ÌRÀNLỌ́WỌ́ FÚN ÌDÍLÉ | ÌGBÉYÀWÓ
Nígbà Tí Àwọn Ọmọ Bá Ti Kúrò Nílé
OHUN TÓ JẸ́ ÌṢÒRO
Kì í rọrùn rárá fún àwọn òbí nígbà tí àwọn ọmọ bá ti dàgbà tí wọ́n sì ti wà láyè ara wọn. Tó bá ti di pé gbogbo àwọn ọmọ ti kúrò nílé báyìí, ńṣe ni àwọn òbí máa ń dà bí àjèjì sí ara wọn. Ọ̀jọ̀gbọ́n kan nípa ìdílé tó ń jẹ́ M. Gary Neuman sọ pé: “Mo máa ń gba àwọn tọkọtaya nímọ̀ràn lórí bí wọ́n ṣe lè pa dà sún mọ́ ara wọn. Torí pé, táwọn ọmọ bá ti kúrò nílé báyìí, àjọṣe àwọn òbí kì í gún régé dáadáa mọ́.” *
Ṣé bí nǹkan ṣe rí nínú ìdílé tìrẹ nìyẹn? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, ọ̀rọ̀ rẹ kò tíì kọjá àtúnṣe. Jẹ́ ká kọ̀kọ̀ sọ̀rọ̀ nípa àwọn nǹkan tó ṣeé ṣe kó fà á tí àárín ìwọ àti ọkọ tàbí aya rẹ kò fi gún régé dáadáa mọ́.
ÌDÍ TÓ FI MÁA Ń ṢẸLẸ̀
Àwọn ọmọ lẹ ti ń fún láfiyèsí jù lọ láti ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn. Ọ̀pọ̀ òbí ló jẹ́ pé ọ̀rọ̀ ọmọ títọ́ nìkan ni wọ́n gbájú mọ́ débi pé wọn ò ráyè ti ìgbéyàwó wọn. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ohun tó dáa ni wọ́n ní lọ́kàn tí wọ́n fi ń ṣe bẹ́ẹ̀, síbẹ̀ ohun tí èyí máa ń yọrí sí ni pé, ojúṣe wọn gẹ́gẹ́ bíi bàbá tàbí ìyá nìkan ni wọ́n máa ń gbájú mọ́, wọ́n á sì pa ojúṣe wọn gẹ́gẹ́ bí ọkọ àti aya tì sẹ́gbẹ̀ẹ́ kan. Ìgbà tí àwọ́n ọmọ bá wá kúrò nílé tán ni àṣírí máa ń tú. Ìyàwó ilé kan tó jẹ́ ẹni ọdún mọ́kàndínlọ́gọ́ta [59] sọ pé: “Nígbà táwọn ọmọ ṣì wà nílé, èmi àti ọkọ mi jọ máa ń ṣe nǹkan ni. Àmọ́, lẹ́yìn tí àwọn ọmọ ti kúrò nílé tán, ńṣe ni kálukú wá ń dá ṣe tiẹ̀.” Ìgbà kan tiẹ̀ wà tó sọ fún ọkọ ẹ̀ pé: “Mi ò rò pé ọ̀rọ̀ wa lè wọ̀ mọ́ rárá.”
Àwọn tọkọtaya kan kò múra sílẹ̀ rárá fún àyípadà tuntun yìí. Ìwé kan tó ń jẹ́ Empty Nesting sọ pé: “Ọ̀pọ̀ àwọn tọkọtaya ló jẹ́ pé ńṣe ló dà bíi pé wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í gbé pọ̀ ni.” Nígbà táwọn tọkọtaya kan rí i pé ọ̀rọ̀ àwọn ò tiẹ̀ wá jọra mọ́ rárá, ọ̀rọ̀ náà kúkú wá di kóńkó-jabele, kálukú ń dá ṣe tiẹ̀. Wọ́n á wá dà bí alájọgbé lásán.
Àmọ́ ọ̀rọ̀ náà kò tíì kọjá àtúnṣe. O lè borí àwọn ìṣòro yìí, tí wàá sì gbádùn ìgbé ayé ọ̀tun yìí. Jẹ́ ká wo bí Bíbélì ṣe lè ràn wá lọ́wọ́.
