Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwọn Nǹkan Táwọn Onímọ̀ Sáyẹ́ǹsì Ò Lè Ṣàlàyé

Àwọn Nǹkan Táwọn Onímọ̀ Sáyẹ́ǹsì Ò Lè Ṣàlàyé

Ọ̀pọ̀ ìwádìí làwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ti ṣe nípa ayé àtàwọn nǹkan tó wà nínú ẹ̀. Síbẹ̀, ọ̀pọ̀ ìbéèrè tó ṣe pàtàkì ni wọn ò lè dáhùn.

Ṣé àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì lè ṣàlàyé bí ayé àti ọ̀run ṣe bẹ̀rẹ̀? Rárá! Àwọn kan gbà pé àwọn onímọ̀ nípa àgbáyé lè ṣàlàyé bí ayé àti ọ̀run ṣe bẹ̀rẹ̀. Àmọ́, ohun tí ọ̀jọ̀gbọ́n kan tó ń jẹ́ Marcelo Gleiser tó ń ṣiṣẹ́ ní Dartmouth College sọ fi hàn pé ọ̀rọ̀ ò rí bẹ́ẹ̀. Onímọ̀ nípa àwọn nǹkan tó wà lójú ọ̀run ni Gleiser, ó sì gbà pé kò sí béèyàn ṣe lè mọ̀ bóyá Ọlọ́run wà tàbí kò sí. Ó ní: “Títí di báyìí, a ò tíì lè ṣàlàyé bí ayé àti ọ̀run ṣe bẹ̀rẹ̀.”

Bákan náà, nígbà tí àpilẹ̀kọ kan nínú ìwé ìròyìn Science News ń sọ̀rọ̀ lórí báwọn nǹkan alààyè ṣe dé ayé, ó sọ pé: “Kò jọ pé a máa lè ṣàlàyé kúlẹ̀kúlẹ̀ nípa báwọn nǹkan alààyè ṣe dé ayé yìí. Torí pé kò sí bá a ṣe lè rí àwọn òkúta, egungun èèyàn àti tẹranko tá a lè fi ṣèwádìí ká lè mọ bí nǹkan ṣe rí níbẹ̀rẹ̀.” Àwọn ọ̀rọ̀ tá a tọ́ka sí yìí jẹ́ ká rí i pé títí di báyìí, àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ò lè ṣàlàyé bí ayé àti ọ̀run ṣe bẹ̀rẹ̀.

Àmọ́ o lè máa rò ó pé, ‘Tí ayé yìí àtàwọn nǹkan tó wà nínú ẹ̀ ò bá ṣàdédé wà, ta ló dá wọn?’ Ó tún ṣeé ṣe kó o ti rò ó rí pé: ‘Tó bá jẹ́ pé Ẹlẹ́dàá kan wà tó jẹ́ ọlọ́gbọ́n, tó sì tún nífẹ̀ẹ́ wa, kí ló dé táwa èèyàn fi ń jìyà? Kí nìdí tí oríṣiríṣi ẹ̀sìn fi wà? Kí nìdí tí ọ̀pọ̀ àwọn tó sọ pé àwọn ń sin Ọlọ́run fi ń hùwà burúkú?’

Àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ò lè dáhùn àwọn ìbéèrè yìí. Àmọ́ ìyẹn ò túmọ̀ sí pé kò sí bó o ṣe lè mọ ìdáhùn. Kódà, ọ̀pọ̀ èèyàn ló ti jẹ́ kí Bíbélì ran àwọn lọ́wọ́ láti mọ ìdáhùn àwọn ìbéèrè náà, ohun tí wọ́n rí nínú Bíbélì sì fi wọ́n lọ́kàn balẹ̀.

Àwọn kan lára àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì gbìyànjú láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, wọ́n sì ti wá gbà pé Ẹlẹ́dàá wà. Tó o bá fẹ́ mọ ohun tó mú kí wọ́n gbà bẹ́ẹ̀, lọ sórí ìkànnì jw.org. Tẹ àkòrí náà “Èrò Àwọn Èèyàn Nípa Ìṣẹ̀dá” síbi tó o ti lè fi ọ̀rọ̀ wá nǹkan, kó o sì wo àwọn fídíò tó wà ní abala náà.