KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ | ṢÉ AYÉ YÌÍ TI BÀ JẸ́ KỌJÁ ÀTÚNṢE?
Ṣé Ayé Yìí Ti Bà Jẹ́ Kọjá Àtúnṣe?—Kí ni Bíbélì Sọ?
ỌGỌ́RỌ̀Ọ̀RÚN ọdún sẹ́yìn ni Bíbélì ti sọ pé ayé yìí máa bà jẹ́ gan-an. Ìyẹn nìkan kọ́ o, Bíbélì tún sọ pé ayé yìí ṣì máa dára gan-an tí gbogbo èèyàn á sì máa gbádùn. Kò yẹ kí èèyàn rò pé àlá tí kò lè ṣẹ ni àwọn nǹkan tí Bíbélì sọ, torí pé ọ̀pọ̀ lára nǹkan tí Bíbélì sọ ló ti ń ṣẹlẹ̀ lọ́nà tó kàmàmà lákòókò tá a wà yìí.
Bí àpẹẹrẹ, ẹ jẹ́ ká wo àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì yìí:
-
“Orílẹ̀-èdè yóò dìde sí orílẹ̀-èdè àti ìjọba sí ìjọba, àìtó oúnjẹ àti ìsẹ̀lẹ̀ yóò sì wà láti ibì kan dé ibòmíràn.”—Mátíù 24:7.
-
“Ṣùgbọ́n mọ èyí, pé ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn, àwọn àkókò lílekoko tí ó nira láti bá lò yóò wà níhìn-ín. Nítorí àwọn ènìyàn yóò jẹ́ olùfẹ́ ara wọn, olùfẹ́ owó, ajọra-ẹni-lójú, onírera, asọ̀rọ̀ òdì, aṣàìgbọràn sí òbí, aláìlọ́pẹ́, aláìdúróṣinṣin, aláìní ìfẹ́ni àdánidá, aláìṣeé bá ṣe àdéhùn kankan, afọ̀rọ̀-èké-banijẹ́, aláìní ìkóra-ẹni-níjàánu, òǹrorò, aláìní ìfẹ́ ohun rere, afinihàn, olùwarùnkì, awúfùkẹ̀ pẹ̀lú ìgbéraga, olùfẹ́ adùn dípò olùfẹ́ Ọlọ́run.”—2 Tímótì 3:1-4.
Táwọn kan bá ka àsọtẹ́lẹ̀ yìí, ohun tí wọ́n máa sọ ni pé ayé yìí ti bà jẹ́ kọjá àtúnṣe. Tá a bá wò ó dáadáa lóòótọ́, ayé ti bà jẹ́ kọjá ààlà torí pé àkóso ayé yìí kò sí lọ́wọ́ èèyàn. Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé èèyàn kò ní ọgbọ́n tàbí agbára láti fòpin sí ìṣòro ayé yìí. Òótọ́ yìí wà nínú àwọn ẹsẹ Bíbélì yìí:
-
“Ọ̀nà kan wà tí ó dúró ṣánṣán lójú ènìyàn, ṣùgbọ́n àwọn ọ̀nà ikú ni òpin rẹ̀ ní àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀.”—Òwe 14:12.
-
“Ènìyàn ti jọba lórí ènìyàn sí ìṣeléṣe rẹ̀.”—Oníwàásù 8:9.
-
“Ọ̀nà ará ayé kì í ṣe tirẹ̀ . . . láti darí àwọn ìṣísẹ̀ ara rẹ̀.”—Jeremáyà 10:23.
Tí àwọn èèyàn bá ń bá a lọ láti máa ṣe ayé yìí bó ṣe wù wọ́n, ìparun ló máa yọrí sí. Àmọ́ ìyẹn kò ní ṣẹlẹ̀ láé! Kí nìdí? Ohun tí Bíbélì sọ ni pé:
-
Ọlọ́run “fi ìpìlẹ̀ ayé sọlẹ̀ sórí àwọn ibi àfìdímúlẹ̀ rẹ̀; a kì yóò mú kí ó ta gbọ̀n-ọ́n gbọ̀n-ọ́n fún àkókò tí ó lọ kánrin, tàbí títí láé.”—Sáàmù 104:5.