OHUN TÓ O LÈ ṢE
Fara mọ́ àyípadà tó dé yìí. Ohun tí Bíbélì sọ nípa àwọn ọmọ tó ti dàgbà ni pé: ‘Ọkùnrin yóò fi baba rẹ̀ àti ìyá rẹ̀ sílẹ̀.’ (Jẹ́nẹ́sísì 2:24) Iṣẹ́ rẹ gẹ́gẹ́ bí òbí ni pé kó o tọ́ ọmọ rẹ, kó o sì kọ́ ọ láwọn ẹ̀kọ́ pàtàkì tó máa jẹ́ kó lè ṣe ojúṣe rẹ̀ bó ṣe tọ́ tó bá dàgbà. Tó o bá fojú ìyẹn wò ó, wàá rí i pé ohun àmúyangàn ló jẹ́ fún ẹ pé ọmọ rẹ ti dàgbà tó ẹni tó ń kúrò nílé.—Ìlànà Bíbélì: Máàkù 10:7.
Síbẹ̀ náà, ìwọ ṣì ni òbí ọmọ rẹ lọ́jọ́kọ́jọ́. Àmọ́ níbi tọ́rọ̀ dé yìí, kò dìgbà tó o bá mọ bí gbogbo nǹkan ṣe ń lọ fún wọn kó o tó lè máa ṣe ojúṣe rẹ, àmọ́ wọ́n lè máa gba ìmọ̀ràn lọ́dọ̀ rẹ. Àyípadà tó dé yìí á ṣì jẹ́ kó o ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ, lẹ́sẹ̀ kan náà, wàá ráyè tó pọ̀ dáadáa fún ẹnì kejì rẹ, ìyẹn sì ló ṣe pàtàkì jù. *—Ìlànà Bíbélì: Mátíù 19:6.
Ẹ sọ bí ọ̀rọ̀ ṣe rí lára yín. Bá ẹnì kejì rẹ sọ̀rọ̀ nípa bí àyípadà yìí ṣe rí lára rẹ, kí ìwọ náà sì fara balẹ̀ gbọ́ ohun tó bá sọ. Ẹ ní sùúrù fún ara yín, kẹ́ ẹ sì máa gba ti ara yín rò. Ó lè gba àkókò díẹ̀ kẹ́ ẹ tó lè pa dà sún mọ́ ara yín dáadáa, àmọ́ inú yín máa dùn gan-an tẹ́ ẹ bá ṣe bẹ́ẹ̀.—Ìlànà Bíbélì: 1 Kọ́ríńtì 13:4.
Ẹ wá àwọn nǹkan tuntun tẹ́ ẹ lè jọ máa ṣe. Ẹ jọ máa sọ̀rọ̀ nípa àwọn nǹkan tẹ́ ẹ lè jọ ṣe pa pọ̀. Ohun tó mú kẹ́ ẹ lè tọ́ àwọn ọmọ yanjú, a jẹ́ pé ọlọgbọ́n èèyàn ni yín. Ẹ ò ṣe máa lo ọgbọ́n yẹn láti ran àwọn míì lọ́wọ́?—Ìlànà Bíbélì: Jóòbù 12:12.
Ẹ jẹ́ kí ìfẹ́ yín lágbára sí i. Ẹ ronú nípa àwọn ìwà rere tó fa ẹ̀yin méjèèjì sún mọ́ra yín. Ẹ ronú nípa àwọn nǹkan tójú yín ti rí gẹ́gẹ́ bíi tọkọtaya àti bẹ́ ẹ ṣe borí àwọn ìṣòro náà. Ní báyìí tó ti wá ku ẹ̀yin méjèèjì, ibi ire náà ni ọ̀rọ̀ yín máa pa dà já sí. Kódà, tẹ́ ẹ bá fọwọ́ sowọ́ pọ̀, ẹ lè lo àǹfààní yìí láti mú kí ìgbéyàwó yín sunwọ̀n sí i, kí iná ìfẹ́ yín sì máa jó lala bíi ti ìgbà tẹ́ ẹ ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀.
^ ìpínrọ̀ 4 Láti inú ìwé náà Emotional Infidelity.
^ ìpínrọ̀ 12 Tó o bá ṣì ń tọ́ ọmọ lọ́wọ́, má gbàgbé pé “ara kan” ni ìwọ àti ẹnì kejì rẹ. (Máàkù 10:8) Ọkàn àwọn ọmọ máa ń balẹ̀ gan-an tí wọ́n bá rí i pé àárín àwọn òbí wọn gún dáadáa.