Kí Lèrò Tìẹ?
“Kò pọn dandan kẹ́nì kan dá àwọn nǹkan tó wà lójú ọ̀run, ayé àtàwọn ohun tó wà nínú ẹ̀, wọn ò kọjá ohun tó lè ṣàdédé wà.”—Stephen Hawking àti Leonard Mlodinow, onímọ̀ físíìsì, 2010.
“Ọlọ́run dá ọ̀run àti ayé.”—Bíbélì, Jẹ́nẹ́sísì 1:1.
Ṣé Ọlọ́run ló dá ayé àtàwọn ohun tó wà nínú ẹ̀ àbí wọ́n kàn ṣàdédé wà ni? Ọ̀rọ̀ táwọn méjì tó jẹ́ onímọ̀ físíìsì yìí sọ àtohun tí Bíbélì sọ nípa bí ayé àtàwọn ohun tó wà nínú ẹ̀ ṣe bẹ̀rẹ̀ yàtọ̀ síra pátápátá. Àwọn kan wà tó jẹ́ pé ohun táwọn onímọ̀ físíìsì yẹn sọ ni wọ́n fara mọ́, bẹ́ẹ̀ sì làwọn kan wà tó jẹ́ pé ohun tí Bíbélì sọ lórí ọ̀rọ̀ yìí ni wọ́n fara mọ́. Àmọ́ àwọn míì tún wà tí wọn ò tiẹ̀ mọ èyí tí wọn ì bá fara mọ́ nínú méjèèjì. Àwọn èèyàn ti ṣe ọ̀pọ̀ ètò orí tẹlifíṣọ̀n, wọ́n sì ti kọ oríṣiríṣi ìwé láti fi ṣe àríyànjiyàn lórí ọ̀rọ̀ yìí.
Ó ṣeé ṣe káwọn olùkọ́ ẹ níléèwé ti fi ìdánilójú sọ fún ẹ pé ńṣe ni ayé àtàwọn ohun tó wà nínú ẹ̀ ṣàdédé wà, pé kì í ṣe Ẹlẹ́dàá kan ló dá wọn. Àmọ́, ṣáwọn olùkọ́ ẹ fẹ̀rí tó dájú hàn ẹ́ pé kò sí Ẹlẹ́dàá? Bákan náà, ó ṣeé ṣe kó o ti máa gbọ́ táwọn olórí ẹ̀sìn ń wàásù pé Ẹlẹ́dàá wà. Àmọ́, ṣé wọ́n fẹ̀rí tó dájú hàn pé Ẹlẹ́dàá wà lóòótọ́? Àbí ńṣe ni wọ́n kàn sọ fún ẹ pé kó o ṣáà gbà gbọ́ pé Ọlọ́run wà?
Ó ṣeé ṣe kíwọ náà ti ronú nípa ìbéèrè yìí, kó o sì máa sọ lọ́kàn ẹ pé kò sẹ́ni tó kúkú mọ̀ bóyá Ẹlẹ́dàá kan wà níbì kan àbí kò sí. Ìyẹn lè wá mú kó o máa ronú pé: Ṣó tiẹ̀ ṣe pàtàkì pé kéèyàn mọ̀ bóyá Ẹlẹ́dàá wà àbí kò sí?
Nínú ìwé yìí, a máa kọ́kọ́ sọ̀rọ̀ nípa àwọn nǹkan táwọn kan rí tó mú kó dá wọn lójú gbangba pé Ẹlẹ́dàá wà lóòótọ́. Lẹ́yìn náà, a máa sọ̀rọ̀ nípa ìdí tó fi ṣe pàtàkì gan-an pé ká mọ bí ayé àtàwọn ohun tó wà nínú ẹ̀ ṣe bẹ̀rẹ̀.