Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Iṣẹ́ ribiribi ló ń lọ nínú sẹ́ẹ̀lì kọ̀ọ̀kan. Ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn sẹ́ẹ̀lì náà ló ní èròjà DNA tó ń jẹ́ kí sẹ́ẹ̀lì kọ̀ọ̀kan mọ ohun tó máa ṣe. Bákan náà, ohun kan wà nínú ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn sẹ́ẹ̀lì náà tó máa ń ṣètò bí wọ́n ṣe máa rí àwọn èròjà tó dà bí oúnjẹ fún wọn kí wọ́n má bàa kú.

Ohun Táwọn Ohun Alààyè Jẹ́ Ká Mọ̀

Ohun Táwọn Ohun Alààyè Jẹ́ Ká Mọ̀

Àwọn ohun alààyè máa ń dàgbà, wọ́n lè mú irú wọn jáde, ọ̀pọ̀ lára wọn sì lè rìn láti ibì kan sí ibòmíì. Wọ́n mú kí ayé yìí rẹwà gan-an kó sì ṣàrà ọ̀tọ̀! Ohun tá a mọ̀ nípa àwọn ohun abẹ̀mí lóde òní ju ohun táwọn tó ti gbé ayé ṣáájú wa mọ̀ lọ. Ṣé ẹnì kan ló dá àwọn ohun alààyè ni àbí wọ́n kàn ṣàdédé wà? Jẹ́ ká gbé àwọn kókó mélòó kan yẹ̀ wò.

Ẹ̀rí fi hàn pé ẹnì kan ló dá àwọn ohun alààyè. Sẹ́ẹ̀lì ló kéré jù lára ohun tó ń gbé ẹ̀mí àwọn ohun alààyè ró. Bó sì ṣe kéré tó yìí, iṣẹ́ ribiribi ló ń ṣe kó lè gbé ẹ̀mí ró, kó sì lè mú káwọn ohun alààyè mú irú wọn jáde. Kò síbi tá a yíjú sí tá ò ní rí iṣẹ́ àrà táwọn sẹ́ẹ̀lì ń ṣe. Jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ ohun tó ń mú ìyẹ̀fun wú táwọn tó ń ṣe búrẹ́dì máa ń lò. Ọ̀kọ̀ọ̀kan sẹ́ẹ̀lì tó wà nínú ẹ̀ kéré gan-an ni, bẹ́ẹ̀ sì rèé ẹ̀dá abẹ̀mí ni wọ́n. Tá a bá fi sẹ́ẹ̀lì tó wà nínú ohun tó ń mú ìyẹ̀fun wú yìí wéra pẹ̀lú sẹ́ẹ̀lì ara àwa èèyàn, ó lè dà bí ohun tí kò jọjú rárá. Àmọ́, iṣẹ́ ribiribi ló ń lọ nínú ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn. Ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn sẹ́ẹ̀lì náà ló ní èròjà DNA tó ń jẹ́ kí sẹ́ẹ̀lì kọ̀ọ̀kan mọ ohun tó máa ṣe. Bákan náà, ohun kan wà nínú ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn sẹ́ẹ̀lì náà tó máa ń ṣètò bí wọ́n ṣe máa rí àwọn èròjà tó dà bí oúnjẹ fún wọn kí wọ́n má bàa kú. Tí kò bá sí oúnjẹ tí sẹ́ẹ̀lì kan máa jẹ mọ́, á dáwọ́ iṣẹ́ dúró, á sì dà bíi pé ó ń sùn. Ìdí nìyẹn tó fi jẹ́ pé èèyàn lè tọ́jú ohun tó ń mú ìyẹ̀fun wú pa mọ́ fún ìgbà pípẹ́, ó sì máa sọ jí pa dà téèyàn bá pò ó mọ́ ìyẹ̀fun láti fi ṣe búrẹ́dì tàbí nǹkan míì.

