ÀWỌN Ọ̀DỌ́
12: Àfojúsùn
OHUN TÓ TÚMỌ̀ SÍ
Àfojúsùn kì í ṣe ọ̀rọ̀ ẹnu lásán, kì í ṣe ohun tó kàn wu èèyàn látọkànwá. Ó gba pé kéèyàn ṣètò, kó sì ṣe gbogbo ohun tó yẹ kó ṣe kí ọwọ́ rẹ̀ lè tẹ ohun tó ń fẹ́.
Àwọn àfojúsùn kan máa ń gba ọjọ́ tàbí ọ̀sẹ̀ díẹ̀ kí ọwọ́ èèyàn tó lè tẹ̀ ẹ́, àwọn míì máa ń gba oṣù díẹ̀, òmíràn sì lè gba ọdún kan tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ. Ọwọ́ ẹni ò lè dédé tẹ àwọn àfojúsùn tó máa ń gba ọdún kan tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ, ó gba kéèyàn ní àwọn àfojúsùn tọ́wọ́ ẹni lè tẹ̀ láàárín ọjọ́ díè tàbí oṣù díẹ̀.
ÌDÍ TÓ FI ṢE PÀTÀKÌ
Tí ọwọ́ rẹ bá tẹ àwọn nǹkan tó ò ń wá, wàá túbọ̀ nígboyà, wàá túbọ̀ sún mọ́ àwọn èèyàn, ayọ̀ rẹ á sì pọ̀ sí i.
Wàá mọ̀ pé o lè ṣe é: Tọ́wọ́ rẹ bá tẹ àwọn àfojúsùn kan, ìyẹn máa fún ẹ nígboyà láti lé àwọn àfojúsùn míì tó ju ti àkọ́kọ́ lọ. Yàtọ̀ sí ìyẹn, wàá lè fi ìgboyà kojú àwọn ìṣòro tó bá yọjú. Àwon èèyàn ò sì ní lè tì ẹ́ ṣe ohun tí kò tọ́.
Àwọn èèyàn máa nífẹ̀ẹ́ rẹ: Ó máa ń wu àwọn èèyàn láti ṣọ̀rẹ́ pẹ̀lú ẹni tó ní àfojúsùn tó sì mọ ohun tó ń ṣe. Ó ṣe tán, tí àwọn méjì bá ń ti ara wọn lẹ́yìn kí ọwọ́ wọn lè tẹ àfojúsùn wọn, ọ̀rẹ́ wọn á túbọ̀ wọ̀.
Ayọ̀: Tí ọwọ́ rẹ bá tẹ àfojúsùn rẹ, inú rẹ máa dùn, ọkan rẹ á sì balẹ̀.
“Inú mi máa ń dùn tí mo bá ní àfojúsùn. Ó máa ń jẹ́ kí n ní ohun kan pàtó tí mo fẹ́ fi àkókò mi ṣe. Tí mo bá bojú wẹ̀yìn tí mo sì rí i pé ọwọ́ mi tẹ àfojúsùn náà, mo máa ń sọ fún ara mi pé: ‘Ọwọ́ mi tẹ̀ ẹ́! Ọwọ́ mi tẹ ohun tí mò ń lé.’ ”—Christopher.
ÌLÀNÀ BÍBÉLÌ: “Ẹni tí ó bá ń ṣọ́ ẹ̀fúùfù kì yóò fún irúgbìn; ẹni tí ó bá sì ń wo àwọsánmà kì yóò kárúgbìn.”—Oníwàásù 11:4.
OHUN TÓ O LÈ ṢE
Tẹ̀ lé àwọn àbá yìí kí ọwọ́ rẹ lè tẹ àwọn àfojúsùn rẹ.
Mọ ohun tó o fẹ́. Kọ àwọn àfojúsùn rẹ sílẹ̀, kó o sì tò wọ́n bí wọ́n ṣe ṣe pàtàkì sí, jẹ́ kí èyí tó ṣe pàtàkì jù wà lókè, kó o wá kọ àwọn míì sí ìsàlẹ̀ ní ení, èjì, ẹ̀ta, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.
Múra sílẹ̀. Fún ọ̀kọọkan àwọn àfojúsùn yẹn, ohun tó o máa ṣe rèé:
-
Kọ ìgbà tí wàá fẹ́ kọ́wọ́ rẹ tẹ àfojúsùn náà.
-
Kọ àwọn nǹkan tó o gbọ́dọ̀ ṣe kọ́wọ́ rẹ tó lè tẹ̀ wọ́n.
-
Ronú ohun tó o lè ṣe láti kápá àwọn nǹkan tó lè fa ìdíwọ́.
Gbé ìgbésẹ̀. Má ṣe dúró dìgbà tó o bá rí ìdáhùn sí gbogbo kúlẹ̀kúlẹ̀ kó o tó bẹ̀rẹ̀. Ohun tó o máa ṣe ni pé, mọ nǹkan àkọ́kọ́ tó o lè ṣe kí ọwọ́ rẹ tó lè tẹ nǹkan tó o fẹ́, kó o sì ṣe nǹkan ọ̀hún. Bó o ṣe ń gbé àwọn ìgbésẹ̀ tó máa jẹ́ kọ́wọ́ rẹ tẹ àfojúsùn rẹ, máa kíyè sí bó o ṣe ń tẹ̀ síwájú.
ÌLÀNÀ BÍBÉLÌ: “Dájúdájú, àwọn ìwéwèé ẹni aláápọn máa ń yọrí sí àǹfààní.”—Òwe 21:5.