Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìpinnu tẹ́ ẹ ṣe láti dúró ti ara yín dà bí ìdákọ̀ró fún ìgbéyàwó yín nígbà ìṣòro

TỌKỌTAYA

1: Jẹ́ Olóòótọ́

1: Jẹ́ Olóòótọ́

OHUN TÓ TÚMỌ̀ SÍ

Ó túmọ̀ sí kí tọkọtaya pinnu pé àwọn kò ní fi ara wọn sílẹ̀ kódà tí ìṣòro bá dé. Èyí fi hàn pé wọ́n fi ọwọ́ pàtàkì mú ẹ̀jẹ́ ìgbéyàwó wọn, ìyẹn máa mú kí wọ́n fọkàn tán ara wọn, ọkàn wọn á sì balẹ̀ pé àwọn jọ máa bá ara wọn kalẹ́.

Àwọn tọkọtaya míì ò gbádùn ìgbéyàwó wọn, ńṣe ni wọ́n kàn ń fara dà á nìṣó nítorí ohun tí àwọn ọ̀rẹ́ tàbí mọ̀lẹ́bí wọn ń sọ. Àmọ́ ohun tó dáa jù ni kí tọkọtaya nífẹ̀ẹ́ ara wọn látọkànwá kí wọ́n sì bọ̀wọ̀ fún ara wọn, ìyẹn máa mú kí wọ́n gbádùn ìgbéyàwó wọn.

ÌLÀNÀ BÍBÉLÌ: ‘Kí ọkọ má ṣe fi aya rẹ̀ sílẹ̀.’1 Kọ́ríńtì 7:11.

“Tó o bá pinnu pé bí iná ń jó bí ìjì ń jà, oò ní fi ẹnì kejì rẹ sílẹ̀, á rọrùn fún ẹ láti dárí jì í tó bá ṣẹ̀ ẹ́, ìwọ náà á sì tètè máa tọrọ àforíjì. Tí ìṣòro bá sì dé, oò ní máa wá ọ̀nà láti fi ẹnì kejì rẹ sílẹ̀.”​—Micah.

ÌDÍ TÓ FI ṢE PÀTÀKÌ

Tí ìṣòro bá dé, kì í pẹ́ tí àwọn tọkọtaya kan fi máa ń sọ pé ‘ẹni tó yẹ kí n fẹ́ kọ́ nìyí,’ wọ́n á sì máa wá ọ̀nà láti kọ ara wọn sílẹ̀. Ìdí tí irú nǹkan bẹ́ẹ̀ fi ń ṣẹlẹ̀ ni pé látilẹ̀ làwọn tọkọtaya yẹn ò ti pinnu pé àwọn máa dúró ti ara àwọn títí di ọjọ́ alẹ́.

“Ọ̀pọ̀ àwọn tó ń ṣègbéyàwó ti máa ń ní in lọ́kàn pé tí nǹkan ò bá lọ dáadáa, àwọn máa fi ẹni táwọn ń fẹ́ sílẹ̀. Tí tọkọtaya bá ti ní irú èrò bẹ́ẹ̀ lọ́kàn nígbà tí wọ́n fẹ́ ara wọn, ìyẹn fi hàn pé àtilẹ̀ ni wọn ò ti jẹ́ olóòótọ́ sí ara wọn.”​—Jean.

OHUN TÓ O LÈ ṢE

DÁN ARA RẸ WÒ

Tí èdèkòyédè bá wáyé . . .

  • Ṣé ó máa ń ṣe ẹ́ bíi pé ẹni tó yẹ kó o fẹ́ kọ́ rèé?

  • Ṣé ó máa ń ṣe ẹ́ bíi pé kó o lọ fẹ́ ẹlòmíì?

  • Ṣé o máa ń sọ fún ìyàwó rẹ pé “màá kọ̀ ẹ́ sílẹ̀” tàbí fún ọkọ rẹ pé “màá lọ fẹ́ ẹlòmíì tó mọyì mi”?

Tó o bá dáhùn bẹ́ẹ̀ ni sí èyíkéyìí nínú ìbéèrè yìí, tètè wá nǹkan ṣe kí ìgbéyàwó rẹ má bàa dà rú, kó o sì pinnu pé oò ní fi ẹnì kejì rẹ sílẹ̀ láé.

Ẹ BÁ ARA YÍN SỌ̀RỌ̀

  • Ṣé ìfẹ́ tá a ní sí ara wa ti dín kù? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, kí ló fà á?

  • Kí la lè ṣe báyìí láti mú kí ìdè ìgbéyàwó wa lágbára?

ÀBÁ

  • Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, ẹ máa fi ọ̀rọ̀ ìfẹ́ ránṣẹ́ sí ara yín

  • O tún lè gbé fọ́tò olólùfẹ́ rẹ sórí tábìlì níbi iṣẹ́

  • Ẹ máa pe ara yín lórí fóònù lójoojúmọ́ tẹ́ ẹ bá wà níbi iṣẹ́ tàbí tẹ́ ò bá sí nítòsí ara yín

ÌLÀNÀ BÍBÉLÌ: “Ohun tí Ọlọ́run ti so pọ̀, kí ènìyàn kankan má ṣe yà á sọ́tọ.”​—Mátíù 19:6.