Ta Ló Ṣiṣẹ́ Àrà Yìí?
Ohun Àrà Kan Nípa Ìṣáwùrú Òkun
ÀWỌN ìṣáwùrú òkun máa ń lẹ̀ mọ́ ara àpáta, pákó tàbí ọkọ̀ ojú omi. Wọ́n ní fọ́nrán okùn wẹ́rẹ́-wẹ́rẹ́ kan tí wọ́n ń pè ní byssus, tó máa ń jẹ́ kí wọ́n lè mì dirọ-dirọ tí wọ́n bá ti lẹ̀ mọ́ nǹkan. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ńṣe ni wọ́n ń lo ọ̀nà yìí láti rìn kí wọ́n sì jẹun lára ohun tí wọ́n lẹ̀ mọ́, ó máa ń yani lẹ́nu pé àwọn fọ́nrán okùn tín-ín-rín yìí lágbára débi pé ìgbì òkun kò lè ṣàn-án kúrò lára ohunkóhun tó bá lẹ̀ mọ́. Báwo ni okùn tínrín-tínrín yìí ṣe ń jẹ́ kí ìṣáwùrú lẹ̀ mọ́ nǹkan tí omi òkun kò fi lè gbé e lọ?
Rò ó wò ná: Ìwádìí fi hàn pé àwọn fọ́nrán okùn ara ìṣáwùrú rí fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ lójú àmọ́ ó le dáadáa nínú. Ìdí nìyẹn tó fi lágbára láti lẹ̀ mọ́ ara nǹkan pẹ́kípẹ́kí. Torí náà, kò sí bí ìgbì òkun ṣe lè bì í síwá-sẹ́yìn tó, digbí ni ìṣáwùrú yìí máa ń wà.
Ọ̀jọ̀gbọ́n kan tó ń jẹ́ Guy Genin sọ pé ohun táwọn olùwádìí ṣàwárí nípa ìṣáwùrú yìí yani lẹ́nu. Ó ní: “Bí apá tó rọ̀ àti apá tó le nínú fọ́nrán okùn ara ìṣáwùrú yìí ṣe ń ṣiṣẹ́ pọ̀ jẹ́ ohun àràmàǹdà.” Àmọ́ àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì gbà pé, àwọn lè wo fọ́nrán okùn ara ìṣáwùrú láti ṣe ohun tó ṣe é fi lẹ nǹkan mọ́ ara ilé, abẹ́ ọkọ̀ ojú omi, egungun àti ojú ibi tí wọ́n ti ṣiṣẹ́ abẹ. Lórí ọ̀rọ̀ yìí, ọ̀jọ̀gbọ́n Herbert Waite tó wà ní University of California ní Santa Barbara, lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà sọ pé: “Ọ̀pọ̀ nǹkan àrà ló kún ilẹ̀ ayé tá a lè kẹ́kọ̀ọ́ lára wọn bíi ti ìṣáwùrú inú òkun.”
Kí lèrò rẹ? Ṣé àwọn fọ́nrán okùn ara ìṣáwùrú kàn ṣàdédé wà bẹ́ẹ̀ ni àbí ẹni kan ló ṣiṣẹ́ àrà yìí?