Sọ́ọ̀lù kọ́kọ́ gbé aṣọ ogun rẹ̀ wọ Dáfídì. Aṣọ ogun náà kò fi bẹ́ẹ̀ yàtọ̀ sí ti Gòláyátì. Bàbà ni wọ́n fi ṣe é, ó ṣeé ṣe kó ní àwọ̀lékè tí wọ́n fi irin ṣe, tó sì wà ní ìpele-ìpele. Bí Dáfídì ṣe gbé e wọ̀, ó gbìyànjú láti rìn káàkiri, àmọ́ ó rí i pé àtàrí àjànàkú ni, kì í ṣe ẹrù ọmọdé. Kò kọ́ṣẹ́ ogun rí, bẹ́ẹ̀ sì ni kò wọṣọ ogun rí. Pàápàá tó wá jẹ́ aṣọ ogun Sọ́ọ̀lù, ẹni tó ga jùlọ nínú gbogbo ọkùnrin tó wà ní orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì! (1 Sámúẹ́lì 9:2) Torí náà, ó bọ́ ọ, ó sì wọ aṣọ tó ti mọ́ ọn lára, ìyẹn aṣọ táwọn olùṣọ́ àgùntàn máa ń wọ̀ láti fi dáàbò bo agbo ẹran wọn.—1 Sámúẹ́lì 17:38-40.
Dáfídì mú ọ̀pá tó fi ń da ẹran, ó gbé àpò kan sí èjìká rẹ̀, ó sì mú kànnàkànnà kan dání. Èèyàn lè máa wò ó pé kí ló fẹ́ fi kànnàkànnà ṣe lójú ogun, àmọ́ ká sòótọ́, ohun ìjà téèyàn ń rí tó ń sá ni. Kànnàkànnà máa ń ní awọ kékeré tí wọ́n fi okùn dè ní ẹ̀gbẹ́ méjèèjì. Ó wúlò gan-an fún àwọn darandaran. Tó bá fẹ́ ta á, Dáfídì máa fi òkúta kan sáàárín awọ yẹn. Á bẹ̀rẹ̀ sí í fi kànnàkànnà náà. Lójijì, á yọwọ́ kúrò lára ọ̀kan nínú okùn tó di kànnàkànnà náà mú, òkúta inú rẹ̀ á sì fò jáde, tààràtà ni òkúta náà á lọ sí ọ̀gangan ibi tí wọ́n bá ta á sí. Kànnàkànnà yìí wúlò gan-an débi pé àwọn ológun náà máa ń lò ó.
Dáfídì ti wá ṣe tán, ó sì yára lọ pàdé ọ̀tá rẹ̀. A lè fojú inú wo Dáfídì tó bẹ̀rẹ̀ mọ́lẹ̀ níbi odò tó wà lẹ́sẹ̀ òkè náà, tó gbàdúrà tọkàntọkàn, tó sì ṣa òkúta kéékèèké márùn-ún tó jọ̀lọ̀ dáadáa. Ó wá sáré lọ sójú ogun náà!
Kí ni Gòláyátì rò nígbà tó rí ẹni tó fẹ́ bá a jà? Bíbélì sọ pé: “Ó bẹ̀rẹ̀ sí tẹ́ńbẹ́lú rẹ̀ nítorí pé ó jẹ́ ọmọdékùnrin àti apọ́nbéporẹ́, tí ó lẹ́wà ní ìrísí.” Gòláyátì bú jáde pé: “Ṣé ajá ni mí, tí ìwọ fi ń bọ̀ lọ́dọ̀ mi pẹ̀lú ọ̀pá?” Ó ṣe kedere pé, Gòláyátì rí ọ̀pá ọwọ́ Dáfídì, àmọ́ kò kíyè sí kànnàkànnà yẹn. Ó fi orúkọ òrìṣà àwọn Filísínì ṣépè fún Dáfídì, ó sì búra pé àwọn ẹyẹ àtàwọn ẹranko ló máa jẹ òkú rẹ̀.—1 Sámúẹ́lì 17:41-44.
Títí dòní, ọ̀rọ̀ tí Dáfídì sọ ṣì fi hàn pé ó ní ìgbàgbọ́ tó lágbára. Fọkàn yàwòrán bí ọ̀dọ́kùnrin yìí ṣe ké jáde sí Gòláyátì pé: “Ìwọ ń bọ̀ lọ́dọ̀ mi pẹ̀lú idà àti ọ̀kọ̀ àti ẹ̀ṣín, ṣùgbọ́n èmi ń bọ̀ lọ́dọ̀ rẹ pẹ̀lú orúkọ Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun, Ọlọ́run àwọn ìlà ogun Ísírẹ́lì, ẹni tí ìwọ ti ṣáátá.” Dáfídì mọ̀ pé agbára tàbí àwọn ohun ìjà kò já mọ́ nǹkan kan. Gòláyátì ti tẹ́ńbẹ́lú Jèhófà Ọlọ́run, Jèhófà sì máa fagbára hàn án. Dáfídì sọ pé, “ti Jèhófà ni ìjà ogun náà.”—1 Sámúẹ́lì 17:45-47.
