JÍ! No. 2 2019 | Ohun Mẹ́fà Tó Yẹ Ká Kọ́ Àwọn Ọmọ
Ohun Mẹ́fà Tó Yẹ Ká Kọ́ Àwọn Ọmọ
Irú èèyàn wo lo fẹ́ káwọn ọmọ rẹ jẹ́ tí wọ́n bá dàgbà?
Ẹni Tó Máa Ń Kó Ara Rẹ̀ Níjàánu
Onírẹ̀lẹ̀
Ẹni Tó Ní Ìforítì
Ẹni Tó Ṣeé Gbára Lé
Ọlọ́gbọ́n
Olóòótọ́
Àwọn ọmọ ò lè ṣàdédé ní àwọn ìwà ọmọlúwàbí yìí. Àfi kó o kọ́ wọn.
Ìwé yìí sọ̀rọ̀ nípa ohun pàtàkì mẹ́fà tó yẹ kó o kọ́ àwọn ọmọ rẹ. Àwọn nǹkan náà sì máa ràn wọ́n lọ́wọ́ gan-an nígbà tí wọ́n bá dàgbà.
Àǹfààní Tó Wà Nínú Kéèyàn Máa Kó Ara Rẹ̀ Níjàánu
Kí nìdí tó fi yẹ ká máa kó ara wa níjàánu, báwo la sì ṣe lè ṣe é?
Kọ́ Ọmọ Rẹ Ní Ìrẹ̀lẹ̀
Tó o bá kọ́ ọmọ rẹ láti jẹ́ onírẹ̀lẹ̀, ó máa ṣe é láàǹfààní ní báyìí àti lọ́jọ́ iwájú.
Kọ́ Ọmọ Rẹ Ní Ìforítì
Tí àwọn ọmọ bá kọ́ láti ní ìforítì, ó máa jẹ́ kí wọ́n lè borí àwọn ìṣòro lọ́jọ́ iwájú.
Kọ́ Ọmọ Rẹ Láti Jẹ́ Ẹni Tó Ṣeé Gbára Lé
Ìgbà wo ló yẹ kí òbí ti kọ́ ọmọ láti dẹni tó ṣeé gbára lé, ṣé nígbà tó ṣì wà lọ́mọdé ni àbí tó bá ti dàgbà?
Ìmọ̀ràn Àgbàlagbà Ṣe Pàtàkì
Àwọn ọmọ nílò ẹni tó máa tọ́ wọn sọ́nà káyé wọn lè dára, àmọ́ ta ló lè ràn wọ́n lọ́wọ́?
Ìdí Tí Ìwà Ọmọlúwàbí Fi Ṣe Pàtàkì
Tó o bá ń kọ́ àwọn ọmọ rẹ ní ìwà ọmọlúwàbí, ọjọ́ ọ̀la wọn máa dára gan-an.
Ìrànlọ́wọ́ fún Àwọn Òbí
Àwọn òbí náà nílò ìtọ́sọ́nà tó ṣeé gbára lé, tó sì máa ṣe wọ́n láǹfààní. Tó o bá fẹ́ mọ̀ sí i, lọ sórí ìkànnì jw.org/yo.