Àkóbá Wo Ni Ẹ̀rọ Ìgbàlódé Lè Ṣe fún Ọkọ àti Aya?
Táwọn tọkọtaya bá lo ẹ̀rọ ìgbàlódé lọ́nà tó dáa, ó lè mú kí ìfẹ́ àárín wọn túbọ̀ lágbára. Bí àpẹẹrẹ, ó máa ń jẹ́ kí tọkọtaya bá ara wọn sọ̀rọ̀ lóòrèkóòrè, bí wọ́n ò tiẹ̀ sí nítòsí ara wọn.
Àmọ́, àwọn tọkọtaya kan máa ń lo ẹ̀rọ ìgbàlódé lọ́nà tí kò dáa, ìyẹn sì ti mú kí wọ́n . . .
-
má ṣe ráyè fún ara wọn mọ́.
-
máa gbé iṣẹ́ wálé láìjẹ́ pé ó pọn dandan.
-
máa fura sí ara wọn, kí wọ́n má sì fọkàn tán ara wọn mọ́.
OHUN TÓ YẸ KÓ O MỌ̀
ÀKÓKÒ TẸ́ Ẹ FI WÀ PA PỌ̀
Ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Michael sọ pé: “Nígbà míì témi àtìyàwó mi bá wà pa pọ̀, kì í ráyè tèmi rárá, torí fóònù ló kàn máa ń tẹ̀ ní tiẹ̀, á sì máa sọ pé, ‘Mi ò tíì ráyè wo fóònù yìí látàárọ̀.’ ” Lórí ọ̀rọ̀ yìí, baálé ilé kan tó ń jẹ́ Jonathan sọ pé: “Ọkọ àtìyàwó lè máa gbé pọ̀ lóòótọ́, àmọ́ ó lè dà bíi pé ìlú ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni wọ́n ń gbé.”
RÒ Ó WÒ NÁ: Ṣé ọ̀pọ̀ ìgbà ni àwọn ọ̀rọ̀ àti ìpè tó ń wọlé sórí fóònù ẹ kì í jẹ́ kó o ráyè gbọ́ ti ọkọ tàbí ìyàwó ẹ?—ÉFÉSÙ 5:33.
IṢẸ́
Iṣẹ́ àwọn kan máa ń gba pé kí wọ́n máa gba ìpè àti lẹ́tà lórí fóònù wọn lóòrèkóòrè, kódà lẹ́yìn tí wọ́n ti kúrò níbiṣẹ́. Àmọ́, ó ṣì ṣòro fáwọn kan tí iṣẹ́ wọn ò le tó bẹ́ẹ̀ láti jẹ́ kọ́rọ̀ iṣẹ́ wọn mọ síbi iṣẹ́. Ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Lee sọ pé: “Nígbà tí mo bá wà pẹ̀lú ìyàwó mi, ó ti mọ́ mi lára kí n máa wo gbogbo ọ̀rọ̀ àti lẹ́tà tó ń wọlé sórí fóònù mi láti ibiṣẹ́.” Ìyàwó ilé kan tó ń jẹ́ Joy sọ pé: “Àtilé ni mo ti ń ṣiṣẹ́, torí náà, ó máa ń ṣòro fún mi láti ṣíwọ́ lásìkò. Téèyàn ò bá ṣọ́ra, kò ní ráyè fún ẹnì kejì ẹ̀.”
RÒ Ó WÒ NÁ: Ṣé o máa ń tẹ́tí sílẹ̀ dáadáa tí ọkọ tàbí ìyàwó ẹ bá ń bá ẹ sọ̀rọ̀?—LÚÙKÙ 8:18.
JẸ́ OLÓÒÓTỌ́
Ìwádìí kan fi hàn pé àwọn kan máa ń fura sí ohun tí ẹnì kejì wọn ń ṣe lórí ìkànnì àjọlò, ìyẹn sì máa ń dá ìjà sílẹ̀ láàárín wọn lọ́pọ̀ ìgbà. Àwọn kan jẹ́wọ́ pé àwọn kì í jẹ́ kẹ́nì kejì àwọn róhun táwọn ń gbé sórí ìkànnì.
Ọ̀pọ̀ èèyàn gbà pé ewu púpọ̀ ló wà lórí ìkànnì àjọlò, ó sì lè mú káwọn tọkọtaya tètè ṣe ìṣekúṣe. Abájọ táwọn agbẹjọ́rò tó ń rí sọ́rọ̀ ìkọ̀sílẹ̀ fi sọ pé wàhálà tí ìkannì àjọlò ń dá sílẹ̀ láàárín àwọn tọkọtaya kì í ṣe kékeré, ìyẹn ló sì fà á tí ọ̀pọ̀ àwọn tọkọtaya fi ń kọ ara wọn sílẹ̀ lóde òní.
RÒ Ó WÒ NÁ: Ṣó o máa ń fàwọn ọ̀rọ̀ tó o fi ń ránṣẹ́ sẹ́ni tí kì í ṣe ọkọ tàbí aya ẹ pa mọ́, kí ẹnì kejì ẹ má bàa rí i?—ÒWE 4:23.
OHUN TÓ O LÈ ṢE
FI OHUN TÓ ṢE PÀTÀKÌ JÙ SÍPÒ ÀKỌ́KỌ́
Tẹ́nì kan bá wà tí kì í fi bẹ́ẹ̀ jẹun, ara onítọ̀hún ò ní le dáadáa. Bọ́rọ̀ tọkọtaya ṣe rí náà nìyẹn, tí wọn ò bá wáyè láti máa gbọ́ ti ara wọn, wọ́n máa níṣòro.—Éfésù 5:28, 29.
ÌLÀNÀ BÍBÉLÌ: “Máa wádìí dájú àwọn ohun tó ṣe pàtàkì jù.”—FÍLÍPÌ 1:10.
Kí ẹ̀yin ọkọ àti aya jọ jíròrò àwọn tó yẹ kẹ́ ẹ ṣe nínú àwọn àbá yìí tàbí kẹ́ ẹ kọ èyí tẹ́yin fúnra yín ronú kàn, tí kò ní jẹ́ kí ẹ̀rọ ìgbàlódé ba àárín yín jẹ́.
-
A fẹ́ jọ máa jẹun pọ̀, ó kéré tán ẹ̀ẹ̀kan lójúmọ́
-
A fẹ́ ya àwọn àsìkò kan sọ́tọ̀ tá a máa fi wà pa pọ̀, tá ò sì ní lo fóònù tàbí kọ̀ǹpútà wa
-
A fẹ́ ṣètò àwọn ọjọ́ kan táwa méjèèjì á jọ máa jáde láti gbádùn ara wa
-
A ò ní máa fi fóònù wa sí tòsí tá a bá ti fẹ́ sùn lálẹ́
-
A fẹ́ máa pa fóònù tàbí kọ̀ǹpútà wa fún ìṣẹ́jú mẹ́ẹ̀ẹ́dógún (15) lójúmọ́, ká lè bára wa sọ̀rọ̀ láìsí ìdíwọ́
-
A fẹ́ yan àkókò kan lójúmọ́ tá ò ni máa tan Íńtánẹ́ẹ̀tì wa