Kì í ṣe pé Dáfídì kò rí bí Gòláyátì ṣe rí fìrìgbọ̀n àtàwọn ohun ìjà tó kó dání. Àmọ́ Dáfídì kò jẹ́ kí ìyẹn dẹ́rù ba òun. Kò ṣe irú àṣìṣe tí Sọ́ọ̀lù àtàwọn ọmọ ogun rẹ̀ ṣe. Dáfídì kò wo bí òun ṣe kéré lẹ́gbẹ̀ẹ́ Gòláyátì. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ló wo bí Gòláyátì ṣe kéré lẹ́gbẹ̀ẹ́ Jèhófà. Gòláyátì ga tó ẹsẹ̀ bàtà
mẹ́sàn-án àtààbọ̀ (2.9 m), kò sì sẹ́ni tó ṣe fìrìgbọ̀n bíi tiẹ̀, àmọ́ ṣe a lè fi títóbi rẹ̀ wé ti Ọba Aláṣẹ ayé àtọ̀run? Ká sòótọ́, Gòláyátì kò yàtọ̀ sí gbogbo èèyàn tó kù lójú Jèhófà. Ọwọ́ kan ni Jèhófà máa gbẹ̀mí ẹ̀, bí ìgbà téèyàn tẹ kòkòrò kékeré kan pa!Dáfídì sáré lọ sọ́dọ̀ ọ̀tá rẹ̀, ó sì mú òkúta kan látinú àpò. Ó fi sínú kànnàkànnà náà, ó sì fì í tagbáratagbára. Ó ṣeé ṣe kí Gòláyátì dúró sẹ́yìn ẹni tó bá a gbé apata rẹ̀, kó sì sún mọ́ Dáfídì. Ìṣòro ni gíga Gòláyátì jẹ́ fún un torí pé ẹni tó bá a gbé apata náà kéré gan-an lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀. Kò lè ṣeé ṣe fún ẹni náà láti gbé apata náà sókè débí táá fi bo orí Gòláyátì. Orí rẹ̀ gangan sì ni Dáfídì fojú sùn.—1 Sámúẹ́lì 17:41.
Dáfídì yọwọ́ lára kànnàkànnà náà, òkúta inú rẹ̀ sì fò jáde. Fojú inú yàwòrán bí òkúta náà ṣe ń lọ tààrà sí agbárí Gòláyátì. Jèhófà ran Dáfídì lọ́wọ́ débi pé kò tá kànnàkànnà yẹn lẹ́ẹ̀kejì. Àfi kòsà lágbárí Gòláyátì, ó sì wọlé ṣinrá. Gòláyátì ṣubú lulẹ̀ gbì, ó sì dojú bolẹ̀! Ẹ̀rù ba ẹni tó gbé apata rẹ̀, ló bá fẹsẹ̀ fẹ. Dáfídì lọ síbi tí Gòláyátì ṣubú sí, ó mú idà rẹ̀, ó sì fi gé orí rẹ̀ féú.—1 Sámúẹ́lì 17:48-51.
Ní báyìí, Sọ́ọ̀lù àtàwọn ọmọ ogun rẹ̀ túra ká. Wọ́n kígbe ìjà ogun, wọ́n sì ya bo àwọn ọmọ ogun Filísínì. Ọ̀rọ̀ náà wá rí bí Dáfídì ṣe sọ fún Gòláyátì pé ó máa rí, pé: “Jèhófà . . . yóò sì fi yín lé wa lọ́wọ́.”—1 Sámúẹ́lì 17:47, 52, 53.
Àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run lóde òní kì í ja irú ogun yìí. Àkókò yẹn ti kọjá. (Mátíù 26:52) Síbẹ̀, a ṣì ní láti tẹ̀ lé àpẹẹrẹ ìgbàgbọ́ Dáfídì. Bíi ti Dáfídì, a gbọ́dọ̀ gbà pé Jèhófà wà fún wa àti pé òun nìkan ni Ọlọ́run tá a gbọ́dọ̀ máa sìn, tá a sì gbọ́dọ̀ bẹ̀rù. Nígbà míì, a lè máa wo àwọn ìṣòro wa bí ohun tó ga ju ẹ̀mí wa lọ, àmọ́ ká máa rántí pé kò sí ìṣòro tí agbára Jèhófà ò ká. Tá a bá fi Jèhófà ṣe Ọlọ́run wa, tá a sì nígbàgbọ́ nínú rẹ̀ bíi ti Dáfídì, kò sí ìṣòro tó máa dẹ́rù bà wá. Kò sí ohun tó kọjá agbára Jèhófà!