Béèyàn Ṣe Lè Ní Ìtẹ́lọ́rùn àti Ìfọ̀kànbalẹ̀
Gbogbo èèyàn ló fẹ́ láyọ̀ kí ọkàn wọn sì balẹ̀, ì báà jẹ́ ọmọdé tàbí àgbà, ọkùnrin tàbí obìnrin. Ohun tí Ẹlẹ́dàá wa sì fẹ́ fún wa nìyẹn. Ìdí nìyẹn tó fi fún wa láwọn ìmọ̀ràn tó dáa jù lọ tó máa jẹ́ ká láyọ̀, kọ́kàn wa sì balẹ̀.
Máa Ṣiṣẹ́ Kára
“Kó máa ṣiṣẹ́ kára, kó máa fi ọwọ́ rẹ̀ ṣe iṣẹ́ rere, kó lè ní nǹkan tó máa fún ẹni tí kò ní.”—ÉFÉSÙ 4:28.
Ẹlẹ́dàá wa fẹ́ ká fọwọ́ pàtàkì mú iṣẹ́. Ìdí sì ni pé, ẹni tó bá ń ṣiṣẹ́ kára á lè bọ́ ara ẹ̀ àti ìdílé ẹ̀, ìyẹn sì máa jẹ́ kó láyọ̀. Kódà á tún lè ran ẹni tí kò ní lọ́wọ́. Yàtọ̀ síyẹn, ẹni tó gbà á síṣẹ́ máa mọyì ẹ̀ gan-an. Torí náà, iṣẹ́ kì í sábà bọ́ lọ́wọ́ irú ẹni bẹ́ẹ̀. Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé èrè púpọ̀ wà nínú iṣẹ́ àṣekára, kódà, ó pè é ní “ẹ̀bùn Ọlọ́run.”—Oníwàásù 3:13.
Jẹ́ Olóòótọ́
“Ó dá wa lójú pé a ní ẹ̀rí ọkàn rere, bó ṣe ń wù wá láti jẹ́ olóòótọ́ nínú ohun gbogbo.”—HÉBÉRÙ 13:18.
Tá a bá jẹ́ olóòótọ́, àá níyì lójú ara wa, ọkàn wa á balẹ̀, àá sì máa sùn dáadáa. Yàtọ̀ síyẹn, àwọn èèyàn á fọkàn tán wa, wọ́n á sì máa bọ̀wọ̀ fún wa. Àwọn aláìṣòótọ́ ò lè gbádùn irú àwọn nǹkan rere bẹ́ẹ̀. Ẹ̀rí ọkàn wọn á máa dá wọn lẹ́bi, ọkàn wọn ò sì ní balẹ̀ torí ẹ̀rù á máa bà wọ́n pé àṣírí àwọn lè tú.
Má Ṣe Jẹ́ Kí Ọ̀rọ̀ Owó Gbà Ẹ́ Lọ́kàn Ju Bó Ṣe Yẹ Lọ
“Ẹ yẹra fún ìfẹ́ owó nínú ìgbésí ayé yín, bí ẹ ṣe ń jẹ́ kí àwọn nǹkan tó wà báyìí tẹ́ yín lọ́rùn.”—HÉBÉRÙ 13:5.
Owó wúlò gan-an, torí òun la fi ń gbọ́ bùkátà. Àmọ́, “ìfẹ́ owó” léwu gan-an. Ó lè mú kẹ́nì kan máa fi gbogbo àkókò àti okun ẹ̀ lépa owó. Níbi tó ti ń ṣe kìràkìtà kó lè rówó púpọ̀ sí i, ó lè má fi bẹ́ẹ̀ ráyè gbọ́ ti ọkọ tàbí aya àtàwọn ọmọ ẹ̀, ó sì lè dá àìsàn sí i lára. (1 Tímótì 6:9, 10) Yàtọ̀ síyẹn, ẹni tó bá nífẹ̀ẹ́ owó lè bẹ̀rẹ̀ sí í tọwọ́ bọ nǹkan tí ò dáa tàbí kó máa parọ́. Ọkùnrin ọlọ́gbọ́n kan sọ pé: “Olóòótọ́ èèyàn yóò gba ọ̀pọ̀ ìbùkún, àmọ́ ọwọ́ ẹni tó ń kánjú láti di olówó kò lè mọ́.”—Òwe 28:20.
Yan Ẹ̀kọ́ Tó Dáa Jù
“Má ṣe jẹ́ kí ọgbọ́n tó gbéṣẹ́ àti làákàyè bọ́ mọ́ ọ lọ́wọ́.”—ÒWE 3:21.
Ẹ̀kọ́ tó dáa máa ń ṣeni láǹfààní, ó máa ń jẹ́ kéèyàn di àgbàlagbà tó ṣeé gbára lé àti òbí tó mọṣẹ́ ẹ̀ níṣẹ́. Àmọ́, ẹ̀kọ́ ìwé nìkan ò lè mú kéèyàn ní ìfọ̀kànbalẹ̀ àti ayọ̀. Tá a bá fẹ́ ṣàṣeyọrí nínú gbogbo ohun tá a bá ń ṣe, àfi ká kẹ́kọ̀ọ́ lọ́dọ̀ Ọlọ́run. Bíbélì sọ bí ayé ẹni tó ń fetí sí Ọlọ́run ṣe máa rí, ó ní: “Gbogbo ohun tó bá ń ṣe yóò máa yọrí sí rere.”—Sáàmù 1:1-3.