Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Kí aláìsàn kan tó lè gbádùn, wọ́n gbọ́dọ̀ mọ ohun tó fa àìsàn náà, kí wọ́n sì fún un ní ìtọ́jú tó yẹ

OHUN TÓ YẸ KÁ MỌ̀

Ó Yẹ Ká Mọ Ohun Tó Ń Fa Ìṣòro Náà

Ó Yẹ Ká Mọ Ohun Tó Ń Fa Ìṣòro Náà

Ǹjẹ́ o rò pé aráyé lè yanjú ọ̀pọ̀ ìṣòro tó ń dènà àlàáfíà àti ìfọ̀kànbalẹ̀, tó sì fẹ́ ba ọjọ́ ọ̀la wa jẹ́? Kí ìṣòro wa tó lè yanjú, a gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ wá ojútùú sí àwọn ohun tó ń fa ìṣoro náà.

Bí àpẹẹrẹ, ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Tom ṣàìsàn, ó sì kú. Kí nìdí tó fi kú? Dókítà kan tó ń ṣiṣẹ́ ní ilé ìwòsàn tí wọ́n gbé Tom lọ kó tó kú sọ pé: “Nígbà tí àìsàn náà bẹ̀rẹ̀, kò sẹ́ni tó ṣe ìwádìí nípa ohun tó fa àìsàn náà. Ó dà bíi pé oògùn tó kàn máa mú kí ara tù ú ni wọ́n ń fún un.

Ṣé kì í ṣe ọ̀nà kan náà ni aráyé gbà ń kojú ìṣòro tó ń bá wọn fínra? Bí àpẹẹrẹ, kí ìjọba lè fòpin sí ìwà ọ̀daràn, wọ́n ṣòfin, wọ́n ń fi kámẹ́rà ṣọ́ àwọn èèyàn, wọ́n sì fi àwọn ọlọ́pàá sí àárín ìlú. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ìgbésẹ̀ yìí ń ṣiṣẹ́ dé ìwọ̀n àyè kan, wọn ò tó láti fòpin sí ohun tó ń fa ìṣòro aráyé. Ìdí ni pé ọ̀nà tí èèyàn gbà ń ṣe nǹkan, ohun tó gbà gbọ́ àti ohun tó wu èèyàn lọ́kàn, ló sábà máa ń pinnu ìwà téèyàn máa ń hù.

Ọ̀gbẹ́ni kan tó ń jẹ́ Daniel, tó ń gbé lórílẹ̀-èdè kan ní South America níbi tí nǹkan ò ti fi bẹ́ẹ̀ ṣẹnuure sọ pé: “Tẹ́lẹ̀, ìgbé ayé ìrọ̀rùn là ń gbé. A kì í bẹ̀rù àwọn olè. Àmọ́ ní báyìí kò sí àlàáfíà níbì kankan. Ọrọ̀ ajé tí ò fara rọ ti sọ àwọn èèyàn di olójúkòkòrò, ẹ̀mí èèyàn ò sì jọ wọ́n lójú.”

Rògbòdìyàn kan tó wáyé ní àárín ìlà oòrùn ayé mú kí ọ̀gbẹ́ni kan tá à ń pè ní Elias sá kúrò nílùú. Nígbà tó yá, ó kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ó sọ ohun tó ṣẹlẹ̀, ó ní: “Ńṣe ni àwọn olóṣèlú, àwọn olórí ẹ̀sìn àti àwọn ìdílé ń rọ àwọn ọ̀dọ́kùnrin ìlú pé kí wọ́n lọ jagun, kí àwọn èèyàn lè kà wọ́n sí akọni. Bẹ́ẹ̀ sì rèé ohun kan náà ni wọ́n ń rọ àwọn tó wà ní apá kejì pé kí wọ́n ṣe! Gbogbo èyí jẹ́ kí n rí i pé ìbànújẹ́ ló máa ń yọrí sí téèyàn bá gbọ́kàn lé àwọn alákòóso ayé yìí.”

