Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìdí Tó Fi Yẹ Kó O Mọ̀ Bóyá Ẹlẹ́dàá Wà

Ìdí Tó Fi Yẹ Kó O Mọ̀ Bóyá Ẹlẹ́dàá Wà

Kí nìdí tó fi yẹ kó o mọ̀ bóyá Ẹlẹ́dàá wà? Ìdí ni pé tó o bá ṣèwádìí, tó sì dá ẹ lójú pé Ọlọ́run Olódùmarè wà, ó máa wù ẹ́ láti wá àwọn ẹ̀rí táá jẹ́ kó o gbà pé òun náà ló mí sí Bíbélì. Tó o bá sì fara mọ́ ohun tí Bíbélì sọ, ó máa ṣe ẹ́ láǹfààní. Lára àwọn àǹfààní tó o máa rí níbẹ̀ nìyí.

Wàá túbọ̀ láyọ̀

OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ: “[Ọlọ́run] ń ṣe rere, ó ń rọ òjò fún yín láti ọ̀run, ó sì ń fún yín ní àwọn àsìkò tí irè oko ń jáde, ó ń fi oúnjẹ bọ́ yín, ó sì ń fi ayọ̀ kún ọkàn yín.”​—Ìṣe 14:17.

OHUN TÓ TÚMỌ̀ SÍ: Ẹ̀bùn látọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni gbogbo ohun tó wà láyé yìí. Wàá túbọ̀ mọyì àwọn ẹ̀bùn yìí tó o bá mọ̀ pé Ọlọ́run tó fún wa láwọn ẹ̀bùn náà nífẹ̀ẹ́ rẹ, ọ̀rọ̀ rẹ sì jẹ ẹ́ lógún gan-an.

Wàá rí ìmọ̀ràn tó máa jẹ́ káyé ẹ dáa

OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ: “Wàá lóye ohun tó jẹ́ òdodo àti ẹ̀tọ́ àti àìṣègbè, gbogbo ipa ọ̀nà ohun rere.”​—Òwe 2:9.

OHUN TÓ TÚMỌ̀ SÍ: Torí pé Ọlọ́run ló dá ẹ, ó mọ ohun táá jẹ́ kó o láyọ̀. Tó o bá ka Bíbélì, wàá rí ọ̀pọ̀ nǹkan tó máa ṣe ẹ́ láǹfààní káyé ẹ lè dáa.

Wàá rí ìdáhùn àwọn ìbéèrè rẹ

OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ: “Wàá . . . rí ìmọ̀ Ọlọ́run.”​—Òwe 2:5.

OHUN TÓ TÚMỌ̀ SÍ: Tó o bá gbà pé Ẹlẹ́dàá wà, ó máa rọrùn fún ẹ láti rí ìdáhùn àwọn ìbéèrè pàtàkì tó lè máa jẹ ọ́ lọ́kàn. Bí àpẹẹrẹ: Kí nìdí tá a fi wà láàyè? Kí nìdí tí ìyà fi pọ̀ tó báyìí? Kí ló ń ṣẹlẹ̀ sáwọn tó ti kú? Bíbélì máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti dáhùn àwọn ìbéèrè yìí, àwọn ìdáhùn náà á sì fi ẹ́ lọ́kàn balẹ̀.

Wàá nírètí pé ọ̀la ń bọ̀ wá dáa

OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ: “‘Mo mọ èrò tí mò ń rò nípa yín dáadáa,’ ni Jèhófà wí, ‘èrò àlàáfíà, kì í ṣe ti àjálù, láti fún yín ní ọjọ́ ọ̀la kan àti ìrètí kan.’”​—Jeremáyà 29:11.

OHUN TÓ TÚMỌ̀ SÍ: Ọlọ́run ṣèlérí pé láìpẹ́, òun máa fòpin sí ìwà ibi àti ìyà, òun á sì mú ikú kúrò. Tó bá dá ẹ lójú pé Ọlọ́run máa ṣe àwọn nǹkan rere yìí, ọkàn ẹ á balẹ̀ pé ọ̀la ń bọ̀ wá dáa, ìyẹn á sì jẹ́ kó rọrùn fún ẹ láti máa fara da àwọn ìṣòro rẹ.