Ṣé Ẹlẹ́dàá Wà Lóòótọ́?
Ìwé yìí sọ̀rọ̀ nípa àwọn ẹ̀rí pàtàkì tó fi hàn gbangba pé ẹnì kan ló dá ayé àtàwọn ohun tó wà lójú ọ̀run. A rọ̀ ẹ́ pé kó o ṣàyẹ̀wò àwọn ẹ̀rí náà fúnra ẹ, kó o lè mọ̀ bóyá Ẹlẹ́dàá wà lóòótọ́ àbí kò sí. Gbìyànjú kó o wo àwọn fídíò tó wà nísàlẹ̀ yìí kó o sì ka àwọn ìwé tó wà níbẹ̀, ó dájú pé ó máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ púpọ̀. Wá àkòrí fídíò àtàwọn ìwé náà lórí jw.org:
Kí ló mú kí ọ̀pọ̀ lára àwọn tó kàwé dáadáa gbà gbọ́ pé Ẹlẹ́dàá wà lóòótọ́?
Wo àwọn fídíò ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò tó wà ní abala tá a pè ní “Èrò Àwọn Èèyàn Nípa Ìṣẹ̀dá.”
Ṣé òótọ́ lohun táwọn ẹlẹ́kọ̀ọ́ ẹfolúṣọ̀n ń kọ́ni?
Ka ìwé náà Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé! Ẹ̀kọ́ 06, àkòrí ẹ̀ ni “Ṣé Ayé àti Ọ̀run Ní Ìbẹ̀rẹ̀?”
Ṣó bọ́gbọ́n mu kéèyàn gbà pé Ẹlẹ́dàá wà lóòótọ́?
Wo fídíò náà Ohun Táwọn Ojúgbà Rẹ Sọ—Ọlọ́run Wà Lóòótọ́.
Ṣó bọ́gbọ́n mu kéèyàn gba ohun tí Bíbélì sọ gbọ́?
Ka ìwé náà Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé! Ẹ̀kọ́ 03, àkòrí ẹ̀ ni “Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Kó O Gbára Lé Bíbélì?”