-
“Ìran kan ń lọ, ìran kan sì ń bọ̀; ṣùgbọ́n ilẹ̀ ayé dúró àní fún àkókò tí ó lọ kánrin.”—Oníwàásù 1:4.
-
“Àwọn olódodo ni yóò ni ilẹ̀ ayé, wọn yóò sì máa gbé títí láé lórí rẹ̀.”—Sáàmù 37:29.
-
“Ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ ọkà yóò wá wà lórí ilẹ̀; àkúnwọ́sílẹ̀ yóò wà ní orí àwọn òkè ńlá.”—Sáàmù 72:16.
Gálátíà 6:7) Ayé yìí kò dà bí ọkọ̀ ojú irin tó ń já lọ ṣòòròṣò tó fẹ́ mórí wọgbó tí èèyàn ò sì lè dá dúró lójijì. Ó níbi tí Ọlọ́run máa fàyè gba àwọn èèyàn láti ṣèpalára fún ara wọn mọ.—Sáàmù 83:18; Hébérù 4:13.
Àwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì yìí jẹ́ ká rí ìdáhùn tó ṣe kedere. Kì í ṣe àìsàn, àìtó oúnjẹ àti omi tàbí bí àwọn èèyàn ṣè ń ba àyíká jẹ́, ló máa pa ìran èèyàn run. Ogun átọ́míìkì ò sì lè pa ayé yìí run. Kí nìdí? Ọlọ́run ló ń darí àgbáálá ayé wa yìí. Òótọ́ ni pé Ọlọ́run ti fàyè gbà á kí àwọn èèyàn ṣe ohun tó wù wọ́n, àmọ́ tí wọ́n bá ṣe ohun tí kò tọ́, wọ́n máa jìyà àbájade rẹ̀. (Ọlọ́run máa ṣe ọ̀pọ̀ nǹkan míì. Ó máa pèsè “ọ̀pọ̀ yanturu àlàáfíà.” (Sáàmù 37:11) Ohun tá a rọra mẹ́nu bà nínú àpilẹ̀kọ yìí kàn jẹ́ díẹ̀ lára àwọn nǹkan rere tó ṣì máa ṣẹlẹ̀ tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kárí ayé ti mọ̀ nípasẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.
Àwọn èèyàn lọ́kùnrin àti lóbìnrin tó wá láti àwọn ibi tó yàtọ̀ síra jákèjádò ayé ló para pọ̀ di àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo ni wọ́n ń jọ́sìn, Jèhófà sì ni orúkọ rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí Bíbélì ṣe sọ. Wọn ò bẹ̀rù ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ ọ̀la, torí Bíbélì sọ pé: “Èyí ni ohun tí Jèhófà wí, Ẹlẹ́dàá ọ̀run, Ẹni tí í ṣe Ọlọ́run tòótọ́, Aṣẹ̀dá ilẹ̀ ayé àti Olùṣẹ̀dá rẹ̀, Òun tí í ṣe Ẹni tí ó fìdí rẹ̀ múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in, ẹni tí kò wulẹ̀ dá a lásán, ẹni tí ó ṣẹ̀dá rẹ̀ àní kí a lè máa gbé inú rẹ̀: ‘Èmi ni Jèhófà, kò sì sí ẹlòmíràn.’ ”—Aísáyà 45:18.
Àpilẹ̀kọ yìí ṣàlàyé àwọn ohun tí Bíbélì sọ nípa ọjọ́ iwájú ayé yìí àtàwọn èèyàn inú rẹ̀. Tó o bá fẹ́ mọ púpọ̀ sí i, wo ẹ̀kọ́ 5 nínú ìwé Ìròyìn Ayọ̀ Látọ̀dọ̀ Ọlọ́run! Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é, ó sì wà lórí ìkànnì wa www.dan124.com/yo
O tún lè wo fídíò Kí Ni Ìdí Tí Ọlọ́run Fi Dá Ayé? Ó wà lórí ìkànnì www.dan124.com/yo. (Wo abẹ́ ÀWỌN ÌTẸ̀JÁDE > ÀWỌN FÍDÍÒ)