JÍ! No. 2 2018 | Ohun Méjìlá Tó Ń Mú Kí Ìdílé Láyọ̀
Ohun Méjìlá Tó Ń Mú Kí Ìdílé Láyọ̀
A máa ń gbọ́ nípa ohun tó fà á táwọn ìdílé kan fi tú ká. Àmọ́ àwọn ìdílé tó ń láyọ̀ ńkọ́, kí ló ń ràn wọ́n lọ́wọ́?
Láàárín ọdún 1990 sí 2015, iye àwọn tó jẹ́ ẹni àádọ́ta ọdún [50] tó kọ ara wọn sílẹ̀ lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ti fi ìlọ́po méjì ju ti tẹ́lẹ̀, nígbà tí àwọn tó jẹ́ ẹni ọdún márùnlélọ́gọ́ta [65] tó kọ ara wọn sílẹ̀ lọ sókè ní ìlọ́po mẹ́ta.
Àwọn òbí ò mọ ohun tí wọ́n máa ṣe mọ́: Àwọn kan sọ pé kí wọ́n máa gbóríyìn fáwọn ọmọ wọn ní gbogbo ìgbà, àwọn míì sọ pé kí wọ́n má ṣe gba gbẹ̀rẹ́ fún wọn rárá.
Ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ ni kò mọ àwọn nǹkan tó lè mú kí wọ́n ṣàṣeyọrí bí wọ́n ṣe ń dàgbà.
Àmọ́, òótọ́ ibẹ̀ ni pé . . .
Ìdílé lè láyọ̀, kó sì wà pẹ́ títí.
Àwọn òbí lè kọ́ bí wọ́n ṣe lè fi ìfẹ́ bá àwọn ọmọ wọn wí.
Àwọn ọ̀dọ́ sì lè kọ́ àwọn nǹkan tó máa ràn wọ́n lọ́wọ́ bí wọ́n ṣe ń dàgbà.
Àmọ́ báwo nìyẹn ṣe lè ṣeé ṣe? Ẹ̀dà Jí! yìí máa sọ̀rọ̀ nípa ohun méjìlá tó máa jẹ́ kí ìdílé rẹ láyọ̀.
1: Jẹ́ Olóòótọ́
Ohun pàtàkì mẹ́ta tó lè mú kí àwọn tọkọtaya ṣe ara wọn lọ́kan.
2: Ìfọwọ́sowọ́pọ̀
Ǹjẹ́ ó ń ṣe ẹ́ bíi pé alájọgbé lásán ni ìwọ àti ẹnì kejì rẹ?
3: Ọ̀wọ̀
Mọ̀ nípa àwọn ọ̀rọ̀ àti ìwà tó máa jẹ́ kí ẹ̀yin méjéèjì lè máa bọ̀wọ̀ fún ara yín.
4: Ìdáríjì
Kí ló lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti má gbójú fo àìpé ẹnì kejì rẹ?
5: Ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀
Ohun mẹ́ta tó o lè ṣe kí ìwọ àti àwọn ọmọ rẹ lè sún mọ́ra.
6: Ìbáwí
Ṣé ìbáwí kì í jẹ́ kí ọmọ mọyì ara rẹ̀?
7: Ìwà Rere
Àwọn ìlànà wo ló yẹ kó o kọ́ àwọn ọmọ rẹ?
8: Àpẹẹrẹ Rere
Tó o bá fẹ́ kí àwọn ọmọ rẹ gbọ́ràn sí ẹ lẹ́nu, o gbọ́dọ̀ máa fi àpẹẹrẹ tó dáa lélẹ̀ fún wọn.
9: Ẹni Tó O Jẹ́
Báwo ni àwọn ọ̀dọ́ ṣe lè dúró lórí ohun tí wọ́n gbà gbọ́?
10: Jẹ́ Ẹni Tó Ṣeé Gbọ́kàn Lé
Táwọn òbí rẹ bá gbọ́kàn lé ẹ, ìyẹn máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ bó o ṣe túbọ̀ ń dàgbà.
11: Máa Ṣiṣẹ́ Kára
Tó o bá kọ́ bó o ṣe lè máa ṣiṣẹ́ kára ní báyìí tó o ṣì jẹ́ ọ̀dọ́, o máa ṣe àṣeyọrí nínú gbogbo nǹkan tó o bá ń ṣe.
12: Àfojúsùn
Tí ọwọ́ rẹ bá tẹ àfojúsùn kan, wàá gbà pé o lè ṣe òmí ì, àwọn èèyàn máa nífẹ̀ẹ́ rẹ, inú rẹ á sì máa dùn sí i.
Ohun Mí ì Tó Máa Ran Ìdílé Lọ́wọ́
Àwọn ìmọ̀ràn tó wà nínú Bíbélì lè ran ìdílé rẹ lọ́wọ́ láti jẹ́ aláyọ̀.