Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ayékòótọ́ aláwọ̀ búlúù àti yẹ́lò. Ó máa ń gùn tó sẹ̀ǹtímítà márùnlélọ́gọ́rin [85]

Ayékòótọ́ Aláwọ̀ Mèremère

Ayékòótọ́ Aláwọ̀ Mèremère

ÀWỌN olùṣèwádìí láti ilẹ̀ Yúróòpù rí ohun kan tó wú wọn lórí nígbà tí wọ́n dé àgbègbè Central America àti South America ní ìparí ọgọ́rùn-ún ọdún kẹẹ̀ẹ́dógún. Wọ́n rí àwọn ẹyẹ ayékòótọ́ onírù gígùn tó ní àwọ̀ mèremère tó ń fò lọ lójú òfúrufú. Àgbègbè olóoru tó wà nílẹ̀ Amẹ́ríkà làwọn ẹyẹ yìí sì ń gbé. Kò pẹ́ sígbà yẹn ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í ya àwòrán ẹyẹ yìí sórí máàpù láti fi ṣe àmì ilẹ̀ tó dára rèǹtèrente tí wọ́n ṣàwárí.

Takọtabo wọn ló máa ń ní àwọ̀ mèremère, èyí mú kí wọ́n yàtọ̀ sí àwọn ẹyẹ aláwọ̀ mèremère míì. Ẹyẹ ayékòótọ́ gbọ́n, wọ́n tún máa ń gbé pọ̀ bí agbo kan. Igbe wọn sì máa ń han èèyàn létí. Wọ́n lè tó ọgbọ̀n [30] nínú agbo kan. Láàárọ̀ kùtù, gbogbo wọn á gbéra láti wá oúnjẹ lọ, èyí sì ní nínú, èso àtàwọn oúnjẹ míì. Wọ́n sábà máa ń lo èékánná ẹsẹ̀ wọn láti fi gbé oúnjẹ, wọ́n á sì fi àgógó ẹnu wọn fa oúnjẹ náà ya. Kódà, wọ́n lè la ẹ̀pà tí èèpo ẹ̀yìn rẹ̀ le gbagidi! Lẹ́yìn tí wọ́n bá jẹun tán, wọ́n sábà máa ń fò lọ sí ẹsẹ̀ òkè tàbí etí odò láti lọ jẹ amọ̀. Amọ̀ yìí máa ń pa oró tó bá wà nínú oúnjẹ tí wọ́n jẹ, á sì fún wọn ní àwọn èròjà míì tó wúlò fún ara wọn.

“Ohun gbogbo ni [Ọlọ́run] ti ṣe rèterète ní ìgbà tirẹ̀.”Oníwàásù 3:11

Akọ kan àti abo kan ló máa ń gbé pọ̀ ní gbogbo ọjọ́ ayé wọn. Àwọn méjèèjì ló sì máa ń pawọ́ pọ̀ tọ́ àwọn ọmọ wọn. Onírúurú àwọn ẹyẹ yìí máa ń kọ́ ìtẹ́ wọn sínú ihò igi, ihò etí odò, inú ilé ikán tàbí inú ihò àpáta. Níbẹ̀, àá rí àwọn takọtabo tí wọ́n ń bá ara wọn yọ ìdọ̀tí inú ìyẹ́. Àwọn ọmọ wọn máa ń dàgbà láàárín oṣù mẹ́fà, síbẹ̀ wọ́n ṣì máa wà pẹ̀lú àwọn òbí wọn fún nǹkan bí ọdún mẹ́ta. Àwọn ayékòótọ́ tó bá ń gbé inú igbó lè lò tó ọgbọ̀n [30] ọdún sí ogójì [40] ọdún láyé. Àmọ́, èyí táwọn èèyàn ń sìn nílé lè lò tó ọgọ́ta [60] ọdún láyé. Onírúurú àwọn ẹyẹ yìí ló wà, díẹ̀ lára wọn ló wà nínú àwòrán yìí.

Ayékòótọ́ aláwọ̀ ewé, tó tún máa ń ní àwọ̀ pupa. Ó máa ń gùn tó sẹ̀ǹtímítà márùndínlọ́gọ́rùn-ún [95]

Ayékòótọ́ aláwọ pupa. Ó máa ń gùn tó sẹ̀ǹtímítà márùnlélọ́gọ́rin [85]

Ayékòótọ́ Hyacinth. Ó máa ń gùn tó ọgọ́rùn-ún sẹ̀ǹtímítà [100]. Òun ló tóbi jù nínú gbogbo àwọn ayékòótọ́, ó sì fẹ́rẹ̀ẹ́ wúwo tó kílógírámù kan ààbọ̀