Ọ̀pọ̀ ọdún làwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ti ń ṣèwádìí nípa sẹ́ẹ̀lì inú ohun tó ń mú ìyẹ̀fun wú, kí wọ́n lè túbọ̀ lóye bí sẹ́ẹ̀lì inú ara èèyàn ṣe ń ṣiṣẹ́. Síbẹ̀, ọ̀pọ̀ nǹkan ni kò tíì yé wọn nípa ẹ̀. Ọ̀jọ̀gbọ́n kan tó ń jẹ́ Ross King, tó jẹ́ onímọ̀ ẹ̀rọ níléèwé gíga Chalmers University of Technology, lórílẹ̀-èdè Sweden sọ pé: “Ó dunni gan-an pé kò sáwọn onímọ̀ nípa ohun alààyè tó pọ̀ tó tí wọ́n lè bá wa ṣe gbogbo ìwádìí tó yẹ nípa ohun tó ń mú ìyẹ̀fun wú. Bẹ́ẹ̀ sì rèé, ṣe ni èròjà yẹn dà bí ohun tí ò tó nǹkan tá a bá fi wé àwọn ohun abẹ̀mí míì tó wà láyé.”

Tó o bá ronú nípa ohun àrà tó wà nínú ohun tó ń mú ìyẹ̀fun wú tó dà bíi pé kò tó nǹkan, ṣé o rò pé ó kàn ṣèèṣì rí bẹ́ẹ̀ ni, àbí ẹnì kan ló dìídì ṣètò ẹ̀?

Ohun alààyè nìkan ló lè mú ohun alààyè bíi tiẹ̀ jáde. Èròjà DNA ló ń pinnu bí ohun alààyè kọ̀ọ̀kan ṣe máa rí. Àwọn èròjà tó para pọ̀ di DNA tó wà nínú ọ̀kọ̀ọ̀kan sẹ́ẹ̀lì ara èèyàn jẹ́ bílíọ̀nù mẹ́ta àti mílíọ̀nù méjì. Àwọn èròjà yìí ló máa ń ṣiṣẹ́ pọ̀ lọ́nà tó ṣe rẹ́gí láti mú kí nǹkan máa lọ bó ṣe yẹ lára àwọn ohun abẹ̀mí.

Àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì sọ pé kódà táwọn èròjà tó para pọ̀ di DNA yìí bá ṣèèṣì dà pọ̀ ní àìmọye mílíọ̀nù ọ̀nà, bóyá la lè rí ìgbà kan ṣoṣo tí wọ́n á mú èròjà DNA jáde fúnra wọn. Ohun tí èyí ń sọ fún wa ni pé kò sí bí èròjà DNA ṣe lè dá nìkan ṣètò ara ẹ̀, ó ní láti jẹ́ pé ẹnì kan ló fara balẹ̀ ṣètò ẹ̀.

Òótọ́ ibẹ̀ ni pé kò tíì ṣẹlẹ̀ rí pé káwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì mú ohun abẹ̀mí jáde látinú ohun tí kì í ṣe ohun abẹ̀mí.

Àwa èèyàn ṣàrà ọ̀tọ̀ gan-an. Ọ̀pọ̀ nǹkan làwa èèyàn lè ṣe tó ń jẹ́ ká gbádùn ayé wa dáadáa, bẹ́ẹ̀ sì rèé kò sóhun alààyè míì tó ń gbádùn àwọn nǹkan yìí bíi tàwa èèyàn. Bí àpẹẹrẹ, a lè ya oríṣiríṣi àwòrán tó jọni lójú gan-an, a lè kẹ́gbẹ́ pẹ̀lú ara wa ká sì bára wa sọ̀rọ̀ tó nítumọ̀, ọ̀nà tá a sì ń gbà fi bí nǹkan ṣe rí lára wa hàn yàtọ̀ pátápátá sí tàwọn ohun abẹ̀mí tó kù. Bákan náà, a mọ oríṣiríṣi adùn, òórùn, ìró àti àwọ̀, a sì tún lè fi ojú wa rí oríṣiríṣi nǹkan. A máa ń ṣètò bá a ṣe fẹ́ kí ọjọ́ ọ̀la wa rí, a sì máa ń fẹ́ mọ ohun tó lè mú kí ayé wa dáa.

Kí lèrò tìẹ? Ṣé torí káwa èèyàn má bàa kú ká sì lè máa bímọ la ṣe lè ṣàwọn nǹkan yìí ni? Àbí ńṣe ló ń fi hàn pé ẹ̀bùn látọ̀dọ̀ Ẹlẹ́dàá wa tó nífẹ̀ẹ́ wa làwọn nǹkan yìí jẹ́?