Ìwé ọgbọ́n kan tó ti wà tipẹ́ sọ pé:

  • “Èrò ọkàn-àyà ènìyàn jẹ́ búburú láti ìgbà èwe rẹ̀ wá.”​—⁠Jẹ́nẹ́sísì 8:⁠21.

  • “Ọkàn-àyà ṣe àdàkàdekè ju ohunkóhun mìíràn lọ, ó sì ń gbékútà. Ta ni ó lè mọ̀ ọ́n?”​—⁠Jeremáyà 17:⁠9.

  • “Láti inú ọkàn-àyà ni àwọn èrò burúkú ti ń wá, ìṣìkàpànìyàn, . . . àgbèrè, olè jíjà, àwọn èké gbólóhùn ẹ̀rí.”​—⁠Mátíù 15:⁠19.

Ẹ̀dá èèyàn ò tíì rí ojútùú sí àwọn ìwà burúkú tó kún ọwọ́ àwọn èèyàn. Kódà, ńṣe ni ìwà ibi ọwọ́ àwọn èèyàn túbọ̀ ń pọ̀ sí i, ìyẹn ló sì fa àwọn ìṣòro tá a mẹ́nu bà nínú àpilẹ̀kọ tó ṣáájú èyí. (2 Tímótì 3:​1-5) Bẹ́ẹ̀ sì rèé àsìkò yìí ni ìmọ̀ ń pọ̀ sí i, tí àwọn ọ̀nà tá à ń gbà fi ìsọfúnni ráńṣẹ́ sì túbọ̀ ń pọ̀ sí i! Kí ló wá dé tí kò fi sí àlàáfíà àti ààbò láyé? Ṣé kì í ṣe pé ohun tí apá àwa ẹ̀dá èèyàn kò lè ká là ń gbìyànjú láti ṣe? Ṣé ìgbà kan tiẹ̀ ń bọ̀ tí àlàáfíà àti ààbò máa wà láyé?

ǸJẸ́ Ó ṢEÉ ṢE?

Ká tiẹ̀ sọ pé a rí ọ̀nà kan láti fòpin sí ìwà ìbàjẹ́ tó kún inú ayé, síbẹ̀, kò sí bí àwa èèyàn ṣe lè mú kí àlàáfíà àti ààbò jọba láyé. Kí nìdí? Ìdí ni pé ó kọjá agbára èèyàn.

Òótọ́ ibẹ̀ ni pé: ‘Kì í ṣe ti ènìyàn láti darí àwọn ìṣísẹ̀ ara rẹ̀.’ (Jeremáyà 10:23) Jèhófà ò dá wa pé ká máa darí ara wa. Bó ṣe jẹ́ pé Ọlọ́run ò dá àwa èèyàn láti máa gbé lábẹ́ omi tàbí nínú òfuurufú, bẹ́ẹ̀ náà ní kò ṣeé ṣe fún wa láti máa darí àwọn ẹlòmíì!

Bó ṣe jẹ́ pé Ọlọ́run ò dá àwa èèyàn láti máa gbé lábẹ́ omi, bẹ́ẹ̀ náà ní kò ṣeé ṣe fún wa láti máa darí ara wa

Òótọ́ kan ni pé àwọn èèyàn kì í fẹ́ kí ẹlòmíì tí wọ́n jọ jẹ́ ẹgbẹ́ máa sọ bí wọ́n á ṣe gbé ìgbé ayé wọn tàbí ìlànà tí wọ́n gbọ́dọ̀ tẹ̀ lé. Kódà, wọn kì í fẹ́ kí àwọn èèyàn sọ ojú tó yẹ kí wọ́n fi wo ọ̀rọ̀ ìṣẹ́yún, irú ẹ̀ṣẹ̀ tó yẹ kí wọ́n torí ẹ̀ pa ẹnì kan tàbí bó ṣe yẹ kí wọ́n tọ́ ọmọ wọn. Díẹ̀ nìyí lára àwọn nǹkan tó ń dá wàhálà sílẹ̀ láàárín àwọn èèyàn. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ó lè ṣòro fún àwọn èèyàn láti gbà bẹ́ẹ̀, òótọ́ ọ̀rọ̀ ni Bíbélì sọ yẹn. Kókó ibẹ̀ ni pé a ò ní ẹ̀tọ́ àti agbára láti darí èèyàn ẹlẹgbẹ́ wa. Ibo wá ni a lè yíjú sí fún ìrànlọ́wọ́?

