Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ohun Tí Ayé Àtàwọn Nǹkan Tó Wà Lójú Ọ̀run Jẹ́ Ká Mọ̀

Ohun Tí Ayé Àtàwọn Nǹkan Tó Wà Lójú Ọ̀run Jẹ́ Ká Mọ̀

Ìyanu gbáà làwọn ohun tó wà lójú ọ̀run máa ń jẹ́ fáwọn onímọ̀ nípa sánmà. Kódà, wọ́n ṣì ń ṣe àwọn irinṣẹ́ tuntun tí wọ́n lè fi kẹ́kọ̀ọ́ sí i nípa àwọn ohun tó wà lójú ọ̀run. Kí làwọn nǹkan tí wọ́n kíyè sí?

Àwọn ohun tó wà lójú ọ̀run wà létòlétò. Ìwé kan tó sọ̀rọ̀ nípa àwọn ìràwọ̀, ìyẹn Astronomy sọ pé: “Kì í ṣe pé àwọn ìràwọ̀ kàn rí gátagàta lójú ọ̀run, àmọ́ ńṣe ni wọ́n wà létòlétò.” Kí ló mú kó rí bẹ́ẹ̀? Àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì gbà pé “ohun kan tí kò ṣeé fojú rí ló gbé àwọn ìṣùpọ̀ ìràwọ̀ dúró, tó sì mú kí wọ́n wà létòlétò.”

Ṣé báwọn ohun tó wà lójú ọ̀run ṣe wà létòlétò yẹn kàn ṣàdédé rí bẹ́ẹ̀ ni? Irú nǹkan bẹ́ẹ̀ ò lè ṣẹlẹ̀ nípa èèṣì, ó ní láti jẹ́ pé ẹnì kan ló ṣètò ẹ̀. Ọ̀gbẹ́ni kan tó ń jẹ́ Allan Sandage sọ ohun kan lórí ọ̀rọ̀ yìí. Onímọ̀ nípa ojú sánmà ni, ó sì gba Ọlọ́run gbọ́. Ó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn onímọ̀ nípa ojú sánmà tó lókìkí jù lọ nígbà ayé ẹ̀.

Ó sọ pé: “Kò bọ́gbọ́n mu láti sọ pé ńṣe nirú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀ ṣàdédé wà létòlétò. Ó ní láti jẹ́ pé nǹkan kan ló wà nídìí ẹ̀.”

Àwọn ohun tó wà lójú ọ̀run ń gbé ẹ̀mí wa ró. Jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ oòrùn. Ńṣe ni oòrùn máa ń ràn ní ìwọ̀n tó yẹ, kò pọ̀ jù kò sì ṣàìtó. Ká ní agbára tó ń díwọ̀n oòrùn fi díẹ̀ dín kù ni, oòrùn ò tiẹ̀ ní yọ rárá. Tó bá sì jẹ́ pé ńṣe ni agbára tó ń díwọ̀n oòrùn fi díẹ̀ pọ̀ sí i, oòrùn á ti jó tán tipẹ́tipẹ́.

Gbogbo ohun tó wà lójú ọ̀run pátá ló ní ìlànà pàtó tó ń darí wọn. Tí kì í bá ṣe bẹ́ẹ̀ ni, kò ní sóhun alààyè kankan láyé. Onímọ̀ sáyẹ́ǹsì àti òǹkọ̀wé kan tórúkọ ẹ̀ ń jẹ́ Anil Ananthaswamy sọ pé kódà tó bá jẹ́ pé ọ̀kan péré lára àwọn ohun tó wà lójú ọ̀run ni kò tẹ̀ lé ìlànà pàtó tó yẹ kó tẹ̀ lé, “kò ní sóhun tó ń jẹ́ ìràwọ̀, àwọn pílánẹ́ẹ̀tì tàbí àwọn ìṣùpọ̀ ìràwọ̀. Kò tiẹ̀ ní sóhun alààyè kankan láyé.”

Ayé yìí ni ibì kan ṣoṣo tó ṣeé gbé fún àwa èèyàn. Ayé yìí nìkan nibi tó tura táwa èèyàn lè gbé, ìwọ̀n omi tó yẹ ló wà láyé, òṣùpá ò tóbi jù bẹ́ẹ̀ ni kò kéré jù, ìyẹn ni kò sì jẹ́ kí ayé yìí yẹ̀ kúrò lápá ibi tó dagun sí. Ìwé kan tó ń jẹ́ National Geographic sọ pé: “Bí ayé yìí ṣe rí àtàwọn ohun alààyè tó wà nínú ẹ̀ jẹ́ kó hàn gbangba pé ayé yìí gangan nibi tó yẹ àwa èèyàn láti gbé.” a

Òǹkọ̀wé kan sọ pé “ibi tí oòrùn wà jìnnà gan-an sáwọn ìràwọ̀ tó kù.” Bó sì ṣe jìnnà sí wọn yẹn ló mú káyé yìí jẹ́ ibi tó ṣeé gbé. Tó bá jẹ́ pé ibi tí oòrùn wà sún mọ́ àwọn ìràwọ̀ tó kù ni, bóyá láàárín wọn gangan tàbí nítòsí wọn, ooru tó ń jáde látara ẹ̀ ò ní jẹ́ kóhun alààyè kankan wà láyé. Àmọ́, ó gbàfiyèsí pé apá ibi tí ohun abẹ̀mí lè gbé ni ayé wà.

Nígbà tí onímọ̀ físíìsì kan tó ń jẹ́ Paul Davies ń sọ̀rọ̀ nípa ayé àtàwọn ohun tó wà nínú ẹ̀, ó ní: “Ní tèmi o, mi ò gbà pé nípa èèṣì làwa èèyàn fi wà láyé yìí. . . . Ibi tó yẹ wá gangan la wà yìí.” Lóòótọ́, ọkùnrin yìí ò sọ pé Ọlọ́run ló dá ayé àtàwa èèyàn, àmọ́ kí lèrò tìẹ? Tó bá jẹ́ pé bí ayé àtàwọn ohun tó wà lójú ọ̀run ṣe rí ló mú káwọn ohun abẹ̀mí lè gbé ayé, ṣé kò bọ́gbọ́n mu láti gbà pé ẹnì kan ló dìídì ṣètò wọn lọ́nà yẹn?

a Ìwé National Geographic yìí ò sọ pé Ọlọ́run ló dá ayé àtàwa èèyàn o. Kàkà bẹ́ẹ̀, ohun tó kàn ń sọ ni pé ayé yìí gangan ni ibi tó dáa jù lọ fáwa èèyàn láti gbé.