Ẹ̀rín Músẹ́ —Ẹ̀bùn Tó O Lè Fúnni
BÁWO ló ṣe máa ń rí lára rẹ tẹ́nì kan bá rẹ́rìn músẹ́ sí ẹ? Ó dájú pé wàá rẹ́rìn-ín sí i pa dà. Inú rẹ á sì tún dùn. Bẹ́ẹ̀ ni, tí ọ̀rẹ́ tàbí àjèjè bá rẹ́rìn-ín tó dénú sí ẹ, ìwọ náà máa rẹ́rìn-ín pa dà ṣáá ni torí pé ẹ̀rín máa ń rànyàn, ó sì máa ń múni láyọ̀. Obìnrin kan tó ń jẹ́ Magdalena sọ pé: “Ẹ̀rín ọkọ mi máa ń dénú gan-an. Kí Georg ọkọ mi tó kú, ńṣe lọkàn mi máa ń balè pẹ̀sẹ̀ ní gbogbo ìgbà tá a bá jọ wojú ara wa.”
Tí ẹnì kan bá rẹ́rìn-ín tó dọ́kàn, ó fi hàn pé ara ẹni náà yá gágá, inú rẹ̀ dùn, ara sì tù ú. Àpilẹ̀kọ kan nínú ìwé ìròyìn Observer, tí àjọ Association for Psychological Science gbé sórí Íńtánẹ́ẹ̀ti sọ pé: ‘Ó jọ pé ńṣe ni wọ́n bí ẹ̀rín mọ́ wa.’ Àpilẹ̀kọ náà fi kún-un pé: “Àwọn ìkókó pàápàá máa ń mọ̀ téèyàn bá rẹ́rìn-ín sí wọn.” Àpilẹ̀kọ yẹn tún sọ pé: “Ẹ̀rín músẹ́ máa ń jẹ́ ká mọ ohun tó wà lọ́kàn ẹlòmíì, èyí sì máa ń mú ká lè pinnu ohun tá a máa ṣe.” *
Àwọn olùṣèwádìí kan ní Harvard University lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ṣèwádìí nípa àwọn àgbàlagbà aláìsàn kan lórí bí wọ́n ṣe máa ń hùwà pa dà sí ìrísí ojú àwọn tó ń tọ́jú wọn. Ìwàdíì náà fi hàn pé tí wọ́n bá kíyè sí i pé ìrísí ojú àwọn tó wá tójú wọn “fáni mọ́ra, tó hàn pé wọ́n káànú wọn, tó sì hàn pé wọ́n fẹ́ láti ṣìkẹ́ wọn,” ara máa ń tu àwọn aláìsàn yìí, ara wọn sì máa ń yá gágá
yàtọ̀ sí ti tẹ́lẹ̀. Àmọ́, tó bá jẹ́ pé ńṣe lojú wọn le, inú àwọn aláìsàn yẹn kì í dùn.Tí ìwọ náà bá ń rẹ́rìn-ín músẹ́, àǹfààní wà níbẹ̀ fún ẹ. Ìwádìí fi hàn pé wàá já fáfá, ayọ̀ á hàn lójú rẹ, ìdààmú rẹ á sì dín kù. Àmọ́, ọ̀rọ̀ ò lè rí bẹ́ẹ̀ tó o bá ń lejú.
Ẹ̀RÍN MÚSẸ́ “JẸ́ KÍ ARA MI YÁ GÁGÁ”
Ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni Magdalena tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ lókè. Nígbà Ogun Àgbáyé Kejì, wọ́n mú òun àtàwọn ẹbí rẹ̀ lọ sí àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ tó wà ní Ravensbrück nílẹ̀ Jámánì torí pé wọ́n kọ̀ láti tẹ̀ lé ìlànà ìjọba Násì. Magdalena sọ pé: “Nígbà míì, àwọn ẹ̀ṣọ́ kì í gbà wá láàyè láti bá ara wa sọ̀rọ̀, àmọ́ wọn ò lè ní ká má fojú bára wa sọ̀rọ̀. Bí mo ṣe ń rí i tí màmá mi àti ẹ̀gbọ́n mi obìnrin ń rẹ́rìn-ín músẹ́ sí mi mú kára mi yá gágá, ẹ̀rín wọn fún mi lókun láti máa fara dà á.”
Ó ṣeé ṣe kó o máa ronú pé àníyàn ayé yìí ti pọ̀ ju kéèyàn máa rẹ́rìn-ín músẹ́ jàre. Ó ṣe tán, wọ́n ní inú dídùn, ló ń mórí yá. (Òwe 15:15; Fílípì 4:8, 9) Lóòótọ́, ipò nǹkan ò fara rọ, àmọ́, ṣé o lè máa rónu lórí àwọn nǹkan tó dáa, táá mára tù ẹ́? * Bíbélì kíkà àti àdúrà ti ran ọ̀pọ̀ èèyàn lọ́wọ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀. (Mátíù 5:3; Fílípì 4:6, 7) Kódà, àwọn ọ̀rọ̀ bí “ìdùnnú” àti “ayọ̀” àtàwọn ọ̀rọ̀ míì tó jọ ọ́ fara hàn lọ́pọ̀ ìgbà nínú Bíbélì! Ṣé o lè gbìyànjú láti ka ojú ìwé kan tàbí méjì lójúmọ́? Ó ṣeé ṣe kí ìwọ náà dẹni tó ń rẹ́rìn-ín músẹ́ dáadáa.
Bákan náà, má ṣe dúró dìgbà tẹ́nì kan bá kọ́kọ́ rẹ́rìn-ín sí ẹ. Ìwọ náà lè kọ́kọ̀ rẹ́rìn-ín sí àwọn tó o bá rí, kó o lè múnú àwọn èèyàn tó o bá pàdé dùn. Torí náà, gbà pé ẹ̀bùn látọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni ẹ̀rín músẹ́, ó sì máa mú kí ayé rẹ àti tàwọn míì dùn bí oyin.
^ ìpínrọ̀ 3 Bíbélì ṣàpèjúwe Ọlọ́run pé ó máa ń rẹ́rìn-ín músẹ́. Sáàmù 119:135 sọ pé: “Mú kí ojú rẹ tàn [rẹ́rìn-ín músẹ́] sára ìránṣẹ́ rẹ.”
^ ìpínrọ̀ 8 Wo àpilẹ̀kọ náà “Ṣé O Máa Ń Jẹ ‘Àsè Nígbà Gbogbo’?” nínú Jí! January–February 2014.