Kò sí ẹlòmíì tó lè ràn wá lọ́wọ́ ju Ẹlẹ́dàá wa lọ. Ó ṣe tán, òun ló dá wa! Àwọn kan lè rò pé Ọlọ́run ti gbàgbé wa, àmọ́ ọ̀rọ̀ kò rí bẹ́ẹ̀. Kódà, Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé ó bìkítà nípa wa. Tá a bá lóye ohun tí Bíbélì sọ dáadáa, ó máa jẹ́ ká mọ bá a ṣe lè yanjú àwọn ìṣòro wa. Ó tún máa jẹ́ ká mọ ìdí tí ayé fi bà jẹ́ tó báyìí. Ìdí nìyẹn tí ọmọ ilẹ̀ Jámánì kan tó jẹ́ onímọ̀ nípa èrò orí fi sọ pé: “Pẹ̀lú gbogbo ohun tí ojú ẹ̀dá èèyàn ti rí nínú ìtàn, a ò fi ọ̀rọ̀ ara wa ṣe àríkọ́gbọ́n, ìwà àwọn èèyàn ò yí pa dà, ìjọba náà ò sì sunwọ̀n.”

ỌGBỌ́N INÚ BÍBÉLÌ Ń DÁÀBÒ BÒ WÁ!

Ọkùnrin ọlọ́gbọ́n kan sọ pé “a fi ọgbọ́n hàn ní olódodo nípasẹ̀ gbogbo àwọn ọmọ rẹ̀,” ìyẹn ohun tó ń mú jáde. (Lúùkù 7:35) Àpẹẹrẹ irú ọgbọ́n bẹ́ẹ̀ wà ní Sáàmù 146:3 tó sọ pé: ‘Ẹ má ṣe gbẹ́kẹ̀ lé ọmọ ará ayé, ẹni tí ìgbàlà kò sí lọ́wọ́ rẹ̀.’ Ìmọ̀ràn ọgbọ́n yẹn lè dáàbò bò wá ní ti pé kò ní jẹ́ ká gbọ́kàn wa lé ìrètí asán tàbí ìlérí òfìfo. Ọ̀gbẹ́ni Kenneth, tó ń gbé níbi tí rògbòdìyàn ti wọ́pọ̀ ní apá Àríwá Ilẹ̀ Amẹ́ríkà, sọ pé: “Àwọn olóṣèlú máa ń ṣèlérí pé àwọn máa mú kí nǹkan sunwọ̀n sí i, àmọ́ wọn kì í rí i ṣe. Èyí máa ń jẹ́ kí n túbọ̀ rí i pé ọ̀rọ̀ ọgbọ́n ló wà nínú Bíbélì.”

Daniel tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ lẹ́ẹ̀kan tún sọ pé: “Ojoojúmọ́ ló túbọ̀ máa ń ṣe kedere sí mi pé ẹ̀dá èèyàn ò lè darí ara wọn dáadáa. . . . Ti pé èèyàn ní owó rẹpẹtẹ sí báǹkì tàbí pé ó ní okòwò tí ó tó fẹ̀yìn tì kò túmọ̀ sí pé ọjọ́ iwájú rẹ̀ máa dára. Ìrírí àwọn tó ti ní ìjákulẹ̀ lórí èyí ti jẹ́ kí n gbà bẹ́ẹ̀.”

Yàtọ̀ sí pé ọ̀rọ̀ ọgbọ́n tó wà nínú Bíbélì kì í jẹ́ ká gbẹ́kẹ̀ lé ìlérí òfìfo, ó tún máa ń fún wa ní ìrètí. A máa kẹ́kọ̀ọ́ nípa èyí bá a ṣe ń bá a nìṣó.